Àwọn Ìnira Ìgbà Ogun Mú Mi Gbára Dì fún Bá A Ṣeé Gbé Ìgbésí Ayé
GẸ́GẸ́ BÍ ERNST KRÖMER ṢE SỌ Ọ́
“Yàrá yín rèé.” Ọ̀rọ̀ yẹn ni wọ́n fi kí èmi àti èkejì mi káàbọ̀ sí orílẹ̀-èdè Gabon ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Ibùsùn nìkan ni yàrá yẹn lè gbà. Oṣù mẹ́fà la lò nínú yàrá náà.
ÌGBÉSÍ ayé tí mo gbé nínú oko lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì ló kọ́ mi béèyàn ṣeé gbé ìgbésí ayé nígbà tí nǹkan ò bá rọgbọ. Nígbà tí ogun náà bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1939, ìjọba Násì ti ilẹ̀ Jámánì gba ilẹ̀ Poland lẹ́yẹ-ò-sọkà. Ọmọ ọdún mẹ́rin ni mí nígbà yẹn. Àwọn òbí mi, àbúrò mi ọkùnrin àti àbúrò mi obìnrin, àtàwọn àǹtí mi méjì la para pọ̀ jẹ́ ìdílé kan. Bàbá wa sọ fún wa pé bí orílẹ̀-èdè Jámánì ò bá ṣẹ́gun, ká yáa máa gbára dì, torí nǹkan ò ní rọgbọ.
Abúlé àwọn ara Jámánì kan tó ń jẹ́ Löwenstein, tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú Silesia Ìsàlẹ̀ tó ti di apá kan Poland báyìí, là ń gbé. A gbin ọkà sínú oko wa tó tóbí tó hẹ́kítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, a sì tún ń sin àwọn ẹran ọ̀sìn níbẹ̀. Bàbá wa ni alákòóso àwọn àgbẹ̀ tó wà lágbègbè yẹn. Nígbà táwọn Násì gbàjọba, wọ́n ní kí Bàbá wa máa darí àwọn àgbẹ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ogun tó ń lọ lọ́wọ́.
Bàbá wa wà lára àwọn tó ja Ogun Àgbáyé Kìíní, àmọ́ iṣẹ́ tó wá ń ṣe lábẹ́ ìjọba Násì báyìí ni ò jẹ́ kí wọ́n kó o mọ́ àwọn tí wọ́n fipá mú wọṣẹ́ ológun. Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn òbí mi ti kọ̀wé fi Ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ nítorí pé ohun táwọn aṣáájú ìsìn ṣe lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní dùn wọ́n. Ohun tó fà á nìyí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìsìn ò sí lọ́kàn mi nígbà tí mo fi máa dàgbà.
Mo bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé lọ́dún 1941, ṣùgbọ́n mo kórìíra ẹ̀ nítorí mo rò pé mo láwọn nǹkan gidi láti ṣe tó kọjá kí n kàn máa ranjú mọ́ ojú pátákó kan lásán. Níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945, nígbà tó ku oṣù bíi mélòó kan kógun parí, àwọn ará Rọ́ṣíà kógun ja ìlú Breslau (tó ti di Wrocław báyìí), tí í ṣe olú ìlú Silesia Ìsàlẹ̀. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé kan, à ń wo ìlú yẹn ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta kìlómítà lọ́ọ̀ọ́kán, ó mọ́lẹ̀ yòó nítorí iná tó ń jó wìì-wìì-wìì àtàwọn bọ́ǹbù tó ń jábọ̀ látinú àwọn ọkọ̀ ojú òfuurufú. Nígbà tó yá, ó di pé a ní láti sá lọ síbi àwọn òkè. Nígbà tí ogun parí, a padà sílé wa lábúlé Löwenstein.
Ìgbẹ̀yìn Ogun Ò Rọrùn
Àtẹ̀yìnbọ̀ ogun náà ò dáa. Wọ́n fipá báwọn obìnrin lò pọ̀, wọ́n sì ń fọ́lé onílé lójoojúmọ́. Wọ́n fẹ́rẹ̀ jí gbogbo ẹran ọ̀sìn wa lọ tán.
Wọ́n mú Bàbá lóṣù July lọ́dún 1945. Lẹ́yìn ọjọ́ méje tí wọ́n fi fìyà jẹ ẹ́ níbi tí wọ́n ti ń fẹ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu ẹ̀ láàárín òru, wọ́n fi í sílẹ̀. Lóṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n tún mú un, wọ́n sì gbé e lọ. Àrímọ ẹ̀ nìyẹn. Àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ ara Poland wá gba oko wa wọ́n sì ní tàwọn ni. Ní oṣù April ọdún 1946 wọ́n ní kí gbogbo àwọn ara Jámánì tó wà lábúlé yẹn jáde kúrò níbẹ̀ kí wọ́n sì gbé kìkì ohun tí wọ́n bá lè gbé.
Màmá wa ti ń retí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí tẹ́lẹ̀, kò sì bẹ̀rù. Ó ti ní apẹ̀rẹ̀ onítáyà ńlá kan níbi tó kó àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀dì sí, gbogbo wa sì ní àwọn àpò tó ṣeé gbé kọ́rùn, níbi tá a kó gbogbo ohun tá a nílò sí. Àwọn ọmọ ogun Poland rọ́ gbogbo wa sínú ọkọ ojú irin tí wọ́n fi ń kó màlúù, ọgbọ̀n èèyàn nínú ọkọ̀ kékeré kan ṣoṣo. Nígbà tó fi máa tó bí ọ̀sẹ̀ méjì, a débi tí wọ́n ń kó wa lọ, níhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Jámánì níbi tí kò jìnnà sí orílẹ̀-èdè Netherlands.
Ìjọba fún ìdílé wa tó fi mọ́ àwọn ìbátan wa, tí gbogbo wa jẹ́ mọ́kàndínlógún, ní yàrà méjì nínú oko kan tí kò ju nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ sí ìlú Quakenbrück. Nígbà tó yá, wọ́n fún àwọn ìbátan wa níbi tí wọ́n lè máa gbé, pẹ̀lú àwọn àgbẹ̀ míì, àyè sì gbà wá díẹ̀ sí i.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Màmá fi du ara rẹ̀ nítorí àwa ọmọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kò ní jẹun kí àwa ọmọ bàa lè jẹun. A ò rí igi tá a lè fi dáná nígbà òtútù tá a kọ́kọ́ lò níbẹ̀. Yìnyín bo gbogbo ara ògiri àti orí àjà ilé wa, àwọn yàrá wa sì dà bí hòrò yìnyín. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn aṣọ bẹ́ẹ̀dì tó móoru tá a ní la fi rù ú là.
Bá A Ṣe Pàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí
Ní nǹkan bí ọdún 1949, Màmá gba ẹ̀dà kan ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ́wọ́ ìyàwó àbúrò rẹ̀ kan. Àpilẹ̀kọ kan nínú ẹ̀ mú kó rántí ohun tó gbọ́ tí Hitler ń sọ lórí rédíò nígbà ogun bó ṣe ń bẹnu àtẹ́ lu ‘àwùjọ àwọn èèyàn kan’ tí wọ́n sọ tẹ́lẹ̀ pé Ìjọba Jámánì yóò wó. Màmá ti ń ṣe kàyéfì nípa irú ẹni táwọn yìí á jẹ́. Nígbà tó wá kà á nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ó ru ú lọ́kàn sókè ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
Lọ́jọ́ kan, lóṣù April ọdún 1954, mo pàdé tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan, tí wọ́n ń kọ́ Màmá lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mo gba ìwé pẹlẹbẹ náà, Njẹ Iwọ lè Gbé orí Ilè-aiyé titilai ki Aiye Sì Tù K’o Bà fun Ọ bi?, mo sì san àsansílẹ̀ láti máa gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Bí mo ṣe ka ìwé pẹlẹbẹ náà báyìí, mo mọ̀ dájú pé mo ti rí òtítọ́. Nítorí náà, mo fún obìnrin tó gbà mí ṣíṣẹ́ pé kó kà á. Nígbà tí mo bi í léèrè pé báwo ló ṣe rí i sí, ó sọ pé: “Àwọn àlàyé tó wà nínú ẹ̀ dára gan-an, ṣùgbọ́n ó ti dùn kọjá kó lè jẹ́ òótọ́. Mi ò tiẹ̀ lè gbà á gbọ́ ni.”
Mo sọ fún un pé: “Toò, ó dá èmi lójú pé òótọ́ nìyí, ohun tí mo sì máa tẹ̀ lé nìyẹn.” Ó mi orí ẹ̀, ó sọ pé: “Èèyàn pẹ̀lẹ́ lọ̀rọ̀ yìí wà fún. Ìpátá tìẹ yìí ti pọ̀ kọjá kó o lè di Ẹlẹ́rìí.” Ṣùgbọ́n mo bẹ̀rẹ̀ sí yí ìgbésí ayé mi padà.
Bí ò tiẹ̀ sí Ẹlẹ́rìí kankan lágbègbè ibẹ̀ yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra mi, mo sì máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ sáwọn ìpàdé tó jìn tó bíi kìlómítà mẹ́wàá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn náà mo lọ sí àpéjọ àyíká, níbi tí ọ̀pọ̀ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí ti máa ń péjọ fún jíjọ́sìn. Ibẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ará. Nígbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù déédéé. Ní July 14, ọdún 1954, èmi àti Màmá ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ìyá ìyá mi náà di Ẹlẹ́rìí lẹ́ni ọgọ́rin ọdún.
Iṣẹ́ tí mò ń ṣe lóko ti ń gba àkókò tó pọ̀ jù lọ́wọ́ mi, nítorí náà mo fi iṣẹ́ yẹn sílẹ̀ mo sì gbaṣẹ́ síbi tí wọ́n ti ń bójú tó igbó tí wọ́n dá sí. Lẹ́yìn náà, ìdílé wa kó lọ sí Reutlingen, ìlú kékeré kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Stuttgart. Ìgbà tá a wà níbẹ̀ ni Ingrid, àbúrò mi obìnrin náà di Ẹlẹ́rìí, òun nìkan ló sì tíì di Ẹlẹ́rìí nínú àwọn ọmọ ìyá mi.
Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù Alákòókò Kíkún
Lọ́dún 1957, ó ṣeé ṣe lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn fún Màmá láti jẹ́ kí wọ́n forúkọ Bàbá sílẹ̀ bí olóògbé. Látàrí èyí, ó ṣeé ṣe fún un láti máa gba owó ìfẹ̀yìntì, èyí tá á lè má rí ná láìsí pé ó tún ń wojú mi mọ́. Nígbà tí mi ò sì ní bùkátà tí mò ń gbọ́ nínú ìdílé mọ́ báyìí, mo gbaṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà lóṣù April ọdún 1957. Lẹ́yìn náà, wọ́n ké sí mi pé kí n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Bí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi ṣe gbọ́ báyìí, ó pè mí lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì sọ pé, “Ó ṣeé ṣe kó o nílò àwọn nǹkan kan.” Ló bá fún mi ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] deutsche mark owó ilẹ̀ Jámánì. Nínú ẹ̀ ni mo ti ra gbogbo aṣọ tí mo nílò tó sì tún ṣẹ́ ku igba owó deutsche mark sílẹ̀.
Lọ́dún 1960, mo yọ̀ọ̀da ara mi láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè Austria. Níbẹ̀, mo gbádùn wíwàásù lábúlé Scheibbs àti ìwọ̀nba díẹ̀ tí mo ráyè ṣe ní ìlú Linz, ṣùgbọ́n nígbà tí ọdún náà ń parí lọ mo ṣubú lórí alùpùpù, ibú ọ̀hún lágbára débi pé mo fẹsẹ̀ mi ọ̀tún dá. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún mi, mo lè máa bá iṣẹ́ mi lọ. Àmọ́, lọ́dún 1962, ó di dandan fún mi láti padà sílé ní Reutlingen kí n lọ yanjú ìṣòro tó jẹ mọ́ àtigbé ìlú. Nígbà tí mo wà níbẹ̀ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ mìíràn fún mi láti yọ irin tí wọ́n fi sínú ẹsẹ̀ mí. Mo dáwọ́ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà dúró fún oṣù mẹ́fà kí n lè rówó tọ́jú ara mi.
Nígbà tí alábòójútó àyíká kan bẹ ìjọ tí mo wà wò, ó dábàá pé kí n kọ̀wé láti sọ pé mo nífẹ̀ẹ́ sí sísìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí tó wà ní Wiesbaden, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Mo kọ̀wé ọ̀hún, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n tẹ wáyà sí mi pé kí n máa bọ̀, wọ́n ní kí n dé bó bá ṣe lè yá tó. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, lóṣù May 1963, mo dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì tí wọ́n ń pè ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé.
Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Taápọntaápọn
Bẹ́tẹ́lì ni ibi tó dáa jù lọ tí mo tíì gbé rí láyé mi, kò sì pẹ́ tí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ fi mọ́ mi lára. Lọ́dún 1965, mo lọ́ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì, mo sì ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọlé ní bòókẹ́lẹ́, nítorí pé nígbà yẹn wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. Ìbẹ̀wò tí mò ń ṣe lákòókò yẹn ló mú kí n fẹ́ kọ́ èdè mìíràn, mo sì pinnu láti kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Gbogbo àǹfààní tí mo ní ni mo fi kẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ sí àkókò yìí ni wọ́n dá àwùjọ àkọ́kọ́ tó ń ṣèpàdé lédè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Jámánì, mo sì dara pọ̀ mọ́ wọn. Nígbà àkọ́kọ́ tí mo máa kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì, wákàtí méje ló gbà mí. Nígbà tí kò gbà ju wákàtí márùn-ún lọ lẹ́ẹ̀kejì, mo mọ̀ pé mo ti ń tẹ̀ síwájú.
Lọ́dún 1966, wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹtàlélógójì ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà níṣẹ́ míṣọ́nnárì. Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n rán èmi àti Günther Reschke lọ sí orílẹ̀-èdè Gabon ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, lóṣù April, ọdún 1967. Nígbà tá a dé ìlú Libreville, tí í ṣe olú ìlú Gabon inú ilé kótópó tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ yẹn la dé sí, a sì fi àwọn aṣọ wa kọ́ ibì kan nínú yàrá ìjẹun. Lóṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, a kó lọ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì mìíràn.
Babańlá ìṣòro tí mo dojú kọ lórílẹ̀-èdè Gabon ni kíkọ́ èdè Faransé. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, láìṣàárẹ̀ láìsinmi, mo gbọ́ èdè náà dé ìwọ̀n àyè kan. Lọ́dún 1970, wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa lórílẹ̀-èdè Gabon lójijì, wọ́n sì fún àwa míṣọ́nnárì lọ́sẹ̀ méjì péré láti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀.
Ó Di Orílẹ̀-Èdè Central African Republic
Wọ́n gbé èmi àtàwọn míṣọ́nnárì mìíràn lọ sí orílẹ̀-èdè Central African Republic. Èdè Faransé lèdè àjùmọ̀lò orílẹ̀-èdè náà, ṣùgbọ́n ká bàa lè wàásù fáwọn tó pọ̀ jù, ó di dandan fún wa ká kọ́ èdè Sango. Wọ́n ní ká lọ dá ilé mísọ́nnárì kan sílẹ̀ nílù Bambari, tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrín kìlómítà sílùú Bangui tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Kò síná mànàmáná, kò sì sómi ẹ̀rọ nílùú Bambari, ṣùgbọ́n àwọn ìjọ méjèèjì tó wà níbẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Ohun tójú mi rí nígbà ogun tó jà nílẹ̀ Yúróòpù ti jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti fi bí ìgbésí ayé ṣe rí nílùú Bambari àtàwọn ibòmíì tá a gbé lẹ́yìn náà kọ́ra.
Lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún méjì nílùú Bambari, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn àjò láti máa bẹ àwọn ìjọ wò. Nǹkan bí ogójì ìjọ péré ló wà lórílẹ̀-èdè náà, mo sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ tí wọ́n bá yàn fún mi láti bẹ̀ wò. Mo ní ọkọ̀ kékeré kan, ṣùgbọ́n nígbà táwọn ọ̀nà eléruku yẹn bá ti bà jẹ́ ju bó ṣe yẹ, mo máa ń lọ wọkọ̀ èrò.
Ìlú Bangui ni ibì kan ṣoṣo téèyàn ti lè rí mọ́tò tún ṣe ní gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ tèmi gba kí n máa rìnrìn àjò púpọ̀, mo ra àwọn ìwé kan tó dá lórí títún mọ́tò ṣe, mo wá àwọn irin iṣẹ́ díẹ̀, èmi fúnra mi ló sì máa ń tún mọ́tò mi ṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Lọ́jọ́ kan, ilé tí wọ́n ṣe fún ọ̀pá tó ń gbé mọ́tò rìn fọ́ nínú ẹ́ńjìnnì mọ́tò mi, mọ́tò bá ta kú. Á tó ọgọ́ta kìlómítà síbi tí mo wà kí n tó lè débi táwọn èèyàn ń gbé, mo bá kúkú gé igi tó gbópọn nínú igbó, mo gbẹ́ ẹ débi tá á fi lè gbé ọ̀pá náà dúró. Mo fi gírísì tó pọ̀ ra á, mo sì fi wáyà dè é mọ́ ọ̀pá náà, mo sì rọra kẹ́ ẹ síbẹ̀ kí n lè máa bá ìrìn àjò mi lọ.
Oríṣiríṣi ìṣòro lèèyàn máa ń bá pàdé téèyàn bá ń sìn nínú oko tó jìnnà sí ìgboro tàbí lábúlé tí ò fi bẹ́ẹ̀ lajú, nítorí pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà níbẹ̀. Nínú ìjọ kan báyìí, ẹnì kan péré ló mọ̀wé kà, ẹni ọ̀hún ò sì tún lè sọ̀rọ̀ kó já gaara. Ó ṣòro gan-an fún wa nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ṣùgbọ́n ó tún máa ń fún ìgbàgbọ́ èèyàn lókun nígbà téèyàn bá rí báwọn ará ìjọ ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé kókó tá à ń jíròrò yé àwọn.
Lẹ́yìn náà, mo béèrè àǹfààní tí wọ́n rí jẹ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ témi fúnra mi rí i pé kò yé wọn dáadáa. Ìdáhùn wọn tó ń wúni lórí ni pé: “Ibí yìí la ti ń fúnra wa níṣìírí.”—Hébérù 10:23-25.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni arákùnrin mi ò mọ̀wé, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n kọ́ mi nípa béèyàn ṣeé gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká “máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù” wá lọ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi dáadáa. (Fílípì 2:3) Àwọn arákùnrin mi nílẹ̀ Áfíríkà kọ́ mi ní ohun púpọ̀ nípa ìfẹ́, inú rere àti aájò àlejò, wọ́n sì tún kọ́ mi béèyàn ṣe ń gbé inú oko. Ọ̀rọ̀ ìdágbére tí Arákùnrin Nathan Knorr, tó jẹ́ ààrẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ lọ́jọ́ tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege wá nítumọ̀ sí mi gan-an. Nígbà yẹn ó sọ fún wa pé: “Ẹ máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ẹ má ṣe rò pé a mọ gbogbo nǹkan tán. A ò tíì mọ̀ ọ́n tán. Ohun tá a ní láti kọ́ ṣì pọ̀ gan-an.”
Ìgbésí Ayé Tí Mo Gbé Nínú Oko Nílẹ̀ Áfíríkà
Bí mo ṣe ń lọ láti ìjọ dé ìjọ, ilé àwọn arákùnrin tí mo bá ń bẹ ìjọ wọn wò ni mo máa ń dé sí. Bí ìgbà àjọ̀dún ni ọ̀sẹ̀ tí mo bá lò lọ́dọ̀ wọn máa ń rí, pàápàá lára àwọn ọmọdé. Ìdí ni pé àwọn ará ìjọ tí mò ń bẹ̀ wò a máa lọ ṣọdẹ tàbí kí wọ́n lọ pẹja, wọ́n á sì rí i dájú pé oúnjẹ pọ̀ tí tọmọdé tàgbà á fi rí jẹ.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ahéré táwọn arákùnrin ń gbé lèmi náà ń bá wọn gbé, gbogbo ohun tí wọ́n ń jẹ lèmi náà ń jẹ látorí ikán dórí erin, gbogbo ẹ̀ àjẹpọ̀. A sábà máa ń jẹ ọ̀bọ. Àjẹpọ́nnulá ni túrùkú àti òòrẹ̀. Àmọ́, ojoojúmọ́ kọ́ ló máa ń dà bí ọdún o. Àwọn oúnjẹ yẹn ò kọ́kọ́ mọ́ mi lára, àmọ́ nígbà tí wọ́n mọ́ mi lára tán, kò sí nǹkan tí ikùn mi kọ̀ mọ́. Mo kọ́ ọ pé jíjẹ ìbẹ́pẹ tòun ti kóró inú ẹ̀ dára fún ikùn èèyàn.
Oríṣiríṣi nǹkan téèyàn ò retí ló lè ṣẹlẹ̀ lábúlé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n rò pé yemọja ni mí, yemọja yìí ni wọ́n mọ̀ sí àǹjọ̀nnú òyìnbó kan tí wọ́n sọ pé o ti kú àmọ́ tí ẹ̀mí ẹ̀ ń gbé inú odò. Àwọn èèyàn gbà pé ó lè fa èèyàn sínú omi tá á sì ṣe é tí onítọ̀hún á fi mu omi yó. Nígbà kan tí mo jáde láti inú odò lẹ́yìn tí mo ti wẹ̀ tán, bí ọmọbìnrin kan tó wá pọnmi ṣe rí mi, ṣe ló feré gé e, tó ń pariwo bó ṣe ń sá lọ. Nígbà tí arákùnrin kan sì gbìyànjú láti ṣàlàyé fún wọn pé oníwàásù tó wá láti ibòmíì ni mí, àwọn èèyàn ò gbà á gbọ́. Wọ́n bá a jiyàn, wọ́n ní, “Òyìnbó kankan ò lè forí lé iyànníyàn inú igbó níbí.”
Ìtagbangba ni mo sábà máa ń sùn nítorí afẹ́fẹ́ tó tura tó ń fẹ́ yẹ́ẹ́ níbẹ̀. Mo máa ń sábà lo àwọ̀n ẹ̀fọn nítorí ejò, àkekèé, eku àtàwọn nǹkan míì. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ìjàlọ ti bò mí rí tó jẹ́ pé àwọ̀n ẹ̀fọn tí mo lò ló yọ mí. Lóru ọjọ́ kan mo tan tọ́ọ̀ṣì mi sí àwọ̀n yẹn, mo rí i pé àwọn ìjàlọ ti bò ó. Kíá ni mo bẹ́sẹ̀ mi sọ̀rọ̀ nítorí pé ìjàlọ ò ṣe e fojú di, bí wọ́n ṣe kéré tó yẹn, wọ́n lè pa kìnnìún pàápàá.
Nígbà tí mo wà lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Central African Republic, nítòsí Odò Kóńgò, mo wàásù fáwọn aràrá tí wọ́n ń pè ní Pygmy, àwọn tó jẹ́ pé inú igbó tí wọ́n ń gbé náà ni wọ́n ti máa ń wá oúnjẹ jẹ. Ògbójú ọdẹ làwọn èèyàn yìí, wọ́n sì mọ ohun tó yẹ kéèyàn jẹ àtèyí tí ò yẹ kéèyàn jẹ. Èdè Sango làwọn kan nínú wọn ń sọ, inú wọn sì máa ń dùn láti gbọ́rọ̀ Bíbélì. Wọ́n á ní ká padà wá bẹ àwọn wò, ṣùgbọ́n nígbà tá a bá fi máa padà débi tá a ti rí wọn, wọ́n á ti ṣí lọ síbòmíràn. Lákòókò tá à ń sọ yìí, kò sí èyíkéyìí nínú wọn tó di Ẹlẹ́rìí, àmọ́ mo gbọ́ pé àwọn aràrá kan pàpà di Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè olómìnira ti Kóńgò.
Ọdún márùn-ún ni mo fi ṣiṣẹ́ bí alábòójútó àyíká lórílẹ̀-èdè Central African Republic. Àwọn ìjọ tí mò ń bẹ̀ wò nínú igbó ló mú mi rìn èyí tó pọ̀ jù lára ìrìn àjò mi káàkiri orílẹ̀-èdè náà.
Iṣẹ́ Ìsìn Mi ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Nàìjíríà
Lóṣù May ọdún 1977, wọ́n ní kí n lọ sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Èkó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000 ] Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè térò pọ̀ sí jù nílẹ̀ Áfíríkà yìí nígbà náà, àwọn bí ọgọ́rin ló sì ń sìn ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà. Ẹ̀ka tí wọ́n ti ń tún ọkọ̀ ṣe ni wọ́n ní kí n ti máa ṣiṣẹ́, ara iṣẹ́ mi sì ni pé kí n máa bá wọn ṣiṣẹ́ lára àwọn ọkọ̀ tó bá ń fẹ́ àtúnṣe.
Lọ́dún 1979, mo padà sídìí iṣẹ́ oko, ìyẹn iṣẹ́ tí mo fi àárọ̀ ọjọ́ ayé mi ṣe nígbà tí mò ń dàgbà nílẹ̀ Yúróòpù. Oko tí wọ́n ti ń gbin oúnjẹ táwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ń jẹ wà ní Ilaro, tó fi bí ọgọ́rin kìlómítà jìnnà sílùú Èkó. Ibẹ̀ ló ti yé mi pé dídáko nínú ẹgàn ilẹ̀ olóoru yàtọ̀ sí irú oko tá à ń dá nílẹ̀ Yúróòpù. Lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́ta àbọ̀ níbẹ̀, mo padà sí Èkó, ibi tí wọ́n ti ń tún ọkọ̀ ṣe ni mo tún padà sí.
Lọ́dún 1986, wọ́n gbé mi lọ sí abúlé Igieduma, ìyẹn ní nǹkan bí ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [360] kìlómítà sí Èkó, wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ńlá tuntun kan síbẹ̀ nígbà yẹn. Ní January ọdún 1990 ni wọ́n yà á sí mímọ́. Lára àwọn ilé tí wọ́n kọ́ síbẹ̀ ni ilé ìtẹ̀wé, ilé kékeré kan tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ oko àtàwọn ilégbèé tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ. Orí ọgọ́ta hẹ́kítà ilẹ̀ tí wọ́n mọ ògiri tó ga tó mítà méjì yí po ni wọ́n kọ́ gbogbo ilé wọ̀nyí sí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, èmi ló ń bójú tó oko àti ìtọ́jú ilẹ̀, àwọn èèyàn márùndínlógójì ni mo sì ń bójú tó lẹ́nu iṣẹ́ yìí.
Láti nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n báyìí, Nàìjíríà ni mò ń gbé, mo sì ti gbádùn oríṣiríṣi iṣẹ́ tí mo ti ṣe ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà. Inú mi dùn pé màmá mi ṣì dúró bí olóòótọ́ ti Jèhófà àti pé Ingrid, àbúrò mi obìnrin tó fi ọdún mẹ́rìnlá sìn bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ṣì ń sin Jèhófà tòun tọkọ ẹ̀.
Láìka ti gbogbo ìṣòro tí mo dojú kọ sí, mo gbádùn sísin Jèhófà àti àwọn arákùnrin mi nípa tẹ̀mí ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Mo dúpẹ́ pé koko lara mi ń le títí di báyìí, àdúrà mi sì ni pé kí n máà rí àárẹ̀ kí n bàa lè máa fi taratara sin Jèhófà, Ọlọ́run ọlọ́lá ńlá nìṣó.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Nàìjíríà
Central African Republic
Gabon
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èmi àti Gertrud ìyá mi àti Ingrid àbúrò mi obìnrin lọ́dún 1939
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìgbà tí mò ń sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Gabon
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè Central African Republic, mo gbé nínú irú àwọn abúlé báyìí