Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
1 “Aláyọ̀ ni ẹni tí ń ka àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí sókè àti àwọn tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa àwọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nítorí àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé.” (Ìṣí. 1:3) Ṣe ni ọ̀rọ̀ yìí sọ bí ìwé Ìṣípayá ṣe ṣe pàtàkì tó, pàápàá léyìí tó jẹ́ pé a ti ń gbé láwọn àkókò tí Ọlọ́run ti yàn pé káwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ nímùúṣẹ. Ìdí nìyẹn tá a fi máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀! láti ọ̀sẹ̀ January 8, 2007 ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
2 Látìgbà tá a ti ka ìwé Ìparí Ìṣípayá ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kẹ́yìn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti yí padà nínú ayé. (1 Kọ́r. 7:31) Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwa tá à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni ò tíì láǹfààní láti bá wa kópa nínú ìjíròrò ìwé Ìṣípayá lẹ́sẹlẹ́sẹ. A retí pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìparí Ìṣípayá ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti máa fiyè sí àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Ìṣí. 16:15.
3 Ẹ jẹ́ ká rí i pé a ò pa ọ̀sẹ̀ kankan jẹ láìlọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Yàtọ̀ sí pé ìwé tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ náà máa ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, àwọn iṣẹ́ tí Jésù rán sí àwọn ìjọ méje yẹn á tún ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ra fáwọn ohun tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ tó sì lè pa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lára.—Ìṣí. 1:11, 19.
4 Múra Sílẹ̀ Dáadáa: Kó o tó wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, kọ́kọ́ ka ẹsẹ Bíbélì tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dá lé lórí látinú ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì. Fọkàn sí àlàyé tó bá Ìwé Mímọ́ mu tá a ṣe lórí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Gbìyànjú láti lóye àwọn kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀ kó bàa lè wọ̀ ẹ́ lọ́kàn. (Neh. 8:8, 12) Wá àkókò láti ronú kó o sì bi ara ẹ pé: ‘Kí lohun tí mo kà yìí ń kọ́ mi nípa Jèhófà, kí ló sì ń jẹ́ kí n mọ̀ nípa bó ṣe máa mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ọ̀nà wo ni mo sì lè gbà ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?’
5 Ó ti pé ọdún méjìléláàádọ́rùn-ún báyìí lẹ́yìn tí “ọjọ́ Olúwa” ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. (Ìṣí. 1:10) Kò ní pẹ́ mọ́ táwọn ohun arabaríbí tí ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìparí Ìṣípayá máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ ó sì máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i pé “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” àti ayé tuntun ti sún mọ́lé.—Ìṣí. 16:14; 21:4, 5.