Wednesday, July 31
Ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin.—Ìfi. 2:25.
A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà. Jésù bá àwọn kan ní Págámù wí torí pé wọ́n ń fa ìyapa nínú ìjọ. (Ìfi. 2:14-16) Ó gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tó wà ní Tíátírà torí wọ́n ti yẹra fún “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Sátánì,” ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ‘di òtítọ́ mú ṣinṣin.’ (Ìfi. 2:24-26) Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó ti gba ẹ̀kọ́ èké ronú pìwà dà. Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe lónìí? A gbọ́dọ̀ ta ko ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó lòdì sí èrò Jèhófà. Àwọn apẹ̀yìndà lè “jọ ẹni tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,” àmọ́ ‘ìṣe wọn ò fi agbára Ọlọ́run hàn.’ (2 Tím. 3:5) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó máa rọrùn fún wa láti mọ ẹ̀kọ́ èké, ká sì ta kò ó. (2 Tím. 3:14-17; Júùdù 3, 4) A gbọ́dọ̀ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, ó yẹ ká ṣàtúnṣe ká lè rí ojúure ẹ̀.—Ìfi. 2:5, 16; 3:3, 16. w22.05 4 ¶9; 5 ¶11
Thursday, August 1
Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.—Mál. 3:16.
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí orúkọ rẹ̀, tó sì wá ń kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Ohun tó wu Jèhófà ni pé káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbádùn ayé wọn títí láé nínú ayé tuntun. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ ló máa fi hàn bóyá Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (Jém. 1:26) Àwọn kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń fìbínú sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ gúnni lára, wọ́n sì máa ń fọ́nnu. (2 Tím. 3:1-5) A ò ní fẹ́ fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kó máa wù wá láti máa sọ ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó tuni lára nípàdé àti lóde ẹ̀rí àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sáwọn tó wà nínú ìdílé wa?—1 Pét. 3:7. w22.04 5 ¶4-5
Friday, August 2
Wọ́n máa kórìíra aṣẹ́wó náà, wọ́n máa sọ ọ́ di ahoro, wọ́n á tú u sí ìhòòhò, wọ́n máa jẹ ẹran ara rẹ̀, wọ́n sì máa fi iná sun ún pátápátá.—Ìfi. 17:16.
Ọlọ́run ti fi sí ọkàn ìwo mẹ́wàá àti ẹranko náà láti pa Bábílónì Ńlá run. Jèhófà máa mú kí àwọn orílẹ̀-èdè lo ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò, ìyẹn Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé láti pa gbogbo ẹ̀sìn èké ayé run pátápátá. (Ìfi. 18:21-24) Kí ló yẹ ká ṣe? “Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run” ló yẹ ká máa ṣe. (Jém. 1:27) A ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kọ́ èké láyè, a ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí àwọn àjọ̀dún tó wá látinú ìbọ̀rìṣà. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ tó kúnnú ayé lónìí tàbí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí Bábílónì Ńlá ń ṣe. Nǹkan míì tá a máa ṣe ni pé ká máa pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n “jáde kúrò nínú [Bábílónì Ńlá],” kí wọ́n má bàa gbà nínú ẹ̀bi rẹ̀ níwájú Ọlọ́run.—Ìfi. 18:4. w22.05 11 ¶17-18