ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 38
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Báwo Lẹ Ṣe Fẹ́ Káyé Yín Rí?
“Ìfòyemọ̀ yóò sì máa dáàbò bò ọ́.”—ÒWE 2:11.
ORIN 135 Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ipò tó nira wo ni Jèhóáṣì, Ùsáyà àti Jòsáyà bá ara wọn?
BÁWO ló ṣe máa rí lára ẹ ká ní o di ọba àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tó o wà lọ́mọdé? Báwo lo ṣe máa darí àwọn èèyàn náà, tí wàá sì máa pàṣẹ fún wọn? Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀dọ́ mélòó kan tí wọ́n di ọba Júdà. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méje ni Jèhóáṣì nígbà tó di ọba, Ùsáyà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), Jòsáyà ní tiẹ̀ sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá nìyẹn! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ náà ò rọrùn, Jèhófà lo àwọn èèyàn ẹ̀ láti ran gbogbo wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro tó yọjú, kí wọ́n sì ṣàṣeyọrí.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jèhóáṣì, Ùsáyà àti Jòsáyà?
2 A kì í ṣe ọba tàbí ọbabìnrin, àmọ́ a lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì lára àwọn ọba mẹ́ta tí Bíbélì sọ yìí. Wọ́n ṣe àwọn ìpinnu tó dáa, wọ́n sì tún ṣe àwọn èyí tí ò dáa. Àpẹẹrẹ wọn máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dáa, ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà.
YAN ÀWỌN Ọ̀RẸ́ TÓ DÁA
3. Kí ni Ọba Jèhóáṣì ṣe tó fi hàn pé ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Àlùfáà Àgbà Jèhóádà fún un?
3 Fara wé Jèhóáṣì tó ṣe ìpinnu tó dáa. Nígbà tí Ọba Jèhóáṣì ṣì kéré, ó ṣe ìpinnu tó dáa. Torí pé bàbá ẹ̀ ti kú, Àlùfáà Àgbà Jèhóádà tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ló ń tọ́ ọ sọ́nà, ó sì ń ṣe ohun tó bá sọ. Ńṣe ni Jèhóádà mú Jèhóáṣì bí ọmọ, ó sì ń bójú tó o. Ìyẹn jẹ́ kí Jèhóáṣì pinnu pé òun á fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú ìjọsìn mímọ́, òun á sì máa sin Jèhófà. Kódà, Jèhóáṣì ṣètò pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe.—2 Kíró. 24:1, 2, 4, 13, 14.
4. Tá a bá mọyì àwọn òfin Jèhófà, àǹfààní wo ló máa ṣe wá? (Òwe 2:1, 10-12)
4 Táwọn òbí ẹ bá ti kọ́ ẹ pé kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kó o sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀, ẹ̀bùn tó ṣeyebíye ni wọ́n fún ẹ yẹn. (Ka Òwe 2:1, 10-12.) Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn òbí máa ń gbà tọ́ àwọn ọmọ wọn. Ẹ jẹ́ ká wo bí bàbá arábìnrin kan tó ń jẹ́ Katya ṣe ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣe ìpinnu tó dáa. Lójoojúmọ́ tí bàbá ẹ̀ bá ń mú un lọ sílé ìwé, ó máa ń jíròrò ẹsẹ ojúmọ́ tọjọ́ yẹn pẹ̀lú ẹ̀. Katya sọ pé: “Àwọn ohun tí bàbá mi máa ń bá mi sọ máa ń jẹ́ kí n borí àwọn ìṣòro tí mo bá ní lọ́jọ́ yẹn.” Àmọ́ tó o bá ń rò pé àwọn ìlànà Bíbélì táwọn òbí ẹ ń kọ́ ẹ ò jẹ́ kó o ṣe bó o ṣe fẹ́ ńkọ́? Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè tẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà tí wọ́n bá fún ẹ? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Anastasia rántí báwọn òbí ẹ̀ ṣe máa ń fara balẹ̀ ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi ṣe àwọn òfin kan. Ó ní: “Àlàyé tí wọ́n máa ń ṣe máa ń jẹ́ kí n rí i pé kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ ká mi lọ́wọ́ kò, ńṣe ni wọ́n fẹ́ dáàbò bò mí torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi.”
5. Tó o bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, báwo ló ṣe máa rí lára àwọn òbí ẹ àti Jèhófà? (Òwe 22:6; 23:15, 24, 25)
5 Tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì táwọn òbí ẹ ń kọ́ ẹ, inú wọn máa dùn. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ, wàá sì di ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí láé. (Ka Òwe 22:6; 23:15, 24, 25.) Àwọn nǹkan tá a sọ yìí yẹ kó mú kó o fara wé àpẹẹrẹ Jèhóáṣì nígbà tó wà lọ́mọdé.
6. Ìmọ̀ràn àwọn wo ni Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé, kí nìyẹn sì yọrí sí? (2 Kíróníkà 24:17, 18)
6 Kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Jèhóáṣì ṣe. Lẹ́yìn tí Jèhóádà kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. (Ka 2 Kíróníkà 24:17, 18.) Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ìjòyè Júdà tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ìwọ náà á gbà pé kò yẹ kí Jèhóáṣì máa bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́ torí èèyàn burúkú ni wọ́n. (Òwe 1:10) Àmọ́, àwọn ọ̀rẹ́ burúkú yìí ló fetí sí. Ó tún ṣe é débi pé nígbà tí Sekaráyà ìbátan ẹ̀ fẹ́ tọ́ ọ sọ́nà, ṣe ló ní kí wọ́n lọ pa á. (2 Kíró. 24:20, 21; Mát. 23:35) Ẹ ò rí i pé ìwà ìkà àti ìwà òmùgọ̀ ni Jèhóáṣì hù yìí! Èèyàn dáadáa ni Jèhóáṣì tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ó di apẹ̀yìndà àti apààyàn. Níkẹyìn, àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pa òun náà. (2 Kíró. 24:22-25) Ẹ ò rí i bí ìgbésí ayé ẹ̀ ì bá ṣe dáa tó ká ní ó tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tó sì fetí sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀! Kí lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yẹn?
7. Àwọn wo ló yẹ kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Ohun tá a rí kọ́ nínú ìpinnu tí ò dáa tí Jèhóáṣì ṣe ni pé ó yẹ ká yan àwọn ọ̀rẹ́ táá jẹ́ ká níwà rere, ìyẹn àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń múnú ẹ̀ dùn. Kì í ṣe àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ nìkan la lè yàn lọ́rẹ̀ẹ́, a tún lè yan àwọn tó dàgbà jù wá lọ tàbí àwọn tó kéré sí wa. Ẹ má gbàgbé pé Jèhóáṣì kéré gan-an sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jèhóádà. Tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn tí mo fẹ́ yàn lọ́rẹ̀ẹ́ yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára? Ṣé wọ́n á jẹ́ kí n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àti òtítọ́ tó ń kọ́ wa? Ṣé wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run? Ṣé wọ́n máa ń bá mi sòótọ́ ọ̀rọ̀ tí mo bá ṣohun tí ò dáa àbí ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé ohun tí mo ṣe dáa?’ (Òwe 27:5, 6, 17) Ká sòótọ́, táwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò yẹ kó o máa bá wọn rìn. Àmọ́ tó o bá láwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ọ̀rẹ́ gidi nìyẹn. Má fi wọ́n sílẹ̀ o!—Òwe 13:20.
8. Tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò, kí ló yẹ ká fi sọ́kàn?
8 Ìkànnì àjọlò máa ń jẹ́ ká lè bá àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa sọ̀rọ̀ déédéé. Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi ìkànnì yìí ṣe fọ́rífọ́rí. Wọ́n máa ń gbé àwọn fọ́tò àtàwọn fídíò wọn síbẹ̀ kí wọ́n lè máa fi ohun tí wọ́n rà àtohun tí wọ́n ń ṣe fọ́nnu. Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé torí kí n lè máa ṣe fọ́rífọ́rí ni mo ṣe ń lò ó? Ṣé mo fẹ́ máa fi ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ni àbí mo fẹ́ máa fi gba ògo? Ṣé mò ń jẹ́ káwọn tá a jọ ń lo ìkànnì àjọlò darí èrò mi, bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ àtàwọn nǹkan tí mò ń ṣe?’ Arákùnrin Nathan Knorr, tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí tẹ́lẹ̀ fún wa nímọ̀ràn yìí pé: “Má ṣe gbìyànjú láti tẹ́ èèyàn lọ́rùn torí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní tẹ́ ẹnikẹ́ni lọ́rùn. Jèhófà ni kó o tẹ́ lọ́rùn, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá tẹ́ gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rùn.”
Ó YẸ KÁ JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀
9. Kí ni Jèhófà ran Ùsáyà lọ́wọ́ láti ṣe? (2 Kíróníkà 26:1-5)
9 Máa ṣe ìpinnu tó dáa bíi ti Ùsáyà. Onírẹ̀lẹ̀ ni Ọba Ùsáyà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) ló lò láyé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ni Jèhófà bù kún un. (Ka 2 Kíróníkà 26:1-5.) Ùsáyà ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀tá wọn, ó sì rí i pé òun dáàbò bo Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 26:6-15) Ó dájú pé inú Ùsáyà dùn gan-an torí gbogbo nǹkan tí Jèhófà jẹ́ kó gbé ṣe.—Oníw. 3:12, 13.
10. Àwọn àṣìṣe wo ni Ùsáyà ṣe, kí ló sì gbẹ̀yìn ẹ̀?
10 Kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe tí Ùsáyà ṣe. Ọba ni Ùsáyà, torí náà ó máa ń pàṣẹ fáwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn lè mú kó ronú pé ohun tó bá wu òun lòun lè ṣe? Lọ́jọ́ kan, Ùsáyà wọ inú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ò gba àwọn ọba láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Kíró. 26:16-18) Torí náà, Àlùfáà Àgbà Asaráyà tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ ńṣe ló gbaná jẹ. Ó ṣeni láàánú pé Ùsáyà ba orúkọ rere tó ní lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́, Jèhófà sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. (2 Kíró. 26:19-21) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀ sí i ká ní ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ ni wá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Nígbà tí Ùsáyà di alágbára, ó gbàgbé pé Jèhófà ló jẹ́ kóun ṣe gbogbo àṣeyọrí tóun ṣe. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun rere tá a ní, òun ló sì ń bù kún wa. Dípò ká máa fi àwọn àṣeyọrí wa yangàn, Jèhófà ló yẹ ká gbé gbogbo ògo náà fún.b (1 Kọ́r. 4:7) Ó yẹ ká gbà pé aláìpé ni wá, ká sì máa fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wa. Arákùnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta (60) ọdún sọ pé: “Mi kì í ro ara mi ju bó ṣe yẹ lọ. Tí wọ́n bá bá mi wí torí àṣìṣe tí mo ṣe, mo máa ń fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, mo sì máa ń ṣàtúnṣe.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tá a bá bẹ̀rù Jèhófà tá a sì nírẹ̀lẹ̀, ìgbésí ayé wa máa dáa, àá sì láyọ̀.—Òwe 22:4.
TÚBỌ̀ MÁA SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ
12. Báwo ni Jòsáyà ṣe wá Jèhófà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́? (2 Kíróníkà 34:1-3)
12 Máa ṣe ìpinnu tó dáa bíi ti Jòsáyà. Ọ̀dọ́ ni Jòsáyà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà. Ó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó sì máa ṣohun tó fẹ́. Àmọ́ nǹkan ò rọrùn fún ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí. Nígbà yẹn, ìjọsìn èké lọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe. Torí náà, ó di dandan pé kí Jòsáyà fìgboyà gbèjà ìjọsìn tòótọ́, ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Kódà, kí Jòsáyà tó pé ọmọ ogún (20) ọdún ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìjọsìn èké kúrò lórílẹ̀-èdè náà.—Ka 2 Kíróníkà 34:1-3.
13. Tó o bá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, kí nìyẹn máa mú kó o ṣe?
13 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, o lè fara wé Jòsáyà tó o bá ń wá Jèhófà, tó o sì ń fàwọn ànímọ́ ẹ̀ ṣèwà hù. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á wù ẹ́ láti ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Kí nìyẹn máa mú kó o ṣe lójoojúmọ́? Arákùnrin Luke tó ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14) sọ pé: “Àtìgbà tí mo ti ya ara mi sí mímọ́ ni mo ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà ló máa gbawájú nígbèésí ayé mi, màá sì máa múnú ẹ̀ dùn.” (Máàkù 12:30) Tíwọ náà bá pinnu pé ohun tó o máa ṣe nìyẹn, wàá láyọ̀!
14. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó jẹ́ ká rí bí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe ń fara wé Ọba Jòsáyà.
14 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó o ní? Johan tó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún méjìlá (12) sọ báwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ ṣe ń fúngun mọ́ ọn pé kó mu sìgá tí wọ́n ń fi páìpù fà. Kó lè kojú ìṣòro yìí, ó máa ń rán ara ẹ̀ létí pé tóun bá ń mu sìgá, ó lè ba ìlera òun jẹ́, ó sì tún lè ba àjọṣe òun àti Jèhófà jẹ́. Rachel tóun náà ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá (14) sọ àwọn nǹkan tó ràn án lọ́wọ́ kó lè borí àwọn ìṣòro tó ní nílé ìwé. Ó ní: “Mo máa ń ronú nípa ohun táá jẹ́ kí n rántí Bíbélì àti Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá ń kọ́ wa nípa ìtàn nílé ìwé, ó máa ń jẹ́ kí n rántí ìtàn kan tàbí àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì. Nígbà míì tí mo bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nílé ìwé, mo máa ń ronú nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo lè ṣàlàyé fún un.” Ó ṣeé ṣe káwọn ìṣòro tó o ní yàtọ̀ sí ti Ọba Jòsáyà, àmọ́ o lè jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kó o sì jẹ́ olóòótọ́ bíi tiẹ̀. Tó o bá ń fara da àwọn ìṣòro tó o ní báyìí, á jẹ́ kó o múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó máa dé lọ́jọ́ iwájú.
15. Kí ló ran Jòsáyà lọ́wọ́ kó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà? (2 Kíróníkà 34:14, 18-21)
15 Nígbà tí Ọba Jòsáyà pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26), ó bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ńpìlì Jèhófà ṣe. Bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ náà, wọ́n rí “ìwé Òfin tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀ Mósè.” Nígbà tí wọ́n ka ìwé náà fún ọba, ohun tó gbọ́ mú kó ṣe àtúnṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Ka 2 Kíróníkà 34:14, 18-21.) Ṣé ìwọ náà á máa ka Bíbélì lójoojúmọ́? Tó o bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé ò ń gbádùn ẹ̀? Ṣé o máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹsẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Luke tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa ràn án lọ́wọ́ tó bá ń ka Bíbélì. Tí ìwọ náà bá fẹ́ máa rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn kókó pàtàkì, á dáa kó o máa ṣàkọsílẹ̀ wọn. Ìdí sì ni pé bó o bá ṣe túbọ̀ ń ka Bíbélì, tó o sì ń gbádùn ohun tó ò ń kà, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa wù ẹ́ láti sin Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran Ọba Jòsáyà lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ran ìwọ náà lọ́wọ́.
16. Kí ló mú kí Jòsáyà ṣàṣìṣe ńlá, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
16 Kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn àṣìṣe tí Jòsáyà ṣe. Nígbà tí Jòsáyà pé ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì (39), ó ṣe àṣìṣe ńlá kan tó gba ẹ̀mí ẹ̀. Ó gbára lé ara ẹ̀ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (2 Kíró. 35:20-25) Kí nìyẹn kọ́ wa? Kò sí bá a ṣe dàgbà tó tàbí bó ṣe wù kó pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Tá a bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba pé ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣàṣìṣe ńlá tó máa gbẹ̀mí wa bíi ti Jòsáyà, àá sì máa láyọ̀.—Jém. 1:25.
Ẹ̀YIN Ọ̀DỌ́, Ẹ̀YIN NÁÀ LÈ GBÁDÙN AYÉ YÍN
17. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la kọ́ lára àwọn ọba Júdà mẹ́ta tá a sọ̀rọ̀ wọn?
17 Oríṣiríṣi nǹkan tó máa ń fún wa láyọ̀ la máa ń ṣe nígbà tá a ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Ìtàn Jèhóáṣì, Ùsáyà àti Jòsáyà jẹ́ ká rí i pé ẹ̀yin ọ̀dọ́ lè ṣe ìpinnu tó tọ́, kẹ́ ẹ sì múnú Jèhófà dùn. Òótọ́ ni pé nǹkan lè má rí bá a ṣe rò. Àmọ́, tá a bá ń ṣe nǹkan tó dáa táwọn ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe, tá ò sì ṣàṣìṣe tí wọ́n ṣe, a máa láyọ̀.
18. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé o lè láyọ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
18 Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀dọ́ míì tí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, tí wọ́n rí ojúure ẹ̀, tí wọ́n sì láyọ̀. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì. Àtikékeré ló ti pinnu pé Ọlọ́run lòun máa sìn, nígbà tó sì yá, ó di ọba tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìgbà kan wà tó ṣàṣìṣe, Jèhófà dárí jì í. (1 Ọba 3:6; 9:4, 5; 14:8) Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Dáfídì ṣe jẹ́ olóòótọ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀, ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. O tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Máàkù tàbí Tímótì. Àtikékeré ni wọ́n ti ń sin Jèhófà, wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n láyọ̀.
19. Báwo lo ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa?
19 Àwọn nǹkan tó o bá ń fayé ẹ ṣe báyìí ló máa sọ bí ìgbésí ayé ẹ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, tó ò sì gbára lé òye tara ẹ, wàá ṣe ìpinnu tó dáa. (Òwe 20:24) Ká sòótọ́, o lè gbé ìgbé ayé táá jẹ́ kó o láyọ̀. Rántí pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe fún un. Torí náà, kò sóhun tó dáa tó kó o fayé ẹ sin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run.
ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
a Ẹ̀yin ọ̀dọ́, Jèhófà mọ̀ pé ó máa ṣòro fún yín láti ṣe ohun tó tọ́, kẹ́ ẹ sì jẹ́ ọ̀rẹ́ òun. Báwo lẹ ṣe máa ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Bàbá yín ọ̀run dùn? A máa wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tó di ọba Júdà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ nínú àwọn ìpinnu tí wọ́n ṣe.
b Lórí ìkànnì jw.org, wo àpótí náà “Ṣọ́ra fún ‘Dídọ́gbọ́n Gbéra Ga’” nínú àpilẹ̀kọ “Ṣó Di Dandan Kéèyàn Púpọ̀ Mọ̀ Mí Lórí Ìkànnì Àjọlò?”
c ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ ń fún arábìnrin ọ̀dọ́ kan nímọ̀ràn tó máa ṣe é láǹfààní.
d ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tó níṣẹ́ ní àpéjọ kan bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́, ó sì gbé ògo fún Jèhófà lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ náà tán.