KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀǸFÀÀNÍ WO LO MÁA RÍ TÓ O BÁ Ń GBÀDÚRÀ
Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fẹ́ Ká Máa Gbàdúrà sí Òun
Ọlọ́run fẹ́ kó o jẹ́ ọ̀rẹ́ òun.
Bí ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́ bá jọ ń sọ̀rọ̀ dáadáa, àárín wọ́n máa gún. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ó ní: “Ẹ ó sì pè mí, ẹ ó sì wá gbàdúrà sí mi, èmi yóò sì fetí sí yín.” (Jeremáyà 29:12) Bó o ṣe ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, wàá “sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ [ẹ].” (Jákọ́bù 4:8) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Bí a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ máa túbọ̀ gún régé.
“Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”—Sáàmù 145:18
Ọlọ́run fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Jésù sọ pé: “Ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì, òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja, òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, bí ẹ̀yin . . . bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Mátíù 7:9-11) Torí náà, Ọlọ́run fẹ́ kó o gbàdúrà sí òun torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ,’ ó sì fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Pétérù 5:7) Kódà, ó fẹ́ kó o sọ gbogbo ìṣòro rẹ fún òun. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.
Ó máa ǹ wu àwa èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run.
Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ẹ̀dá kíyè sí i pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló máa ń fẹ́ gbàdúrà. Títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà.a Èyí fi hàn pé Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó fi máa wù wá láti sún mọ́ ọn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run ni pé ká máa gbàdúrà sí i déédéé.
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run?
a Lọ́dún 2012, iléeṣẹ́ ìwádìí kan tó ń jẹ́ Pew Research Center ṣe ìwádìí kan nípa àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìwádìí náà fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́wàá lára wọn máa ń gbàdúrà ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lóṣù.