ÌTÀN 64
Sólómọ́nì Kọ́ Tẹ́ńpìlì
KÍ DÁFÍDÌ tó kú, ó fún Sólómọ́nì ní àwọn àwòrán tí Ọlọ́run fún wọn fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ní ọdún kẹrin ìjọba Sólómọ́nì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì yẹn, ọdún méje àtààbọ̀ ló sì fi kọ́ ọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ṣiṣẹ́ níbi tẹ́ńpìlì náà, ó sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìnáwó dání. Ìdí ni pé wọ́n lo ọ̀pọ̀ wúrà àti fàdákà láti kọ́ ọ.
Tẹ́ńpìlì náà ní yàrá ńlá méjì, bíi ti àgọ́ ìjọsìn. Ṣùgbọ́n àwọn yàrá wọ̀nyí tóbi tó ìlọ́po méjì àwọn yàrá tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn. Sólómọ́nì gbé àpótí májẹ̀mú sínú yàrá tó wà nínú lọ́hùn-ún nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì kó àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n kó pa mọ́ sínú àgọ́ ìjọsìn wá sínú yàrá kejì.
Nígbà tí wọ́n parí tẹ́ńpìlì náà tán, àjọyọ̀ ńláǹlà wáyé. Gẹ́gẹ́ bó o ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí, Sólómọ́nì kúnlẹ̀ ní iwájú tẹ́ńpìlì yẹn ó ń gbàdúrà. Sólómọ́nì sọ fún Jèhófà pé: ‘Gbogbo ọ̀run pàápàá kò tiẹ̀ tóbi tó láti gbà ọ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí tẹ́ńpìlì yìí gbà ọ́. Ṣùgbọ́n o, Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́ fetí sí àwọn èèyàn rẹ nígbà tí wọ́n bá kọjú sí apá ibí yìí gbàdúrà.’
Nígbà tí Sólómọ́nì parí àdúrà rẹ̀, iná wá láti ọ̀run. Ó sì jó gbogbo àwọn ẹran tí wọ́n fi rúbọ. Ìmọ́lẹ̀ tó mọ́ yòò láti ọ̀dọ̀ Jèhófà sì tàn ká tẹ́ńpìlì náà. Èyí ló fi hàn pé Jèhófà gbọ́, àti pé inú rẹ̀ dùn sí tẹ́ńpìlì náà àti àdúrà tí Sólómọ́nì gbà. Dípò àgọ́ ìjọsìn, tẹ́ńpìlì yìí ló wá di ibi táwọn èèyàn á máa wá fún ìjọsìn nísinsìnyí.
Sólómọ́nì fi ọgbọ́n ṣe ìjọba rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn èèyàn náà sì láyọ̀. Ṣùgbọ́n Sólómọ́nì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó láti orílẹ̀-èdè àwọn míì tí wọn ò sin Jèhófà. Ṣó ò ń wo ọ̀kan lára wọn tó ń jọ́sìn níwájú ère? Nígbà tó yá, àwọn ìyàwó Sólómọ́nì sún òun náà débi tó ti sin àwọn ọlọ́run mìíràn. Ṣé o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òrìṣà? Kò ṣe dáadáa sáwọn èèyàn mọ́. Ó di ìkà, inú àwọn èèyàn ò sì dùn mọ́.
Èyí mú kí Jèhófà bínú sí Sólómọ́nì, ó sì sọ fún un pé: ‘Màá gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ màá sì fi fún ẹlòmíì. Àmọ́ mi ò ní gbà á nígbà ayé rẹ, ó dìgbà ìṣàkóso ọmọ rẹ kí n tó gba ìjọba náà. Síbẹ̀ mi ò ní gba gbogbo èèyàn ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ ọmọ rẹ.’ Jẹ́ ká wo bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀.