ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—LÚÙKÙ 22:19.
ORIN 19 Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Kí nìdí tá a fi ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún?
NÍ NǸKAN tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí wa ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, ó ṣe ìpàdé ráńpẹ́ kan pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó lo búrẹ́dì àti wáìnì níbẹ̀, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa rántí bóun ṣe kú nítorí tiwọn.—1 Kọ́r. 11:23-26.
2 A máa ń pa àṣẹ Jésù yìí mọ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Jòh. 14:15) Lọ́dọọdún, láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a máa ń gbàdúrà, a sì máa ń ronú dáadáa nípa ìdí tí Jésù fi kú, ká lè fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, inú wa máa ń dùn láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lákòókò yẹn, a sì máa ń pe ọ̀pọ̀ èèyàn pé kí wọ́n wá dara pọ̀ mọ́ wa níbi ìpàdé pàtàkì náà. Àwa fúnra wa sì máa ń rí i dájú pé ohunkóhun ò dí wa lọ́wọ́ láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́jọ́ náà.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè rántí ọjọ́ tí Jésù kú. Àwọn nǹkan mẹ́ta tá a máa ń ṣe lákòókò náà ni: (1) a máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi bí Jésù ṣe ní ká ṣe é, (2) a máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti (3) a kì í jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi.
A MÁA Ń ṢE ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI BÍ JÉSÙ ṢE NÍ KÁ ṢE É
4. Lọ́dọọdún, àwọn ìbéèrè wo la máa ń rí ìdáhùn wọn níbi Ìrántí Ikú Kristi, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn? (Lúùkù 22:19, 20)
4 Lọ́dọọdún, níbi Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń gbọ́ àsọyé Bíbélì tó ń jẹ́ ká rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì kan. Àsọyé yẹn máa ń jẹ́ ká mọ ìdí tí aráyé fi nílò ìràpadà àti bí ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe gba ọ̀pọ̀ èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. A tún máa ń rán wa létí ohun tí búrẹ́dì àti wáìnì tá a máa ń lò níbi Ìrántí Ikú Kristi ṣàpẹẹrẹ àtàwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ, kí wọ́n sì mu nínú rẹ̀. (Ka Lúùkù 22:19, 20.) Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáwọn tó nírètí láti gbé ayé. (Àìsá. 35:5, 6; 65:17, 21-23) Òótọ́ làwọn nǹkan tá à ń gbọ́ níbi àsọyé yẹn, kò sì yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú wọn. Àìmọye èèyàn ni ò mọ àwọn nǹkan yìí, wọn ò sì mọyì bí Jésù ṣe kú nítorí wa. Bákan náà, wọn kì í ṣe Ìrántí Ikú Kristi bí Jésù ṣe ní ká ṣe é. Kí nìdí?
5. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, báwo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
5 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà wọnú ìjọ Kristẹni. (Mát. 13:24-27, 37-39) Wọ́n sọ “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Ọ̀kan lára “àwọn ọ̀rọ̀ békebèke” táwọn Kristẹni afàwọ̀rajà yẹn fi ń kọ́ni ni pé Jésù ò fi ara ẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé, kó lè ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀” bí Bíbélì ṣe sọ. Àmọ́ wọ́n ń kọ́ni pé Jésù gbọ́dọ̀ fi ara ẹ̀ rúbọ léraléra. (Héb. 9:27, 28) Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gba ẹ̀kọ́ èké yìí gbọ́. Wọ́n máa ń péjọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, nígbà míì lójoojúmọ́, kí wọ́n lè ṣe ààtò kan tí wọ́n ń pè ní “Máàsì.”b Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì míì kì í ṣe é lemọ́lemọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ ìjọ wọn ni ò mọ ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ. Àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Ṣé ikú Jésù máa jẹ́ kí n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà?’ Kí nìdí tí wọ́n fi ń béèrè bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tí ò gbà pé ikú Jésù máa jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà ló ń mú kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣiyèméjì. Àmọ́, báwo làwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń ran àwọn èèyàn yìí lọ́wọ́?
6. Lọ́dún 1872, kí làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ nípa Jésù?
6 Lọ́dún 1870, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí Charles Taze Russell jẹ́ alábòójútó wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa ìdí tí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú ẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún 1872, wọ́n ti mọ ohun tí Bíbélì sọ pé Jésù fi ara ẹ̀ ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn pa dà. Wọn ò fi ohun tí wọ́n mọ̀ yìí pa mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ẹ̀ torí wọ́n tẹ̀ ẹ́ sínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn àti ìwé àtìgbàdégbà. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti ń fara wé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, tí wọ́n sì ń pàdé lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi.
7. Báwo la ṣe ń jàǹfààní ìwádìí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe nínú Bíbélì?
7 Lónìí, à ń jàǹfààní ìwádìí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn ṣe nínú Bíbélì kí wọ́n lè mọ òtítọ́. Lọ́nà wo? Jèhófà ti ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ òtítọ́ nípa bí Jésù ṣe fi ara ẹ̀ rúbọ àti àǹfààní tó ṣe gbogbo aráyé. (1 Jòh. 2:1, 2) A tún ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì pé àwùjọ èèyàn méjì tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló máa rí ojú rere rẹ̀. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn tó nírètí láti gbé lọ́run, wọn ò sì ní kú mọ́. Àwùjọ kejì ni àìmọye àwọn èèyàn tó nírètí láti gbé ayé títí láé. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, tá à ń rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, tá a sì tún rí i pé ẹbọ ìràpadà Jésù ń ṣe wá láǹfààní ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (1 Pét. 3:18; 1 Jòh. 4:9) Torí náà, bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, a máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ká lè ṣe é bó ṣe ní ká máa ṣe é.
A MÁA Ń PE ÀWỌN ÈÈYÀN WÁ SÍ ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
8. Kí làwa èèyàn Jèhófà ti ṣe ká lè pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Ọjọ́ pẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ti máa ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ní ọdún 1881, gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pàdé pọ̀ nílé arákùnrin kan ní Allegheny, Pennsylvania láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Nígbà tó yá, wọ́n ní kí ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi fúnra wọn. Ní March 1940, wọ́n sọ fáwọn ará pé wọ́n lè pe àwọn tó bá fìfẹ́ hàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ọdún 1960 ni Bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ tẹ ìwé táwọn ará ìjọ máa fi pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Látìgbà yẹn, a ti pín àìmọye ìwé yìí fáwọn èèyàn. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pe àwọn èèyàn wá sí ìpàdé pàtàkì yìí?
9-10. Bá a ṣe ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, àwọn wo ló ń jàǹfààní ẹ̀? (Jòhánù 3:16)
9 Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi ni pé a fẹ́ káwọn tó wá fúngbà àkọ́kọ́ mọ ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún aráyé. (Ka Jòhánù 3:16.) A retí pé ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́ níbẹ̀ máa mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà sí i, kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ rẹ̀. Àmọ́ àwọn tó ti ń wá tẹ́lẹ̀ náà máa ń jàǹfààní.
10 A tún máa ń pe àwọn tó ń sin Jèhófà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí wọn ò sìn ín mọ́ wá síbi ìpàdé pàtàkì yìí. Ìdí tá a fi ń pè wọ́n ni pé a fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń wá, inú wa sì máa ń dùn láti rí wọn. Ìrántí Ikú Kristi máa ń rán wọn létí ayọ̀ tí wọ́n máa ń ní nígbà tí wọ́n ṣì ń sin Jèhófà. Wo àpẹẹrẹ Monica.c Nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà, ó pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Lẹ́yìn tó lọ sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2021, ó sọ pé: “Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí ṣe pàtàkì sí mi gan-an. Ìdí ni pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé láti ogún (20) ọdún sẹ́yìn tí mo ti wàásù fáwọn èèyàn, tí mo sì pè wọ́n wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti pe àwọn èèyàn wá torí mo mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún mi.” (Sm. 103:1-4) Torí náà, bóyá àwọn èèyàn tá a pè wá tàbí wọn ò wá, a ṣì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pè wọ́n wá sí Ìrántí Ikú Kristi torí a mọ̀ pé Jèhófà mọyì ohun tá à ń ṣe.
11. Àṣeyọrí wo ni Jèhófà ti jẹ́ ká ṣe bá a ṣe ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Hágáì 2:7)
11 Jèhófà ti jẹ́ ká ṣàṣeyọrí bá a ṣe ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́dún 2021, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ àrùn ò jẹ́ ká lè jáde nílé, àwọn 21,367,603 ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Iye yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ààbọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láyé! Àmọ́ iye àwọn tó wá kọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí i ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wá síbẹ̀. (Lúùkù 15:7; 1 Tím. 2:3, 4) Torí náà, ó dá wa lójú pé tá a bá ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn tó fẹ́ mọ Ọlọ́run.—Ka Hágáì 2:7.
A KÌ Í JẸ́ KÍ OHUNKÓHUN DÍ WA LỌ́WỌ́ LÁTI ṢE ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
12. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ìṣòro kan máa dé bá wa, irú bí àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé, inúnibíni, ogun, àjàkálẹ̀ àrùn àtàwọn ìṣòro míì. (Mát. 10:36; Máàkù 13:9; Lúùkù 21:10, 11) Nígbà míì, àwọn nǹkan yìí máa ń jẹ́ kó ṣòro fún wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, báwo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ṣe borí àwọn ìṣòro yìí, báwo sì ni Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
13. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Artem lọ́wọ́ torí pé ó nígboyà tó sì pinnu pé òun máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lẹ́wọ̀n?
13 Tí wọ́n bá fi wá sẹ́wọ̀n. Àwọn ará wa tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Artem. Nígbà Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2020, wọ́n fi sínú yàrá ẹ̀wọ̀n kékeré kan tí wọ́n kó èèyàn márùn-ún sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n ló wà, ó rí i pé òun gba àwọn nǹkan tá a máa fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ó sì ṣètò bó ṣe máa sọ àsọyé fúnra ẹ̀. Àmọ́ àwọn tí wọ́n jọ wà nínú yàrá ẹ̀wọ̀n yẹn máa ń mu sìgá, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ èébú. Kí ni Artem wá ṣe? Ó sọ fún wọn pé ṣé wọ́n máa lè ṣe é kí wọ́n má mu sìgá, kí wọ́n má sì sọ̀rọ̀ èébú fún wákàtí kan péré. Ó yà á lẹ́nu pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n yẹn gbà pé àwọn ò ní mu sìgá, àwọn ò sì ní sọ̀rọ̀ èébú nígbà tó bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Artem sọ pé, “Mo lo àǹfààní yẹn láti sọ fún wọn nípa Ìrántí Ikú Kristi.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ pé àwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan pàtàkì tó fẹ́ ṣe, lẹ́yìn tí wọ́n rí bó ṣe ṣe é, wọ́n sọ pé kó ṣàlàyé Ìrántí Ikú Kristi fáwọn.
14. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀ àrùn wáyé, kí làwa èèyàn Jèhófà ṣe ká lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
14 Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà wáyé. Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn yìí wáyé, àwa èèyàn Jèhófà ò lè pàdé ní ilé ìjọsìn wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́ a ò jẹ́ kíyẹn dí wa lọ́wọ́ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi.d Àwọn ìjọ tó ní Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe é lórí ìkànnì kí wọ́n lè rí ara wọn. Àmọ́, báwo ni àìmọye èèyàn tí kò ní Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe ṣe é? Láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ṣètò láti sọ àsọyé náà lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì gba ohùn àsọyé Ìrántí Ikú Kristi sílẹ̀ ní èdè tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lọ, kí àwọn ará lè gbọ́ ọ, pàápàá àwọn tó wà ní àdádó. Wọ́n sì ṣètò pé kí àwọn arákùnrin lọ fún àwọn ará tó wà ní àdádó láwọn àsọyé náà.
15. Kí lo rí kọ́ lára akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Sue?
15 Àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé. Ìṣòro ńlá tí kì í jẹ́ káwọn kan lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi ni àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Sue. Ní ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2021, Sue sọ fún ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé òun ò ní lè wá torí pé ìdílé òun ń ta ko òun. Ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá ka Lúùkù 22:44. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé fún un pé tá a bá ní ìṣòro, a gbọ́dọ̀ fara wé Jésù, ká gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Lọ́jọ́ kejì, Sue ṣètò àwọn ohun tá a fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ó sì tún wo àkànṣe Ìjọsìn Òwúrọ̀ lórí ìkànnì jw.org. Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, òun nìkan dá lọ sínú yàrá ẹ̀, ó sì fi fóònù ẹ̀ gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi látorí ìkànnì. Lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, ó kọ lẹ́tà sí ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ bá mi sọ lánàá fún mi níṣìírí gan-an. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́. Inú mi dùn gan-an, mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà!” Tó o bá bá ara ẹ nírú ipò yìí, ṣé o rò pé Jèhófà lè ran ìwọ náà lọ́wọ́?
16. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (Róòmù 8:31, 32)
16 Jèhófà máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tá a bá mọyì ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ó dájú pé ó máa bù kún wa. (Ka Róòmù 8:31, 32.) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa wá sí Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nígbà Ìrántí Ikú Kristi.
ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà
a Ní Tuesday, April 4, 2023, àìmọye èèyàn kárí ayé ló máa kóra jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa wá nìyí. Àwọn kan tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́, tó sì ti pẹ́ tí wọ́n ti wá sí Ìrántí Ikú Kristi náà máa wà níbẹ̀. Àwọn nǹkan kan lè má jẹ́ kó rọrùn fáwọn kan láti wá, àmọ́ wọ́n ṣì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè wà níbẹ̀. Ohun yòówù kó jẹ́, mọ̀ dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ tó o bá wá.
b Àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣe ààtò Máàsì gbà pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣe Máàsì, búrẹ́dì máa yí pa dà di ara Jésù, wáìnì á sì di ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Torí náà, wọ́n rò pé gbogbo ìgbà táwọn bá ń ṣe ààtò yìí ni Jésù ń fi ara àti ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ rúbọ.
c A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
d Tún wo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021” lórí ìkànnì jw.org/yo.
e ÀWÒRÁN: Láti ọdún 1960 ni ètò Ọlọ́run ti ń tẹ ìwé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, tí wọ́n sì ń ṣàtúnṣe ẹ̀. Ní báyìí, a máa ń tẹ̀ ẹ́ jáde, ó sì tún wà lórí ìkànnì.
f ÀWÒRÁN: Nínú àwòrán yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi nígbà rògbòdìyàn.