ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35
Ẹ Máa “Gbé Ara Yín Ró”
“Ẹ máa fún ara yín níṣìírí, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró.” —1 TẸS. 5:11.
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni 1 Tẹsalóníkà 5:11 sọ pé kí gbogbo wa máa ṣe?
ṢÉ ÌJỌ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yín ni àbí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ tún un ṣe? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá rántí ìpàdé àkọ́kọ́ tó o ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà. Ṣe ni inú ẹ ń dùn, tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Kódà, inú ẹ dùn gan-an débi pé omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú ẹ, kò sì rọrùn fún ẹ láti kọrin tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lọ́jọ́ yẹn. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà tá a kọ́ máa ń mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Àmọ́, a máa mú ìyìn tó ga jù lọ bá orúkọ Jèhófà tá a bá ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì míì tó ní ká máa ṣe. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ. Iṣẹ́ náà ni pé tá a bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ká máa gbé àwọn ará wa ró. Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ tó wà ní 1 Tẹsalóníkà 5:11 tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé.—Kà á.
2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká gbé àwọn ará ró. Ó máa ń gba tiwọn rò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn ará lọ́wọ́ (1) láti fara da ìṣòro, (2) láti jẹ́ ẹni àlàáfíà àti (3) láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà lágbára sí i. Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù, káwa náà lè máa gbé àwọn ará wa ró.—1 Kọ́r. 11:1.
PỌ́Ọ̀LÙ RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ LÁTI FARA DA ÌṢÒRO
3. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ò ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹ̀ pa ìjọsìn ẹ̀ lára?
3 Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, ìyà tó jẹ ò sì kéré rárá. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń gba tàwọn ará rò tí wọ́n bá níṣòro, tó sì máa ń ṣàánú wọn. Ìgbà kan wà tí owó tán lọ́wọ́ ẹ̀, ìyẹn sì gba pé kó máa ṣiṣẹ́ kó lè pèsè fún ara ẹ̀ àtàwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀. (Ìṣe 20:34) Iṣẹ́ àgọ́ pípa ni Pọ́ọ̀lù ń ṣe. Nígbà tó dé Kọ́ríńtì, òun pẹ̀lú Ákúílà àti Pírísílà ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa. Àmọ́ “gbogbo sábáàtì” ló fi máa ń wàásù fáwọn Júù àtàwọn Gíríìkì. Nígbà tí Sílà àti Tímótì tún wá sọ́dọ̀ ẹ̀, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an.” (Ìṣe 18:2-5) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa fayé ẹ̀ sin Jèhófà ló ṣe pàtàkì lójú ẹ̀, kò jẹ́ káwọn nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Torí pé Pọ́ọ̀lù ò ṣọ̀lẹ tó sì tún ṣiṣẹ́ kára kó lè gbọ́ bùkátà ara ẹ̀, ìyẹn jẹ́ kẹ́nu ẹ̀ gbà á láti fún àwọn ará níṣìírí. Ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àníyàn bí wọ́n ṣe máa pèsè fún ìdílé wọn mú kí wọ́n pa “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tì, ìyẹn gbogbo apá ìjọsìn wọn.—Fílí. 1:10.
4. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ṣe ran àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà lọ́wọ́ láti fara da inúnibíni?
4 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà sílẹ̀, àwọn ará tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni dojú kọ inúnibíni tó le gan-an. Nígbà táwọn alátakò kan tí inú ń bí burúkú burúkú ò rí Pọ́ọ̀lù àti Sílà mú, wọ́n wọ́ “àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú,” wọ́n sì ń pariwo pé: “Àwọn ọkùnrin yìí ló ń ta ko àwọn àṣẹ Késárì.” (Ìṣe 17:6, 7) Ṣé ẹ rò pé ẹ̀rù ò ní máa ba àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yẹn nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọkùnrin ìlú yẹn ń ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni? Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kí wọ́n dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò fẹ́ kíyẹn ṣẹlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù àti Sílà ní láti fi ibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n rí i dájú pé àwọn bójú tó àwọn ará tó wà ní ìjọ tuntun náà dáadáa. Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará Tẹsalóníkà létí pé: ‘A rán Tímótì, arákùnrin wa . . . , kí ó lè mú kí ẹ fìdí múlẹ̀, kí ó sì tù yín nínú nítorí ìgbàgbọ́ yín, kí àwọn ìpọ́njú yìí má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀.’ (1 Tẹs. 3:2, 3) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣenúnibíni sí Tímótì náà nígbà tó wà nílùú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Lísírà. Ó ti rí bí Pọ́ọ̀lù ṣe fún àwọn ará níṣìírí ní Lísírà kí wọ́n lè lókun. Tímótì rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bò wọ́n, ìyẹn ló jẹ́ kó fi dá àwọn ará Tẹsalóníkà lójú pé Jèhófà máa wà pẹ̀lú àwọn náà.—Ìṣe 14:8, 19-22; Héb. 12:2.
5. Báwo ni Bryant ṣe jàǹfààní nígbà tí alàgbà kan ràn án lọ́wọ́?
5 Nǹkan míì wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe kó lè fún àwọn ará lókun? Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pa dà sí Lísírà, Íkóníónì àti Áńtíókù, wọ́n “yan àwọn alàgbà fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan.” (Ìṣe 14:21-23) Ó dájú pé àwọn alàgbà tí wọ́n yàn yẹn tu àwọn ará ìjọ nínú bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣe láwọn ìjọ wa lóde òní. Ẹ wo ohun tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Bryant sọ, ó ní: “Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), bàbá mi filé sílẹ̀, wọ́n sì yọ ìyá mi kúrò nínú ìjọ. Àwọn méjèèjì já mi jù sílẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí n rẹ̀wẹ̀sì.” Kí ló jẹ́ kí Bryant lè fara dà á? Ó sọ pé: “Tá a bá wà nípàdé, ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ wa tó ń jẹ́ Tony máa ń tù mí nínú nípàdé àti láwọn ìgbà míì tó bá rí mi. Ó máa ń sọ̀rọ̀ àwọn ará tó dojú kọ ìṣòro fún mi, àmọ́ tí inú wọn ṣì máa ń dùn. Ó ka Sáàmù 27:10 fún mi, ó sì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa Hesekáyà tó fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá ẹ̀ ò fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀.” Báwo ni ohun tí alàgbà yìí ṣe ṣe ran Bryant lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Bí Arákùnrin Tony ṣe fún mi níṣìírí jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.” Torí náà, ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa kíyè sí àwọn ará tó níṣòro tẹ́ ẹ lè sọ “ọ̀rọ̀ rere” fún, kẹ́ ẹ sì tù wọ́n nínú bí wọ́n ṣe tu Bryant nínú.—Òwe 12:25.
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ìtàn àwọn tó nígbàgbọ́ láti fi ran àwọn ará lọ́wọ́?
6 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà pé Jèhófà ló ran “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” lọ́wọ́ tí wọ́n fi fara da ìṣòro tí wọ́n dojú kọ. (Héb. 12:1) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó fara da oríṣiríṣi ìṣòro nígbà àtijọ́ lè fún àwọn ará lókun kí wọ́n lè nígboyà, kí wọ́n sì máa ronú nípa “ìlú Ọlọ́run alààyè.” (Héb. 12:22) Àwọn ìtàn yẹn ti ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí. Ẹ wo bí ìgbàgbọ́ wa ṣe túbọ̀ máa ń lágbára tá a bá ka ìtàn bí Jèhófà ṣe ran Gídíónì, Bárákì, Dáfídì, Sámúẹ́lì àtàwọn míì lọ́wọ́! (Héb. 11:32-35) Bákan náà lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́. Ní orílé iṣẹ́ wa, a sábà máa ń gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ àwọn ará wa. Wọ́n máa ń sọ fún wa pé ìgbàgbọ́ àwọn túbọ̀ lágbára nígbà táwọn ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní.
PỌ́Ọ̀LÙ RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́ LÁTI JẸ́ ẸNI ÀLÀÁFÍÀ
7. Kí lo rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá ní Róòmù 14:19-21?
7 Tá a bá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa nínú ìjọ, ìyẹn máa fi hàn pé à ń gbé wọn ró. Tí èrò wa bá tiẹ̀ yàtọ̀ síra, a kì í jẹ́ kíyẹn dá ìyapa sáàárín wa. A kì í rin kinkin mọ́ èrò wa, tí nǹkan náà ò bá ti ta ko ohun tí Bíbélì sọ. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni àtàwọn Kèfèrí tó di Kristẹni ló wà ní ìjọ Róòmù. Nígbà tí Òfin Mósè kásẹ̀ nílẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò tẹ̀ lé òfin tó sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn oúnjẹ kan mọ́. (Máàkù 7:19) Àtìgbà yẹn làwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ti lómìnira láti jẹ oúnjẹ tó bá wù wọ́n. Àmọ́ àwọn Júù kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé àwọn ò lè jẹ oúnjẹ tí Òfin sọ pé káwọn má jẹ. Ọ̀rọ̀ yìí dá ìyapa sáàárín àwọn ará inú ìjọ nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wọn. Ó sọ pé: “Ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má jẹ ẹran tàbí kó má mu ọtí tàbí kó má ṣe ohunkóhun tó máa mú arákùnrin rẹ̀ kọsẹ̀.” (Ka Róòmù 14:19-21.) Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà rí ìpalára tí irú àríyànjiyàn bẹ́ẹ̀ lè ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn àti gbogbo ìjọ lápapọ̀. Bákan náà, ó gbà láti má ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, kó má bàa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (1 Kọ́r. 9:19-22) Táwa náà ò bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ dá ìyapa sáàárín wa, àá máa gbé ara wa ró, àlàáfíà á sì wà láàárín wa.
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tí ọ̀rọ̀ pàtàkì kan dá awuyewuye sílẹ̀ nínú ìjọ?
8 Nígbà tí èdèkòyédè wáyé lórí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì kan, Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ torí pé kò bá àwọn tó ń ṣe awuyewuye jà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lára àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ń rin kinkin mọ́ ọn pé dandan ni kí àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni dádọ̀dọ́, káwọn Júù má bàa sọ̀rọ̀ wọn láìdáa. (Gál. 6:12) Pọ́ọ̀lù ò fara mọ́ èrò wọn rárá, àmọ́ kò sọ pé dandan ni kí wọ́n fara mọ́ èrò tòun. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ní kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, èyí sì fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 15:1, 2) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe bójú tó ọ̀rọ̀ yìí mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ, inú àwọn ará sì ń dùn.—Ìṣe 15:30, 31.
9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni àlàáfíà bíi ti Pọ́ọ̀lù?
9 Tí èdèkòyédè bá wáyé, a lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni àlàáfíà tá a bá jẹ́ káwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó wa tọ́ wa sọ́nà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ètò Ọlọ́run máa ń lo Bíbélì láti tọ́ wa sọ́nà, àwọn ìtọ́sọ́nà náà sì máa ń wà nínú ìwé àtàwọn ìlànà tí wọ́n ń fún wa. Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí wọ́n ń fún wa yìí, a ò ní máa rin kinkin mọ́ èrò wa, ìyẹn sì máa jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ.
10. Nǹkan míì wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tó fi hàn pé ó fẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ?
10 Nǹkan míì tí Pọ́ọ̀lù ṣe tó jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ ni pé nǹkan tó dáa ló máa ń sọ nípa àwọn ará, kì í sọ ohun tí kò dáa nípa wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fẹ́ parí lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ní Róòmù, ó dárúkọ ọ̀pọ̀ lára wọn, ó sì sọ ohun tó dáa nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn. Táwa náà bá ń sọ ohun tó dáa nípa àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, à ń fara wé Pọ́ọ̀lù nìyẹn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ra wa, ìfẹ́ tó wà láàárín wa sì máa lágbára sí i.
11. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín wa, báwo la ṣe lè yanjú ẹ̀?
11 Nígbà míì, èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ nìyẹn. Nígbà tí wọ́n fẹ́ rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, àwọn méjèèjì bá ara wọn jiyàn gan-an. Ẹnì kan sọ pé kí wọ́n mú Máàkù dání, ẹnì kejì sì sọ pé kí wọ́n má mú un dání. Bíbélì sọ pé ‘àwọn méjèèjì gbaná jẹ,’ wọ́n sì pínyà. (Ìṣe 15:37-39) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n fẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ìjọ káwọn ará lè wà níṣọ̀kan. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó dáa nípa Bánábà àti Máàkù. (1 Kọ́r. 9:6; Kól. 4:10) Ó yẹ káwa náà máa yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àtàwọn ará ìjọ wa, ká sì máa wo ibi tí wọ́n dáa sí. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ, káwọn ará sì wà níṣọ̀kan.—Éfé. 4:3.
PỌ́Ọ̀LÙ MÚ KÍ ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN ARÁ LÁGBÁRA
12. Sọ díẹ̀ lára ìṣòro táwọn ará wa kan ń dojú kọ.
12 Tá a bá ń ṣe ohun tó mú kí ìgbàgbọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lágbára, à ń gbé wọn ró nìyẹn. Nígbà míì, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ọmọ ilé ìwé wọn máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn ará wa kan ń ṣàìsàn tó le gan-an, àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè borí ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wọn. Àwọn míì sì rèé, wọ́n ti ṣèrìbọmi ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àmọ́ wọ́n ń dúró de ìgbà tí ayé burúkú yìí máa dópin. Àwọn nǹkan yìí ló ń dán ìgbàgbọ́ àwọn ará wa wò lónìí. Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà sì dojú kọ irú àwọn ìṣòro yìí. Àmọ́, kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára?
13. Nígbà tí wọ́n ń fàwọn ará ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe?
13 Pọ́ọ̀lù lo Ìwé Mímọ́ láti fún ìgbàgbọ́ àwọn ará lókun. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni lè má mọ ohun tí wọ́n máa sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Kristẹni tó ń sọ pé ẹ̀sìn Júù dáa ju ẹ̀sìn Kristẹni lọ. Àmọ́ ó dájú pé lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni yẹn fún ìgbàgbọ́ wọn lókun. (Héb. 1:5, 6; 2:2, 3; 9:24, 25) Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú lẹ́tà yẹn máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n máa sọ fáwọn tó ń ta kò wọ́n. Bákan náà lónìí, a lè jẹ́ káwọn ará wa mọ bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ìwé wa tó dá lórí Bíbélì láti fi ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Tí wọ́n bá ń fi àwọn ọ̀dọ́ wa ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo, a lè jọ ṣèwádìí nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Was Life Created? àti The Origin of Life—Five Questions Worth Asking kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n máa fi ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo.
14. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ni Pọ́ọ̀lù gbájú mọ́, kí ló tún ṣe?
14 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará pé kí wọ́n máa ṣe “iṣẹ́ rere” kí wọ́n lè fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. (Héb. 10:24) Yàtọ̀ sí pé Pọ́ọ̀lù máa ń sọ ohun tó ń gbé àwọn ará ró, ó tún máa ń ṣoore fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí ìyàn mú àwọn ará ní Jùdíà, Pọ́ọ̀lù wà lára àwọn tó lọ pín nǹkan fún wọn. (Ìṣe 11:27-30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni ni Pọ́ọ̀lù gbájú mọ́, ó tún máa ń fún àwọn èèyàn lóhun tí wọ́n nílò. (Gál. 2:10) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe yìí jẹ́ káwọn ará gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa bójú tó àwọn. Bákan náà lónìí, tá a bá ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ẹ̀bùn wa láti ran àwọn ará tí àjálù dé bá lọ́wọ́, àwa náà ń gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará wa ró nìyẹn. A tún ń gbé ìgbàgbọ́ wọn ró tá a bá ń fowó ṣètìlẹyìn déédéé fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì, ó máa jẹ́ káwọn ará wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní fi wọ́n sílẹ̀.
15-16. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára?
15 Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára sú òun. Pọ́ọ̀lù máa ń fàánú hàn sáwọn ará, ó sì máa ń sọ̀rọ̀ tó tù wọ́n lára. (Héb. 6:9; 10:39) Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “ká” àti “a” jálẹ̀ lẹ́tà náà láti fi hàn pé òun náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tóun fún àwọn ará. (Héb. 2:1, 3) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a ò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára sú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa ràn wọ́n lọ́wọ́, àá sì máa fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí wọn, ìyẹn ló máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn lóòótọ́. Torí náà, tá a bá ń sọ ọ̀rọ̀ tó tura fáwọn ará wa, ìyẹn máa gbé wọn ró.
16 Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí àwọn ará mọ̀ pé Jèhófà mọyì iṣẹ́ rere tí wọ́n ń ṣe. (Héb. 10:32-34) Àwa náà lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù tá a bá fẹ́ ran ẹnì kan tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ ò lágbára lọ́wọ́. A lè ní kó sọ bó ṣe kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fún wa, kó sì tún ronú nípa àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn án lọ́wọ́. A lè lo àǹfààní yìí láti jẹ́ kó mọ̀ pé Jèhófà ò gbàgbé àwọn nǹkan tó ti ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ àti pé Jèhófà ò ní fi í sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 6:10; 13:5, 6) Tá a bá ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí, á jẹ́ kó wù wọ́n láti máa sin Jèhófà nìṣó.
“Ẹ MÁA FÚN ARA YÍN NÍṢÌÍRÍ”
17. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ máa gbé àwọn ará ró?
17 Bí kọ́lékọ́lé kan bá ṣe ń kọ́lé sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa mọṣẹ́ sí i. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń gbé àwọn ará wa ró, àá túbọ̀ máa sunwọ̀n sí i. A lè fún àwọn ará lókun láti fara da ìṣòro tá a bá ń sọ ìrírí àwọn ará wa tó ti fara da ìṣòro fún wọn. A lè mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ tá a bá ń sọ ibi táwọn ará wa dáa sí, tá ò sì bá ara wa jà tí èdèkòyédè bá wáyé. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ ká tètè máa yanjú aáwọ̀ láàárín ara wa, ká sì máa gbé àwọn ará wa ró. A sì tún lè mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará lágbára tá a bá ń fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì hàn wọ́n, tá à ń ṣoore fún wọn, tá a sì ń ran àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn ò lágbára lọ́wọ́.
18. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?
18 Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run máa ń láyọ̀, wọ́n sì máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn. Àwa náà máa láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tá a bá ń ran àwọn ará lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára. Ilé tá a kọ́ lè wó kó sì pa run, àmọ́ ìrànlọ́wọ́ tá a ṣe fáwọn ará wa láti gbé wọn ró máa wà lọ́kàn wọn títí láé! Torí náà, ẹ jẹ́ ká ‘máa fún ara wa níṣìírí, ká sì máa gbé ara wa ró.’—1 Tẹs. 5:11.
ORIN 100 Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò
a Nǹkan ò rọrùn nínú ayé burúkú tá à ń gbé yìí. Ọ̀pọ̀ ìṣòro làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sì ń dojú kọ. Àmọ́, tá a bá ń wá bá a ṣe lè gbé wọn ró kára lè tù wọ́n, wọ́n á rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa gbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ká lè mọ bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
b ÀWÒRÁN: Bàbá kan ń fi ohun kan han ọmọ ẹ̀ nínú ìwé wa, kọ́mọ náà lè mọ bó ṣe máa ṣàlàyé ìdí tí kò fi yẹ kóun ṣe Kérésìmesì.
c ÀWÒRÁN: Tọkọtaya kan lọ sí apá ibì kan lórílẹ̀-èdè wọn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá.
d ÀWÒRÁN: Alàgbà kan lọ wo arákùnrin kan tí ìgbàgbọ́ ẹ̀ ò lágbára mọ́. Ó fi àwòrán Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà tí wọ́n jọ lọ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn hàn án. Àwọn àwòrán yẹn jẹ́ kí arákùnrin náà rántí bí inú wọn ṣe ń dùn nígbà yẹn. Ó ń wu arákùnrin náà pé kóun máa fayọ̀ sin Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀. Nígbà tó yá, ó pa dà sínú ìjọ.