Orí Kẹta
Di Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Mú Ṣinṣin
1. (a) Báwo ni Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́? (b) Kí ló mú kí ìyẹn fà wá mọ́ra?
“Ẹ̀YIN . . . mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.” (Jóṣúà 23:14-16) Ohun tí Jóṣúà sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì nìyí lẹ́yìn tí wọ́n tẹ̀ dó sí Ilẹ̀ Ìlérí. Dájúdájú, ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣe é gbíyè lé. Nítorí tiwa la fi pa àkọsílẹ̀ náà mọ́ àti gbogbo ìyókù Bíbélì lápapọ̀ “kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
2. (a) Ọ̀nà wo ni Bíbélì fi jẹ́ ìwé tí “Ọlọ́run mí sí”? (b) Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì, kí wá ni ojúṣe wa?
2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn bí ogójì ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì, Òun gan-an ni Orísun ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Ṣé pé òun gan-an ló darí bí wọ́n ṣe kọ gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ pátá? Bẹ́ẹ̀ ni. Ó lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, láti fi ṣe èyí. Òótọ́ lọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí . . . kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” Gbogbo àwọn ènìyàn níbi gbogbo tí wọ́n gbà pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì ló ń ṣègbọràn sí ohun tó sọ, wọ́n sì ń gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.—2 Tímótì 3:16, 17; 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Mọyì Bíbélì?
3. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ láti gbà ran ọ̀pọ̀ tí kò gbà pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́?
3 Ọ̀pọ̀ àwọn tí à ń wàásù fún ni kò gbà pẹ̀lú wa pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa dára jù ni pé ká ṣí Bíbélì ká sì fi ohun tó wà nínú rẹ̀ hàn wọ́n. “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” kì í ṣe àkọsílẹ̀ ṣákálá kan lásán tí kò bágbà mu; ó wà láàyè! Àwọn ìlérí Bíbélì ń yára ṣẹ kánkán láìṣeé dá dúró. Ipa tí ìsọfúnni inú Bíbélì ń ní lórí àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́ tọkàntọkàn lágbára gan-an ju ohunkóhun tí a lè fi ẹnu lásán sọ lọ.
4. Àwọn àlàyé wo nípa òtítọ́ Bíbélì ló ti mú káwọn kan yí ojú tí wọ́n fi ń wo Bíbélì padà, kí ló sì fà á?
4 Rírí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì ti sún ọ̀pọ̀ láti túbọ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ dáadáa. Àwọn kan ti gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tí a fi ohun tó sọ nípa ète ìgbésí ayé hàn wọ́n, ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi, ìtumọ̀ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, àti ìrètí ìyè ayérayé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Láwọn ilẹ̀ kan tí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ti mú kí àwọn ẹ̀mí búburú máa fòòró àwọn èèyàn, àlàyé Bíbélì nípa ohun tó fa èyí àti bí èèyàn ṣe lè rí ìtura ti ru ìfẹ́ àwọn ènìyàn sókè. Kí ló mú kí àwọn kókó yìí wọ àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́kàn? Ìdí rẹ̀ ni pé, Bíbélì nìkan ṣoṣo lorísun ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nínú gbogbo irú àwọn ọ̀ràn pàtàkì bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 119:130.
5. (a) Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí àwọn kan sọ pé àwọn ò gba Bíbélì gbọ́? (b) Báwo la ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?
5 Àmọ́ ká ní àwọn kan sọ fún wa pé àwọn ò gba Bíbélì gbọ́ ńkọ́? Ṣe ó yẹ kí ìyẹn fòpin sí ìjíròrò wa? Kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá ṣe tán láti ronú nípa ohun tá a fẹ́ sọ. Ó lè jẹ pé ńṣe ni wọ́n ń wo Bíbélì pé ìwé àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni. Ó lè jẹ́ àkọsílẹ̀ nípa ìwà àgàbàgebè wọ́n àti bí wọ́n ṣe ń tojú bọ ọ̀ràn ìṣèlú, títí kan bí wọ́n ṣe máa ń bẹ̀bẹ̀ fún owó nígbà gbogbo ni kò jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. O ò ṣe béèrè bóyá ohun tó fà á nìyẹn? Dídá tí Bíbélì dá àwọn ọ̀nà ayé tí àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń tọ̀ lẹ́bi, àtàwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àti ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ lè ru ìfẹ́ wọn sókè.—Míkà 3:11, 12; Mátíù 15:7-9; Jákọ́bù 4:4.
6. (a) Kí ni ohun tó mú un dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì? (b) Àwọn àlàyé mìíràn wo lo tún lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gbà pé Bíbélì wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run lóòótọ́?
6 Ní ti àwọn mìíràn, ìjíròrò tó sojú abẹ níkòó nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Bíbélì ní ìmísí Ọlọ́run ni lè ṣèrànwọ́. Kí ló mú kó dá ọ lójú ṣáká pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá? Ṣé ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ nípa ibi tó ti pilẹ̀ṣẹ̀ ni? Àbí nítorí bí Bíbélì ṣe ní ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nínú tó ń fi hàn pé ó mọ púpọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la, ìyẹn àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n wá láti orísun kan tó ga ju ti ènìyàn lọ? (2 Pétérù 1:20, 21) Àbí kẹ̀ nítorí bí àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe wà ní ìṣọ̀kan lọ́nà tó ga ni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba ogójì ọkùnrin ní ohun tó ju ẹgbẹ̀jọ ọdún [1,600] lọ láti kọ ọ́? Àbí nítorí bó ṣe bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu wẹ́kú láìdàbí àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tó wà láyé ìgbà yẹn ni? Àbí ṣé ti àìfọ̀rọ̀sábẹ́-ahọ́n-sọ àwọn tó kọ ọ́ ni? Àbí nítorí bá a ṣe pa á mọ́ láìka gbogbo akitiyan láti pa á run sí ni? O tún lè lo ohunkóhun tó o bá mọ̀ pé ó lè wọni lọ́kàn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́.a
Bíbélì Kíkà Tiwa Fúnra Wa
7, 8. (a) Kí ló yẹ ká máa ṣe pẹ̀lú Bíbélì? (b) Kí la nílò láfikún sí kíka Bíbélì láyè ara wa? (d) Ọ̀nà wo lo ti gbà jèrè òye nípa àwọn ète Jèhófà?
7 Láfikún sí ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gba Bíbélì gbọ́, ó yẹ kí àwa fúnra wa wá àkókò láti máa kà á déédéé. Ṣé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀? Nínú gbogbo ìwé táwọn èèyàn tíì ṣe láyé, òun ló ṣe pàtàkì jù lọ. Àmọ́ ṣá o, èyí kò túmọ̀ sí pé a kò tún nílò ohun mìíràn mọ́ tá a bá ṣáà ti ń ka Bíbélì fúnra wa. Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ ya ara wa sọ́tọ̀. Kò yẹ ká ronú pé gbogbo nǹkan la lè lóye tá a bá ṣáà ti ń dá kẹ́kọ̀ọ́. A ní láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ kí á sì máa lọ sí ìpàdé àwọn èèyàn Ọlọ́run ká bàa lè jẹ́ Kristẹni tó wà déédéé.—Òwe 18:1; Hébérù 10:24, 25.
8 Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó sọ nípa ìjòyè ará Etiópíà kan tó ń ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. Áńgẹ́lì kan darí Fílípì tó jẹ́ Kristẹni ajíhìnrere láti béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Ó rọ Fílípì láti ṣàlàyé àyọkà Ìwé Mímọ́ náà fún òun. Ní ti gidi, Fílípì kì í kàn ṣe ẹni tó máa ń dá Bíbélì kà láyè ara rẹ̀ tá á wá máa gbé èrò tára rẹ̀ kalẹ̀ lórí Ìwé Mímọ́. Pẹ́kípẹ́kí ló sún mọ́ ètò àjọ Ọlọ́run tó ṣeé fojú rí. Ìyẹn ló jẹ́ kó lè ran ará Etiópíà náà lọ́wọ́ láti jàǹfààní látinú ìtọ́ni tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ náà. (Ìṣe 6:5, 6; 8:5, 26-35) Lọ́jọ́ òní pẹ̀lú, kò sẹ́ni tó lè ní òye tó pé nípa àwọn ète Jèhófà láyè ara rẹ̀. Gbogbo wa la nílò ìrànwọ́ tí Jèhófà ń fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀.
9. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà wo ló lè ṣe gbogbo wa láǹfààní?
9 Láti ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì, ètò àjọ Jèhófà ń pèsè àwọn àlàyé Ìwé Mímọ́ tí kò lẹ́gbẹ́ nínú oríṣiríṣi ìwé. Ní àfikún sí ìyẹn, a tún ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíka Bíbélì déédéé ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí à ń ṣe ní gbogbo ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé. A lè jàǹfààní ńláǹlà látinú ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ fúnra wa. (Sáàmù 1:1-3; 19:7, 8) Ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa ka Bíbélì déédéé. Ká tiẹ̀ ní o ò lóye gbogbo rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, wíwulẹ̀ mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yóò ṣe ọ́ láǹfààní tó pọ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, bó bá jẹ́ kìkì ojú ewé mẹ́rin sí márùn-ún lò ń kà lójoojúmọ́, o lè parí Bíbélì ní nǹkan bí ọdún kan.
10. (a) Ìgbà wo lo fi Bíbélì kíkà rẹ sí? (b) Àwọn mìíràn wo ló yẹ kó máa kópa nígbà tá a bá ń ka Bíbélì, ìdí wo ló sì fi ṣe pàtàkì ká máa kà á déédéé?
10 Ìgbà wo lo lè fi Bíbélì kíkà rẹ sí? Bó bá jẹ́ kìkì ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lò ń yà sọ́tọ̀ fún un lójúmọ́, àǹfààní kékeré kọ́ lo máa jẹ. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ó kéré tán, ṣètò àwọn àkókò tí wàá fi máa kà á déédéé láàárín ọ̀sẹ̀ kó o má sì jẹ́ kó yẹ̀. Bó o bá ti ṣègbéyàwó, ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lè jọ máa kà á síra yín létí. Bẹ́ ẹ bá ní àwọn ọmọ tó ti mọ̀wéé kà, wọ́n lè máa kà á sókè lọ́kọ̀ọ̀kan. Ohun téèyàn á máa ṣe títí ayé ló yẹ kí Bíbélì kíkà jẹ́, bí oúnjẹ téèyàn ń jẹ. Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, tí ẹnì kan kì í bá jẹun dáadáa, á ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀. Bákan náà lọ̀ràn rí pẹ̀lú ipò tẹ̀mí wa. Nítorí náà, ìyè ayérayé wa sinmi lórí gbígbà tí à ń gba “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà” sínú déédéé.—Mátíù 4:4.
Ohun Tó Yẹ Kó Sún Wa Máa Ka Bíbélì
11. Kí ló yẹ kó sún wa máa ka Bíbélì?
11 Kí ló yẹ kó sún wa máa ka Bíbélì? Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kìkì nítorí ká lè sọ pé a ti ka ojú ewé tó pọ̀ la ṣe ń kà á. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ nítorí pé a fẹ́ túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáradára sí i kí ìfẹ́ tá a ní fún un lè túbọ̀ pọ̀ sí i, ká sì lè sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. (Jòhánù 5:39-42) Bí ọ̀ràn ṣe rí lára òǹkọ̀wé Bíbélì kan ló yẹ kó rí lára wa, ẹni tó sọ pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.”—Sáàmù 25:4.
12. (a) Èé ṣe tí níní “ìmọ̀ pípéye” fi pọn dandan, àwọn ìsapá wo lèyí sì lè béèrè pé ká ṣe nígbà tá a bá ń kàwé ká lè ní ìmọ̀ yẹn? (b) Nípa lílo àwọn kókó mẹ́rin wo la fi lè ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ohun tí à ń kà nínú Bíbélì lọ́nà tó máa ṣeni láǹfààní? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 30) (d) Ṣàlàyé àwọn kókó wọ̀nyí nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nínú ìpínrọ̀ yìí. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí ṣùgbọ́n tí a kò fa ọ̀rọ̀ wọn yọ.
12 Bá a ti ń gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ìfẹ́ ọkàn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti ní “ìmọ̀ pípéye.” Tá ò bá ní ìmọ̀ pípéye, báwo la ṣe máa lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò bó ṣe yẹ nínú ìgbésí ayé wa, báwo la sì ṣe máa lè ṣàlàyé rẹ̀ yékéyéké fún àwọn ẹlòmíràn? (Kólósè 3:10; 2 Tímótì 2:15) Níní ìmọ̀ pípéye ń béèrè pé ká fara balẹ̀ kàwé, tí ibì kan bá sì díjú, yóò pọn dandan pé kí á kà á lákàtúnkà ká lè lóye ohun tó ń sọ. Àá tún jàǹfààní gan-an tá a bá ń lo àkókò láti ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kà náà, tá à ń ronú síwá sẹ́yìn nípa rẹ̀. Àwọn ọ̀nà pàtàkì mẹ́rin tá a fi lè ronú nípa rẹ̀ la fi han lójú ìwé 30. Ọ̀pọ̀ apá Ìwé Mímọ́ la lè fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ́nà tó máa ṣàǹfààní nípa lílo ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn kókó wọ̀nyí. Bó o ti ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà láwọn ojú ewé tó tẹ̀ lé e yìí, wàá rí bí ìyẹn ṣe jẹ́ òótọ́.
(1) Lọ́pọ̀ ìgbà, apá ibi tí ò ń kà nínú Ìwé Mímọ́ lè sọ ohun kan fún ọ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ní Sáàmù 139:13, 14, a kọ́ nípa bí Ọlọ́run kò ṣe fi ọwọ́ kékeré mú ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ tí a kò tíì bí. Ó kà pé: “Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi. Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” Àgbàyanu mà ni àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà o! Ọ̀nà tó gbà dá àwa èèyàn ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ ńláǹlà tó ní fún wa.
Níbàámu pẹ̀lú ohun tí Jòhánù 14:9, 10 sọ, nígbà tá a bá ń kà nípa bí Jésù ṣe bá àwọn ẹlòmíràn lò, ńṣe nìyẹn ń sọ fún wa nípa bí Jèhófà fúnra rẹ̀ ṣe máa hùwà. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, irú ẹni wo la lè sọ pé Jèhófà jẹ́ bá a ti ń ka àwọn ìtàn tí a kọ sínú ìwé Lúùkù 5:12, 13 àti Lúùkù 7:11-15?
(2) Ronú nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì: ìyẹn ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà àti ìsọdimímọ́ orúkọ rẹ̀ nípasẹ̀ Ìjọba náà lábẹ́ Jésù Kristi, Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà.
Báwo ni Ìsíkíẹ́lì àti Dáníẹ́lì ṣe tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì? (Ìsíkíẹ́lì 38:21-23; Dáníẹ́lì 2:44; 4:17; 7:9-14)
Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn kedere pé Jésù ni Irú Ọmọ tá a ṣèlérí náà? (Gálátíà 3:16)
Báwo ni Ìṣípayá ṣe ṣàpèjúwe bí ẹṣin ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ṣe máa nímùúṣẹ lọ́nà tó pabanbarì? (Ìṣípayá 11:15; 12:7-10; 17:16-18; 19:11-16; 20:1-3; 21:1-5)
(3) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ nípa bí ìwọ fúnra rẹ ṣe lè fi ohun tí ò ń kà sílò. Bí àpẹẹrẹ, a kà nínú ìwé Ẹ́kísódù títí lọ dé Diutarónómì nípa ìṣekúṣe àti ìṣọ̀tẹ̀ Ísírẹ́lì. A kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn ìwà àti ìṣesí wọn yọrí sí nǹkan tí kò dára. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ìyẹn sún wa láti mú inú Jèhófà dùn, ká má bàa fara wé àpẹẹrẹ búburú Ísírẹ́lì. “Nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́ríńtì 10:11.
Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú ìtàn bí Kéènì ṣe pa Ébẹ́lì? (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-12; Hébérù 11:4; 1 Jòhánù 3:10-15; 4:20, 21)
Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà fún àwọn Kristẹni tó ní ìrètí ti ọ̀run tún kan àwọn tó ní ìrètí gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé? (Númérì 15:16; Jòhánù 10:16)
Ká tiẹ̀ ní à ń ṣe dáadáa nínú ìjọ Kristẹni, èé ṣe tó fi yẹ ká ronú nípa bí a ṣe lè túbọ̀ fi ìmọ̀ràn Bíbélì tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ sílò? (2 Kọ́ríńtì 13:5; 1 Tẹsalóníkà 4:1)
(4) Ronú lórí bí o ṣe lè lo ohun tí ò ń kà láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Gbogbo èèyàn pátá ni ìṣòro ìlera ń bá fínra, nítorí náà a lè ka ohun tí Jésù ṣe fún wọn. Èyí ń fi ohun tí yóò ṣe lọ́nà gbígbòòrò hàn nígbà tó bá di Ọba alágbára nínú Ìjọba Ọlọ́run. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tọ̀ ọ́ wá, tí wọ́n mú àwọn ènìyàn tí wọ́n yarọ, aláàbọ̀ ara, afọ́jú, odi, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn wá pẹ̀lú wọn, wọ́n sì rọra gbé wọn kalẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn.”—Mátíù 15:30.
Àwọn wo ni a lè fi àkọsílẹ̀ nípa àjíǹde ọmọbìnrin Jáírù ràn lọ́wọ́? (Lúùkù 8:41, 42, 49-56)
13. Irú àbájáde wo la lè máa retí látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà wa tí kò dáwọ́ dúró àti kíkẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà?
13 Tá a bá ṣàmúlò àwọn kókó mẹ́rin tá a mẹ́nu bà lókè yìí, Bíbélì kíkà á mà lérè nínú gan-an o! Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti ka Bíbélì. Àmọ́ ó lè ṣàǹfààní fún wa títí ayé, nítorí pé bá a bá ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ la ó máa tẹ̀ síwájú nínú òye wa nípa tẹ̀mí. Kíka Bíbélì déédéé yóò túbọ̀ mú wa sún mọ́ Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́ àtàwọn Kristẹni arákùnrin wa. Á ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn náà sílò pé ká di “ọ̀rọ̀ ìyè mú ṣinṣin.”—Fílípì 2:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò nípa ìdí tó fi yẹ ká yẹ Bíbélì wò, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Ìdí wo la fi kọ Bíbélì tá a sì pa á mọ́ di ọjọ́ wa?
• Báwo la ṣe lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti mọyì Bíbélì?
• Èé ṣe tí kíka Bíbélì fúnra ẹni fi lérè nínú? Nípa lílo àwọn kókó mẹ́rin wo la fi lè ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ohun tí à ń kà lọ́nà tó máa ṣàǹfààní?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
NÍGBÀ TÓ O BÁ KA IBÌ KAN NÍNÚ BÍBÉLÌ, RONÚ LÓRÍ
Ohun tó ń sọ fún ọ nípa Jèhófà fúnra rẹ̀
Bó ṣe kan ẹṣin ọ̀rọ̀ Bíbélì lódindi
Bó ṣe yẹ kó nípa lórí ìgbésí ayé rẹ
Bó o ṣe lè lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́