Ìsinsìnyí Ló Yẹ Ká Máa Fún Ara Wa Níṣìírí Ju ti Ìgbàkigbà Rí Lọ
‘Ẹ jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì, kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.’—HÉB. 10:24, 25.
1. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rọ àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé kí wọ́n túbọ̀ máa fún ara wọn níṣìírí?
KÍ NÌDÍ tó fi yẹ ká túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí? Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, ó ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Héb. 10:24, 25) Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, àwọn ará yẹn rí ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní káwọn túbọ̀ máa fún ara wọn níṣìírí. Wọ́n kíyè sí i pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti dé tán sórí Jerúsálẹ́mù àti pé ó ti tó àkókò tó yẹ káwọn fi ibẹ̀ sílẹ̀ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 2:19, 20; Lúùkù 21:20-22) Nígbà tó sì máa di ọdún 70 Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Róòmù mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ sórí ìlú náà, wọ́n sì pa á run.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí lásìkò yìí?
2 Bíi tàwọn Júù ìgbà yẹn làsìkò tiwa yìí náà rí. Ìdí sì ni pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, ó “tóbi, ó sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an.” (Jóẹ́lì 2:11) Wòlíì Sefanáyà sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sef. 1:14) Ohun tí wòlíì yẹn sọ kan àwa náà lónìí. Torí àwa náà ti mọ̀ pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, ó yẹ ká fọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé “kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (Héb. 10:24) Torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ará wa máa jẹ wá lógún, ká sì máa fún wọn níṣìírí nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀.
ÀWỌN WO LÓ NÍLÒ ÌṢÍRÍ?
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fúnni níṣìírí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
3 Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Kò sírọ́ ńbẹ̀ torí pé gbogbo wa la máa ń ṣàníyàn. Torí náà, a nílò ìṣírí látìgbàdégbà. Pọ́ọ̀lù sọ ohun kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ní ojúṣe láti máa fúnni níṣìírí náà nílò ìṣírí. Ó sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Ó ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù tó máa ń fúnni níṣìírí gan-an náà nílò ìṣírí.—Ka Róòmù 15:30-32.
4, 5. Àwọn wo ló yẹ ká máa fún níṣìírí lónìí, kí sì nìdí?
4 Ó yẹ ká máa gbóríyìn fáwọn ará wa tí wọ́n yááfì àwọn nǹkan kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn tó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn míì làwọn míṣọ́nnárì, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn alábòójútó àyíká àti ìyàwó wọn àtàwọn tó ń sìn ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Gbogbo wọn ló yááfì àwọn nǹkan kí wọ́n lè lo ara wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, ó yẹ ká máa fún wọn níṣìírí. Yàtọ̀ síyẹn, ó wu àwọn míì pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nìṣó àmọ́ ipò nǹkan kò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kò yẹ ká gbàgbé irú wọn torí pé àwọn náà nílò ìṣírí.
5 Àwọn míì tó tún nílò ìṣírí làwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọn ò tíì ṣègbéyàwó torí pé wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Bákan náà, inú àwọn ìyàwó ilé máa ń dùn táwọn ọkọ wọn bá ń gbóríyìn fún wọn. (Òwe 31:28, 31) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì tó tún nílò ìṣírí ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin lójú àtakò tàbí tí wọ́n ń fara da àìsàn. (2 Tẹs. 1:3-5) Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yìí, wọ́n sì ń tù wọ́n nínú.—Ka 2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.
ÀWỌN ALÀGBÀ MÁA Ń FÚNNI NÍṢÌÍRÍ
6. Bí Aísáyà 32:1, 2 ṣe sọ, kí ló yẹ káwọn alàgbà máa ṣe?
6 Ka Aísáyà 32:1, 2. Jésù Kristi máa ń lo àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn ọmọ aládé” tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn láti fún wa níṣìírí àti ìtọ́sọ́nà. Ìdí ni pé a máa ń soríkọ́, a sì máa ń rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì. Bó ti wù kó rí, àwọn alàgbà yìí kì í ṣe “ọ̀gá” lórí ìgbàgbọ́ wa. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n “jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú wa, wọ́n sì fẹ́ ká láyọ̀.—2 Kọ́r. 1:24.
7, 8. Yàtọ̀ sí pé káwọn alàgbà sọ̀rọ̀ ìṣírí, kí ni wọ́n tún lè ṣe láti gbé àwọn míì ró?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn alàgbà. Nígbà tó kọ̀wé sáwọn ará Tẹsalóníkà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí, ó ní: “Ní níní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún yín, ó dùn mọ́ wa nínú jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ọkàn àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ di olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún wa.”—1 Tẹs. 2:8.
8 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn alàgbà ìjọ Éfésù sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan ni wọ́n á fi máa fún àwọn ará níṣìírí, ó ní: “Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’ ” (Ìṣe 20:35) Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù kàn ń fún àwọn ará níṣìírí nìkan ni, ó tún lo ara rẹ̀ fún wọn, kódà ó sọ pé “a ó sì ná mi tán pátápátá fún” yín. (2 Kọ́r. 12:15) Lọ́nà kan náà, kò yẹ kó jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan làwọn alàgbà á fi máa fún àwọn ará níṣìírí, ó tún yẹ kọ́rọ̀ àwọn ará máa jẹ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀.—1 Kọ́r. 14:3.
9. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fúnni ní ìbáwí lọ́nà tó ń gbéni ró?
9 Àwọn ìgbà míì wà tó yẹ káwọn alàgbà báni wí. Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ń gbéni ró, ó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó báni wí nínú Bíbélì. Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tó jíǹde. Ó bá àwọn ìjọ kan wí ní Éṣíà Kékeré, àmọ́ kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kíyè sí ohun tó ṣe. Ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún àwọn ìjọ tó wà ní Éfésù, Págámù àti Tíátírà. (Ìṣí. 2:1-5, 12, 13, 18, 19) Ó tiẹ̀ sọ fún ìjọ tó wà ní Laodíkíà pé: “Gbogbo àwọn tí mo ní ìfẹ́ni fún ni mo ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, tí mo sì ń bá wí. Nítorí náà, jẹ́ onítara, kí o sì ronú pìwà dà.” (Ìṣí. 3:19) Ó yẹ káwọn alàgbà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tí wọ́n bá fẹ́ báni wí.
IṢẸ́ ÀWỌN ALÀGBÀ NÌKAN KỌ́
10. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè máa fún ara wa níṣìírí?
10 Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó máa fúnni níṣìírí. Pọ́ọ̀lù rọ gbogbo àwa Kristẹni pé ká máa sọ ohun tó ‘dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, ká lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn’ míì. (Éfé. 4:29) Ó yẹ kí gbogbo wa máa kíyè sí ohun tó jẹ́ “àìní” àwọn míì. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níyànjú pé: “Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ yín, kí ohun tí ó rọ má bàa yẹ̀ kúrò ní oríkèé, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí a lè mú un lára dá.” (Héb. 12:12, 13) Gbogbo wa pátá títí kan àwọn ọmọdé ló yẹ kó máa fún àwọn míì níṣìírí.
11. Kí ló ran Marthe lọ́wọ́ nígbà tó ní ìsoríkọ́?
11 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Marthea sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà kan tó ní ìsoríkọ́, ó ní: “Lọ́jọ́ kan tí mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́, mo rí arábìnrin àgbàlagbà kan tó fìfẹ́ hàn sí mi, tó sì fún mi níṣìírí. Kí n sòótọ́, ohun tí mo nílò lásìkò yẹn gan-an nìyẹn. Arábìnrin yẹn tún sọ ìgbà tóun náà nírú ìṣòro tí mo ní. Mo wá rí i pé èmi nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí, èyí sì mára tù mí.” Ó ṣeé ṣe kí arábìnrin àgbàlagbà yẹn má mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tóun sọ máa fún Marthe níṣìírí tó bẹ́ẹ̀.
12, 13. Báwo la ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:1-4 sílò?
12 Pọ́ọ̀lù fún gbogbo àwọn tó wà níjọ Fílípì nímọ̀ràn pé: “Nígbà náà, bí ìṣírí èyíkéyìí bá wà nínú Kristi, bí ìtùnú onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí bá wà, bí àjọpín ẹ̀mí èyíkéyìí bá wà, bí àwọn ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àwọn ìyọ́nú èyíkéyìí bá wà, ẹ mú ìdùnnú mi kún ní ti pé ẹ ní èrò inú kan náà, ẹ sì ní ìfẹ́ kan náà, bí a ti so yín pọ̀ nínú ọkàn, kí ẹ ní ìrònú kan ṣoṣo nínú èrò inú yín, láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílí. 2:1-4.
13 Bí Bíbélì yẹn ṣe sọ, ó yẹ ká jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn míì máa jẹ wá lógún. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fìfẹ́ tù wọ́n nínú, tá à ń péjọ pẹ̀lú wọn ká lè máa gbé ara wa ró nípa tẹ̀mí, tá a sì ń fi ‘ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìyọ́nú’ hàn sí wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa fún àwọn ará wa níṣìírí.
ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁ A LÈ GBÀ FÚNNI NÍ ÌṢÍRÍ
14. Ọ̀nà míì wo la tún lè gbà rí ìṣírí?
14 Tá a bá gbọ́ nípa bí àwọn tá a ràn lọ́wọ́ ṣe ń tẹ̀ síwájú, ó máa ń múnú wa dùn gan-an. Bó ṣe rí fún àpọ́sítélì Jòhánù náà nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòh. 4) Táwọn aṣáájú-ọ̀nà bá gbọ́ pé ẹni tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run, bóyá ẹni náà tiẹ̀ ti di aṣáájú-ọ̀nà, inú wọn máa ń dùn gan-an, ó sì máa ń fún wọn níṣìírí. Torí náà, tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá rẹ̀wẹ̀sì, a lè rán an létí àwọn àṣeyọrí tó ti ṣe sẹ́yìn, ó dájú pé ìyẹn máa tù ú nínú.
15. Báwo la ṣe lè fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ sìn nínú ètò Ọlọ́run níṣìírí?
15 Ọ̀pọ̀ àwọn alábòójútó àyíká ti sọ bí inú àwọn àti ìyàwó wọn ṣe máa ń dùn tí wọ́n bá gba lẹ́tà ìdúpẹ́ láti ìjọ kan tí wọ́n bẹ̀ wò. Bákan náà, inú àwọn alàgbà, àwọn míṣọ́nnárì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì máa ń dùn tá a bá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
BÍ GBOGBO WA ṢE LÈ MÁA FÁWỌN MÍÌ NÍṢÌÍRÍ
16. Ṣé ó dìgbà tá a bá sọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ ká tó lè fúnni ní ìṣírí? Ṣàlàyé.
16 Kò yẹ ká máa ronú pé a ò lè fún àwọn míì níṣìírí bóyá torí pé a ò mọ ohun tá a máa sọ. Ká sòótọ́, kò dìgbà tá a bá sọ̀rọ̀ rẹpẹtẹ ká tó lè fúnni ní ìṣírí, kódà a lè má ṣe ju pé ká rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹnì kan. Tá a bá rẹ́rìn-ín sẹ́nì kan àmọ́ tí kò rẹ́rìn-ín pa dà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan kan ń jẹ ẹni náà lọ́kàn. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, tá a bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, ìyẹn á jẹ́ kí ara tù ú.—Ják. 1:19.
17. Kí ló ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ nígbà tí ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò?
17 Ìbànújẹ́ dorí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Henri kodò nígbà tí àwọn kan nínú ẹbí rẹ̀ fi òtítọ́ sílẹ̀, títí kan bàbá ẹ̀ tó jẹ́ alàgbà. Alábòójútó àyíká kan kíyè sí i pé inú Henri ò dùn rárá, torí náà ó gbé Henri jáde, ó sì ra kọfí fún un, lẹ́yìn náà ó jẹ́ kí ọ̀dọ́kùnrin yẹn sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí i. Henri wá rí i pé tóun bá máa ran àwọn ẹbí òun tó fi òtítọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́, àfi kóun jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ara tù ú gan-an lẹ́yìn tó ka Sáàmù 46; Sefanáyà 3:17; àti Máàkù 10:29, 30.
18. (a) Kí ni Ọba Sólómọ́nì sọ nípa fífúnni ní ìṣírí? (b) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa ṣe?
18 Àpẹẹrẹ Marthe àti Henri jẹ́ ká rí i pé gbogbo wa la lè fún àwọn ará wa tó nílò ìtùnú ní ìṣírí. Ọba Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o! Ìtànyòò ojú tàbí ọ̀yàyà a máa mú kí ọkàn-àyà yọ̀; ìròyìn tí ó dára a máa mú àwọn egungun sanra.’ (Òwe 15:23, 30) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ àtèyí tó wà lórí ìkànnì wa lè ran ẹni tó bá ní ẹ̀dùn ọkàn lọ́wọ́. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé kíkọ orin Ìjọba Ọlọ́run pa pọ̀ máa ń fúnni ní ìṣírí. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní kíkọ́ ara yín àti ní ṣíṣí ara yín létí lẹ́nì kìíní-kejì pẹ̀lú àwọn sáàmù, àwọn ìyìn sí Ọlọ́run, àwọn orin tẹ̀mí pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, kí ẹ máa kọrin nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.”—Kól. 3:16; Ìṣe 16:25.
19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí, kí ló sì yẹ ká ṣe?
19 Ó ṣe pàtàkì gan-an ká túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí lákòókò yìí torí pé ọjọ́ Jèhófà ti ń “sún mọ́lé.” (Héb. 10:25) Ó yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ìgbà ayé rẹ̀ sọ́kàn, ó ní: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.”—1 Tẹs. 5:11.
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.