Ilẹ̀ Ayé—Èé Ṣe Tí Ó Fi Wà Níhìn-ín?
Ìbéèrè kan wà tí ó yẹ kí o ronú lé lórí: Ṣé Ẹlẹ́dàá onílàákàyè tí ó ní ète fún ilẹ̀ ayé àti fún àwọn ènìyàn tí ó wà lórí rẹ̀ ni ó ṣẹ̀dá pílánẹ́ẹ̀tì wa ẹlẹ́wà? Wíwá ojútùú tí ó tẹ́ ọ lọ́rùn sí ìbéèrè yẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún pílánẹ́ẹ̀tì wa.
Ọ̀PỌ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa àgbáálá ayé àti ilẹ̀ ayé wa ti rí àwọn ẹ̀rí tí ó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà, pé Ọlọ́run ni ó wà lẹ́yìn rẹ̀. Ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí ọ̀kan ṣoṣo lára wọn sọ:
Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul Davies kọ̀wé nínú ìwé náà, The Mind of God pé: “Wíwà àgbáálá ayé tí ó wà létòlétò, tí ó ní àwọn ìṣètò dídíjú, tí ó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀, ń béèrè fún àwọn òfin àti ipò àrà ọ̀tọ̀.”
Lẹ́yìn jíjíròrò “àwọn àkọsẹ̀bá” mélòó kan tí àwọn onímọ̀ nípa ojú sánmà àti àwọn mìíràn ti ṣàkíyèsí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Davies fi kún un pé: “Nígbà tí a bá ronú lórí gbogbo rẹ̀, wọ́n pèsè ẹ̀rí wíwúnilórí pé ìwàláàyè, ní bí a ti mọ̀ ọ́n, sinmi pátápátá lórí àwọn apá pàtàkì nínú òfin físíìsì, àti lórí àwọn ohun tí ó jọ pé ó ṣèèṣì bọ́ sí i ní ti iye pàtó tí ipá ìṣẹ̀dá yàn fún onírúurú nǹkan, ìwọ̀n agbára, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. . . . Ti àsọdùn kọ́, bí a óò bá ṣe bí Ọlọ́run, kí a sì ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí yan oríṣiríṣi iye pàtó fún nǹkan wọ̀nyí nípa yíyí àwọn ìkànnì kan, a óò rí i pé yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ibi tí a yí àwọn ìkànnì náà sí ni yóò fòpin sí ìwàláàyè ní àgbáálá ayé. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ṣe ni ó jọ pé a ní láti fara balẹ̀ yí ìkànnì kọ̀ọ̀kan sí ọ̀gangan tí ó gún régé-régé bí ìwàláàyè yóò bá máa bá a nìṣó ní àgbáálá ayé. . . . Òtítọ́ náà pé kódà ìyípadà ṣín-ń-ṣín sí bí àwọn nǹkan ti rí lè sọ àgbáálá ayé di aláìṣeérí fún ènìyàn jẹ́ òtítọ́ tí ó ṣe pàtàkì gidi gan-an.”
Ohun tí ìwádìí wọ̀nyí túmọ̀ sí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn ni pé Ẹlẹ́dàá tí ó ní ète ni ó ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé wa, papọ̀ pẹ̀lú ìyókù àgbáálá ayé. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ó pọndandan kí a ṣàwárí ìdí tí ó fi ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé. Bí ó bá ṣeé ṣe, ó pọndandan pẹ̀lú pé kí a mọ ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé. Lórí kókó yìí, ohun kan tí ó ṣàjèjì rèé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àìgbọlọ́rungbọ́ gbajúmọ̀, ó yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá onílàákàyè. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ń fi ẹnu lásán sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run Olódùmarè àti Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé wa. Síbẹ̀, ó ṣọ̀wọ́n kí èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí fi ìdánilójú àti ìfọwọ́sọ̀yà sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ ayé nínú ète Ọlọ́run.
Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ó bọ́gbọ́n mu pé kí a yíjú sí orísun ìsọfúnni tí gbogbo gbòò gbà pé ó ti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wá. Bíbélì ni orísun yẹn. Ọ̀kan lára àwọn gbólóhùn tí ó rọrùn jù lọ, tí ó sì ṣe kedere jù lọ nínú rẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ ayé ni a rí nínú Oníwàásù 1:4. Ó kà pé: “Ìran kan lọ, ìran mìíràn sì bọ̀: ṣùgbọ́n ayé dúró títí láé.” (King James Version) Bíbélì sọjú abẹ níkòó nígbà tí ó ń ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé. Ó tún fi hàn pé ó fi sí ipò tí ó yẹ wẹ́kú ní àgbáálá ayé àti ibi tí ó yẹ kí ó wà sí oòrùn kí ìwàláàyè lè máa bá a nìṣó lórí rẹ̀. Ọlọ́run Olódùmarè mí sí wòlíì ìgbàanì náà, Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’”—Aísáyà 45:18.
Ṣùgbọ́n nípa pé ènìyàn lè ṣe àwọn ohun tí yóò fi pa gbogbo ìwàláàyè run kúrò lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Nínú ọgbọ́n rẹ̀ aláìláfiwé, Ọlọ́run polongo pé òun yóò dá sí i kí aráyé tó pa gbogbo ìwàláàyè run kúrò lórí pílánẹ́ẹ̀tì wa. Ṣàkíyèsí ìlérí tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ yìí nínú Ìṣípayá, ìwé tí ó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì: “Ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ sì dé, àti àkókò tí a yàn kalẹ̀ láti ṣèdájọ́ àwọn òkú, àti láti fi èrè wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ wòlíì àti fún àwọn ẹni mímọ́ àti fún àwọn tí ń bẹ̀rù orúkọ rẹ, ẹni kékeré àti ẹni ńlá, àti láti run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.
Jèhófà fi hàn wá ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó fi dá ilẹ̀ ayé, ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye yìí ní gbalasa òfuurufú, gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan tí ó ń yí ilẹ̀ ayé po ti ṣàpèjúwe rẹ̀. Ọlọ́run pète pé kí ó jẹ́ párádísè kárí ayé, tí àwọn ènìyàn—lọ́kùnrin àti lóbìnrin—kún inú rẹ̀ láìpọ̀ jù, tí gbogbo wọ́n ń gbé ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. Ó ṣètò láti fi àwọn ènìyàn kún pílánẹ́ẹ̀tì yìí díẹ̀díẹ̀ nípa fífàyègba tọkọtaya àkọ́kọ́ láti bímọ. Fún fàájì àti ìgbádùn tọkọtaya àkọ́kọ́, Jèhófà ṣe apá kéréje ilẹ̀ ayé ní párádísè. Bí ọmọ bíbí àwọn ìdílé ẹ̀dá ènìyàn yóò ti máa tẹ̀ síwájú ní àwọn ọdún àti ọ̀rúndún tí ó tẹ̀ lé e, ọgbà Édẹ́nì yóò máa fẹ̀ sí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ títí Jẹ́nẹ́sísì 1:28 yóò fi ní ìmúṣẹ, pé: “Ọlọ́run sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’”
Bí a ti wá rí ipò bíbaninínújẹ́ tí ilẹ̀ ayé àti àwọn olùgbé rẹ̀ wà nísinsìnyí, èyí ha túmọ̀ sí pé ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ilẹ̀ ayé ti forí ṣánpọ́n bí? Tàbí kẹ̀, ó ha ti yí ète rẹ̀ padà, tí ó sì ti pinnu pé nítorí ìwàkíwà aráyé, òun yóò jẹ́ kí wọ́n run pílánẹ́ẹ̀tì ọ̀hún pátápátá, kí òun sì tún wá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀? Ó tì o, kí ó dá wa lójú pé kò sí ìkankan nínú ipò wọ̀nyí tí ó jẹ́ òótọ́. Bíbélì sọ fún wa pé ohun yòówù tí Jèhófà bá pète gbọ́dọ̀ ṣẹ, bó pẹ́ bó yá, pé ẹnikẹ́ni tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ òjijì pàápàá kò lè ké ohun yòówù tí ó bá pinnu nígbèrí. Ó mú un dá wa lójú pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.
A Dá Ète Ọlọ́run Dúró fún Ìgbà Díẹ̀, A Kò Yí I Padà
Nígbà tí Ádámù àti Éfà yapa, tí a sì lé wọn kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, ó ṣe kedere pé ète Ọlọ́run fún párádísè ilẹ̀ ayé ni a óò mú ṣẹ láìsí wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, Jèhófà fi hàn níbẹ̀ yẹn gan-an pé àwọn kan lára ọmọ wọn yóò mú ohun tí òun pa láṣẹ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. Òtítọ́ ni, èyí yóò gba àkókò, àní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ṣùgbọ́n kò sí nǹkan kan tí ó tọ́ka sí àkókò tí ì bá gbà láti mú àṣẹ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ṣẹ kódà bí Ádámù àti Éfà bá ń wà láàyè nìṣó ní ìjẹ́pípé. Òtítọ́ náà ni pé nígbà tí ó bá máa fi di òpin Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi Jésù—èyí tí ó fi díẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún sí àkókò tí a wà yìí—àwọn ipò Párádísè tí ó wà ní Édẹ́nì yóò ti kárí ilẹ̀ ayé, pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé yóò sì kún fún àwọn àtọmọdọ́mọ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti aláyọ̀ ti tọkọtaya àkọ́kọ́. Ní tòótọ́, agbára Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùpète tí kò lè ṣàṣìṣe ni a óò dá láre títí láé!
Nígbà náà ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń ru ìmọ̀lára sókè tí Ọlọ́run mí sí tipẹ́tipẹ́ yóò ní ìmúṣẹ. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí Aísáyà 11:6-9 yóò ní ìmúṣẹ ológo: “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. Abo màlúù àti béárì pàápàá yóò máa jẹun; àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pa pọ̀. Kìnnìún pàápàá yóò jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Dájúdájú, ọmọ ẹnu ọmú yóò máa ṣeré lórí ihò ṣèbé; ihò tí ó ní ìmọ́lẹ̀, tí í ṣe ti ejò olóró ni ọmọ tí a já lẹ́nu ọmú yóò sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí ní ti gidi. Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”
Àìlera àti àìsàn tí kò gbóògùn yóò di ohun àtijọ́, àti ikú pàápàá. Kí ni ó tún lè ṣe kedere ju ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí a rí nínú ìwé tí ó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì? “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Bẹ́ẹ̀ ni, a lè fọkàn balẹ̀—pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé wa ẹlẹ́wà yóò wà títí lọ kánrin. Kí ó jẹ́ àǹfààní tìrẹ láti la òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí já, pẹ̀lú gbogbo ìṣe rẹ̀ tí ń run ilẹ̀ ayé. Ayé tuntun mímọ́ tónítóní tí Ọlọ́run yóò mú wá ti sún mọ́lé. Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ wa yóò sì jíǹde kúrò nínú ikú nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29) Lóòótọ́, ilẹ̀ ayé wa yóò wà títí lọ kánrin, àwa náà lè wà pẹ̀lú rẹ̀, kí a sì máa gbádùn rẹ̀.