Sáàmù
ÌWÉ KARÙN-ÚN
(Sáàmù 107-150)
2 Kí àwọn tí Jèhófà gbà* pa dà sọ bẹ́ẹ̀,
Àwọn tó gbà pa dà lọ́wọ́* ọ̀tá,+
3 Àwọn tó kó jọ láti àwọn ilẹ̀,+
Láti ìlà oòrùn àti láti ìwọ̀ oòrùn,*
Láti àríwá àti láti gúúsù.+
4 Wọ́n rìn kiri ní aginjù, ní aṣálẹ̀;
Wọn ò rí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dé ìlú tí wọ́n lè máa gbé.
5 Ebi pa wọ́n, òùngbẹ sì gbẹ wọ́n;
Àárẹ̀ mú wọn* torí wọn ò lókun mọ́.
8 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà+ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀
Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+
9 Nítorí ó mú kí àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ mu àmutẹ́rùn,
10 Àwọn kan ń gbé inú òkùnkùn biribiri,
Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ìyà ń jẹ, tí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sì wà lọ́wọ́ wọn.
11 Nítorí wọ́n ta ko ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;
Wọn ò ka ìmọ̀ràn Ẹni Gíga Jù Lọ sí.+
12 Torí náà, ó fi ìnira rẹ ọkàn wọn sílẹ̀;+
Wọ́n kọsẹ̀, kò sì sí ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Wọ́n ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn,
Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
14 Ó mú wọn jáde nínú òkùnkùn biribiri,
Ó sì fa ìdè wọn já.+
15 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀+
Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.
16 Nítorí ó ti fọ́ àwọn ilẹ̀kùn bàbà,
Ó sì ti gé àwọn ọ̀pá ìdábùú onírin.+
18 Oúnjẹ kankan ò lọ lẹ́nu wọn;*
Wọ́n sún mọ́ àwọn ẹnubodè ikú.
19 Wọ́n á ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nítorí wàhálà tó bá wọn;
Á sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
20 Á fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn, á mú wọn lára dá,+
Á sì yọ wọ́n nínú kòtò tí wọ́n há sí.
21 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀
Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.
22 Kí wọ́n rú ẹbọ ọpẹ́,+
Kí wọ́n sì máa fi igbe ayọ̀ kéde àwọn iṣẹ́ rẹ̀.
23 Àwọn tó ń fi ọkọ̀ rìnrìn àjò lórí òkun,
Tí wọ́n ń ṣòwò lórí agbami òkun,+
24 Wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ Jèhófà
Àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ nínú ibú;+
25 Bó ṣe fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú kí ìjì máa jà,+
Tó sì ń ru ìgbì òkun sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run;
Wọ́n já wálẹ̀ ṣòòròṣò sínú ibú.
Ọkàn wọn domi nítorí àjálù tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀.
28 Ni wọ́n bá ké pe Jèhófà nínú wàhálà tó bá wọn,+
Ó sì gbà wọ́n nínú ìnira wọn.
29 Ó mú kí ìjì náà rọlẹ̀,
Ìgbì òkun sì pa rọ́rọ́.+
30 Inú wọn dùn nígbà tí gbogbo rẹ̀ pa rọ́rọ́,
Ó sì ṣamọ̀nà wọn dé èbúté tí wọ́n fẹ́.
31 Kí àwọn èèyàn máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀
Àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ lórí àwọn ọmọ èèyàn.+
33 Ó ń sọ àwọn odò di aṣálẹ̀,
Ó sì ń sọ ìṣàn omi di ilẹ̀ tó gbẹ táútáú,+
34 Ó ń sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀,+
Nítorí ìwà burúkú àwọn tó ń gbé orí rẹ̀.
38 Ó bù kún wọn, wọ́n sì pọ̀ gidigidi;
Kò jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn pẹ̀dín.+
39 Àmọ́ wọ́n tún dín kù, ẹ̀tẹ́ sì bá wọn
Nítorí ìnilára, àjálù àti ẹ̀dùn ọkàn.
40 Ó rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,
Ó sì mú kí wọ́n rìn kiri ní ilẹ̀ tó ti di ahoro, tí kò sì lójú ọ̀nà.+