Àwọn Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù—Ta ni Wọ́n?
NÍNÚ ìwé Ìṣe nínú Bíbélì àti nínú àwọn lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ, a mẹ́nu kan nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èèyàn, tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni tí wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:13) Àwọn kan nínú àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ pé a mọ ohun púpọ̀ nípa wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mọ̀ nípa ìgbòkègbodò Ápólò, Bánábà, àti Sílà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó lè ṣòro fún ẹ láti sọ ohun púpọ̀ nípa Ákípọ́sì, Kíláúdíà, Dámárì, Línúsì, Pésísì, Púdéńsì, tàbí Sópátérì.
Ní àwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ní àwọn ipò tó yàtọ̀ síra, ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ipa pàtàkì láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan bí Àrísítákọ́sì, Lúùkù, àti Tímótì sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àpọ́sítélì náà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn kan wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àwọn mìíràn wà pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́nu ìrìn àjò, yálà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń bá a rìnrìn àjò tàbí kí wọ́n gbà á lálejò. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn mìíràn bí Alẹkisáńdà, Démásì, Hẹmojẹ́nísì, àti Fíjẹ́lọ́sì, kò ní ìforítì nínú ẹ̀sìn Kristẹni.
Nípa ti àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù yóòkù, àwọn bí Asinkirítọ́sì, Hẹ́másì, Júlíà, tàbí Fílólógọ́sì kí á kàn mẹ́nu kàn díẹ̀ lára wọn, a ò mọ púpọ̀ nípa wọn ju orúkọ wọn tí a mọ̀ lọ. Ní ti arábìnrin Néréúsì tàbí màmá Rúfọ́ọ̀sì tàbí àwọn ará ilé Kílóè, a ò tilẹ̀ mọ orúkọ àwọn yẹn rárá. (Róòmù 16:13-15; 1 Kọ́ríńtì 1:11) Síbẹ̀síbẹ̀, àyẹ̀wò ìsọfúnni díẹ̀ táa ní nípa àwọn èèyàn bí ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ yìí jẹ́ ká mọ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣiṣẹ́ tó. Ó tún kọ́ wa ní ohun kan nípa àǹfààní tó wà nínú kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa yí wa ká, kí a sì jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀.
Àwọn Tí Wọ́n Bá A Rìnrìn Àjò, àti Àwọn Tó Gbà Á Lálejò
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kó rìnrìn àjò púpọ̀. Òǹkọ̀wé kan ṣírò rẹ̀ pé ibi tó rìnrìn àjò dé lórí ilẹ̀ àti lójú òkun gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú ìwé Ìṣe nìkan tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún kìlómítà [16,000]. Kì í ṣe pé ìrìn àjò nígbà náà ń tánni lókun nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún léwu. Lára àwọn ewu tó dojú kọ ni ọkọ̀ rírì, ewu odò àti àwọn ọlọ́ṣà, ewu aginjù, àti ewu òkun. (2 Kọ́ríńtì 11:25, 26) Gẹ́gẹ́ bó ti yẹ, Pọ́ọ̀lù kì í sábà dá rìnrìn àjò láti ibì kan sí ibì kan.
Àwọn tí wọ́n bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò yóò ti jẹ́ orísun ìfararora, ìṣírí, àti ìrànlọ́wọ́ tó gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Nígbà kan, Pọ́ọ̀lù fi wọ́n sẹ́yìn kí wọn bàa lè bójú tó àìní tẹ̀mí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́. (Ìṣe 17:14; Títù 1:5) Ṣùgbọ́n tí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ ẹni bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó ààbò ńlá ló jẹ́, ó sì tún ń ranni lọ́wọ́ láti lè kojú wàhálà ojú ọ̀nà. Nítorí náà, àwọn èèyàn bí Sópátérì, Síkúńdọ́sì, Gáyọ́sì, àti Tírófímù, àwọn táa mọ̀ pé wọ́n wà lára àwọn tí ń bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò ti ní láti di ipò pàtàkì mú nínú mímú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kẹ́sẹ járí.—Ìṣe 20:4.
Bákan náà ló tún mọrírì gbígbà tí àwọn kan gbà á lálejò. Bí Pọ́ọ̀lù bá dé ìlú kan tó ti fẹ́ wàásù tàbí tó fẹ́ sùn di ọjọ́ kejì, ohun tí yóò kọ́kọ́ ṣe ni pé yóò wá ibi tí yóò sùn. Ẹnikẹ́ni tó bá rin irú ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù rìn yìí yóò ní láti fara da sísun onírúurú ibùsùn. Ì bá kúkú máa sun ilé èrò nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n àwọn òpìtàn sọ pé àwọn ilé wọ̀nyí “léwu, ó sì kún fún ìwà ìbàjẹ́,” nítorí náà, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ilé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù ló sábà máa ń sùn.
A mọ̀ díẹ̀ lára orúkọ àwọn tó gba Pọ́ọ̀lù lálejò—Ákúílà àti Pírísíkà, Gáyọ́sì, Jásónì, Lìdíà, Mínásónì, Fílémónì, àti Fílípì. (Ìṣe 16:14, 15; 17:7; 18:2, 3; 21:8, 16; Róòmù 16:23; Fílémónì 1, 22) Ní Fílípì, Tẹsalóníkà, àti Kọ́ríńtì, irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ táa fi wọ̀ sí jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù rí ibi tó ti lè ṣètò ìgbòkègbodò míṣọ́nnárì rẹ̀. Ní Kọ́ríńtì, tọwọ́tẹsẹ̀ ni Títíọ́sì Jọ́sítù fi gba àpọ́sítélì náà sínú ilé rẹ̀, tó sì pèsè ibi tó ti lè máa gbà bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ fún un.—Ìṣe 18:7.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ Ọ̀rẹ́
Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, Pọ́ọ̀lù rántí àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ní onírúurú ọ̀nà nítorí pé ipò tó bá wọn yàtọ̀ síra. Fún àpẹẹrẹ, Màríà, Pésísì, Fébè, Tírífénà, àti Tírífósà jẹ́ àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, àwọn tó gbóríyìn fún nítorí òpò àti iṣẹ́ àṣekára wọn. (Róòmù 16:1, 2, 6, 12) Pọ́ọ̀lù ló ṣèrìbọmi fún Kírípọ́sì, Gáyọ́sì, àti agbo ilé Sítéfánásì. Ìgbà tó wà ní Áténì ni Díónísíù àti Dámárì tipasẹ̀ rẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́. (Ìṣe 17:34; 1 Kọ́ríńtì 1:14, 16) Andironíkọ́sì àti Júníásì, “ọkùnrin olókìkí láàárín àwọn àpọ́sítélì” tí wọ́n ti jẹ́ onígbàgbọ́ fún ìgbà pípẹ́ ṣáájú Pọ́ọ̀lù, ni a tún pè ní “òǹdè ẹlẹgbẹ́” rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti wà lẹ́wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀ ní àwọn àkókò kan. Àwọn méjì wọ̀nyí, bíi ti Hẹ́ródíónì, Jásónì, Lúkíọ́sì, àti Sósípátérì, ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí “ìbátan” òun. (Róòmù 16:7, 11, 21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò níhìn-ín lè túmọ̀ sí “ọmọ ìlú mi,” ohun tó túmọ̀ sí ní pàtàkì ni “ẹbí.”
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù bá a rìnrìn àjò nítorí ìhìn rere. Yàtọ̀ sí àwọn tí a mọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ dáadáa tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò, Ákáíkọ́sì, Fọ́túnátù, àti Sítéfánásì tún wà, àwọn tí wọ́n ti Kọ́ríńtì wá sí Éfésù láti bá Pọ́ọ̀lù jíròrò nípa ipò tẹ̀mí ìjọ wọn. Átémásì àti Tíkíkọ́sì ṣe tán láti rìnrìn àjò kí wọ́n lè lọ bá Títù, ẹni tí ń sìn ní erékùṣù Kírétè, Sénásì sì ní láti bá Ápólò rìnrìn àjò.—1 Kọ́ríńtì 16:17; Títù 3:12, 13.
Àwọn kan tún wà tí Pọ́ọ̀lù fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ díẹ̀ tó fani mọ́ra nípa wọn. Fún àpẹẹrẹ, a sọ fún wa pé, Épénétù ni, “àkọ́so Éṣíà,” ó sọ pé Érásítù jẹ́ “ìríjú ìlú ńlá” ní Kọ́ríńtì, ó ní Lúùkù jẹ́ oníṣègùn, ó ní Lìdíà ń ta ohun aláwọ̀ àlùkò, Pọ́ọ̀lù tún jẹ́ ká mọ̀ pé Tẹ́tíọ́sì ni ó bá òun kọ lẹ́tà tóun kọ sí àwọn ará Róòmù. (Róòmù 16:5, 22, 23; Ìṣe 16:14; Kólósè 4:14) Fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn èèyàn wọ̀nyẹn, bí àwọn ìsọfúnni yìí ṣe kúrú tó wọ́n fani mọ́ra gan-an.
Àwọn mìíràn lára àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù rí ìhìn iṣẹ́ gbà, tó sì ti wá di apá kan Bíbélì báyìí. Fún àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Kólósè, Pọ́ọ̀lù gba Ákípọ́sì níyànjú pé: “Máa ṣọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí o tẹ́wọ́ gbà nínú Olúwa, kí o lè mú un ṣẹ.” (Kólósè 4:17) Ó dájú pé Yúódíà àti Síńtíkè ní èdè àìyedè kan tí wọ́n fẹ́ yanjú. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù lo ẹnì kan tó pè ní “alájọru àjàgà” àmọ́ tí kò dárúkọ rẹ̀, tí onítọ̀hún sì wà ní Fílípì láti gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “ní èrò inú kan náà nínú Olúwa.” (Fílípì 4:2, 3) Dájúdájú, ìmọ̀ràn rere lèyí jẹ́ fún wa.
Ìtìlẹ́yìn Gbágbáágbá Nígbà Tó Wà Lẹ́wọ̀n
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n. (2 Kọ́ríńtì 11:23) Ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn àwọn Kristẹni àdúgbò, ní àwọn àgbègbè tí wọ́n bá wà, á ti gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí ó fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Róòmù, wọ́n yọ̀ǹda fún un pé kó háyà ilé tirẹ̀ lọ́tọ̀ fún ọdún méjì, wọ́n sì yọ̀ǹda pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 28:30) Ní àkókò yẹn, ó kọ̀wé sí àwọn ìjọ tó wà ní Éfésù, Fílípì, àti Kólósè, ó tún kọ̀wé sí Fílémónì. Àwọn ìsọfúnni wọ̀nyí jẹ́ ká mọ púpọ̀ nípa àwọn tó sún mọ́ Pọ́ọ̀lù nígbà tó wà ní àhámọ́.
Fún àpẹẹrẹ, a gbọ́ pé Ónẹ́símù, ẹrú Fílémónì tó sá lọ, ṣe kòńgẹ́ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, bẹ́ẹ̀ náà ni Tíkíkọ́sì, ẹni tí yóò wá mú Ónẹ́símù padà lọ bá ọ̀gá rẹ̀. (Kólósè 4:7-9) Ẹlòmíràn tún ni Ẹpafíródítù, ẹni tó rìnrìn àjò wá láti iyàn-niyàn Fílípì, tó kó ẹ̀bùn wá látọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀, tí àìsàn sì dá a wó nígbà tó débẹ̀. (Fílípì 2:25; 4:18) Àrísítákọ́sì, Máàkù, àti Jésù tí wọ́n ń pè ní Jọ́sítù tún wà lára àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pọ́ọ̀lù ní Róòmù, àwọn tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn pé: “Àwọn wọ̀nyí nìkan ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.” (Kólósè 4:10, 11) Pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí, Tímótì àti Lúùkù táa mọ̀ bí ẹní mowó kò gbẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Démásì, ẹni tó tìtorí ìfẹ́ fún ayé pa Pọ́ọ̀lù tì nígbà tó yá.—Kólósè 1:1; 4:14; 2 Tímótì 4:10; Fílémónì 24.
Ó ṣe kedere pé, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó jẹ́ ọmọ Róòmù, síbẹ̀ wọ́n dúró ti Pọ́ọ̀lù gbágbáágbá. Bóyá àwọn kan tilẹ̀ ti lọ ràn án lọ́wọ́ nígbà tó fi wà lẹ́wọ̀n. Kò sí àní-àní pé àwọn kan ń jíṣẹ́ fún Pọ́ọ̀lù, ó rán àwọn mìíràn níṣẹ́ lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, ó sì ń pe lẹ́tà fún àwọn mìíràn kí wọ́n lè bá a kọ ọ́ sílẹ̀. Ẹ̀rí lílágbára mà ní èyí jẹ́ o láti jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn wọ̀nyí ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, wọ́n dúró tì í gbágbáágbá, wọn kò sì fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú iṣẹ́ Ọlọ́run!
Láti inú àwọn ọ̀rọ̀ ìkádìí lẹ́tà Pọ́ọ̀lù kan, a lóye pé ó ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n yí i ká pọ̀ ju àwọn orúkọ díẹ̀ táa mọ̀ lọ. Ní àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹni mímọ́ kí yín,” ó tún sọ pé, “gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi kí ọ.”—2 Kọ́ríńtì 13:13; Títù 3:15; Fílípì 4:22.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nígbà kejì ní Róòmù, nígbà tí ikú ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù ló gbà á lọ́kàn. Ó ṣì jẹ́ ògbóṣáṣá nínú bíbójútó àti ṣíṣe kòkárí àwọn ìgbòkègbodò àwọn kan lára wọn. Ó ti rán Títù àti Tíkíkọ́sì níṣẹ́, Kírẹ́sẹ́ńsì ti lọ sí Gálátíà, Érásítù ti dúró sí Kọ́ríńtì, Tírófímù wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn ní Mílétù, ṣùgbọ́n Máàkù àti Tímótì yẹ kí wọ́n wá bá a. Ṣùgbọ́n Lúùkù kò fi Pọ́ọ̀lù sílẹ̀, nígbà tí àpọ́sítélì náà sì ń kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí Tímótì, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́, títí kan Yúbúlọ́sì, Púdéńsì, Línúsì, àti Kíláúdíà, wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti fi ìkíni wọn ránṣẹ́. Kò sí àní-àní pé wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Lọ́wọ́ kan náà, Pọ́ọ̀lù alára fi ìkíni ránṣẹ́ sí Pírísíkà àti Ákúílà àti agboolé Ónẹ́sífórù. Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé ní àkókò ìdààmú yẹn, Démásì kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Alẹkisáńdà sì ṣe é léṣe púpọ̀.—2 Tímótì 4:9-21.
“Àwa Jẹ́ Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run”
Pọ́ọ̀lù kì í sábà dá wàásù. Alálàyé E. Earle Ellis sọ pé: “Ohun tó fara hàn kedere ni míṣọ́nnárì kan tó ní àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní tòótọ́, ó ṣọ̀wọ́n láti rí kí Pọ́ọ̀lù máa dá ṣiṣẹ́.” Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti ru ọ̀pọ̀ èèyàn sókè, kó sì ṣètò iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó gbéṣẹ́. Àwọn alájọṣiṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn, àwọn olùrànlọ́wọ́ fún ìgbà díẹ̀, àwọn kan tí wọ́n jẹ́ alákitiyan, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ ni wọ́n yí i ká. Síbẹ̀, àwọn wọ̀nyí kì í wulẹ̀ ṣe alábàáṣiṣẹ́pọ̀ lásán. Láìka ìwọ̀n tí wọ́n bá Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ mọ sí, tàbí bí wọn ṣe rìn mọ́ ọn tó, ìdè ìfẹ́ Kristẹni àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín wọn ṣe kedere.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ohun kan tí a pè ní “ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ fún bíbáni dọ́rẹ̀ẹ́.” Ó gbìyànjú gidigidi láti mú ìhìn rere náà tọ àwọn orílẹ̀-èdè lọ, ṣùgbọ́n kò gbìyànjú láti dá a ṣe. Ó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ Kristẹni tí wọ́n dá sílẹ̀, ó sì lo ìṣètò náà dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Pọ́ọ̀lù kò gbé ògo kankan fún ara rẹ̀ nítorí àṣeyọrí tó ṣe ṣùgbọ́n ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ẹrú lòun àti pé gbogbo ọlá yẹ kó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹni tó mú kí ìdàgbàsókè náà ṣeé ṣe.—1 Kọ́ríńtì 3:5-7; 9:16; Fílípì 1:1.
Àkókò Pọ́ọ̀lù yàtọ̀ sí tiwa, ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ẹnì kankan nínú ìjọ Kristẹni lónìí tó yẹ kó retí pé òun lè máa dá nǹkan tòun ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ètò àjọ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìjọ àdúgbò wa, àti pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. A nílò ìrànlọ́wọ́ wọn, ìtìlẹ́yìn wọn, àti ìtùnú ní àkókò rere àti ní àkókò ìdààmú. A ní àǹfààní ṣíṣeyebíye ti jíjẹ́ apá kan ‘ẹgbẹ́ àwọn ará nínú ayé.’ (1 Pétérù 5:9) Báa bá fi tòótọ́tòótọ́ àti tìfẹ́tìfẹ́ bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí a sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú gbogbo wọn, nígbà náà gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, àwa pẹ̀lú lè sọ pé “àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 3:9.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
ÁPÓLÒ
ÀRÍSÍTÁKỌ́SÌ
BÁNÁBÀ
LÌDÍÀ
ÓNẸ́SÍFÓRÙ
TẸ́TÍỌ́SÌ
TÍKÍKỌ́SÌ