Jóẹ́lì
2 “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+
Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi.
2 Ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+
Ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà,+
Bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ lórí àwọn òkè.
Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n pọ̀, tí wọ́n sì lágbára;+
Kò tíì sí irú wọn rí,
Irú wọn kò sì ní sí mọ́ láé,
Jálẹ̀ àwọn ọdún láti ìran dé ìran.
3 Iná ń jẹ àwọn ohun tó wà níwájú wọn,
Ọwọ́ iná sì ń run àwọn ohun tó wà lẹ́yìn wọn.+
Ilẹ̀ iwájú wọn dà bí ọgbà Édẹ́nì,+
Àmọ́ aginjù tó ti di ahoro ló wà lẹ́yìn wọn,
Kò sì sí ohun tó lè yè bọ́.
4 Wọ́n rí bí ẹṣin,
Wọ́n sì ń sáré bí ẹṣin ogun.+
5 Ìró wọn dà bíi ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń bẹ́ gìjà lórí àwọn òkè,+
Bí ìró iná ajófòfò tó ń jó àgékù pòròpórò.
Wọ́n dà bí àwọn alágbára, tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti jagun.+
6 Ìdààmú máa bá àwọn èèyàn náà nítorí wọn,
Ìbẹ̀rù yóò sì hàn lójú gbogbo èèyàn.
7 Wọ́n ń rọ́ gììrì bí àwọn jagunjagun,
Wọ́n gun ògiri bí àwọn ọmọ ogun,
Wọ́n tò tẹ̀ léra,
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kò sì kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀.
8 Wọn kì í ti ara wọn;
Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀.
Bí ohun ìjà* bá gbé àwọn kan ṣubú lára wọn,
Àwọn tó ṣẹ́ kù kì í tú ká.
9 Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, wọ́n sáré lórí ògiri.
Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé* wọlé bí olè.
10 Ilẹ̀ mì tìtì níwájú wọn, ọ̀run sì mì jìgìjìgì.
Oòrùn àti òṣùpá ti ṣókùnkùn,+
Àwọn ìràwọ̀ kò sì mọ́lẹ̀ mọ́.
11 Jèhófà yóò gbé ohùn sókè níwájú àwọn ọmọ ogun rẹ̀,+ torí wọ́n pọ̀ gan-an nínú ibùdó rẹ̀.+
Alágbára ni ẹni tó ń mú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣẹ;
Torí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jèhófà, ó sì ń bani lẹ́rù.+
Ta ló lè fara dà á?”+
12 “Síbẹ̀, ẹ fi gbogbo ọkàn yín pa dà sọ́dọ̀ mi báyìí,” ni Jèhófà wí,+
“Kí ẹ gbààwẹ̀,+ kí ẹ sunkún, kí ẹ sì pohùn réré ẹkún.
13 Ọkàn yín ni kí ẹ fà ya,+ kì í ṣe ẹ̀wù yín,+
Kí ẹ sì pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín,
Torí ó ń gba tẹni rò,* ó jẹ́ aláàánú, kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,+
Òun yóò sì pèrò dà* nípa àjálù náà.
14 Ta ló mọ̀ bóyá ó máa tún ìpinnu ṣe, kó sì pèrò dà,*+
Kó sì mú kí ìbùkún ṣẹ́ kù fún yín,
Kí ẹ lè fi ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà Ọlọ́run yín?
15 Ẹ fun ìwo ní Síónì!
Ẹ kéde ààwẹ̀;* ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+
16 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ; ẹ sọ ìjọ di mímọ́.+
Ẹ kó àwọn àgbà ọkùnrin* jọ, kí ẹ sì kó àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ọwọ́ jọ.+
Kí ọkọ ìyàwó jáde kúrò nínú yàrá rẹ̀ tó wà ní inú, kí ìyàwó pẹ̀lú kúrò nínú yàrá* rẹ̀.
‘Jèhófà, jọ̀ọ́ ṣàánú àwọn èèyàn rẹ;
Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn fi ogún rẹ ṣẹlẹ́yà,
Kó wá di pé àwọn orílẹ̀-èdè á máa jọba lórí wọn,
Tí àwọn èèyàn á fi máa sọ pé, “Ibo ni Ọlọ́run wọn wà?”’+
19 Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn rẹ̀ lóhùn pé:
‘Màá fi ọkà àti wáìnì tuntun àti òróró ránṣẹ́ sí yín,
Yóò sì tẹ́ yín lọ́rùn;+
Mi ò ní jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè fi yín ṣẹlẹ́yà mọ́.+
20 Màá lé àwọn ará àríwá jìnnà sí yín;
Màá fọ́n wọn ká sí ilẹ̀ tí kò lómi tó sì ti di ahoro,
Àwọn tó wà níwájú yóò forí lé ọ̀nà òkun* ìlà oòrùn*
Àwọn tó wà lẹ́yìn yóò sì forí lé ọ̀nà òkun ìwọ̀ oòrùn.*
21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀.
Máa yọ̀, kí inú rẹ sì dùn, torí pé Jèhófà máa ṣe àwọn ohun ńlá.
22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹran inú igbó,
Torí àwọn ibi ìjẹko inú aginjù yóò hu ewéko tútù,+
Àwọn igi yóò sì mú èso jáde;+
Igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi àjàrà yóò so wọ̀ǹtìwọnti.+
23 Ẹ̀yin ọmọ Síónì, ẹ máa yọ̀, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì mú inú yín dùn;+
Torí ó máa rọ òjò fún yín ní ìwọ̀n tó yẹ nígbà ìwọ́wé,
Yóò sì rọ òjò lé yín lórí,
Nígbà ìwọ́wé àti nígbà ìrúwé, bíi ti tẹ́lẹ̀.+
24 Ọkà tó mọ́ máa kún àwọn ibi ìpakà,
Wáìnì tuntun àti òróró á sì kún àwọn ibi ìfúntí yín ní àkúnwọ́sílẹ̀.+
25 Màá sì san àwọn ohun tí ẹ ti pàdánù láwọn ọdún yẹn fún yín
Àwọn ọdún tí ọ̀wọ́ eéṣú, eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, ọ̀yánnú eéṣú àti eéṣú tó ń jẹ nǹkan run fi jẹ irè oko yín,
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán sáàárín yín.+
26 Ó dájú pé ẹ ó jẹ àjẹyó,+
Ẹ ó sì yin orúkọ Jèhófà Ọlọ́run yín,+
Ẹni tó ti ṣe ohun ìyanu fún yín;
Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.+
Wọn ò ní dójú ti àwọn èèyàn mi mọ́ láé.
28 Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi + sára onírúurú èèyàn,
Àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀,
Àwọn àgbà ọkùnrin yín yóò máa lá àlá.
Àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín yóò sì máa rí ìran.+
29 Kódà, ní àwọn ọjọ́ náà,
Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi.