ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 52
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́bìnrin, Ẹ Jẹ́ Kí Òtítọ́ Jinlẹ̀ Nínú Yín
“Kí àwọn obìnrin pẹ̀lú . . . má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.”—1 TÍM. 3:11.
ORIN 133 Sin Jèhófà Nígbà Ọ̀dọ́
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Tí Kristẹ́ni kan bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú òun, kí ló yẹ kó ṣe?
Ó MÁA ń yà wá lẹ́nu gan-an bá a ṣe ń rí i táwọn ọmọdé ń yára dàgbà. Ńṣe làwọn àyípadà yẹn máa ń ṣàdédé wáyé bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa Kristẹ́ni ò rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wa.b (1 Kọ́r. 13:11; Héb. 6:1) Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. A tún gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ká kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe wá láǹfààní, ká sì múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tá a máa ní lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 1:5.
2. Kí la rí kọ́ nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:27, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nígbà tí Jèhófà dá àwa èèyàn, akọ àti abo ló dá wa. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27.) Ó hàn gbangba pé ìrísí ọkùnrin yàtọ̀ sí ti obìnrin, àmọ́ wọ́n tún yàtọ̀ síra láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe kan, torí náà ó yẹ kí wọ́n láwọn ànímọ́ tó dáa, kí wọ́n sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe náà. (Jẹ́n. 2:18) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan tí ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan lè ṣe kó lè di obìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò nǹkan táwọn ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni náà lè ṣe.
ÀWỌN ÀNÍMỌ́ TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÓ O NÍ
3-4. Ibo ni àwọn ọ̀dọ́bìnrin ti lè rí àwọn obìnrin rere tí wọ́n lè fara wé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn obìnrin oníwà rere tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì sìn ín. (Wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Obìnrin inú Bíbélì—Kí La Rí Kọ́ Lára Wọn?” lórí jw.org.) Wọn kì í ṣe “aláṣejù,” “wọ́n [sì] jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo” bí ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé ṣe sọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin máa rí àwọn obìnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ìjọ wọn, tí wọ́n lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
4 Ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin, ẹ máa rí àwọn obìnrin rere nínú ìjọ yín tẹ́ ẹ lè fara wé. Ẹ máa kíyè sáwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wo bẹ́ ẹ ṣe lè láwọn ànímọ́ náà. Nínú àwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ mẹ́ta tó ṣe pàtàkì táwọn obìnrin rere gbọ́dọ̀ ní.
5. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn obìnrin Kristẹni nírẹ̀lẹ̀?
5 Ó ṣe pàtàkì pé káwa Kristẹni nírẹ̀lẹ̀. Tí obìnrin kan bá nírẹ̀lẹ̀, ó máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn. (Jém. 4:6) Bí àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìrẹ̀lẹ̀ máa jẹ́ kó tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà tó sọ pé orí obìnrin ni ọkùnrin. (1 Kọ́r. 11:3) A lè lo ìlànà yìí nínú ìjọ àti nínú ìdílé.c
6. Kí lẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin lè kọ́ lára Rèbékà tó bá dọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ̀?
6 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Rèbékà yẹ̀ wò. Obìnrin tó gbọ́n tó sì nígboyà ni, ìyẹn ló mú kó ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. (Jẹ́n. 24:58; 27:5-17) Síbẹ̀, ó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn ọkùnrin, ó sì máa ń tẹrí ba fún wọn. (Jẹ́n. 24:17, 18, 65) Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin, tẹ́ ẹ bá nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Rèbékà, tẹ́ ẹ sì ń ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà ní kó máa bójú tó ìdílé àti ìjọ, ẹ máa jẹ́ àpẹẹrẹ rere.
7. Báwo làwọn ọ̀dọ́bìnrin ṣe lè mọ̀wọ̀n ara wọn bíi ti Ẹ́sítà?
7 Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni lànímọ́ míì tó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ní. Bíbélì sọ pé “ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.” (Òwe 11:2) Obìnrin tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, tó sì bẹ̀rù Ọlọ́run ni Ẹ́sítà. Torí pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, kò gbéra ga nígbà tó di ayaba. Nígbà tí Módékáì ìbátan ẹ̀ tó jù ú lọ gbà á nímọ̀ràn, ó ṣe ohun tó sọ. (Ẹ́sít. 2:10, 20, 22) Torí náà, tó o bá ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà ẹ̀ nímọ̀ràn tó dáa, tó o sì ṣe ohun tí wọ́n sọ, ìyẹn á fi hàn pé o mọ̀wọ̀n ara ẹ.—Títù 2:3-5.
8. Bí 1 Tímótì 2:9, 10 ṣe sọ, báwo ni arábìnrin kan ṣe lè mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ tó bá fẹ́ múra?
8 Ẹ́sítà tún ṣe nǹkan míì tó fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀. Obìnrin yìí “lẹ́wà gan-an, ìrísí rẹ̀ sì fani mọ́ra,” síbẹ̀ kò fi ẹwà tó ní ṣe fọ́rífọ́rí. (Ẹ́sít. 2:7, 15) Ẹ̀kọ́ wo ni obìnrin Kristẹni kan lè kọ́ lára Ẹ́sítà? Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ náà wà nínú 1 Tímótì 2:9, 10. (Kà á.) Nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn obìnrin Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa múra lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn, wọ́n sì láròjinlẹ̀. Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni pé obìnrin Kristẹni kan gbọ́dọ̀ máa wọ aṣọ tó buyì kúnni, kí aṣọ náà sì fi hàn pé ó gba tàwọn ẹlòmíì rò. A mọyì ẹ̀yin arábìnrin wa gan-an torí pé ẹ máa ń múra dáadáa!
9. Kí la rí kọ́ lára Ábígẹ́lì?
9 Ànímọ́ míì tó yẹ kí gbogbo àwọn obìnrin Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ní ni ìfòyemọ̀. Kí ni ìfòyemọ̀? Ìfòyemọ̀ ni kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, kó sì ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábígẹ́lì yẹ̀ wò. Ọkọ ẹ̀ ṣe ìpinnu kan tí ò dáa, ìyẹn sì máa kó gbogbo ìdílé wọn síṣòro. Ábígẹ́lì ò fọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rárá, ojú ẹsẹ̀ ló gbé ìgbésẹ̀. Torí pé ó jẹ́ olóye, ó gba agbo ilé ẹ̀ là. (1 Sám. 25:14-23, 32-35) Ìfòyemọ̀ tún máa ń jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àtìgbà tó yẹ ká dákẹ́. Bákan náà, tá a bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, ìfòyemọ̀ máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ láì tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn.—1 Tẹs. 4:11.
KỌ́ ÀWỌN NǸKAN TÓ MÁA ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ
10-11. Tó o bá mọ̀wé kọ tó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa, báwo nìyẹn ṣe máa ṣe ìwọ àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ó yẹ kí obìnrin Kristẹni kan kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe é láǹfààní. Àwọn nǹkan tí ọmọbìnrin kan bá kọ́ nígbà tó wà ní kékeré máa ràn án lọ́wọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan.
11 Kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Láwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, wọ́n gbà pé kò pọn dandan kí obìnrin kọ́ bó ṣe lè mọ̀wé kọ, kó sì mọ̀ ọ́n kà. Àmọ́, gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká mọ̀wé kọ, ká sì mọ̀ ọ́n kà.d (1 Tím. 4:13) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti kọ́ bó o ṣe lè mọ̀wé kọ, kó o sì mọ̀ ọ́n kà dáadáa. Àǹfààní wo lo máa rí? Á jẹ́ kó o ríṣẹ́ tí wàá fi máa gbọ́ bùkátà ara ẹ, tí ò sì ní bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á sì jẹ́ kíwọ náà di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. Àmọ́ àǹfààní tó dáa jù tó o máa rí bó o ṣe ń ka Bíbélì, tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀ ni pé á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—Jóṣ. 1:8; 1 Tím. 4:15.
12. Báwo ni Òwe 31:26 ṣe jẹ́ kó o mọ bó o ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?
12 Kọ́ bá a ṣe ń béèyàn sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń tẹ́tí sílẹ̀. Ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni kọ́ bá a ṣe máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa. Ìdí nìyẹn tí Jémíìsì fi gbà wá nímọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní, ó ní: ‘Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n sì lọ́ra láti sọ̀rọ̀.’ (Jém. 1:19) Tó o bá ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀, á jẹ́ kó o fọ̀rọ̀ ẹni náà ro ara ẹ wò tàbí kó o bá a “kẹ́dùn.” (1 Pét. 3:8) Tó o bá rí i pé ohun tẹ́ni náà ń sọ ò yé ẹ tàbí tó ò mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀, bi í láwọn ìbéèrè tó yẹ. Lẹ́yìn náà, ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀. (Òwe 15:28, àlàyé ìsàlẹ̀) Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé òótọ́ ni mo fẹ́ sọ, ṣé ó sì máa gbé ẹni náà ró? Ṣé ohun tí mo fẹ́ sọ ò ní kó ìtìjú bá a, táá sì fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀?’ Máa kíyè sí àwọn arábìnrin tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, kó o sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. (Ka Òwe 31:26.) Máa kíyè sí ohun tí wọ́n ń sọ àti bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́. Bó o bá ṣe mọ bá a ṣe ń béèyàn sọ̀rọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àárín ìwọ àtàwọn èèyàn á ṣe gún régé tó.
13. Báwo lo ṣe lè kọ́ béèyàn ṣe ń bójú tó ilé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Kọ́ béèyàn ṣe ń bójú tó ilé. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn obìnrin ló sábà máa ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ ilé. Mọ́mì ẹ tàbí arábìnrin míì tó mọṣẹ́ ilé ṣe dáadáa lè kọ́ ẹ láwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Cindy sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tí mọ́mì mi kọ́ mi ni pé téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ kára, ó máa láyọ̀. Bí mo ṣe kọ́ bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ, bí wọ́n ṣe ń ṣe ìmọ́tótó ilé, bí wọ́n ṣe ń ránṣọ àti bí wọ́n ṣe ń ra nǹkan lọ́jà ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi rọrùn, ó sì ti jẹ́ kí n lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Mọ́mì mi tún kọ́ mi bí mo ṣe lè máa ṣe àlejò, ìyẹn sì jẹ́ kí n mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin àtàtà tí mo lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.” (Òwe 31:15, 21, 22) Torí náà, tí obìnrin kan bá ń ṣiṣẹ́ kára, tó ń ṣàlejò, tó sì ti kọ́ béèyàn ṣe ń bójú tó ilé, ó máa wúlò fún ìdílé ẹ̀ àti ìjọ.—Òwe 31:13, 17, 27; Ìṣe 16:15.
14. Kí lo kọ́ lára Crystal, kí lo sì pinnu pé wàá ṣe?
14 Kọ́ bó o ṣe lè ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó ṣe pàtàkì kí gbogbo àwa Kristẹni ní ìtẹ́lọ́rùn. (Fílí. 4:11) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Crystal sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ girama, àwọn òbí mi gbà mí nímọ̀ràn pé kí n kọ́ṣẹ́ ọwọ́ níbẹ̀ kó lè wúlò fún mi lọ́jọ́ iwájú. Bàbá mi sọ pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣirò owó, ìyẹn sì ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Kéèyàn kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ owó nìkan ò tó, ó tún yẹ kó o kọ́ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. (Òwe 31:16, 18) Torí náà, tó o bá jẹ́ káwọn nǹkan tó o ní tẹ́ ẹ lọ́rùn, tó ò sì tọrùn bọ gbèsè, wàá lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.—1 Tím. 6:8.
MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ
15-16. Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ? (Máàkù 10:29, 30)
15 Tó o bá láwọn ànímọ́ Kristẹni, tó o sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní, wàá lè ṣe àwọn ojúṣe tó o máa ní lọ́jọ́ iwájú dáadáa. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe.
16 O lè pinnu pé o ò ní lọ́kọ fáwọn àkókò kan. Nítorí ohun tí Jésù sọ, àwọn obìnrin kan ti pinnu pé àwọn ò ní lọ́kọ, kódà tí àṣà ìbílẹ̀ wọn ò bá tiẹ̀ fàyè gbà á. (Mát. 19:10-12) Àwọn míì sì lè pinnu pé àwọn ò ní lọ́kọ nítorí àwọn ìdí kan. Mọ̀ dájú pé Jèhófà àti Jésù ò fojú àbùkù wo àwọn Kristẹni tí ò lọ́kọ. Kárí ayé làwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ ti ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ìjọ. Bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn, tí wọ́n sì ń jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wọ́n lógún ti jẹ́ kí wọ́n di arábìnrin àti ìyá ọ̀pọ̀ àwọn ará.—Ka Máàkù 10:29, 30; 1 Tím. 5:2.
17. Kí ni ọ̀dọ́bìnrin kan lè ṣe kó lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún?
17 O lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn obìnrin Kristẹni ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. (Sm. 68:11) Ṣé o lè ṣètò àkókò ẹ báyìí kó o lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? O lè di aṣáájú-ọ̀nà, o lè yọ̀ǹda ara ẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run tàbí kó o lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Gbàdúrà nípa nǹkan tó o fẹ́ ṣe. Bá àwọn tó ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sọ̀rọ̀, kó o sì ní kí wọ́n sọ ohun tó o lè ṣe kó o lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn náà, ṣètò bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀. Tọ́wọ́ ẹ bá tẹ àfojúsùn ẹ, wàá lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
18. Kí nìdí tó fi yẹ kí arábìnrin kan fara balẹ̀ yan ọkọ tó máa fẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 O lè pinnu pé wàá lọ́kọ. Àwọn ànímọ́ Kristẹni àtàwọn nǹkan tó o lè kọ́ tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di aya tó dáńgájíá. Torí náà, tó o bá ń ronú láti lọ́kọ, ó yẹ kó o fara balẹ̀ yan ẹni tó o máa fẹ́. Ọ̀kan lára ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù tó o máa ṣe láyé ẹ nìyẹn. Rántí pé ọkọ tó o bá fẹ́ ni Ọlọ́run sọ pé ó máa jẹ́ orí ẹ. (Róòmù 7:2; Éfé. 5:23, 33) Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ni? Ṣé ìjọsìn Jèhófà gbawájú láyé ẹ̀? Ṣé ó máa ń ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu? Ṣé ó máa ń gbà pé òun ṣàṣìṣe? Ṣé ó máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin? Ṣé á jẹ́ kí n túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ṣé á lè pèsè àwọn nǹkan tí mo nílò, tá á sì dúró tì mí nígbà ìṣòro? Ṣé ó máa ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n gbé fún un nínú ìjọ dáadáa? Bí àpẹẹrẹ, àwọn iṣẹ́ wo ló ń bójú tó nínú ìjọ, ṣé ọwọ́ pàtàkì ló sì fi mú wọn?’ (Lúùkù 16:10; 1 Tím. 5:8) Ká sòótọ́, tó o bá fẹ́ rí ọkọ rere, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé o máa jẹ́ aya rere.
19. Kí nìdí tó fi yẹ kínú aya kan máa dùn torí pé Bíbélì pè é ní “olùrànlọ́wọ́”?
19 Bíbélì sọ pé aya rere máa jẹ́ “olùrànlọ́wọ́” ọkọ àti “ẹnì kejì” rẹ̀. (Jẹ́n. 2:18) Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ò bu àwọn aya kù? Rárá o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni bó ṣe jẹ́ olùrànlọ́wọ́ buyì kún un. Kódà, Bíbélì sábà máa ń pe Jèhófà ní “olùrànlọ́wọ́.” (Sm. 54:4; Héb. 13:6) Aya kan máa fi hàn pé lóòótọ́ lòun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ tó bá ń ti ọkọ ẹ̀ lẹ́yìn, tí kì í sì í ta ko àwọn ìpinnu tọ́kọ ẹ̀ bá ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí orúkọ rere tí ọkọ ẹ̀ ní má bàa bà jẹ́. (Òwe 31:11, 12; 1 Tím. 3:11) Torí náà, tó o bá fẹ́ ṣe ojúṣe tó o máa ní lọ́jọ́ iwájú dáadáa, jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára, kó o sì máa ran àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ àtàwọn ará ìjọ lọ́wọ́.
20. Àwọn nǹkan rere wo ni ìyá kan lè ṣe fún ìdílé ẹ̀?
20 O lè di ìyá. Lẹ́yìn tó o bá lọ́kọ, ó ṣeé ṣe kíwọ àti ọkọ ẹ bímọ. (Sm. 127:3) Torí náà, á dáa kó o ronú ṣáájú nípa àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o di ìyá rere. Àwọn ànímọ́ Kristẹni àtàwọn nǹkan tó o lè kọ́ tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá lọ́kọ tó o sì bímọ. Tó o bá ń fìfẹ́ hàn, tó ò ń finúure hàn, tó o sì ń ní sùúrù, ìdílé ẹ máa láyọ̀, ọkàn àwọn ọmọ ẹ á sì balẹ̀.—Òwe 24:3.
21. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn arábìnrin wa ṣe rí lára ẹ, kí sì nìdí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
21 A nífẹ̀ẹ́ ẹ̀yin arábìnrin wa gan-an nítorí gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹ̀. (Héb. 6:10) Ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ kára láti ní àwọn ànímọ́ Kristẹni, ẹ̀ ń kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe ẹ̀yin àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní, ẹ sì ń múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú. Ètò Ọlọ́run mọyì yín gan-an nítorí àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe yìí!
ORIN 137 Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa
a A mọyì ẹ̀yin ọ̀dọ́bìnrin tẹ́ ẹ wà nínú ìjọ gan-an. Ẹ máa di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti ní àwọn ànímọ́ tó dáa, tẹ́ ẹ kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe yín láǹfààní, tẹ́ ẹ sì ń múra sílẹ̀ de àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ máa ní lọ́jọ́ iwájú. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ẹ máa gbádùn ọ̀pọ̀ ohun rere lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí òun, kì í sì í jẹ́ kí ọgbọ́n ayé yìí darí òun. Ó máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó sì máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn látọkàn wá.
d Kó o lè mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa kàwé, wo àpilẹ̀kọ náà “Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?” lórí jw.org.