Ṣé Òótọ́ Ni Ábúráhámù Ní Ràkúnmí?
BÍBÉLÌ sọ pé ràkúnmí wà lára àwọn ẹran ọ̀sìn tí Ábúráhámù gbà lọ́wọ́ Fáráò. (Jẹ́n. 12:16) Nígbà tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù rin ìrìn àjò lọ sí Mesopotámíà, ó “mú ràkúnmí mẹ́wàá láti inú àwọn ràkúnmí ọ̀gá rẹ̀.” Torí náà Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn pé Ábúráhámù ní ràkúnmí.—Jẹ́n. 24:10.
Àwọn kan kò gba ohun tí Bíbélì sọ yìí gbọ́. Nínú ìwádìí kan tí a ṣe, ìwé New International Version Archaeological Study Bible, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé kò gbà pé ìtàn yìí jẹ́ òótọ́ torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò tíì sọ ràkúnmí di ẹran ọ̀sìn títí di nǹkan bí ẹgbẹ̀fà [1200] ọdún Ṣáájú Kristi, èyí tó jẹ́ àkókò gígùn lẹ́yìn ìgbà tí Ábúráhámù gbé láyé.” Torí náà, wọ́n gbà pé àṣìṣe ló jẹ́ bí Bíbélì bá mẹ́nu kan ràkúnmí ṣáájú ìgbà yẹn torí pé àwọn èèyàn ò tíì máa lo ràkúnmí lọ́nà yẹn.
Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé míì sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà [3,000] ọdún sẹ́yìn ni àwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú sísọ ràkúnmí di ẹran ọ̀sìn, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn ò tíì máa lo ràkúnmí kó tó dìgbà yẹn. Ìwé Civilizations of the Ancient Near East sọ pé: “Ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí mú ká gbà pé ó ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún lọ táwọn èèyàn ti sọ ràkúnmí di ẹran ọ̀sìn ní ìlú Arébíà tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn ayé. Àwọn èèyàn kọ́kọ́ máa ń sìn ín kí wọ́n lè lo wàrà, irun àti awọ ara rẹ̀ àti fún pípa jẹ. Àmọ́ kò lè tíì pẹ́ púpọ̀ tí wọ́n rí i pé àwọn lè máa lò ó láti kó ẹrù.” Síbẹ̀, ó dà bíi pé àwọn àfọ́kù egungun àtàwọn ohun mìíràn táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí fi hàn pé wọ́n ti ń lo ràkúnmí ṣáájú àkókò Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ.
Àwọn àkọ́sílẹ̀ míì tún wà tó jẹ́rìí sí èyí. Ìwé tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ yẹn sọ pé: “[Ràkúnmí] wà lára àwọn ẹranko tí wàláà tí wọ́n rí ní Mesopotámíà dárúkọ, ó sì tún wà nínú àwọn èdìdì mélòó kan tá a rí, èyí tó fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí ẹranko náà ti wà ní Mesopotámíà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn,” ìyẹn ní àkókò tí Ábúráhámù gbé láyé.
Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé àwọn ará Gúúsù Arébíà tó jẹ́ oníṣòwò tùràrí máa ń fi ràkúnmí kó ẹrù wọn gba aṣálẹ̀ kọjá ní apá àríwá, bí wọ́n bá ń lọ sí àwọn agbègbè bí Íjíbítì àti Síríà, wọ́n sì tipa báyìí kó ràkúnmí débẹ̀. Irú òwò yìí wọ́pọ̀ gan-an ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 37:25-28 tiẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì tí wọ́n jẹ́ oníṣòwò tí wọ́n máa ń fi ràkúnmí kó àwọn èròjà tí wọ́n fi ń ṣe tùràrí wá sí Íjíbítì ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà Ábúráhámù.
Ó ṣeé ṣe káwọn tó ń gbé nítòsí àárín gbùngbùn ìlà oòrùn ayé má tíì fi bẹ́ẹ̀ máa lo ràkúnmí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún sẹ́yìn, àmọ́ ó jọ pé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé kì í ṣe pé wọn kò rí ràkúnmí rí. Torí náà, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé: “Kò tún yẹ ká máa ka ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ràkúnmí ní ìgbà àwọn baba ńlá sí àṣìṣe mọ́ níwọ̀n bí a ti rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó látinú ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde pé ṣáájú ìgbà àwọn baba ńlá ni wọ́n ti ń sin ràkúnmí.”