Sí Àwọn Ará Éfésù
5 Nítorí náà, ẹ máa fara wé Ọlọ́run,+ bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, 2 kí ẹ sì máa rìn nínú ìfẹ́,+ bí Kristi pẹ̀lú ṣe nífẹ̀ẹ́ wa,*+ tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún wa* bí ọrẹ àti ẹbọ, tó jẹ́ òórùn dídùn sí Ọlọ́run.+
3 Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe* àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín,+ bí ó ṣe yẹ àwọn èèyàn mímọ́;+ 4 bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà àìnítìjú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ẹ̀fẹ̀ rírùn,+ àwọn ohun tí kò yẹ, dípò bẹ́ẹ̀ kí ẹ máa dúpẹ́.+ 5 Nítorí ẹ mọ èyí, ó sì ṣe kedere sí ẹ̀yin fúnra yín, pé kò sí oníṣekúṣe* kankan+ tàbí aláìmọ́ tàbí olójúkòkòrò,+ tó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà, tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú Ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.+
6 Ẹ má ṣe jẹ́ kí èèyàn kankan fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ, ìdí ni pé torí irú àwọn nǹkan yìí ni ìrunú Ọlọ́run ṣe ń bọ̀ lórí àwọn ọmọ aláìgbọràn. 7 Nítorí náà, ẹ má ṣe di alájọpín pẹ̀lú wọn; 8 nítorí pé ẹ jẹ́ òkùnkùn nígbà kan rí, àmọ́ ẹ ti di ìmọ́lẹ̀+ báyìí nínú Olúwa.+ Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀, 9 nítorí pé oríṣiríṣi ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ ló jẹ́ èso ìmọ́lẹ̀.+ 10 Ẹ máa wádìí dájú ohun tí Olúwa tẹ́wọ́ gbà;+ 11 ẹ sì jáwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ tí kò lérè tó jẹ́ ti òkùnkùn;+ ṣe ni kí ẹ tú wọn fó. 12 Torí pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe níkọ̀kọ̀ ń tini lójú láti sọ. 13 Gbogbo nǹkan tí à ń tú síta* ni ìmọ́lẹ̀ ń fi hàn kedere, torí pé gbogbo ohun tí à ń fi hàn kedere jẹ́ ìmọ́lẹ̀. 14 Torí náà la ṣe sọ pé: “Jí, ìwọ olóorun, sì dìde láti inú ikú,+ Kristi yóò sì tàn sórí rẹ.”+
15 Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, 16 kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ,*+ torí pé àwọn ọjọ́ burú. 17 Torí náà, ẹ yéé ṣe bí aláìnírònú, àmọ́ ẹ máa fi òye mọ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà* jẹ́.+ 18 Bákan náà, ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara,+ torí ó ń yọrí sí ìwà pálapàla,* àmọ́ ẹ máa kún fún ẹ̀mí. 19 Ẹ máa fi àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara yín sọ̀rọ̀, kí ẹ máa kọrin+ sí Jèhófà,*+ kí ẹ sì máa fi ohùn orin+ gbè é nínú ọkàn yín, 20 ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo+ lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba wa lórí ohun gbogbo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi.+
21 Ẹ máa tẹrí ba fún ara yín+ nínú ìbẹ̀rù Kristi. 22 Kí àwọn aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ+ wọn bíi fún Olúwa, 23 nítorí ọkọ ni orí aya rẹ̀+ bí Kristi ṣe jẹ́ orí ìjọ,+ òun sì ni olùgbàlà ara yìí. 24 Kódà, bí ìjọ ṣe ń tẹrí ba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya máa ṣe fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo. 25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín,+ bí Kristi ṣe nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún un,+ 26 kí ó lè sọ ọ́ di mímọ́, kí ó fi omi wẹ̀ ẹ́ mọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà,+ 27 kí ó lè mú ìjọ wá síwájú ara rẹ̀ nínú ògo, láìní ìdọ̀tí kan tàbí ìhunjọ kan tàbí èyíkéyìí nínú irú àwọn nǹkan yìí,+ àmọ́ kí ó jẹ́ mímọ́ kí ó má sì lábààwọ́n.+
28 Lọ́nà kan náà, kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn bí ara wọn. Ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, 29 torí pé kò sí èèyàn kankan tó jẹ́ kórìíra ara* rẹ̀, àmọ́ á máa bọ́ ara rẹ̀, á sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, bí Kristi ti ń ṣe sí ìjọ, 30 nítorí a jẹ́ ẹ̀yà ara rẹ̀.+ 31 “Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan.”+ 32 Àṣírí mímọ́+ yìí ga lọ́lá. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ nípa Kristi àti ìjọ ni mò ń sọ.+ 33 Síbẹ̀, kálukú yín gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀+ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; bákan náà, kí aya ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.+