Ikọ́ Fée Jà Padà!
LÁTI àwọn ọdún 1950, iye ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ fée (TB) ti dín kù ní United States, ní ìwọ̀n ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, láti 1985, iye ìṣẹ̀lẹ̀ TB tí a ròyìn ti ní ìbísí ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún. Èyí tí ó túbọ̀ dani láàmú pàápàá ni oríṣi tuntun àrùn náà tí kì í gbóògùn. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àrun TB ń pa bí àádọ́jọ ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́dọọdún. Èé ṣe tí ìgbógun ti àrùn TB kò fi gbéṣẹ́ mọ́?
Ìdí kan ni pé ọ̀pọ̀ olùgbàtọ́jú kì í lo egbòogi wọn fún àkókò tí ó yẹ—tí ó sábà máa ń jẹ́ oṣù mẹ́fà sí mẹ́sàn-án. Fún àpẹẹrẹ, ní New York City, ìwádìí kan fi hàn pé ìpín 89 nínú ọgọ́rùn-ún àwùjọ 200 olùgbàtọ́jú tí àrun TB náà ń bá jà lọ́wọ́lọ́wọ́, kò gba ìtọ́jú wọn pé. Dókítà Lee Reichman, ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìtọ́jú Ẹ̀dọ̀fóró Nílẹ̀ America, sọ pé: “Èyíinì burú jáì, nítorí pé àwọn ènìyàn yẹn (a) kì yóò sàn, àti pé (b) ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní àrùn TB tí àwọn egbòogi tí ó wọ́pọ̀ kì yóò lè kojú.” Ṣùgbọ́n àwọn alárùn wọ̀nyí lè ṣàkóbá tí ó ju ti ìlera tiwọn fúnra wọn lọ. Dókítà Reichman fi kún un pé: “Nípa àìlo egbòogi wọn tán, wọ́n lè kó o ran àwọn mìíràn.” Láìsí iyè méjì, èyí ti jẹ́ kókó kan tí ó fa ìròyìn àfojúbù mílíọ̀nù mẹ́jọ ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun tí a ń dá mọ̀ kárí ayé lọ́dọọdún.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ‘àwọn àjàkálẹ̀ àrùn láti ibì kan dé ibòmíràn’ jẹ́ apá kan àmì pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí. (Lúùkù 21:11; Tímótì Kejì 3:1) Kí ni yóò tẹ̀ lé e? Ayé tuntun kan, nínú èyí tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Aísáyà 33:24) Bẹ́ẹ̀ ni, ìlérí Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe fún ìtura onígbà díẹ̀, bí kò ṣe ìdásílẹ̀ pátápátá lọ́wọ́ àìsàn àti ikú.—Ìṣípayá 21:1-4.