ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 34
‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
‘Ẹ máa rìn nínú òtítọ́.’—3 JÒH. 4.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ bá a ṣe rí “òtítọ́”?
“BÁWO lo ṣe rí òtítọ́?” Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ti bi ẹ́ ní ìbéèrè yìí tó o sì dá wọn lóhùn. Ọ̀kan lára ìbéèrè tá a máa ń kọ́kọ́ bi àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà nìyẹn tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ wọ́n. Ó máa ń wù wá ká mọ bí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe mọ Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì tún máa ń wù wá láti sọ ìdí tá a fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún wọn. (Róòmù 1:11) Bá a ṣe ń bá ara wa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí, ó máa ń jẹ́ ká ronú nípa ohun tó mú ká di ìránṣẹ́ Jèhófà. Á tún jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé àá máa “rìn nínú òtítọ́,” ìyẹn ni pé àá máa gbé ìgbé ayé tí inú Jèhófà dùn sí.—3 Jòh. 4.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ká sì mọyì ẹ̀. Ó dájú pé àwọn nǹkan tá a máa gbé yẹ̀ wò yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ ká rí òtítọ́. (Jòh. 6:44) Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
ÌDÍ TÁ A FI NÍFẸ̀Ẹ́ “ÒTÍTỌ́”
3. Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù tá a fi nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?
3 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú wọn ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló lágbára jù lọ, òun ló sì dá ayé àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, òun ni Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ń bójú tó wa. (1 Pét. 5:7) A tún mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ “aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Ẹ́kís. 34:6) Jèhófà tún nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Àìsá. 61:8) Ó máa ń dùn ún tá a bá ń jìyà, ó sì ṣe tán láti mú gbogbo ìyà náà kúrò ní àkókò tó tọ́ lójú ẹ̀. (Jer. 29:11) À ń fojú sọ́nà fún ìgbà ọ̀tun yẹn! Ìdí nìyẹn tá a fi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an!
4-5. Kí ló mú kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìrètí tá a ní wé ìdákọ̀ró?
4 Nǹkan míì wo ló mú ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́? Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí torí pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ bí ìrètí yẹn ti ṣe pàtàkì tó, ó sọ pé: “A ní ìrètí yìí bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó [sì] fìdí múlẹ̀.” (Héb. 6:19) Bí ìdákọ̀ró kì í ṣeé jẹ́ kí omi gbé ọkọ̀ ojú omi lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa kì í jẹ́ kí ìṣòro bò wá mọ́lẹ̀.
5 Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní pé ọ̀run làwọn ń lọ àti bí wọ́n ṣe mọyì ẹ̀ tó. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn tún kan àwọn Kristẹni tó nírètí pé àwọn máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. (Jòh. 3:16) Ó dájú pé ìrètí tá a ní pé a máa rí ìyè àìnípẹ̀kun ti mú káyé wa dáa sí i.
6-7. Báwo ni Yvonne ṣe jàǹfààní nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?
6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Yvonne. Àwọn òbí ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì máa ń bẹ̀rù ikú nígbà tó wà ní kékeré. Ó rántí ọ̀rọ̀ kan tó kà tí ò lè gbàgbé, ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo nǹkan máa pa run.” Ó sọ pé: “Tí mo bá rántí ọ̀rọ̀ yẹn, ńṣe ló máa ń gba oorun lójú mi, àyà mi á sì máa já torí mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Mo máa ń ronú pé ‘A ò kàn lè wà láyé yìí lásán.’ ‘Kí nìdí tí mo fi wà láyé?’ Mi ò fẹ́ kú o!”
7 Nígbà tí Yvonne di ọ̀dọ́, ó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í nírètí pé màá gbé ayé títí láé nínú Párádísè.” Báwo ni arábìnrin wa yìí ṣe jàǹfààní òtítọ́ tó kọ́? Ó sọ pé: “Oorun ò dá lójú mi mọ́ torí mi ò bẹ̀rù ikú àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la mọ́.” Ẹ ò rí i pé Yvonne nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ gan-an! Inú ẹ̀ máa ń dùn bó ṣe ń sọ ìrètí tó ní pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa fáwọn èèyàn.—1 Tím. 4:16.
8-9. (a) Nínú àkàwé kan tí Jésù sọ, báwo ni ọkùnrin tó rí ìṣúra kan ṣe mọyì ẹ̀ tó? (b) Báwo lo ṣe mọyì òtítọ́ tó?
8 Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wà lára ẹ̀kọ́ òtítọ́. Jésù fi òtítọ́ yìí wé ìṣúra kan tá a fi pa mọ́. Nínú Mátíù 13:44, Jésù sọ pé: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tó sì fi pa mọ́; torí pé inú rẹ̀ ń dùn, ó lọ ta gbogbo ohun tó ní, ó sì ra pápá yẹn.” Ṣé ẹ kíyè sí i pé ọkùnrin náà ò wá ìṣúra náà kiri. Àmọ́ nígbà tó rí i, ó yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó lè rà á. Kódà, ó ta gbogbo ohun tó ní. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ bí ìṣúra náà ṣe ṣeyebíye tó, ó sì mọ̀ pé ìṣúra náà ṣeyebíye ju gbogbo nǹkan tóun ti yááfì lọ.
9 Ṣé bí òtítọ́ ṣe ṣeyebíye lójú tìẹ náà nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! A mọ̀ pé kò sí ohun tí ayé yìí lè fún wa tó lè dà bí ayọ̀ tá à ń rí bá a ṣe ń sin Jèhófà àti ìrètí tá a ní pé a máa rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú nínú Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí ohunkóhun tá a lè yááfì báyìí tó ṣeyebíye tó àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Bá a ṣe ń “ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún” lohun tó ń fún wa láyọ̀ jù lọ.—Kól. 1:10.
10-11. Kí ló mú kí Michael yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà?
10 Ọ̀pọ̀ lára wa ló ti yááfì nǹkan ńlá ká lè rí ojúure Jèhófà. Àwọn kan ti pa iṣẹ́ tó lè sọ wọ́n di olókìkí tì, àwọn míì ò sì lépa owó mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan ti yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn pa dà lẹ́yìn tí wọ́n mọ Jèhófà. Ohun tí Michael ṣe nìyẹn. Àwọn òbí ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó lọ kọ́ ìjà kọnfú. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí mi ni pé kí n máa ṣe eré ìmárale kára mi lè le pọ́n-ún pọ́n-ún. Kódà, mo máa ń rò pé apá ẹnikẹ́ni ò lè ká mi mọ́.” Àmọ́ nígbà tí Michael bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó rí i pé Jèhófà kórìíra ìwà ipá. (Sm. 11:5) Ohun tí Michael sọ nípa tọkọtaya tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni pé: “Wọn ò sọ fún mi rárá pé kí n fi ìjà kọnfú sílẹ̀, ṣe ni wọ́n kàn ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó.”
11 Bí Michael ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ ló ń nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Ohun tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn jù lọ ni bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwọn èèyàn ẹ̀. Nígbà tó yá, Michael rí i pé ó yẹ kóun ṣe ìpinnu kan tó máa yí ìgbésí ayé òun pa dà. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ohun tó máa ṣòro jù lọ láyé mi ni kí n fi ìjà kọnfú sílẹ̀. Àmọ́ mo mọ̀ pé inú Jèhófà máa dùn tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dá mi lójú pé kò sóhun téèyàn ò lè yááfì láti sin Jèhófà.” Michael mọyì òtítọ́ tó rí, ó sì mú kó yí ìgbésí ayé ẹ̀ pa dà.—Jém. 1:25.
12-13. Báwo ni ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì ṣe ran Mayli lọ́wọ́?
12 Ká lè mọ bí òtítọ́ ṣe ṣeyebíye tó, Bíbélì fi wé fìtílà tó ń tàn nínú òkùnkùn. (Sm. 119:105; Éfé. 5:8) Obìnrin kan tó ń jẹ́ Mayli tó wá láti orílẹ̀-èdè Azerbaijan mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó kọ́ nínú Bíbélì gan-an. Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn òbí ẹ̀ ń ṣe. Mùsùlùmí ni bàbá ẹ̀, Júù sì ni ìyá ẹ̀. Ó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo gbà pé Ọlọ́run wà, àwọn ìbéèrè kan ṣì wà lọ́kàn mi. Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn? Kí nìdí téèyàn fi máa jìyà láyé tí á tún lọ joró ní ọ̀run àpáàdì?’ Àwọn èèyàn máa ń sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá dé bá ẹ̀dá, èyí máa ń mú kí n béèrè pé, ‘Ṣé Ọlọ́run kàn ń ṣe wá bó ṣe wù ú ni, tínú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń wò wá tá à ń jìyà?’”
13 Mayli ṣì ń wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lọ́kàn ẹ̀. Nígbà tó yá, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí mo kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ káyé mi dáa. Àwọn ìdáhùn tó bọ́gbọ́n mu tí mo rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.” Bíi ti Mayli, gbogbo wa là ń yin Jèhófà, “ẹni tó pè [wá] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 Pét. 2:9.
14. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́? (Tún wo àpótí náà “Àwọn Àfiwé Míì.”)
14 Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé òtítọ́ ṣeyebíye gan-an. O sì tún lè ronú kan àwọn àpẹẹrẹ míì. O ò ṣe ṣèwádìí nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè rí àwọn ìdí míì tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́? Bá a bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa hàn nígbèésí ayé wa.
BÁ A ṢE LÈ FI HÀN PÉ A NÍFẸ̀Ẹ́ ÒTÍTỌ́
15. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?
15 Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Kódà, tá a bá tiẹ̀ ti pẹ́ nínú òtítọ́, ó yẹ ká ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Ẹ̀dà àkọ́kọ́ Ilé Ìṣọ́ yìí sọ pé: “Òtítọ́ dà bí òdòdó kékeré kan tó wà láàárín àwọn èpò ní aginjù. Kó o tó lè rí i, wàá máa wá a káàkiri. . . . Tó o bá wá rí òdòdó náà, ṣe lo máa bẹ̀rẹ̀ kó o tó lè já a. Àmọ́ má ṣe jẹ́ kí ẹyọ kan yẹn tó ẹ, máa wá òdòdó sí i. . . . Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ṣe rí náà nìyẹn. Ńṣe ló yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i, kó o lè mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó pọ̀.” Torí náà, ó gba iṣẹ́ àṣekára kéèyàn tó lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ó lérè.
16. Báwo lo ṣe máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè jàǹfààní ẹ̀? (Òwe 2:4-6)
16 Gbogbo wa kọ́ ló máa ń wù pé ká kàwé tàbí ká dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa “wá” òtítọ́ kiri ká lè mọ òtítọ́. (Ka Òwe 2:4-6.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jàǹfààní gan-an. Arákùnrin Corey sọ pé tóun bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹsẹ Bíbélì kan lòun máa ń gbájú mọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń ka àlàyé ìsàlẹ̀ ẹsẹ Bíbélì náà, màá wo àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tá a tọ́ka sí, màá sì ṣèwádìí ẹ̀. . . . Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo máa ń rí kọ́ torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yìí!” Tá a bá ń lo okun àti àkókò wa láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà yìí tàbí láwọn ọ̀nà míì, á fi hàn pé a mọyì òtítọ́ gan-an.—Sm. 1:1-3.
17. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí òtítọ́ tá a mọ̀ máa hàn nígbèésí ayé wa? (Jémíìsì 1:25)
17 Àmọ́ ṣá o, ká kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìkan ò tó. Ká tó lè jàǹfààní ẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa hàn nígbèésí ayé wa, ìyẹn ni pé ká máa fi ohun tá à ń kọ́ ṣèwàhù, ìgbà yẹn la máa ní ayọ̀ tòótọ́. (Ka Jémíìsì 1:25.) Báwo la ṣe lè jẹ́ kí òtítọ́ tá a ti mọ̀ máa hàn nígbèésí ayé wa? Arákùnrin kan dábàá pé ká máa wo àwọn ibi tá a dáa sí àtàwọn ibi tá a kù sí ká lè ṣàtúnṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.”—Fílí. 3:16.
18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè “máa rìn nínú òtítọ́”?
18 Ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣiṣẹ́ kára láti “máa rìn nínú òtítọ́”! Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayé wa máa dáa sí i, a tún máa múnú Jèhófà dùn. Yàtọ̀ síyẹn, inú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà náà máa dùn. (Òwe 27:11; 3 Jòh. 4) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé àwọn nǹkan pàtàkì yìí ló máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, ká sì máa fi ṣèwàhù.
ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!
a Àwọn ohun tá a gbà gbọ́ nínú Bíbélì àti bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa la sábà máa ń pè ní ọ̀nà “òtítọ́.” Bóyá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni àbí a ti pẹ́ nínú òtítọ́, a máa jàǹfààní gan-an tá a bá ronú nípa ìdí tá a fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé nǹkan tí inú Jèhófà dùn sí làá máa ṣe.