ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ẹ Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Káwọn Míì Fọkàn Tán Yín
“O ní àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tó ń sẹ̀.”—SM. 110:3.
ORIN 39 Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí la lè sọ nípa àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú ìjọ?
Ẹ̀YIN ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú ìjọ wúlò gan-an. Eegun ọ̀dọ́ wà lára yín, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ sì lè ṣe. (Òwe 20:29) Onírúurú ọ̀nà lẹ lè gbà ran àwọn ará lọ́wọ́ nínú ìjọ. Ó dájú pé ó ń wu ẹ̀yin náà pé kẹ́ ẹ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àmọ́, ó lè máa ṣe yín bíi pé àwọn kan ń fojú ọmọdé wò yín tàbí pé ẹ ti kéré jù láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ ṣì kéré lọ́jọ́ orí, àwọn nǹkan kan wà tẹ́ ẹ lè ṣe báyìí táá mú káwọn tó wà nínú ìjọ fọkàn tán yín kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún yín.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tí Ọba Dáfídì ṣe. Bákan náà, a máa sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ohun tí Ọba Ásà àti Ọba Jèhóṣáfátì ṣe nígbà tí wọ́n ṣàkóso nílẹ̀ Júdà. A máa jíròrò ìṣòro táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kojú, ohun tí wọ́n ṣe àtohun tẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin lè kọ́ lára wọn.
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ỌBA DÁFÍDÌ
3. Sọ ọ̀nà kan tẹ́yin ọ̀dọ́ lè gbà ran àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ lọ́wọ́.
3 Àtikékeré ni Dáfídì ti fi hàn pé òun ní àwọn ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kò sí àní-àní pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, ó kọ́ béèyàn ṣe ń kọrin, kódà ó mọ̀ ọ́n kọ débi pé ó máa ń kọrin fún Ọba Sọ́ọ̀lù kára lè tù ú. (1 Sám. 16:16, 23) Ṣé ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà ní àwọn ẹ̀bùn tẹ́ ẹ lè fi ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ? Ó dájú pé ẹ ní. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti kíyè sí i pé àwọn àgbàlagbà kan ò mọ bí wọ́n ṣe lè lo tablet tàbí fóònù wọn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí wọ́n bá wà nípàdé. Inú wọn máa dùn gan-an tẹ́ ẹ bá kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lò ó.
4. Bíi ti Dáfídì, àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin ní? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
4 Ohun tí Dáfídì ṣe fi hàn pé ó ṣeé fọkàn tán, kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré. Bí àpẹẹrẹ, àtikékeré ló ti ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀, àmọ́ iṣẹ́ yìí ò rọrùn rárá. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ̀mí ẹ̀ máa ń wà nínú ewu. Dáfídì sọ fún Ọba Sọ́ọ̀lù pé: “Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀, kìnnìún kan wá, lẹ́yìn náà bíárì kan wá pẹ̀lú, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbé àgùntàn lọ nínú agbo ẹran. Mo gbá tẹ̀ lé e, mo mú un balẹ̀, mo sì gba àgùntàn náà sílẹ̀ lẹ́nu rẹ̀.” (1 Sám. 17:34, 35) Dáfídì mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti bójú tó àwọn àgùntàn náà, ó sì fìgboyà dáàbò bò wọ́n. Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin náà lè fara wé Dáfídì tẹ́ ẹ bá ń rí i dájú pé ẹ ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún yín.
5. Kí ni Sáàmù 25:14 sọ pé ó ṣe pàtàkì jù kẹ́yin ọ̀dọ́kùnrin ṣe?
5 Àtikékeré ni Dáfídì ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Àjọṣe tí Dáfídì ní yìí ṣe pàtàkì ju ìgboyà rẹ̀ àti bó ṣe mọ orin kọ lọ. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run Dáfídì, ó tún jẹ́ Ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. (Ka Sáàmù 25:14.) Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ohun tó ṣe pàtàkì jù tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí àjọṣe tẹ́ ẹ ní pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn lè mú kẹ́ ẹ ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.
6. Èrò tí ò dáa wo làwọn kan ní nípa Dáfídì?
6 Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí Dáfídì ní ni pé àwọn kan máa ń fojú ọmọdé wò ó, wọ́n sì ronú pé kì í fọwọ́ gidi múṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì sọ pé òun máa bá Gòláyátì jà, Ọba Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti dá a dúró, ó sọ pé: “Ọmọdé ni ọ́.” (1 Sám. 17:31-33) Ṣáájú ìgbà yẹn, ẹ̀gbọ́n Dáfídì sọ fún un pé ó máa ń kọjá àyè ẹ̀. (1 Sám. 17:26-30) Àmọ́ Jèhófà mọ Dáfídì dáadáa, kò fojú ọmọdé wò ó, kò sì wò ó bí ẹni tó ń kọjá àyè ẹ̀. Torí pé Dáfídì gbára lé Jèhófà Ọ̀rẹ́ rẹ̀, Jèhófà fún un lókun, ó sì ṣẹ́gun Gòláyátì.—1 Sám. 17:45, 48-51.
7. Kí lo rí kọ́ nínú ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì?
7 Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Dáfídì ṣe? A kẹ́kọ̀ọ́ pé ká máa mú sùúrù. Ó lè má rọrùn fáwọn tó mọ̀ ẹ́ nígbà tó o wà ní kékeré láti gbà pé o ti dàgbà báyìí. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò fojú ọmọdé wò ẹ́ mọ́. Ó mọ̀ ẹ́, ó sì mọ ohun tó o lè ṣe. (1 Sám. 16:7) Torí náà, ṣe ohun táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Dáfídì ṣe ní tiẹ̀? Ṣe ló máa ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ó wá ronú nípa ohun táwọn nǹkan yẹn kọ́ òun nípa Ẹlẹ́dàá. (Sm. 8:3, 4; 139:14; Róòmù 1:20) Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn ọmọléèwé rẹ máa ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da ìṣòro yìí. Yàtọ̀ síyẹn, fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run sílò, títí kan àwọn fídíò. Bó o ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro kan tẹ̀ lé òmíì, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára. Báwọn míì sì ṣe ń rí i pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa mú kí wọ́n fọkàn tán ẹ.
8-9. Kí ló jẹ́ kí Dáfídì lè mú sùúrù dìgbà tó di ọba, kí lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin sì rí kọ́ lára rẹ̀?
8 Ẹ jẹ́ ká wo ìṣòro míì tí Dáfídì kojú. Lẹ́yìn tí wọ́n fòróró yàn án, Dáfídì ṣì ní láti dúró fún ọ̀pọ̀ ọdún kó tó di ọba ilẹ̀ Júdà. (1 Sám. 16:13; 2 Sám. 2:3, 4) Kí ló jẹ́ kó lè mú sùúrù ní gbogbo àsìkò yẹn? Dípò tí Dáfídì á fi rẹ̀wẹ̀sì, ṣe ló lo àkókò yẹn láti ṣe àwọn nǹkan míì tó nítumọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì sá lọ sí ilẹ̀ Filísínì, ó lo àkókò yẹn láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dàábò bo ilẹ̀ Júdà.—1 Sám. 27:1-12.
9 Kí lẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin lè kọ́ lára Dáfídì? Ẹ lo àǹfààní tẹ́ ẹ ní báyìí láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Ricardo.b Àtikékeré ló ti wù ú pé kó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́ àwọn alàgbà sọ fún un pé kó ṣe sùúrù. Dípò táá fi rẹ̀wẹ̀sì, ṣe ni Ricardo bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó sọ pé: “Tí n bá ń ronú pa dà sẹ́yìn, mo rí i pé àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kí n ṣe nígbà yẹn. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà lọ sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, mo sì máa ń múra ìpadàbẹ̀wò wọn sílẹ̀. Kódà, mo darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúngbà àkọ́kọ́. Bí mo ṣe túbọ̀ ń wàásù, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi túbọ̀ ń balẹ̀ lóde ẹ̀rí.” Ní báyìí, Ricardo ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
10. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà kan tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì?
10 Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ míì tá a tún lè kọ́ lára Dáfídì. Lásìkò tí Dáfídì àtàwọn ọkùnrin rẹ̀ ń sá fún Sọ́ọ̀lù, wọ́n fi ìdílé wọn sílé láti lọ jagun. Àmọ́ kí wọ́n tó dé, àwọn ọ̀tá ti kó wọn lẹ́rù, wọ́n sì ti kó àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn lọ. Dáfídì lè ronú pé ṣè bí jagunjagun lòun, kó sì lọ bá àwọn èèyàn náà jà, kó lè gba gbogbo ohun tí wọ́n kó lọ pa dà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Dáfídì ní kí àlùfáà Ábíátárì bá òun mú éfódì wá, Dáfídì sì bi Jèhófà pé: “Ṣé kí n lépa àwọn jàǹdùkú yìí?” Jèhófà sọ fún Dáfídì pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì fi dá a lójú pé á ṣẹ́gun. (1 Sám. 30:7-10) Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí Dáfídì ṣe yìí?
11. Kí ló yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèpinnu?
11 Máa gbàmọ̀ràn kó o tó ṣèpinnu. Bí àpẹẹrẹ, o lè fọ̀rọ̀ lọ àwọn òbí rẹ, o sì lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alàgbà tó ní ìrírí. Jèhófà fọkàn tán àwọn alàgbà yìí, ó sì yẹ kíwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe ni Jèhófà fi wọ́n jíǹkí wa nínú ìjọ. Abájọ tí Bíbélì fi pè wọ́n ní “ẹ̀bùn.” (Éfé. 4:8) Tó o bá fara wé ìgbàgbọ́ wọn, tó o sì fi ìmọ̀ràn tí wọ́n fún ẹ sílò, wàá ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè kọ́ lára Ọba Ásà.
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ỌBA ÁSÀ
12. Irú ẹni wo ni Ásà nígbà tó di ọba?
12 Nígbà tí Ọba Ásà wà lọ́dọ̀ọ́, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì nígboyà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Ábíjà bàbá rẹ̀ kú, Ásà di ọba, ó sì gbógun ti ìbọ̀rìṣà. Ó tún sọ fáwọn èèyàn ilẹ̀ “Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì máa pa Òfin àti àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (2 Kíró. 14:1-7) Nígbà tí Síírà ará Etiópíà wá gbéjà kò wọ́n pẹ̀lú ọmọ ogun mílíọ̀nù kan, Ásà ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu, ó bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó ní: “Jèhófà, kò jẹ́ nǹkan kan lójú rẹ bóyá àwọn tí o fẹ́ ràn lọ́wọ́ pọ̀ tàbí wọn ò lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ la gbẹ́kẹ̀ lé.” Àdúrà tí Ásà gbà yìí jẹ́ ká rí bó ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó, tó sì dá a lójú pé Jèhófà lágbára láti dá òun àtàwọn èèyàn ẹ̀ nídè. Ásà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Jèhófà [sì] ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà.”—2 Kíró. 14:8-12.
13. Kí ni Ásà ṣe nígbà tó yá, kí sì nìdí?
13 Ìwọ náà máa gbà pé ẹ̀rù máa ba Ásà gan-an nígbà táwọn ọmọ ogun mílíọ̀nù kan wá gbéjà kò ó. Síbẹ̀, torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó ṣẹ́gun wọn. Àmọ́, nígbà táwọn ọmọ ogun tí ò tóyẹn wá gbéjà kò ó, Ásà ò yíjú sí Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Ọba Bááṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì wá gbógun ja Ásà, àmọ́ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ọba Síríà ló bẹ̀ lọ́wẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn múnú bí Jèhófà gan-an. Jèhófà wá tipasẹ̀ wòlíì Hánáánì sọ fún Ọba Ásà pé: “Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé ọba Síríà, tí o kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àwọn ọmọ ogun ọba Síríà ti bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.” Látìgbà yẹn lọ ni ogun ti ń ja Ọba Ásà. (2 Kíró. 16:7, 9; 1 Ọba 15:32) Kí lo rí kọ́?
14. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí sì ni 1 Tímótì 4:12 sọ pé o máa jẹ́ fáwọn míì?
14 Jẹ́ kó máa hàn nínú ohun tó ò ń ṣe pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, o sì ń gbára lé Jèhófà. Nígbà tó o ṣèrìbọmi, o fi hàn pé o nígbàgbọ́, o sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ohun tó o ṣe yẹn múnú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ kó o di ara ìdílé òun. Ohun tó o máa ṣe báyìí ni pé kó o túbọ̀ máa gbára lé Jèhófà. Ó lè rọrùn fún ẹ láti gbára lé Jèhófà tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan míì tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ńkọ́? Ó ṣe pàtàkì gan-an kó o máa gbára lé Jèhófà tó o bá fẹ́ ṣe ìpinnu, títí kan eré ìnàjú tó o máa ṣe, iṣẹ́ tó o máa gbà, àtohun tó o máa fayé ẹ ṣe! Má ṣe gbára lé ọgbọ́n ara rẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣèwádìí nínú Bíbélì kó o lè mọ àwọn ìlànà tó bá ipò rẹ mu, kó o sì fi wọ́n sílò. (Òwe 3:5, 6) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá múnú Jèhófà dùn, àwọn tó wà nínú ìjọ á sì fọkàn tán ẹ.—Ka 1 Tímótì 4:12.
Ẹ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ỌBA JÈHÓṢÁFÁTÌ
15. Àwọn àṣìṣe wo ni 2 Kíróníkà 18:1-3; 19:2 sọ pé Ọba Jèhóṣáfátì ṣe?
15 Bíi tàwa yòókù, aláìpé nìwọ náà, ìyẹn sì fi hàn pé o lè ṣàṣìṣe. Àmọ́, ìyẹn ò ní kó o má ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Ọba Jèhóṣáfátì. Ọ̀pọ̀ nǹkan dáadáa ló ṣe. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, “ó wá Ọlọ́run bàbá rẹ̀, ó [sì] ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Yàtọ̀ síyẹn, ó ní kí àwọn ìjòyè lọ sí gbogbo ìlú tó wà ní ilẹ̀ Júdà, kí wọ́n sì máa kọ́ àwọn èèyàn náà nípa Jèhófà. (2 Kíró. 17:4, 7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhóṣáfátì ṣe àwọn nǹkan tó dáa, àwọn ìgbà kan wà tó ṣàṣìṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe ìpinnu kan tó múnú bí Jèhófà, Jèhófà sì tìtorí ẹ̀ rán wòlíì kan pé kó bá a wí. (Ka 2 Kíróníkà 18:1-3; 19:2.) Kí lo rí kọ́ nínú ìtàn yìí?
16. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Arákùnrin Rajeev ṣe?
16 Máa gbàmọ̀ràn, kó o sì máa fi í sílò. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin míì, ó lè ṣòro fún ẹ láti fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé ẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Rajeev ṣe. Ó sọ bí nǹkan ṣe rí fún un nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ní: “Àwọn ìgbà kan wà tí mi ò mọ ohun tí màá fayé mi ṣe. Bíi tàwọn ọ̀dọ́ yòókù, ohun tó gbà mí lọ́kàn jù ni kí n máa ṣeré ìdárayá tàbí kí n máa gbafẹ́ kiri, mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbádùn kí n máa lọ sípàdé tàbí òde ẹ̀rí.” Kí ló ràn án lọ́wọ́? Alàgbà kan kíyè sí Rajeev, ó sì fún un nímọ̀ràn. Rajeev sọ pé: “Ó jẹ́ kí n ronú lórí ìlànà tó wà nínú 1 Tímótì 4:8.” Rajeev gba ìmọ̀ràn tí alàgbà náà fún un tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, ó sì ṣàtúnṣe tó yẹ. Ó sọ pé: “Ohun tí alàgbà náà bá mi sọ mú kí n pinnu pé ìjọsìn Jèhófà ló máa gbawájú láyé mi.” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Rajeev sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, mo di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.”
Ẹ ṢE OHUN TÁÁ MÚNÚ BÀBÁ YÍN Ọ̀RUN DÙN
17. Táwọn ará nínú ìjọ bá rí àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń sin Jèhófà, báwo ló ṣe máa ń rí lára wọn?
17 Inú àwọn ará máa ń dùn tí wọ́n bá ń rí i tí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin ń ‘sin Jèhófà ní ìṣọ̀kan’ pẹ̀lú wọn! (Sef. 3:9) Inú wọn máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá rí i tẹ́ ẹ̀ ń fi ìtara àti gbogbo okun yín ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún yín nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé wọ́n mọyì yín gan-an.—1 Jòh. 2:14.
18. Kí ni Òwe 27:11 sọ tó jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin tẹ́ ẹ̀ ń jọ́sìn rẹ̀?
18 Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ẹ fi sọ́kàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, ó sì fọkàn tán yín. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin máa yọ̀ǹda ara wọn tinútinú. (Sm. 110:1-3) Ó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, o sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn òun. Torí náà, máa ṣe sùúrù. Tó o bá sì ṣàṣìṣe, gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ torí àtọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá. (Héb. 12:6) Yàtọ̀ síyẹn, ọwọ́ pàtàkì ni kó o fi mú iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún ẹ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa ṣe ohun táá múnú Jèhófà Baba rẹ ọ̀run dùn nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe.—Ka Òwe 27:11.
ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
a Bí òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́kùnrin, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa wù wọ́n láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kí wọ́n tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá jẹ́ kí àwọn míì nínú ìjọ fọkàn tán wọn. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.