Dáníẹ́lì
2 Ní ọdún kejì tí Nebukadinésárì di ọba, ó lá àwọn àlá kan, ọkàn* rẹ̀ ò sì balẹ̀ rárá+ débi pé kò rí oorun sùn. 2 Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn oṣó àti àwọn ará Kálídíà* láti rọ́ àwọn àlá ọba fún un. Torí náà, wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró níwájú ọba.+ 3 Ọba wá sọ fún wọn pé: “Mo lá àlá kan, ọkàn* mi ò sì balẹ̀ torí mo fẹ́ mọ àlá tí mo lá.” 4 Àwọn ará Kálídíà fún ọba lésì ní èdè Árámáíkì+ pé:* “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. Rọ́ àlá náà fún àwa ìránṣẹ́ rẹ, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
5 Ọba dá àwọn ará Kálídíà lóhùn pé: “Mi ò ní sọ jù báyìí lọ: Tí ẹ ò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, a máa gé yín sí wẹ́wẹ́, a sì máa sọ ilé yín di ilé ìyàgbẹ́ gbogbo èèyàn.* 6 Àmọ́ tí ẹ bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀, màá fún yín ní ẹ̀bùn, màá san yín lẹ́san, màá sì dá yín lọ́lá lọ́pọ̀lọpọ̀.+ Torí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
7 Wọ́n dáhùn lẹ́ẹ̀kejì pé: “Kí ọba rọ́ àlá náà fún àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
8 Ọba fèsì pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé ṣe lẹ kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ yìí falẹ̀, torí ẹ mọ̀ pé ohun tí mo bá sọ ni abẹ gé. 9 Tí ẹ ò bá sọ àlá náà fún mi, ìyà kan náà ni màá fi jẹ gbogbo yín. Àmọ́ ẹ ti pinnu pé ẹ máa parọ́ fún mi, ẹ sì máa tàn mí jẹ títí dìgbà tí nǹkan fi máa yí pa dà. Torí náà, ẹ rọ́ àlá náà fún mi, màá sì mọ̀ pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”
10 Àwọn ará Kálídíà dá ọba lóhùn, wọ́n ní: “Kò sí ẹnì kankan ní ayé* tó lè ṣe ohun tí ọba ń béèrè, torí kò sí ọba ńlá tàbí gómìnà tó tíì béèrè irú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àlùfáà onídán, pidánpidán tàbí ará Kálídíà kankan. 11 Àmọ́ ohun tí ọba ń béèrè ṣòro gan-an, kò sí ẹnì kankan tó lè sọ ọ́ fún ọba àfi àwọn ọlọ́run, tí kì í gbé láàárín àwọn ẹni kíkú.”*
12 Inú wá bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo amòye Bábílónì run.+ 13 Lẹ́yìn tó pàṣẹ, tí wọ́n sì ti fẹ́ pa àwọn amòye náà, wọ́n wá Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà kí wọ́n lè pa wọ́n.
14 Ìgbà yẹn ni Dáníẹ́lì rọra fọgbọ́n bá Áríókù tó jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ ọba sọ̀rọ̀, òun ló jáde lọ láti pa àwọn amòye Bábílónì. 15 Ó bi Áríókù, ẹni tó ń bá ọba ṣiṣẹ́ pé: “Kí ló dé tí ọba fi pa irú àṣẹ tó le tó báyìí?” Áríókù wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Dáníẹ́lì.+ 16 Torí náà, Dáníẹ́lì wọlé, ó sì ní kí ọba yọ̀ǹda àkókò fún òun kóun lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.
17 Dáníẹ́lì wá lọ sí ilé rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, Hananáyà, Míṣáẹ́lì àti Asaráyà. 18 Ó ní kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run fún àánú nípa àṣírí yìí, kí wọ́n má bàa pa Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ run pẹ̀lú àwọn amòye Bábílónì yòókù.
19 Lẹ́yìn náà, a ṣí àṣírí náà payá fún Dáníẹ́lì nínú ìran lóru.+ Dáníẹ́lì sì yin Ọlọ́run ọ̀run. 20 Dáníẹ́lì sọ pé:
21 Ó ń yí ìgbà àti àsìkò pa dà,+
Ó ń mú ọba kúrò, ó sì ń fi ọba jẹ,+
Ó ń fún àwọn ọlọ́gbọ́n ní ọgbọ́n, ó sì ń fún àwọn tó ní òye ní ìmọ̀.+
22 Ó ń ṣí àwọn ohun tó jinlẹ̀ àti àwọn ohun tó pa mọ́ payá,+
Ó mọ ohun tó wà nínú òkùnkùn,+
Ìmọ́lẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
23 Ìwọ Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi, ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, tí mo sì ń fìyìn fún,
Torí o ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára.
O sì ti wá jẹ́ kí n mọ ohun tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ;
O ti jẹ́ ká mọ ohun tó ń da ọba láàmú.”+
24 Dáníẹ́lì wá wọlé lọ bá Áríókù, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Bábílónì run,+ ó sì sọ fún un pé: “Má pa ìkankan nínú àwọn amòye Bábílónì. Mú mi wọlé lọ síwájú ọba, màá sì sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”
25 Áríókù yára mú Dáníẹ́lì wọlé síwájú ọba, ó sì sọ fún un pé: “Mo ti rí ọkùnrin kan lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn ní Júdà,+ tó lè sọ ìtumọ̀ náà fún ọba.” 26 Ọba sọ fún Dáníẹ́lì, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bẹtiṣásárì+ pé: “Ṣé lóòótọ́ lo lè rọ́ àlá tí mo lá fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”+ 27 Dáníẹ́lì dá ọba lóhùn pé: “Ìkankan nínú àwọn amòye, àwọn pidánpidán, àwọn àlùfáà onídán àti àwọn awòràwọ̀ ò lè sọ àṣírí tí ọba ń béèrè fún un.+ 28 Àmọ́ Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run, tó jẹ́ Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá,+ ó sì ti jẹ́ kí Ọba Nebukadinésárì mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́. Àlá rẹ nìyí, àwọn ìran tí o sì rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ nìyí:
29 “Ní tìrẹ, ọba, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló wá sí ọ lọ́kàn lórí ibùsùn rẹ, Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá sì ti jẹ́ kí o mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. 30 Ní tèmi, kì í ṣe torí pé mo gbọ́n ju ẹnikẹ́ni tó wà láàyè ni a ṣe ṣí àṣírí yìí payá fún mi; àmọ́ ó jẹ́ torí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá náà, kí o lè mọ èrò tó wá sí ọ lọ́kàn.+
31 “Ìwọ ọba ń wò, o sì rí ère ńlá kan. Ère yẹn tóbi, ó sì ń tàn yòò, ó dúró níwájú rẹ, ìrísí rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù gidigidi. 32 Wúrà tó dáa ni orí ère yẹn,+ fàdákà ni igẹ̀ àti apá rẹ̀,+ bàbà sì ni ikùn àti itan rẹ̀,+ 33 irin ni ẹsẹ̀ rẹ̀,+ apá kan irin àti apá kan amọ̀* sì ni àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.+ 34 Ò ń wò títí a fi gé òkúta kan jáde, tó jẹ́ pé ọwọ́ kọ́ ló gé e, ó kọ lu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ ọ túútúú.+ 35 Ìgbà yẹn ni gbogbo irin, amọ̀, bàbà, fàdákà àti wúrà fọ́ túútúú, ó sì dà bí ìyàngbò* láti ibi ìpakà ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, atẹ́gùn sì gbé wọn lọ títí kò fi ṣẹ́ ku nǹkan kan. Àmọ́ òkúta tó kọ lu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.
36 “Àlá náà nìyí, a sì máa sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 37 Ìwọ ọba, ọba àwọn ọba, tí Ọlọ́run ọ̀run ti fún ní ìjọba,+ agbára, okun àti ògo, 38 tó sì ti fi àwọn èèyàn lé lọ́wọ́, ibi yòówù kí wọ́n máa gbé, títí kan àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àtàwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, tó sì fi ṣe ọba lórí gbogbo wọn,+ ìwọ fúnra rẹ ni orí wúrà náà.+
39 “Àmọ́ ìjọba míì máa dìde lẹ́yìn rẹ,+ tí kò tó ọ; lẹ́yìn èyí ni ìjọba míì, ìkẹta, tó jẹ́ bàbà, tó máa ṣàkóso gbogbo ayé.+
40 “Ní ti ìjọba kẹrin, ó máa le bí irin.+ Torí bí irin ṣe ń fọ́ gbogbo nǹkan míì túútúú, tó sì ń lọ̀ ọ́, àní, bí irin ṣe ń rún nǹkan wómúwómú, ó máa fọ́ gbogbo èyí túútúú, ó sì máa rún un wómúwómú.+
41 “Bí o sì ṣe rí i pé àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ ti amọ̀kòkò àti apá kan irin, ìjọba náà máa pínyà, àmọ́ ó ṣì máa le bí irin lápá kan, bí o ṣe rí i pé irin náà dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀. 42 Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ sì ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba náà ṣe máa lágbára lápá kan, tí kò sì ní lágbára lápá kan. 43 Bí o ṣe rí i tí irin dà pọ̀ mọ́ amọ̀ rírọ̀, wọ́n máa dà pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn;* àmọ́ wọn ò ní lẹ̀ mọ́ra, ọ̀kan mọ́ ìkejì, bí irin àti amọ̀ ò ṣe lè lẹ̀ mọ́ra.
44 “Ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn, Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,+ tí kò ní pa run láé.+ A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì.+ Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú,+ ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé,+ 45 bí o ṣe rí i tí òkúta kan gé kúrò lára òkè náà, tó jẹ́ pé ọwọ́ kọ́ ló gé e, tó sì fọ́ irin, bàbà, amọ̀, fàdákà àti wúrà túútúú.+ Ọlọ́run Atóbilọ́lá ti jẹ́ kí ọba mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.+ Òótọ́ ni àlá náà, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”
46 Ọba Nebukadinésárì wá dojú bolẹ̀ níwájú Dáníẹ́lì, ó sì júbà rẹ̀. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un lẹ́bùn, kí wọ́n sì sun tùràrí fún un. 47 Ọba sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Lóòótọ́, Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba ni Ọlọ́run yín, ó sì jẹ́ Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá, torí pé o rí àṣírí yìí ṣí payá.”+ 48 Ọba wá gbé Dáníẹ́lì ga, ó fún un ní ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tó dáa, ó sì fi ṣe alákòóso lórí gbogbo ìpínlẹ̀* Bábílónì+ àti olórí àwọn aṣíwájú gbogbo amòye Bábílónì. 49 Bí Dáníẹ́lì sì ṣe béèrè, ọba yan Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò+ láti máa bójú tó ìpínlẹ̀* Bábílónì, àmọ́ Dáníẹ́lì ń ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba.