Àkọsílẹ̀ Jòhánù
15 “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni ẹni tó ń dáko. 2 Ó ń mú gbogbo ẹ̀ka tí kì í so èso nínú mi kúrò, ó sì ń wẹ gbogbo èyí tó ń so èso mọ́, kó lè so èso púpọ̀ sí i.+ 3 Ẹ ti mọ́ torí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.+ 4 Ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, màá sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín. Bí ẹ̀ka ò ṣe lè dá so èso àfi tó bá dúró lára àjàrà, ẹ̀yin náà ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, àfi tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi.+ 5 Èmi ni àjàrà náà; ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni yìí ń so èso púpọ̀;+ torí láìsí èmi, ẹ ò lè ṣe ohunkóhun. 6 Tí ẹnikẹ́ni ò bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, a máa sọ ọ́ nù bí ẹ̀ka, á sì gbẹ. Àwọn èèyàn á kó àwọn ẹ̀ka yẹn jọ, wọ́n á sọ wọ́n sínú iná, wọ́n á sì jóná. 7 Tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí àwọn ọ̀rọ̀ mi sì wà nínú yín, ẹ béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, ó sì máa rí bẹ́ẹ̀ fún yín.+ 8 Èyí ń fògo fún Baba mi, pé ẹ̀ ń so èso púpọ̀, ẹ sì fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín.+ 9 Bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ mi,+ èmi náà nífẹ̀ẹ́ yín; ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. 10 Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ máa dúró nínú ìfẹ́ mi, bí mo ṣe pa àwọn àṣẹ Baba mọ́ gẹ́lẹ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.
11 “Mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ayọ̀ mi lè wà nínú yín, kí ayọ̀ yín sì lè kún rẹ́rẹ́.+ 12 Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.+ 13 Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.+ 14 Ọ̀rẹ́ mi ni yín, tí ẹ bá ń ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.+ 15 Mi ò pè yín ní ẹrú mọ́, torí pé ẹrú kì í mọ ohun tí ọ̀gá rẹ̀ ń ṣe. Àmọ́ mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi. 16 Ẹ̀yin kọ́ lẹ yàn mí, èmi ni mo yàn yín, mo sì yàn yín pé kí ẹ lọ, kí ẹ túbọ̀ máa so èso, kí èso yín ṣì máa wà, kó lè jẹ́ pé tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.+
17 “Mò ń pa àwọn nǹkan yìí láṣẹ fún yín, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 18 Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín.+ 19 Tí ẹ bá jẹ́ apá kan ayé, ayé máa nífẹ̀ẹ́ ohun tó jẹ́ tirẹ̀. Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé,+ àmọ́ mo ti yàn yín látinú ayé, torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.+ 20 Ẹ fi ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín sọ́kàn pé: Ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà;+ tí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n máa pa ọ̀rọ̀ yín náà mọ́. 21 Àmọ́ wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ Ẹni tó rán mi.+ 22 Ká ní mi ò wá bá wọn sọ̀rọ̀ ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan.+ Àmọ́ ní báyìí, wọn ò ní àwíjàre kankan fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ 23 Ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra mi kórìíra Baba mi náà.+ 24 Ká ní mi ò ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹnì kankan ò ṣe rí láàárín wọn ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan;+ àmọ́ ní báyìí wọ́n ti rí mi, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi. 25 Àmọ́ èyí ṣẹlẹ̀ torí kí ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn lè ṣẹ pé: ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’+ 26 Nígbà tí olùrànlọ́wọ́ tí màá rán sí yín látọ̀dọ̀ Baba bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ tó wá látọ̀dọ̀ Baba, ó máa jẹ́rìí nípa mi;+ 27 kí ẹ̀yin náà sì jẹ́rìí,+ torí pé ẹ ti wà pẹ̀lú mi láti ìbẹ̀rẹ̀.