Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Bẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́ náà Nísinsìnyí?
“Bẹ̀rù Ọlọrun kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.”—ONIWASU 12:13.
1, 2. Èé ṣe tí ìbẹ̀rù yíyẹ fún Ọlọrun fi bá a mu wẹ́kú?
ÓDÁRA, kí ènìyàn ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí ó gbámúṣé fún Ọlọrun. Bẹ́ẹ̀ ni, bí ọ̀pọ̀ ìbẹ̀rù ẹ̀dá ènìyàn tilẹ̀ ń dani láàmú ní ti èrò ìmọ̀lára, kódà, tí ó ń ṣàkóbá fún ire wa, ó dára kí a bẹ̀rù Jehofa Ọlọrun.—Orin Dafidi 112:1; Oniwasu 8:12.
2 Ẹlẹ́dàá náà mọ èyí. Nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó pàṣẹ pé kí gbogbo wa bẹ̀rù òun, kí a sì jọ́sìn òun. A kà pé: “Mo . . . rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìnrere àìnípẹ̀kun lati polongo gẹ́gẹ́ bí awọn làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún awọn wọnnì tí ń gbé lórí ilẹ̀-ayé, ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ahọ́n ati ènìyàn, ó ń wí ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun kí ẹ sì fi ògo fún un, nitori wákàtí ìdájọ́ lati ọwọ́ rẹ̀ ti dé, ati nitori naa ẹ jọ́sìn Ẹni tí ó dá ọ̀run ati ilẹ̀-ayé.’”—Ìṣípayá 14:6‚ 7.
3. Kí ni Ẹlẹ́dàá náà ṣe fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́?
3 Ó dájú pé kò yẹ kí a pa Ẹlẹ́dàá gbogbo nǹkan tì, Orísun ìwàláàyè, nítorí pé òun ni ó ni àwa àti pílánẹ́ẹ̀tì yìí. (Orin Dafidi 24:1) Ní fífi ìfẹ́ rẹ̀ tí ó ga lọ́lá hàn, Jehofa fún àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ní ìwàláàyè, ó sì pèsè ibi àgbàyanu kan fún wọn láti máa gbé nínú—paradise kan tí ó lẹ́wà. Síbẹ̀, ẹ̀bùn àgbàyanu yìí ni a gbé karí ipò àfilélẹ̀ kan. Ní tòótọ́, a fi sí ìkáwọ́ àwọn kan. Àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ní láti bójú tó ilé wọn, kí wọ́n sì mú un gbòòrò títí tí wọn yóò fi kún ilẹ̀ ayé, tí wọn yóò sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀. Wọ́n ní àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ láti bójú tó àwọn ẹranko ilẹ̀, àwọn ẹyẹ, àti ẹja—gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè mìíràn tí yóò gbé ilẹ̀ ayé pẹ̀lú wọn àti àwọn ọmọ wọn. Nítorí ohun ńlá tí a fi sí ìkáwọ́ wọn yìí, ènìyàn ní láti jíhìn.
4. Kí ni ènìyàn ti ṣe sí ìṣẹ̀dá Ọlọrun?
4 Láìka ìbẹ̀rẹ̀ àgbàyanu náà sí, wo ohun tí ènìyàn ṣe láti ba ilé ilẹ̀ ayé rẹ̀ tí ó rẹwà jẹ́! Nítorí fífojú tẹ́ḿbẹ́lú Ọlọrun pẹ̀lú ìwà àìlọ́wọ̀, àwọn ènìyàn ti fi ẹ̀gbin ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Ìbàjẹ́ náà ti dé ibi tí ó ti ń wu ìwàláàyè ọ̀pọ̀ jáǹtìrẹrẹ onírúurú àwọn ẹranko, ẹyẹ, àti ẹja léwu. Ọlọrun wa olódodo àti onífẹ̀ẹ́ kì yóò fàyè gba èyí títí gbére. Bíba ilẹ̀ ayé jẹ́ ti ń ké fún ìjíhìn, èyí tí ó jẹ́ ìdí tí ó fí yẹ kí ọ̀pọ̀ bẹ̀rù. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, fún àwọn tí wọ́n ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun, ó jẹ́ ohun tí ń tuni nínú láti mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Jehofa yóò béèrè fún ìjíhìn, ilẹ̀ ayé ni a óò sì mú padà bọ̀ sípò. Dájúdájú, èyí jẹ́ ìròyìn ayọ̀ fún gbogbo àwọn ọlọ́kàn títọ́ lórí ilẹ̀ ayé.
5, 6. Báwo ni Jehofa yóò ṣe hùwà padà sí ohun tí ènìyàn tí ṣe sí ìṣẹ̀dá Rẹ̀?
5 Nípasẹ̀ ta ni Ọlọrun yóò fi mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ? Nípasẹ̀ Jesu Kristi, tí a ti gbé karí ìtẹ́ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run. Nípasẹ̀ Ọmọkùnrin ọ̀run náà, Jehofa yóò mú ètò ìgbékalẹ̀ aláìmọ́, ọlọ̀tẹ̀ ti ìsinsìnyí wá sí òpin. (2 Tessalonika 1:6-9; Ìṣípayá 19:11) Ọ̀nà yìí ni òun yóò gbà mú ìtura wá fún àwọn tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, tí òun yóò sì gba ilé ilẹ̀ ayé wa là, tí yóò sì pa á mọ́ ní ọwọ́ kan náà.
6 Báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Bibeli sọ nípa ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀, tí yóò dé òtéńté rẹ̀ nígbà ogun Armagedoni. (Ìṣípayá 7:14; 16:16) Èyí ni yóò jẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun lórí ètò ìgbékalẹ̀ tí a ti bàjẹ́ yìí àti àwọn tí wọ́n bà á jẹ́. Ẹ̀dá ènìyàn kankan yóò ha ṣẹ́kù láàyè bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Yóò jẹ́ àwọn tí wọ́n fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ńlá fún Ọlọrun, kì í ṣe ìbẹ̀rù tí kò gbámúṣé, tí ń múni gbọ̀n jìnnìjìnnì. A óò gbà wọ́n là.—Owe 2:21‚ 22.
Fífi Agbára Hàn Lọ́nà Tí Ó Múni Ta Gìrì
7. Èé ṣe tí Ọlọrun fi dá sí i nítorí àwọn ọmọ Israeli ní ọjọ́ Mose?
7 Ìgbésẹ̀ amúnijígìrì tí Jehofa Ọlọrun yóò gbé yìí ni ìṣe alágbára tí ó ṣe nítorí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ní nǹkan bíi 1,500 ọdún ṣáájú Sànmánnì Tiwa yìí ń ṣàpẹẹrẹ. Agbára ológun ńlá ti Egipti ti sọ ọ̀wọ́ òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n ṣí lọ síbẹ̀ di ẹrú, wọ́n tilẹ̀ ń gbìyànjú láti pa gbogbo ìran náà run nígbà tí alákòóso rẹ̀, Farao, pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin Israeli tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí. Ṣíṣẹ́gun tí Ọlọrun ṣẹ́gun Egipti jẹ́ láti dá Israeli sílẹ̀ lómìnira kúrò lábẹ́ ètò ìgbékalẹ̀ olóṣèlú atẹnilóríba, àti kúrò lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè tí ìjọsìn ọ̀pọ̀ ọlọrun ti sọ dìbàjẹ́.
8, 9. Báwo ni Mose àti àwọn ọmọ Israeli ṣe hùwà padà sí bí Ọlọrun ṣe dá sí i?
8 Eksodu orí 15, ṣàkọsílẹ̀ ìhùwàpadà Israeli sí ìdásílẹ̀ kúrò ní Egipti. Ṣíṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà ní fínnífínní yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí a ṣe lè gba àwọn Kristian sílẹ̀ kúrò nínú ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí tí ó ti díbàjẹ́ nípa tẹ̀mí àti ti ara. Jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò Eksodu orí 15, kí a pe àfiyèsí sí àwọn àṣàyàn ẹsẹ kan, kí a ba lè kẹ́kọ̀ọ́ ìdí tí ó fi yẹ kí a yàn láti bẹ̀rù Jehofa, Ọlọrun tòótọ́ náà. A óò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ẹsẹ 1 àti 2:
9 “Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israeli kọ orin yìí sí OLUWA wọ́n sì wí pé, Èmi óò kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó pọ̀ ní ògo: àti ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin òun ni ó bì ṣubú sínú òkun. OLUWA ni agbára àti orin mi, òun ni ó sì di ìgbàlà mi.”
10. Kí ni ó fà á tí Ọlọrun fi pa àwọn ọmọ ogun Egipti run?
10 Àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé mọ̀ nípa àkọsílẹ̀ bí Jehofa ṣe dá Israeli sílẹ̀ lómìnira kúrò ní Egipti. Ó mú ìyọnu wá sórí agbára ayé ńlá náà títí tí Farao, nígbẹ̀yìngbẹ́yín fi yọ̀ọ̀da fún àwọn ọmọ Israeli láti lọ. Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọmọ ogun Farao sáré lé àwọn ènìyàn yìí tí kò ní ohun ìjà, ó sì dà bíi pé wọ́n ká wọn mọ́ etí Òkun Pupa. Bí ó tilẹ̀ dà bíi pé àwọn ọmọ Israeli yóò pàdánù òmìnira tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ rí gbà ní kíákíá, ohun mìíràn ni Jehofa ní lọ́kàn. Ó la ọ̀nà gba òkun náà kọjá lọ́nà ìyanu, ó sì mú àwọn ènìyàn rẹ̀ kọjá láìséwu. Nígbà tí àwọn ọmọ Egipti gbá tọ̀ wọ́n, ó pa Òkun Pupa dé mọ́ wọn, Farao àti àwọn agbo ọmọ ogun rẹ̀ sì rì.—Eksodu 14:1-31.
11. Kí ni ìgbésẹ̀ Ọlọrun lòdì sí Egipti yọrí sí?
11 Pípa tí Jehofa pa agbo ọmọ ogun Egipti run gbé e lékè lójú àwọn olùjọsìn rẹ̀, ó sì mú kí orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ káàkiri. (Joṣua 2:9‚ 10; 4:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni, a gbé orúkọ rẹ̀ ga borí àwọn ọlọrun èké àwọn ará Egipti, tí kò lágbára, tí wọ́n fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n kò lè gba àwọn tí ń jọ́sìn wọn là. Gbígbé tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọlọrun wọn àti àwọn ènìyàn tí wọ́n lè kú àti agbára ológun yọrí sí ìjákulẹ̀ kíkorò. (Orin Dafidi 146:3) Abájọ tí èyí fi sún àwọn ọmọ Israeli láti kọrin tí ó fi ìbẹ̀rù gbígbámúṣé nínú Ọlọrun tí ń bẹ láàyè hàn, tí ó fi agbára rẹ gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là!
12, 13. Kí ni ó yẹ kí a kọ́ láti ara ìṣẹ́gun Ọlọrun ní Òkun Pupa?
12 Lọ́nà kan náà, a ní láti mọ̀ pé kò sí àwọn ọlọrun èké kankan ti àkókò wa àti alágbára ńlá kankan, tí ó lè dọ́gba pẹ̀lú Jehofa, àní pẹ̀lú bọ́m̀bù ìjà ogun pàápàá. Ó lè, yóò sì gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là. “Òun a . . . máa ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti wù ú nínú ogun ọrun, àti láàárín àwọn aráyé: kò sì sí ẹni tí í dá ọwọ́ rẹ̀ dúró tàbí ẹni tí í wí fún un pé, Kí ni ìwọ ń ṣe nì?” (Danieli 4:35) Nígbà tí a bá lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní kíkún, a ń sún àwa pẹ̀lú láti kọrin ìyìn rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.
13 Orin ìṣẹ́gun ní Òkun Pupa ń bá a lọ pé: “Akin ọkùnrin ogun ni Jehofa. Jehofa ni orúkọ rẹ̀.” Nígbà náà, Jagunjagun tí a kò lè borí rẹ̀ yìí, kì í wulẹ̀ ṣe aláìlórúkọ tí a kàn finú rò. Ó ní orúkọ! Òun ni ‘Ẹni tí ó mú kí ó wà,’ Atóbilọ́lá Aṣẹ̀dá, Ẹni tí ‘orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jehofa, Ọ̀gá ògo lórí ayé gbogbo.’ (Eksodu 3:14, NW; 15:3-5, NW; Orin Dafidi 83:18) Ìwọ kò ha gbà pé ì bá ti bọ́gbọ́n mu fún àwọn ará Egipti ìgbàanì láti ní ìbẹ̀rù tí ó lọ́gbọ́n nínú, tí ó sì fi ọ̀wọ̀ hàn fún Olódùmarè, kàkà tí wọ́n fi pè é níjà?
14. Báwo ni a ṣe fi ìníyelórí ìbẹ̀rù Ọlọrun hàn ní Òkun Pupa?
14 Gẹ́gẹ́ bí Olùṣe ilẹ̀ ayé, Olùṣẹ̀dá òkun ní agbára ìdarí pátápátá lórí gbogbo ohun tí ó wà nínú omi. (Eksodu 15:8) Ní lílo agbára ìdarí rẹ̀ lórí afẹ́fẹ́ pẹ̀lú, ó ṣàṣeparí ohun tí ó dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe. Ó pín omi jíjìn níyà ní ibì kan, ó sì fi dandan darí rẹ̀ sí ibòmíràn, kí ó baà lè pèsè ọ̀nà láàárín omi fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láti sá àsálà. Fojú inú wo ìran náà: àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tọ́ọ̀nù omi òkun ga sókè bí àwọn ògiri tí ó dọ́gba, tí ó sì di ọ̀nà aláàbò fún Israeli láti gbà kọjá. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí wọ́n fi ìbẹ̀rù gbígbámúṣé hàn fún Ọlọrun rí ààbò gbà. Lẹ́yìn náà, Jehofa yááfì omi náà, ní mímú kí ó ru gùdù padà bí àkúnya omi ńláǹlà, ó sì bo agbo ọmọ ogun Farao àti gbogbo ohun èlò wọn mọ́lẹ̀. Ẹ wo bí ìfihàn agbára àtọ̀runwá ṣe tó lórí àwọn ọlọrun tí kò já mọ́ nǹkan kan àti ipá ọmọ ogun ẹ̀dá ènìyàn! Dájúdájú, Jehofa ni ẹni tí ó yẹ kí a bẹ̀rù, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—Eksodu 14:21, 22, 28; 15:8.
Fífi Ìbẹ̀rù Wa fún Ọlọrun Hàn
15. Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìhùwà padà wa sí ìdáàbòbò alágbára tí Ọlọrun ṣe?
15 Bí a bá ti dúró ti Mose láìséwu, ó dájú pé à bá sún wa láti kọrin pé: “Ta ni ó dà bí ìwọ, OLUWA, nínú àwọn alágbára? ta ni ó dà bí ìwọ, ológo ní mímọ́, ẹlẹ́rù ní ìyìn, tí ń ṣe ohun ìyanu?” (Eksodu 15:11) A ti sọ irú èrò ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ ni àsọtúnsọ jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún láti ìgbà náà wá. Nínú ìwé tí ó kẹ́yìn Bibeli, aposteli Johannu ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun pé: “Wọ́n . . . ń kọ orin Mose ẹrú Ọlọrun ati orin Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa.” Kí ni orin ńlá náà? “Títóbi ati àgbàyanu ni awọn iṣẹ́ rẹ, Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè. Òdodo ati òótọ́ ni awọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo, nitori pé iwọ nìkan ni adúróṣinṣin?”—Ìṣípayá 15:2-4.
16, 17. Àgbàyanu ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni a rí tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí?
16 Nítorí náà, lónìí bákan náà, àwọn olùjọsìn tí a dá sílẹ̀ lómìnira wà, tí kì í ṣe kìkì iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọrun nìkan ni wọ́n mọrírì, wọ́n mọrírì àwọn òfin rẹ̀ pẹ̀lú. A ti dá àwọn ènìyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo sílẹ̀ lómìnira nípa tẹ̀mí, a ti yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé tí ó ti bàjẹ́ yìí, nítorí wọ́n mọ àwọn òfin òdodo Ọlọrun, wọ́n sì ń fi wọ́n sílò. Lọ́dọọdún, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń bọ́ lọ́wọ́ ayé tí ó ti díbàjẹ́ yìí láti lè gbé pẹ̀lú ètò àjọ mímọ́ tónítóní, adúróṣánṣán, ti àwọn olùjọsìn Jehofa. Láìpẹ́, lẹ́yìn tí a bá ti mú ìdájọ́ Ọlọrun, tí ó mú bí iná, ṣẹ lórí ìsìn èké àti ìyókù ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí, wọn yóò wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun òdodo.
17 Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá 14:6, 7, aráyé ń gbọ́ ìkìlọ̀ oníhìn iṣẹ́ ìdájọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń kéde lábẹ́ ìdarísọ́nà àwọn áńgẹ́lì nísinsìnyí. Ní ọdún tí ó kọjá, ní iye tí ó lé ní 230 ilẹ̀, nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun àti wákàtí ìdájọ́ rẹ̀. Láti lè dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún lílàájá, àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ìbẹ̀wò déédéé sí ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́fẹ̀ẹ́. Nípa báyìí, lọ́dọọdún, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń kọ́ ohun tí ó tó láti bẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ náà lọ́nà tí ó mọ́gbọ́n wá, wọ́n ń ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún un, wọ́n sì ń ṣe batisí. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ni tó pé, irú àwọn bẹ́ẹ̀ ti wá bẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ náà!—Luku 1:49-51; Ìṣe 9:31; fi wé Heberu 11:7.
18. Kí ni ó ṣàkàwé pé àwọn áńgẹ́lì ń lọ́wọ́ nínú ìwàásù wa?
18 Òtítọ́ ha ni pé àwọn áńgẹ́lì ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù yìí bí? Tóò, dájúdájú ó hàn gbangba pé, ìtọ́sọ́nà àwọn áńgẹ́lì ti sábà máa ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá sí ilé tí àwọn ọkàn tí ó kún fún ìdààmú ti ń yán hànhàn, tí wọ́n tilẹ̀ ń gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí! Fún àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa méjì, tí ọmọdé kan tẹ̀ lé, ń sọ nípa ìhìn rere náà ní erékùṣù Caribbean. Bí ó ti ń di ọwọ́ ìyálẹ̀ta, àwọn àgbàlagbà méjì yìí pinnu pé àwọn yóò ṣíwọ́ fún ti ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n ọmọ náà ní ìfẹ́ ọkàn láti bẹ ilé tí ó tẹ̀ lé e wò, èyí tí kì í fìgbà gbogbo rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó rí i pé àwọn àgbàlagbà náà kò fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní àkókò náà, ó dá lọ, ó sì kan ilẹ̀kùn. Ọ̀dọ́bìnrin kan ṣí ilẹ̀kùn. Nígbà tí àwọn àgbàlagbà náà rí èyí, wọ́n sún mọ́ ọn láti bá a sọ̀rọ̀. Ó ké sí wọn wọlé, ó sì ṣàlàyé pé, nígbà tí òun gbọ́ kíkàn ilẹ̀kùn, òun ń gbàdúrà pé kí Ọlọrun rán àwọn Ẹlẹ́rìí sí òun láti wá kọ́ òun ní Bibeli. Wọ́n ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
19. Kí ni a lè tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àǹfààní bíbẹ̀rù Ọlọrun?
19 Bí a ti ń fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ jíṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun, a tún ń fi àwọn òfin òdodo rẹ̀ kọ́ni. Nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àwọn wọ̀nyí sílò nínú ìgbésí ayé wọn, ó máa ń yọrí sí ìbùkún nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli ṣe kedere nípa dídá gbogbo ìwà pálapàla takọtabo lẹ́bi. (Romu 1:26‚ 27‚ 32) Lónìí, a ń pa ọ̀pá ìdiwọ̀n àtọ̀runwá tì ní ayé níbi gbogbo. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó ń forí ṣánpọ́n. Ìyapòkíì ń gogò sí i. Àwọn àrùn tí ń sọni di abirùn tàbí tí ń ṣekú pani tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré, tí ó ti di àjàkáyé ní ọ̀rúndún ogún yìí, ń tàn kálẹ̀. Ní ti gidi, àrùn bíbani lẹ́rù náà AIDS, dé ìwọ̀n àyè tí ó pọ̀, ń tàn kálẹ̀ nípasẹ̀ ìwà pálapàla takọtabo. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọrun kò ha ti fi ẹ̀rí jíjẹ́ ààbò gíga hàn fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ bí?—2 Korinti 7:1; Filippi 2:12; tún wo Ìṣe 15:28‚ 29.
Àwọn Ìyọrísí Bíbẹ̀rù Ọlọrun Nísinsìnyí
20. Kí ni ó ṣàkàwé pé àwọn mìíràn mọ̀ nípa orúkọ rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní?
20 Ìbùkún wà lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn tí ń bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn òfin rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣàkàwé mímọ̀ tí ń pọ̀ sí i nípa òkodoro òtítọ́ náà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn ará ẹlẹ́mìí àlàáfíà ti àwọn Kristian adúróṣánṣán ní ti ìwà híhù. Àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n jẹ́ àyànṣaṣojú ní àpéjọpọ̀ àgbáyé kan ní South America, dé sí hòtẹ́ẹ̀lì kan, tí àwùjọ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pẹ̀lú lò ní alẹ́ ọjọ́ kan láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ààrẹ orílẹ̀-èdè náà. Bí àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ ṣe ń kánjú mú olórí ìjọba náà wọ inú ẹ̀rọ agbéniròkè, Ẹlẹ́rìí kan tí kò mọ ẹni tí ó wà nínú ẹ̀rọ agbéniròkè wọ ibẹ̀, èyí jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi fún àwọn ẹ̀ṣọ́ náà! Nígbà tí ó mọ ohun tí òun ti ṣe, Ẹlẹ́rìí náà tọrọ àforíjì fún jíjá lù wọ́n. Ó fi báàjì àpéjọpọ̀ rẹ̀, tí ó ń fi í hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí hàn wọ́n, ó sì sọ pé òun kì í ṣe ẹni tí ó lè wu ààrẹ náà léwu. Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà sọ pé: “Bí gbogbo ènìyàn bá rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni, a kì bá tí nílò irú ìdáàbòbò báyìí.”—Isaiah 2:2-4.
21. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ni ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn lónìí?
21 Irú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni Jehofa ń kó jọ tí ó sì ń múra wọn sílẹ̀ nísinsìnyí láti ‘jáde wá lati inú ìpọ́njú ńlá náà,’ tí yóò fòpin sí ètò ìgbékalẹ̀ yìí. (Ìṣípayá 7:9‚ 10‚ 14) Irú lílàájá bẹ́ẹ̀ kì yóò ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Láti jẹ́ olùlàájá, ẹnì kan gbọ́dọ̀ bẹ̀rù Jehofa, kí ó sì mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ sí Ipò Ọba Aláṣẹ náà, kí ó sì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un. Bí ó ti wù kí ó rí, òkodoro òtítọ́ náà ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ ni kì yóò mú irú ìbẹ̀rù tí yóò mú wọn yẹ fún ààbò dàgbà. (Orin Dafidi 2:1-6) Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ẹ̀rí tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ti fi hàn, Alákòóso tí Jehofa ti yàn, Jesu Kristi, ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba láti ọdún líle koko náà, 1914 wá. Èyí túmọ̀ sí pé, àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti ń tán lọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti mú ìbẹ̀rù gbígbámúṣé fún Jehofa dàgbà kí wọ́n sì fi í hàn. Síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá wa ń yọ̀ọ̀da fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, àní àwọn tí wọ́n wà ní ipò agbára pàápàá, láti dáhùn padà pé: “Nítorí náà kí ẹ̀yin kí ó gbọ́n, ẹyin ọba: kí a sì kọ́ yín, ẹ̀yin onídàájọ́ ayé. Ẹ fi ìbẹ̀rù sin Oluwa, ẹ sì máa yọ̀ ti ẹ̀yin ti ìwárìrì. Fi ẹnu ko Ọmọ náà lẹ́nu, kí ó má ṣe bínú, ẹ̀yin a sì ṣègbé ní ọ̀nà náà, bí inú rẹ̀ bá ru díẹ̀ kíún. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.”—Orin Dafidi 2:7-12.
22. Kí ni ó wà ní ìpamọ́ fún àwọn tí ń bẹ̀rù Ọlọrun nísinsìnyí?
22 Ǹjẹ́ kí a wà lára àwọn tí yóò yin Ẹlẹ́dàá wa gẹ́gẹ́ bí Ẹni náà tí ó gbà wá là. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ń béèrè pé kí a bẹ̀rù Ọlọrun òtítọ́ náà nísinsìnyí! (Fi wé Orin Dafidi 2:11; Heberu 12:28; 1 Peteru 1:17.) A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti máa kọ́ àwọn àṣẹ òdodo rẹ̀ kí a sì ṣègbọràn sí wọn. Orin Mose àti ti Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí a kọ sílẹ̀ nínú Ìṣípayá 15:3‚ 4, yóò dé ògógóró rẹ̀ nígbà tí Jehofa yóò kásẹ̀ gbogbo ìwà ìkà orí ilẹ̀ ayé nílẹ̀, tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ènìyàn àti ilé ilẹ̀ ayé rẹ̀ tí a ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà jẹ́ lára dá kúrò lọ́wọ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀. Nígbà náà, pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, a óò kọrin pé: “Títóbi ati àgbàyanu ni awọn iṣẹ́ rẹ, Jehofa Ọlọrun, Olódùmarè. Òdodo ati òótọ́ ni awọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yoo bẹ̀rù rẹ níti gidi, Jehofa, tí kì yoo sì yin orúkọ rẹ lógo?”
O Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí Jehofa fi lẹ́tọ̀ọ́ sí ìbẹ̀rù wa gbígbámúṣé?
◻ Kí ni ohun tí Ọlọrun ṣàṣeparí rẹ̀ ní Òkun Pupa fi hàn?
◻ Àwọn àǹfààní wo ní ń wá láti inú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ wa fún Jehofa?
◻ Ọjọ́ ọ̀la wo ní ń dúró de àwọn tí ń bẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ náà nísinsìnyí?