Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
28 Lẹ́yìn tí a gúnlẹ̀ ní àlàáfíà, a gbọ́ pé Málítà ni wọ́n ń pe erékùṣù náà.+ 2 Àwọn tó ń sọ èdè àjèjì* ṣe inú rere àrà ọ̀tọ̀* sí wa. Wọ́n dá iná, wọ́n sì gba gbogbo wa tọwọ́tẹsẹ̀ nítorí òjò tó ń rọ̀ àti nítorí òtútù tó mú. 3 Àmọ́ nígbà tí Pọ́ọ̀lù kó igi jọ, tó sì kó o sórí iná, paramọ́lẹ̀ kan jáde nítorí ooru, ó sì wé mọ́ ọn lọ́wọ́. 4 Nígbà tí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tajú kán rí ejò olóró tó rọ̀ dirodiro ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ara wọn pé: “Ó dájú pé apààyàn ni ọkùnrin yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gúnlẹ̀ ní àlàáfíà láti orí òkun, Ìdájọ́ Òdodo* kò jẹ́ kó máa wà láàyè nìṣó.” 5 Àmọ́, ó gbọn ejò náà dà nù sínú iná, nǹkan kan ò sì ṣe é. 6 Síbẹ̀, wọ́n ń retí pé kí ara rẹ̀ wú tàbí pé lójijì, kó ṣubú lulẹ̀, kó sì kú. Nígbà tí wọ́n dúró títí, tí wọ́n sì rí i pé nǹkan kan ò ṣe é, wọ́n yí èrò wọn pa dà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ọlọ́run kan ni.
7 Ní àdúgbò ibẹ̀, àwọn ilẹ̀ kan wà tó jẹ́ ti olórí erékùṣù náà, Púbílọ́sì ni orúkọ rẹ̀, ó gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, ó sì ṣe wá lálejò fún ọjọ́ mẹ́ta. 8 Ó ṣẹlẹ̀ pé bàbá Púbílọ́sì wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ ọ́ lẹ́nu, Pọ́ọ̀lù wá wọlé lọ bá a, ó sì gbàdúrà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá.+ 9 Lẹ́yìn tí èyí ṣẹlẹ̀, ìyókù àwọn èèyàn erékùṣù náà tó ń ṣàìsàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń rí ìwòsàn.+ 10 Wọ́n tún fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn yẹ́ wa sí, nígbà tí a sì fẹ́ lọ wọkọ̀, wọ́n di gbogbo ohun tí a nílò fún wa.
11 Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, a wọkọ̀ òkun kan tí wọ́n kọ “Àwọn Ọmọ Súúsì” sára ère iwájú orí rẹ̀. Alẹkisáńdíríà ni ọkọ̀ òkun náà ti wá, ó sì ti lo ìgbà òtútù ní erékùṣù náà. 12 A gúnlẹ̀ sí èbúté Sírákúsì, a sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀; 13 látibẹ̀, a tẹ̀ síwájú, a sì dé Régíómù. Ọjọ́ kan lẹ́yìn náà, ẹ̀fúùfù gúúsù kan bẹ̀rẹ̀, síbẹ̀ náà, a dé Pútéólì lọ́jọ́ kejì. 14 A rí àwọn ará níbẹ̀, wọ́n sì rọ̀ wá pé ká lo ọjọ́ méje lọ́dọ̀ àwọn, lẹ́yìn náà a forí lé Róòmù. 15 Nígbà tí àwọn ará gbọ́ ìròyìn nípa wa, wọ́n wá láti ibẹ̀, títí dé iyànníyàn Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta láti wá pàdé wa. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kàn le.+ 16 Níkẹyìn, a wọ Róòmù, wọ́n sì gba Pọ́ọ̀lù láyè kó máa gbé láyè ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ ogun tó ń ṣọ́ ọ.
17 Àmọ́, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù pe àwọn sàràkí-sàràkí jọ lára àwọn Júù. Nígbà tí wọ́n pé jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣe ohunkóhun tó lòdì sí àwọn èèyàn tàbí sí àṣà àwọn baba ńlá wa,+ síbẹ̀ wọ́n fà mí lé ọwọ́ àwọn ará Róòmù ní ẹlẹ́wọ̀n láti Jerúsálẹ́mù.+ 18 Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò,+ wọ́n fẹ́ dá mi sílẹ̀, nítorí kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kí wọ́n pa mí.+ 19 Àmọ́ nígbà tí àwọn Júù fárí gá, ó di dandan fún mi láti ké gbàjarè sí Késárì,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe torí pé mo ní ẹ̀sùn tí mo fẹ́ fi kan orílẹ̀-èdè mi. 20 Ìdí nìyí tí mo fi ní kí n pè yín kí n lè bá yín sọ̀rọ̀, torí pé, nítorí ìrètí Ísírẹ́lì ni ẹ̀wọ̀n yìí ṣe yí mi ká.”+ 21 Wọ́n sọ fún un pé: “A ò tíì gba lẹ́tà kankan nípa rẹ láti Jùdíà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkankan lára àwọn ará tó wá láti ibẹ̀ tó ròyìn tàbí tó sọ ohun burúkú nípa rẹ. 22 Àmọ́, a rí i pé á dáa ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu rẹ, ká lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, torí a mọ̀ lóòótọ́ pé, tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀ya ìsìn yìí,+ ibi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa.”+
23 Wọ́n wá ṣètò ọjọ́ kan láti wá bá a, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ibi tó ń gbé, kódà àwọn tó wá pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ. Láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, ó ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn bí ó ṣe ń jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run, kó lè yí èrò tí wọ́n ní nípa Jésù pa dà+ nípasẹ̀ Òfin Mósè+ àti ìwé àwọn Wòlíì.+ 24 Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í gba ohun tó sọ gbọ́; àmọ́ àwọn míì ò gbà á gbọ́. 25 Tóò, nígbà tí èrò wọn ò ṣọ̀kan, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ sílẹ̀, Pọ́ọ̀lù wá sọ ọ̀rọ̀ kan, ó ní:
“Ẹ̀mí mímọ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà fún àwọn baba ńlá yín, 26 pé, ‘Lọ sọ fún àwọn èèyàn yìí pé: “Ó dájú pé ẹ ó gbọ́, àmọ́ kò ní yé yín rárá; ó dájú pé ẹ ó wò, àmọ́ ẹ ò ní rí nǹkan kan.+ 27 Nítorí ọkàn àwọn èèyàn yìí ti yigbì, wọ́n ti fi etí wọn gbọ́ àmọ́ wọn ò dáhùn, wọ́n ti di ojú wọn, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran láé, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kó má sì yé wọn nínú ọkàn wọn, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”’+ 28 Torí náà, ẹ jẹ́ kó yé yín pé, ìgbàlà yìí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni a ti kéde fún àwọn orílẹ̀-èdè;+ ó dájú pé wọ́n á fetí sí i.”+ 29 * ——
30 Torí náà, ó lo odindi ọdún méjì ní ilé tí òun fúnra rẹ̀ gbà,+ ó sì máa ń gba gbogbo àwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀, 31 ó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, ó sì ń kọ́ wọn nípa Jésù Kristi Olúwa ní fàlàlà,*+ láìsí ìdíwọ́.