Ṣé Àdúrà Olúwa Ni Àdúrà Tó Dáa Jù Láti Gbà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Àdúrà Olúwa jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti ohun tó yẹ ká máa gbàdúrà fún. Jésù gba àdúrà náà nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bi í pé: “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe máa gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Àmọ́, kì í ṣe Àdúrà Olúwa nìkan ni àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́.a Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù fi àdúrà náà ṣe àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tá a lè máa béèrè nínú àdúrà wa.
Nínú àpilẹ̀kọ̀ yìí
Báwo ni wọ́n ṣe ń gba Àdúrà Olúwa?
Bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ṣe sọ ọ̀rọ̀ Àdúrà Olúwa tó wà nínú Mátíù 6:9-13 yàtọ̀ síra. Wo àwọn àpẹẹrẹ méjì yìí
Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”
Bíbélì Mímọ́: “Baba wa ti mbẹ li ọrun, ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ̃ni li aiye. Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi.”b
Kí ni Àdúrà Olúwa túmọ̀ sí?
Àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni bá gbogbo Ìwé Mímọ́ mu, torí náà, a lè retí pé àwọn apá tó kù nínú Bíbélì máa jẹ́ ká lóye ohun tí Àdúrà Olúwa túmọ̀ sí.
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run”
Ó bá a mu tá a bá pe Ọlọ́run ní “Baba wa,” torí pé òun ló dá wa tó sì fún wa ní ìwàláàyè.—Àìsáyà 64:8.
“Kí orúkọ rẹ di mímọ́”
Ó yẹ ká bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run tó ń jẹ́ Jèhófà. Ó sì yẹ ká kà á sí mímọ́. Àwa èèyàn lè jẹ́ kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, tá a sì ń jẹ́ káwọn míì mọ ohun tó fẹ́ ṣe.—Sáàmù 83:18; Àìsáyà 6:3.
“Kí Ìjọba rẹ dé”
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan ní ọrun tí Jésù máa jẹ́ Ọba rẹ̀. Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé kí ìjọba yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gbogbo ayé.—Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 11:15.
“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run”
Bó ṣe jẹ́ pé kò sí ìwà ibi àti ikú ní ọ̀run, ìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé ní pé kí àwa èèyàn máa gbébẹ̀ ní àlàáfíà àti láìséwu.—Sáàmù 37:11, 29.
“Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí”
Ká máa rántí pé ó yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ẹlẹ́dàá wa pé ó máa pèsè àwọn ohun tá a nílò láti gbé ẹ̀mí wa ró.—Ìṣe 17:24, 25.
“Kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè”
Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, ẹ̀ṣẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà “gbèsè” túmọ̀ sí. (Lúùkù 11:4) Gbogbo wa la máa ń ṣẹ̀, tá a sì nílò ìdáríjì. Àmọ́ tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti dárí ji àwọn míì tó bá ṣẹ̀ wá.—Mátíù 6:14, 15.
“Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà”
Jèhófà Ọlọ́run ò ní dẹ wá wò láti ṣe ohun tí ò dáa. (Jémíìsì 1:13) Sátánì Èṣù tó jẹ́ “ẹni burúkú náà,” tí Bíbélì tún pè ní “Adánniwò náà” ló máa ń dán wa wò.” (1 Jòhánù 5:19; Mátíù 4:1-4) A máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí àdánwò bá dé.
Ṣé Àdúrà Olúwa nìkan ni àdúrà tá a gbọ́dọ̀ máa gbà?
Jésù kàn fi Àdúrà Olúwa ṣe àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ ká gbàdúrà. Kò yẹ ká máa sọ ọ́ lásọtúnsọ. Kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ Àdúrà Olúwa, ó kìlọ̀ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé: “Tí o bá ń gbàdúrà, má sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) Nígbà míì tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, àwọn ọ̀rọ̀ míì ló lò.—Lúùkù 11:2-4.
Ọ̀nà tó dáa jù láti gbàdúrà ni pé ká sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Ọlọ́run.—Sáàmù 62:8.
Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?
Àdúrà Olúwa jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè sọ nínú àdúrà wa tínú Ọlọ́run máa dùn sí. Jẹ́ ká wo bí àdúrà yìí ṣe bá ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì míì sọ nípa àdúrà mu.
Ọlọ́run nìkan ni kó o máa gbàdúrà sí
Ohun tí Bíbélì sọ: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run.”—Fílípì 4:6.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí, kì í ṣe Jésù, Màríà tàbí àwọn ẹni mímọ́. Bí Jésù ṣe fi ọ̀rọ̀ náà “Baba wa” bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀, ṣe ló ń kọ́ wa pé Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí.
Gbàdúrà fún àwọn ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu
Ohun tí Bíbélì sọ: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”—1 Jòhánù 5:14
Ohun tó túmọ̀ sí: A lè gbàdúrà fún ohunkóhun tó bá bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Jésù jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó nígbà tó sọ nínú àdúrà náà pé, “kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.” Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àá mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ayé àti fún àwa èèyàn.
Sọ àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn fún Jèhófà nínú àdúrà
Ohun tí Bíbélì sọ: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn. Nínú Àdúrà Olúwa tí Jésù gbà, ó béèrè àwọn nǹkan tara mélòó kan. Èyí fi hàn pé, a lè gbàdúrà fún àwọn nǹkan tara tí a nílò fún ọjọ́ kan. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa lókun tá a bá ní ìṣòro, a sì lè gbàdúrà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wá.c
a Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì tí Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbàdúrà, wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ míì tó yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n lò nínú Àdúrà Olúwa.—Lúùkù 23:34; Fílípì 1:9.
b Bíbélì Mímọ́ fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí parí Àdúrà Olúwa: “Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi yin Ọlọ́run lógo yìí wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì. Síbẹ̀, The Jerome Biblical Commentary sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí . . . ò sí nínú àwọn Bíbélì àtijọ́ tó ṣeé gbára lé.”
c Ó lè ṣòro fún àwọn tó bá ti dẹ́ṣẹ̀ láti gbàdúrà, torí pé ẹ̀rí ọkàn ń dá wọn lẹ́bi. Àmọ́ Jèhófà ń sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ ká yanjú ọ̀rọ̀ láàárín ara wa.” (Àìsáyà 1:18) Àwọn tó bá tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ látọkàn wá máa rí ìdáríjì gbà.