Ìrántí Ikú Kristi Ń Mú Ká Wà Níṣọ̀kan
‘Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé ká máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!’—SM. 133:1.
1, 2. Ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ló máa mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan lọ́dún 2018, kí sì nìdí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
NÍRỌ̀LẸ́ March 31, 2018, àwa èèyàn Jèhófà àtàwọn míì tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa kóra jọ fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Bí àsìkò ṣe ń tó ní apá ibi gbogbo láyé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn máa kóra jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ọdọọdún ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù yìí máa ń mú káwa èèyàn Jèhófà kárí ayé túbọ̀ wà níṣọ̀kan.
2 Ẹ wo bí inú Jèhófà àti Jésù ṣe máa ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn níbi gbogbo láyé ń kóra jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, bẹ̀rẹ̀ látọwọ́ ìrọ̀lẹ́ títí ilẹ̀ fi máa ṣú. Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò [ní] lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Ó sọ pé wọ́n á máa kọrin sókè pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.” (Ìṣí. 7:9, 10) Kò sí àní-àní pé ṣe là ń bọlá fún Jèhófà àti Jésù bá a ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún!
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè kan tó jẹ yọ. (1) Báwo ni gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè múra sílẹ̀ ká sì jàǹfààní nínú Ìrántí Ikú Kristi? (2) Àwọn ọ̀nà wo ni Ìrántí Ikú Kristi ń gbà mú káwa èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan? (3) Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè pa kún ìṣọ̀kan yìí? (4) Ṣé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó kẹ́yìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo ni?
BÁ A ṢE LÈ MÚRA SÍLẸ̀ KÁ SÌ JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣe gbogbo ohun tó bá gbà ká lè wà níbi Ìrántí Ikú Kristi?
4 Máa ronú nípa ìdí tó fi yẹ kó o máa pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Máa fi sọ́kàn pé lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ wà lára ìjọsìn rẹ. Mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù ń kíyè sí gbogbo àwọn tó ń sapá láti pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi, tó jẹ́ ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ́dún. A fẹ́ kí Jèhófà àti Jésù mọ̀ pé a máa ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti wá síbi Ìrántí Ikú Kristi àfi tó bá kọjá agbára wa tàbí torí àìlera tó le gan-an. Tá a bá ń fi hàn pé ìpàdé ṣe pàtàkì sí wa, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ kí orúkọ wa wà nínú “ìwé ìrántí” ìyẹn “ìwé ìyè,” níbi tí orúkọ àwọn tó máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun wà.—Mál. 3:16; Ìṣí. 20:15.
5. Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, báwo la ṣe lè ‘dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́’?
5 Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, ká sì ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5.) Báwo la ṣe lè ṣe é? Bíbélì ní ká máa ‘dán ara wa wò bóyá a wà nínú ìgbàgbọ́.’ Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mo gbà lóòótọ́ pé inú ètò kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ sí tó sì ń lò ni mo wà yìí? Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí mo sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Ǹjẹ́ ìwà mi ń fi hàn pé mo gbà lóòótọ́ pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí àti pé òpin ètò Sátánì ti sún mọ́lé? Ṣé mo ṣì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti Jésù bí mo ṣe ní in nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara mi sí mímọ́?’ (Mát. 24:14; 2 Tím. 3:1; Héb. 3:14) Tá a bá ń ronú lórí irú àwọn ìbéèrè yìí, á ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tá a jẹ́ gan-an.
6. (a) Kí lohun kan ṣoṣo tó lè mú ká jogún ìyè? (b) Báwo ni alàgbà kan ṣe máa ń múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, báwo ni ìwọ náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
6 Ka àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run tó sọ̀rọ̀ nípa bí Ìrántí Ikú Kristi ti ṣe pàtàkì tó, kó o sì ṣàṣàrò lé wọn lórí. (Ka Jòhánù 3:16; 17:3.) Ohun kan ṣoṣo tó lè mú ká jogún ìyè àìnípẹ̀kun ni pé ká ‘gba ìmọ̀’ Jèhófà ká sì máa “lo ìgbàgbọ́” nínú Jésù, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Tó o bá fẹ́ múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi, á dáa kó o dìídì ṣètò láti ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa lọ́nà táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù. Ẹ wo ohun tí alàgbà kan máa ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Ó máa ń tọ́jú àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ìrántí Ikú Kristi àti bí ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní fún wa ti pọ̀ tó. Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, ó máa ń tún àwọn àpilẹ̀kọ yẹn kà, ó sì máa ń ṣàṣàrò lórí ìdí tí Ìrántí Ikú Kristi fi ṣe pàtàkì. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ó tún máa ń fi àwọn àpilẹ̀kọ míì kún àwọn tó ti ní tẹ́lẹ̀. Alàgbà yìí wá rí i pé ọdọọdún lòun ń kọ́ ohun tuntun bóun ṣe ń ka àwọn àpilẹ̀kọ yẹn àti bóun ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a máa ń kà nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ọdọọdún ni ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà àti Jésù ń jinlẹ̀ sí i. Tíwọ náà bá a ń ṣe bíi ti alàgbà yìí, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà àti Jésù máa jinlẹ̀ sí i, wàá túbọ̀ mọyì wọn, wàá sì jàǹfààní kíkún nínú Ìrántí Ikú Kristi.
BÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI ṢE Ń MÚ KÁ WÀ NÍṢỌ̀KAN
7. (a) Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, kí ló gbàdúrà fún? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn?
7 Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, Jésù gbàdúrà pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wà níṣọ̀kan bí òun pẹ̀lú Baba òun ti wà. (Ka Jòhánù 17:20, 21.) Ó dájú pé Jèhófà dáhùn àdúrà tí Jésù gbà lálẹ́ ọjọ́ yẹn, torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá gbà pé Jèhófà ló rán Jésù wá sáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpàdé wa máà ń mú ká wà níṣọ̀kan, Ìrántí Ikú Kristi túbọ̀ mú kó ṣe kedere pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà níṣọ̀kan. Àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọ̀ wọn sì yàtọ̀ síra máa ń kóra jọ pọ̀ láwọn ibi ìpàdé wa kárí ayé. Láwọn ibì kan, àwọn kan ò gbà pé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tí àwọ̀ wọn tàbí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra máa kóra jọ láti jọ́sìn pa pọ̀. Tí wọ́n bá sì rí irú ẹ̀, ṣe ni inú máa ń bí wọn. Àmọ́ irú ìkórajọpọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà àti Jésù dùn!
8. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì nípa ìṣọ̀kan àwa èèyàn Ọlọ́run?
8 Kò ya àwa èèyàn Jèhófà lẹ́nu pé a wà níṣọ̀kan. Kódà Jèhófà ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀. Ó sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó so ọ̀pá méjì pọ̀, ọ̀pá kan “fún Júdà” àti ìkejì “fún Jósẹ́fù.” (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:15-17.) “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ July 2016 ṣàlàyé pé: “Jèhófà fi ọkàn àwọn èèyàn rẹ̀ balẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé wọ́n máa pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n á sì tún pa dà di orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún jẹ́ ká mọ bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa wà níṣọ̀kan láwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”
9. Kí ló mú ká gbà pé àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ nípa ìṣọ̀kan ń nímùúṣẹ nígbà Ìrántí Ikú Kristi?
9 Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919 ni Jèhófà ti ń tún àwọn ẹni àmì òróró tá a lè pè ní “Júdà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tò, ó sì ń mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan. Bí àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé tí wọ́n dà bí igi “Jósẹ́fù” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró ti mú kí àwùjọ méjèèjì di “agbo kan.” (Jòh. 10:16; Sek. 8:23) Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa so igi méjèèjì pọ̀, wọ́n á sì di ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ òun. (Ìsík. 37:19) Ní báyìí, àwùjọ méjèèjì ń ṣiṣẹ́ sìn pa pọ̀ lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi Ọba tá a ṣe lógo, ẹni tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì pè ní “Dáfídì ìránṣẹ́” Ọlọ́run. (Ìsík. 37:24, 25) Ọdọọdún ni ìṣọ̀kan tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ máa ń hàn kedere nígbà táwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” bá kóra jọ pọ̀ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́, kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti pa kún ìṣọ̀kan yìí?
BÁ A ṢE LÈ PA KÚN ÌṢỌ̀KAN WA
10. Báwo la ṣe lè pa kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run?
10 Ọ̀nà kan tá a lè gbà pa kún àlàáfíà tó wà láàárín wa ni pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. (Mát. 23:12) Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, a ò ní jẹ́ kí ìgbéraga tó wọ́pọ̀ nínú ayé yìí wọ̀ wá lẹ́wù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a ní máa mú ká jẹ́ onígbọràn sáwọn tó ń mú ipò iwájú, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ àá máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ inú Jèhófà máa dùn sí wa torí pé ó ń “kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pét. 5:5.
11. Tá a bá ń ronú nípa ohun táwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún, báwo nìyẹn ṣe lè mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan?
11 Ọ̀nà kejì tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa ronú lórí ohun táwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún. Kó tó di alẹ́ ọjọ́ yẹn àti lálẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an, ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí àkàrà aláìwú àti wáìnì pupa náà ṣàpẹẹrẹ. (1 Kọ́r. 11:23-25) Àkàrà aláìwú dúró fún ara pípé tí Jésù fi rúbọ, wáìnì náà sì dúró fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ta sílẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe pé ká kàn lóye ohun táwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ yẹn dúró fún nìkan. Ó tún yẹ ká máa rántí pé ńṣe ni ìràpadà Jésù mú ká túbọ̀ mọyì bí Jèhófà àti Jésù ṣe fìfẹ́ tó ga jù lọ hàn sí wa. Jèhófà yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún wa, Jésù náà sì fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Tá a bá ń ronú lórí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí wa yìí, á mú káwa náà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn. Ìfẹ́ tí gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run ní fún Jèhófà dà bí okùn tó so gbogbo wa pọ̀ tó sì ń mú ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan.
12. Kí ni Jésù sọ nínú àpèjúwe kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká máa dárí ji ara wa?
12 Ọ̀nà kẹta tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa dárí ji ara wa ní fàlàlà. Tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ṣe là ń fi hàn pé a mọrírì bí Jèhófà ṣe ń dárí àwọn ẹ̀sẹ̀ tiwa náà jì wá lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. Ṣó o ráńtí ìtàn tí Jésù sọ nípa ọba kan àtàwọn ẹrú rẹ̀ nínú Mátíù 18:23-34? Pẹ̀lú ìtàn yẹn lọ́kàn rẹ, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń fi ohun tí Jésù kọ́ wa sílò? Ǹjẹ́ mo máa ń fi sùúrù bá àwọn ará lò, ṣé mo sì máa ń gba tiwọn rò? Ṣé mo ṣe tán láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ mí?’ Lóòótọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó lè nira gan-an fún àwa èèyàn láti dárí rẹ̀ jini. Síbẹ̀, àpèjúwe yẹn sọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká ṣe. (Ka Mátíù 18:35.) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ò ní dárí jì wá tá ò bá dárí ji àwọn ará wa nígbà tó bá yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yẹn gbàrònú! Tá a bá ń dárí ji àwọn ẹlòmíì bí Jésù ṣe kọ́ wa, àá mú kí ìsọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára, ohunkóhun ò sì ní da àárín wa rú.
13. Tá a bá lẹ́mìí àlàáfíà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan?
13 Tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Má gbàgbé ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká “máa fi taratara sakun láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Torí náà, lásìkò Ìrántí Ikú Kristi yìí pàápàá jù lọ lálẹ́ ọjọ́ tá a máa ṣe é, ronú jinlẹ̀ lórí bó o ṣe máa ń bá àwọn míì lò. Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ mí sẹ́ni tó ń tètè dárí jini? Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ pé mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba?’ Àwọn ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì, ó sì gba ìrònú gan-an lásìkò Ìrántí Ikú Kristi.
14. Báwo la ṣe lè máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́’?
14 Ọ̀nà kẹrin tá a lè gbà mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa túbọ̀ lágbára ni pé ká máa nífẹ̀ẹ́ bíi ti Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Ó dájú pé kò sẹ́nì kankan lára wa tó máa sọ nípa àwọn ará míì pé, “Ṣebí wọ́n ṣáà ti ní ká nífẹ̀ẹ́, mo lè nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ kò jù bẹ́ẹ̀ lọ”! Irú èrò bẹ́ẹ̀ lòdì sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá pé ká máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́.’ (Éfé. 4:2) Kì í wulẹ̀ ṣe pé ká kàn máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’ Ó tún fi kún un pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ “nínú ìfẹ́.” Ẹ kíyè sí i pé ìyàtọ̀ wà níbẹ̀. Onírúurú èèyàn ló wà nínú ìjọ wa, Jèhófà ló sì fa gbogbo wọn wá ṣọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Jòh. 6:44) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fà wọ́n ṣọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó dájú pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Báwo la ṣe máa wá sọ pé Kristẹni kan ò yẹ lẹ́ni téèyàn nífẹ̀ẹ́? Torí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa dénú, kì í ṣe ìfẹ́ ojú lásán!—1 Jòh. 4:20, 21.
ÌGBÀ WO LA MÁA ṢE ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI TÓ KẸ́YÌN?
15. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó kẹ́yìn?
15 Ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó kẹ́yìn. Báwo la ṣe mọ̀? Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà nílùú Kọ́ríńtì, ó sọ pé bí wọ́n ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún, ṣe ni wọ́n “ń pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.” (1 Kọ́r. 11:26) Dídé Olúwa tí Pọ́ọ̀lù sọ níbí ń tọ́ka sí ìgbà tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa dé lákòókò òpin. Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, ó sọ pé: “Àmì Ọmọ ènìyàn yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò, wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá. [Jésù] yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí, wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti ìkángun kan ọ̀run sí ìkángun rẹ̀ kejì.” (Mát. 24:29-31) Kíkó tí a óò ‘kó àwọn àyànfẹ́ jọ pọ̀’ ń tọ́ka sí ìgbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù máa lọ gba èrè wọn ní ọ̀run. Èyí máa wáyé lẹ́yìn tí apá ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá àmọ́ ṣáájú ogun Amágẹ́dọ́nì. Ẹ̀yìn náà ni àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ṣẹ́gun àwọn ọba ayé. (Ìṣí. 17:12-14) Ìrántí Ikú Kristi tá a bá ṣe kẹ́yìn ká tó kó àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lọ sọ́run la máa ṣe gbẹ̀yìn, torí pé Jésù á ti dé nígbà yẹn.
16. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá wà níbi Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí?
16 Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa wà níbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe ní March 31, 2018 ká lè jàǹfààní ní kíkún. Ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìṣọ̀kan wa túbọ̀ lágbára. (Ka Sáàmù 133:1.) Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó gbẹ̀yìn. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà níbi Ìrántí Ikú Kristi, ká sì rí i pé a mọyì ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa.