Ọ̀rẹ́ Rẹ́rùnrẹ́rùn
NÍ 1959, àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ní United States sọ tẹ́lẹ̀ pé ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) kò ní pẹ́ tán nílẹ̀. Ní tòótọ́, ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e, àrùn náà yára kúrò nílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi rò pé a ti rí tirẹ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n ikọ́ ẹ̀gbẹ tún ti dé, òun àti ọ̀rẹ́ rẹ́rùnrẹ́rùn kan—HIV, fáírọ́ọ̀sì tí ń sọ ìgbékalẹ̀ ìdènà àrùn nínú ara di aláìlera, tí ó sì sábà máa ń yọrí sí àrùn AIDS.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn tí iye wọn lé ní bílíọ̀nù kan—nǹkan bí ìdá mẹ́ta iye àwọn olùgbé ayé—ló ní bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ, nígbà tí ó kọ́kọ́ kọ lu àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n wà nínú ewu níní àrùn náà ní ìwọ̀n ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún ìgbà tí wọn óò fi wà láàyè. A mọ̀ pé, àwọn tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì HIV wà nínú ewu níní àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ lójú méjèèjì ní ìwọ̀n ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dọọdún. Nítorí náà, bí ènìyàn púpọ̀ sí i ti ń kó fáírọ́ọ̀sì HIV ni ewu kíkó àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí ènìyàn púpọ̀ sí i.
Dókítà Richard J. O’Brien ti àjọ WHO (Àjọ Ìlera Àgbáyé) sọ pé ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn tí àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ ń kọ lù ní United States ti fi nǹkan bí ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ó sọ pé, èyí jẹ́ “ní pàtàkì, nítorí àjọṣe tó wà láàárín fáírọ́ọ̀sì HIV àti ikọ́ ẹ̀gbẹ.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ni ewu náà ti le koko jù lọ. Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù lọ ni odindi ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ lù ti ń ṣẹlẹ̀, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta lára àwọn alárùn wọ̀nyí ló sì ń kú.
Jákèjádò ayé, nǹkan bí mílíọ̀nù 4.4 ènìyàn ni àwọn àrùn panipani méjì náà ń bá fínra. Àjọ WHO sọ tẹ́lẹ̀ pé, ní àìpẹ́ sí àsìkò yìí, ikọ́ ẹ̀gbẹ yóò máa gbẹ̀mí mílíọ̀nù kan lára àwọn tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì HIV. Peter Piot, olùdarí àgbà Ètò Àpawọ́pọ̀ṣe Lórí Fáírọ́ọ̀sì HIV òun Àrùn AIDS ti Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé: “Àwọn àjàkálẹ̀ oníbejì yìí ti para pọ̀ di ewu ìlera tí ó le koko jù lọ lórí ará ìlú ní ẹ̀wádún yìí.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti New Jersey—Ibùdó Ìtọ́jú Ikọ́ Ẹ̀gbẹ