ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4
Ìdí Tá A Fi Ń Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi
“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—LÚÙKÙ 22:19.
ORIN 20 O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Ọjọ́ wo la sábà máa ń rántí àwọn èèyàn wa tó ti kú? (b) Kí ni Jésù ṣe ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀?
BÓ TIẸ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn wa lè ti kú tipẹ́, a ṣì máa ń rántí wọn. Àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n kú la sì sábà máa ń ronú nípa wọn jù.
2 Lọ́dọọdún, a máa ń dara pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn kárí ayé láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní àyájọ́ ọjọ́ tó kú torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Pét. 1:8) A máa ń pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú ẹni tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rà wá pa dà kó lè gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Mát. 20:28) Kódà, Jésù fẹ́ káwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa ṣe Ìrántí Ikú òun. Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó sì pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Àwọn díẹ̀ lára àwọn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ló nírètí láti gbé lọ́run. Àmọ́ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó nírètí àtigbé ayé náà máa ń wà níbẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ìdí tó fi máa ń wu àwùjọ méjì yìí láti wà níbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá wá síbẹ̀. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìdí táwọn ẹni àmì òróró fi máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.
ÌDÍ TÁWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ FI MÁA Ń WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
4. Kí nìdí táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi máa ń jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì máa ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi?
4 Lọ́dọọdún, àwọn ẹni àmì òróró máa ń fẹ́ wà níbi Ìrántí Ikú Kristi kí wọ́n lè jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu wáìnì náà? Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú. Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Ìrékọjá, Jésù dá ohun kan sílẹ̀ tá a wá mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Ó gbé búrẹ́dì àti wáìnì náà fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá (11), ó sì ní kí wọ́n gbé e káàkiri láàárín ara wọn kí wọ́n lè jẹ, kí wọ́n sì mu nínú rẹ̀. Jésù sọ fún wọn nípa májẹ̀mú méjì, ìyẹn májẹ̀mú tuntun àti májẹ̀mú Ìjọba.b (Lúùkù 22:19, 20, 28-30) Májẹ̀mú méjì yìí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn èèyàn kéréje míì láti di ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Ìfi. 5:10; 14:1) Kìkì àwọn tó ṣẹ́ kùc lára àwọn ẹni àmì òróró tí májẹ̀mú méjì náà wà fún, ló máa jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi.
5. Kí làwọn ẹni àmì òróró mọ̀ nípa ìrètí tí wọ́n ní?
5 Ìdí míì táwọn ẹni àmì òróró fi ń wá síbì Ìrántí Ikú Kristi ni pé bí wọ́n ṣe wà níbẹ̀ ń jẹ́ kí wọ́n lè máa ronú nípa ìrètí tí wọ́n ní. Ìrètí tí Jèhófà fún wọn yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé wọ́n máa gba àìleèkú àti àìdíbàjẹ́ ní ọ̀run. Àwọn àti ìyókù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tó ti wà lọ́run máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n máa láǹfààní láti rí Jèhófà Ọlọ́run! (1 Kọ́r. 15:51-53; 1 Jòh. 3:2) Àwọn ẹni àmì òróró mọ̀ pé Jèhófà ti yan àwọn láti gbádùn àwọn àǹfààní yìí lọ́run. Àmọ́ kí wọ́n tó lè lọ sọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú. (2 Tím. 4:7, 8) Inú àwọn ẹni àmì òróró máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń ronú nípa ìrètí tí wọ́n ní láti gbé lọ́run. (Títù 2:13) “Àwọn àgùntàn mìíràn” ńkọ́? (Jòh. 10:16) Kí nìdí táwọn náà fi ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
ÌDÍ TÁWỌN ÀGÙNTÀN MÌÍRÀN FI Ń WÁ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
6. Kí nìdí táwọn àgùntàn mìíràn fi máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún?
6 Àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kì í jẹ búrẹ́dì, wọn kì í sì í mu wáìnì. Àmọ́, inú wọn máa ń dùn pé àwọn náà wá síbẹ̀. Ọdún 1938 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n pe àwọn tí wọ́n nírètí àtigbé ayé wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1938 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ó tọ̀nà pé kí àwọn àgùntàn mìíràn náà máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. . . . Ó yẹ kínú àwọn náà máa dùn tí wọ́n bá wà níbẹ̀ torí pé ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ yẹn.” Bí inú àwọn tá a pè wá síbi ìgbéyàwó ṣe máa ń dùn, bẹ́ẹ̀ náà ni inú àwọn àgùntàn mìíràn máa ń dùn tí wọ́n bá wà níbi Ìrántí Ikú Kristi.
7. Kí nìdí tó fi máa ń wu àwọn àgùntàn mìíràn pé káwọn náà gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi?
7 Àwọn àgùntàn mìíràn náà máa ń ronú nípa ìrètí tí wọ́n ní. Wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi torí àsọyé náà sábà máa ń dá lórí ohun tí Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá a ṣàkóso máa ṣe fún àwọn olóòótọ́ èèyàn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso rẹ̀. Nígbà tí Jésù Kristi Ọba bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, òun àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa sọ ayé di Párádísè, wọ́n sì máa ran àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn lọ́wọ́ láti di ẹni pípé. Ẹ wo bí inú ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń fojú inú wo ìgbà táwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì máa ṣẹ, irú bí Àìsáyà 35:5, 6; 65:21-23; àti Ìfihàn 21:3, 4. Bí wọ́n ṣe ń fojú inú wo ara wọn àtàwọn èèyàn wọn nínú ayé tuntun, ìyẹn ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé àwọn máa gbé ayé lọ́jọ́ iwájú. Ó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa sin Jèhófà nìṣó láìyẹsẹ̀.—Mát. 24:13; Gál. 6:9.
8. Kí ni nǹkan míì tó ń mú káwọn àgùntàn mìíràn máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?
8 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan míì tó ń mú káwọn àgùntàn mìíràn máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Wọ́n fẹ́ fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹni àmì òróró àti pé àwọn ń tì wọ́n lẹ́yìn. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àjọṣe tó lágbára máa wà láàárín àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn tó nírètí àtigbé ayé. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
9. Kí ni Sekaráyà 8:23 jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ojú tí àwọn àgùntàn mìíràn fi ń wo àwọn ẹni àmì òróró?
9 Ka Sekaráyà 8:23. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ irú ojú tí àwọn àgùntàn mìíràn fi ń wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó jẹ́ ẹni àmì òróró. Àwọn ọ̀rọ̀ náà “Júù kan” àti “yín” ń tọ́ka sí àwọn èèyàn kan náà, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù sáyé. (Róòmù 2:28, 29) Gbólóhùn náà “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ń tọ́ka sí àwọn àgùntàn mìíràn. Wọ́n “di” àwọn ẹni àmì òróró “mú ṣinṣin,” ìyẹn ni pé wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn mímọ́. Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, àwọn àgùntàn mìíràn máa ń wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró láti fi hàn pé àjọṣe tó wà láàárín wọn lágbára.
10. Kí ni Jèhófà ṣe kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:15-19, 24, 25 lè ṣẹ?
10 Ka Ìsíkíẹ́lì 37:15-19, 24, 25. Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, Jèhófà mú kí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa igi méjì. Àwọn tí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run ni igi “Júdà” ṣàpẹẹrẹ (ìyẹn ẹ̀yà tí wọ́n ti máa ń yan àwọn ọba Ísírẹ́lì), nígbà tí igi “Éfúrémù”d ṣàpẹẹrẹ àwọn tó nírètí àtigbé ayé. Jèhófà máa mú kí àwùjọ méjèèjì yìí wà níṣọ̀kan kí wọ́n lè di “igi kan ṣoṣo.” Ìyẹn ni pé wọ́n á máa ṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan, wọ́n á sì jẹ́ kí Jésù Kristi Ọba máa darí àwọn. Lọ́dọọdún, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi pa pọ̀ bí “agbo kan,” “olùṣọ́ àgùntàn kan” ló sì ń darí wọn.—Jòh. 10:16.
11. Báwo ni “àwọn àgùntàn” tí Mátíù 25:31-36, 40 mẹ́nu kàn ṣe ń fi hàn pé àwọn ń ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn?
11 Ka Mátíù 25:31-36, 40. “Àwọn àgùntàn” inú àkàwé yìí ṣàpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn ní àkókò òpin yìí tí wọ́n nírètí àtigbé ayé, ìyẹn àwọn àgùntàn mìíràn. Wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì ń ti àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti pé, wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ pàtàkì kárí ayé, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 24:14; 28:19, 20.
12-13. Àwọn ọ̀nà míì wo làwọn àgùntàn mìíràn ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn?
12 Lọ́dọọdún, ọ̀nà míì táwọn àgùntàn mìíràn ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn ni pé, láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé láti pe àwọn tó fìfẹ́ hàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Wo àpótí náà “Ṣé Ò Ń Múra Ìrántí Ikú Kristi Sílẹ̀?”) Bákan náà, kárí ayé ni wọ́n ti máa ń rí i dájú pé àwọn ṣe ètò tó yẹ kí wọ́n lè ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ìjọ wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má sí ẹni àmì òróró kankan tó máa jẹ búrẹ́dì, tó sì máa mu wáìnì níbẹ̀. Ara àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn nìyẹn, inú wọn sì máa ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá àwọn àgùntàn mìíràn lójú pé Jésù mọ gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe fáwọn ẹni àmì òróró, ó sì mọ̀ pé òun gan-an ni wọ́n ń ṣe é fún.—Mát. 25:37-40.
13 Àwọn nǹkan míì wo ló ń mú kí gbogbo wa máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé?
OHUN TÓ Ń JẸ́ KÍ GBOGBO WA MÁA LỌ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
14. Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wa gan-an?
14 À ń fi hàn pé a mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa. Jèhófà ti fi ìfẹ́ hàn sí wa lóríṣiríṣi ọ̀nà, àmọ́ ọ̀nà kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú wọn. Ọlọ́run fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an ní ti pé ó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé kó lè jìyà, kó sì kú nítorí wa. (Jòh. 3:16) Jésù náà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa torí pé ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòh. 15:13) Kò sóhun tá a lè ṣe láti san oore tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa yìí pa dà. Àmọ́ a lè fi hàn pé a mọrírì ohun tí wọ́n ṣe tá a bá ń ronú lórí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. (Kól. 3:15) Torí náà, gbogbo wa máa ń lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi torí pé ó ń jẹ́ ká rántí ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa, ó sì ń jẹ́ káwa náà lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.
15. Kí nìdí tí àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn fi mọyì ẹ̀bùn ìràpadà gan-an?
15 A mọyì ẹ̀bùn ìràpadà gan-an. (Mát. 20:28) Àwọn ẹni àmì òróró mọyì ìràpadà torí pé òun ló jẹ́ kí wọ́n nírètí àtigbé lọ́run. Nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, Jèhófà pè wọ́n ní olódodo, ó sì sọ wọ́n dọmọ rẹ̀. (Róòmù 5:1; 8:15-17, 23) Àwọn àgùntàn mìíràn náà fi hàn pé àwọn mọrírì ìràpadà. Torí pé àwọn náà nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, ó jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ń jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ‘àwọn máa la ìpọ́njú ńlá já.’ (Ìfi. 7:13-15) Torí náà, ọ̀nà kan táwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn gbà ń fi hàn pé àwọn mọyì ìràpadà ni pé wọ́n máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún.
16. Nǹkan míì wo ló ń jẹ́ ká máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
16 Nǹkan míì tó ń jẹ́ ká máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi ni pé a fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù. Bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé, gbogbo wa la fẹ́ ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù tó pa ní alẹ́ ọjọ́ tó dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó ní: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—1 Kọ́r. 11:23, 24.
ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ LỌ SÍBI ÌRÁNTÍ IKÚ KRISTI
17. Báwo ni Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà?
17 Ó ń jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà. (Jém. 4:8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ìrántí Ikú Kristi máa ń jẹ́ ká ronú nípa ìrètí tí Jèhófà fún wa, ó sì tún jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Jer. 29:11; 1 Jòh. 4:8-10) Torí náà, tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa ìrètí ọjọ́ ọ̀la tó dájú yìí àti ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, ó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àjọṣe àwa àti ẹ̀ á sì túbọ̀ lágbára.—Róòmù 8:38, 39.
18. Tá a bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, kí nìyẹn máa jẹ́ ká ṣe?
18 Ó ń jẹ́ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. (1 Pét. 2:21) Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń kà nípa ọ̀sẹ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ikú rẹ̀ àti bó ṣe jíǹde. Tó bá wá di ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀, àsọyé Bíbélì tá a máa ń gbọ́ níbẹ̀ máa ń rán wa létí ìfẹ́ tí Jésù ní sí wa. (Éfé. 5:2; 1 Jòh. 3:16) Torí náà, tá a bá ń kà nípa àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ ní ti bó ṣe kú nítorí wa, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí, ìyẹn á jẹ́ ká lè ‘máa rìn bí Jésù ṣe rìn.’—1 Jòh. 2:6.
19. Kí ló máa jẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
19 Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ pinnu pé a máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Júùdù 20, 21) A máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, tá à ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, tá a sì ń múnú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11; Mát. 6:9; 1 Jòh. 5:3) Torí náà, Ìrántí Ikú Kristi tá à ń ṣe máa ń jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa túbọ̀ pinnu pé ‘Títí láé la máa dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run!’
20. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi?
20 Bóyá à ń retí láti gbé títí láé ní ọ̀run tàbí ayé, ó ṣe pàtàkì pé ká máa lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́dọọdún, a máa ń pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní ọjọ́ tó kú láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Ìrántí Ikú Kristi máa ń jẹ́ ká rántí ìfẹ́ tó ga jù lọ tí Jèhófà fi hàn sí wa torí pé ó fún wa ní Ọmọ rẹ̀ láti rà wá pa dà. Lọ́dún yìí, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní Friday, April 15, 2022. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ gan-an. Torí náà, ní ọjọ́ àyájọ́ ikú Jésù, ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa lọ síbi Ìrántí Ikú rẹ̀.
ORIN 16 Ẹ Yin Jáà Nítorí Ọmọ Rẹ̀ Tó Fòróró Yàn
a Bóyá a nírètí láti gbé lọ́run tàbí ayé nínú Párádísè, gbogbo wa la máa ń fojú sọ́nà láti wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dọọdún. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.
b Kó o lè mọ̀ sí i nípa májẹ̀mú tuntun àti májẹ̀mú Ìjọba, wo àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀yin Yóò Di ‘Ìjọba Àwọn Àlùfáà’” nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2014, ojú ìwé 15-17.
c ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Gbólóhùn náà àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró ń tọ́ka sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé.
d Kó o lè mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ igi méjì tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì orí 37, wo ìwé Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!, ojú ìwé 130-135, ìpínrọ̀ 3-17.