ORÍ 51
Wọ́n Pa Èèyàn Níbi Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí Kan
MÁTÍÙ 14:1-12 MÁÀKÙ 6:14-29 LÚÙKÙ 9:7-9
HẸ́RỌ́DÙ NÍ KÍ WỌ́N BẸ́ ORÍ JÒHÁNÙ ARINIBỌMI
Bí àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣe ń wàásù fàlàlà nílùú Gálílì, Jòhánù Arinibọmi tó múra ọ̀nà sílẹ̀ de Jésù kò nírú òmìnira bẹ́ẹ̀. Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọdún méjì báyìí tó ti wà lẹ́wọ̀n.
Jòhánù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò bójú mu bí Ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà ṣe gba Hẹrodíà tó jẹ́ ìyàwó Fílípì ọbàkan rẹ̀. Hẹ́rọ́dù kọ ìyàwó tó kọ́kọ́ fẹ́ sílẹ̀ kó lè fẹ́ Hẹrodíà. Lóòótọ́, Ọba Hẹ́rọ́dù sọ pé òun ń pa Òfin Mósè mọ́, àmọ́ àgbèrè ló ṣe, ìyẹn sì ta ko Òfin náà. Torí pé Jòhánù dẹ́bi fún Hẹ́rọ́dù, Hẹ́rọ́dù jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Hẹrodíà ló ní kó ṣe bẹ́ẹ̀.
Hẹ́rọ́dù ò mọ ohun tó lè ṣe sí Jòhánù torí àwọn èèyàn gbà pé “wòlíì ni.” (Mátíù 14:5) Hẹrodíà ní tiẹ̀ ti mọ ohun tóun fẹ́ ṣe. Bíbélì sọ pé ó “dì í sínú,” kódà ṣe ló ń wá bó ṣe máa pa á. (Máàkù 6:19) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àyè wá ṣí sílẹ̀ fún un.
Bí àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ọdún 32 S.K. ṣe ń sún mọ́lé, Hẹ́rọ́dù ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ó pe àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn àtàwọn ọ̀gá ológun, títí kan àwọn tó lẹ́nu láwùjọ síbi ayẹyẹ náà. Bí wọ́n ṣe ń jẹ tí wọ́n ń mu, Sàlómẹ̀, ìyẹn ọmọbìnrin tí Hẹrodíà bí fún Fílípì bọ́ sójú agbo, ó sì jó fáwọn àlejò tó pé jọ. Orí gbogbo wọn wú gan-an sí bí ọmọbìnrin náà ṣe jó.
Inú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an, ó wá sọ fún ọmọbìnrin náà pé: “Bi mí ní ohunkóhun tí o bá fẹ́, màá sì fún ọ.” Kódà ó tún búra pé: “Ohunkóhun tí o bá bi mí, màá fún ọ, títí dórí ìdajì ìjọba mi.” Kí Sàlómẹ̀ tó dá ọba lóhùn, ó lọ bi ìyá rẹ̀ pé: “Kí ni kí n béèrè?”—Máàkù 6:22-24.
Àsìkò tí Hẹrodíà ń retí ló dé yìí! Kíá ló sọ fún ọmọ ẹ̀ pé, “Orí Jòhánù Onírìbọmi.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Sàlómẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ ọba Hẹ́rọ́dù, ó sì sọ fún un pé: “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi nínú àwo pẹrẹsẹ ní báyìí.”—Máàkù 6:24, 25.
Ohun tí ọmọbìnrin yìí béèrè ba Hẹ́rọ́dù nínú jẹ́ gan-an, àmọ́ ojú gbogbo àlejò tó wà níbẹ̀ ló ti búra. Ìtìjú ló máa jẹ́ tí ò bá ṣe ohun tí ọmọbìnrin náà béèrè bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ni wọ́n fẹ́ pa. Nítorí náà, Hẹ́rọ́dù rán ẹ̀ṣọ́ kan pé kó lọ bẹ́ orí Jòhánù wá. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, ẹ̀ṣọ́ náà ti dé pẹ̀lú orí Jòhánù nínú àwo pẹrẹsẹ. Ó gbé e fún Sàlómẹ̀, òun náà sì gbé e lọ fún ìyá rẹ̀.
Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀ wọ́n sì sin ín. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sọ fún Jésù.
Nígbà tó yá, Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé Jésù ń wo àwọn èèyàn sàn, ó sì ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, torí náà ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀ rárá. Ó ń ronú pé bóyá Jòhánù Arinibọmi tó ‘ti jí dìde’ ni Jésù. (Lúùkù 9:7) Torí náà, ó ń wá bó ṣe máa rí Jésù lójú méjèèjì. Ó dájú pé kì í ṣe pé ó fẹ́ gbọ́ ìwàásù Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ rí Jésù kó lè mọ̀ bóyá òun ni Jòhánù tàbí òun kọ́.