ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15
Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ Máa Ń Tu Àwọn Èèyàn Lára?
“Jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀.”—1 TÍM. 4:12.
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ta ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ?
JÈHÓFÀ Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Àtìgbà tí Jèhófà ti dá Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ ló ti ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Ó tún mọ bó ṣe lè hun àwọn ọ̀rọ̀ kan pọ̀ kó lè di gbólóhùn. Ohun tó ṣe nìyẹn nígbà tó ń sọ gbogbo àwọn ẹranko lórúkọ. (Jẹ́n. 2:19) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ wo bí inú Ádámù ṣe máa dùn tó nígbà tó kọ́kọ́ bá èèyàn bíi tiẹ̀ sọ̀rọ̀, ìyẹn nígbà tó bá Éfà ìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀!—Jẹ́n. 2:22, 23.
2. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà àtijọ́ àti lákòókò wa yìí tó fi hàn pé wọn ò mọyì ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ?
2 Kò pẹ́ sígbà tí Jèhófà dá Ádámù, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí ò dáa. Sátánì parọ́ fún Éfà, irọ́ tó pa yìí ló mú káwa èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé. (Jẹ́n. 3:1-4) Nígbà tí Ádámù ṣàṣìṣe, ó sọ ohun tí ò dáa torí ó dá Éfà àti Jèhófà lẹ́bi fún ohun tó ṣe. (Jẹ́n. 3:12) Kéènì náà parọ́ fún Jèhófà lẹ́yìn tó pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. (Jẹ́n. 4:9) Nígbà tó yá, àtọmọdọ́mọ Kéènì kan tó ń jẹ́ Lámékì kọ ewì tó jẹ́ ká mọ bí ìwà ipá ṣe pọ̀ tó nígbà ayé rẹ̀. (Jẹ́n. 4:23, 24) Báwo lọ̀rọ̀ ṣe rí lákòókò tiwa yìí? Nígbà míì, àwọn olóṣèlú máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa. Bákan náà, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn fíìmù táwọn èèyàn ń ṣe jáde ni wọ́n ti máa ń sọ̀sọkúsọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọmọ iléèwé máa ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ̀sọkúsọ nílé ìwé wọn, àwọn àgbàlagbà náà sì máa ń dojú kọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ níbiiṣẹ́. Torí náà, ó bani nínú jẹ́ pé bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ̀sọkúsọ lónìí fi hàn pé àwọn èèyàn ò hùwà ọmọlúwàbí mọ́ àti pé ayé yìí ti bà jẹ́ bàlùmọ̀.
3. Ewu wo ló yẹ ká yẹra fún, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Tá ò bá kíyè sára, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀sọkúsọ bíi tàwọn tó wà láyìíká wa. Torí pé Kristẹni ni wá, a fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Jèhófà dùn, èyí sì gba pé ká yẹra fún ìsọkúsọ. A fẹ́ lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún wa láti máa fi yìn ín. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ (1) tá a bá wà lóde ẹ̀rí, (2) tá a bá wà nípàdé àti (3) tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa ń sọ ṣe ń rí lára Jèhófà.
BÍ Ọ̀RỌ̀ TÁ À Ń SỌ ṢE Ń RÍ LÁRA JÈHÓFÀ
4. Bí Málákì 3:16 ṣe sọ, kí nìdí táwọn ọ̀rọ̀ tá à ń sọ fi ṣe pàtàkì sí Jèhófà?
4 Ka Málákì 3:16. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jèhófà fi ń fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣàṣàrò lórí orúkọ rẹ̀, tó sì wá ń kọ orúkọ wọn sínú “ìwé ìrántí” rẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Jésù sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tó wà nínú ọkàn ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Àwọn nǹkan tá à ń sọ máa ń fi hàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Ohun tó sì wu Jèhófà ni pé káwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gbádùn ayé wọn títí láé nínú ayé tuntun.
5. (a) Báwo ni ọ̀rọ̀ ẹnu wa ṣe kan ìjọsìn wa? (b) Bó ṣe wà nínú àwòrán yẹn, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń sọ̀rọ̀?
5 Àwọn ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ ló máa fi hàn bóyá Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (Jém. 1:26) Àwọn kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa ń fìbínú sọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ gúnni lára, wọ́n sì máa ń fọ́nnu. (2 Tím. 3:1-5) Kò yẹ ká fìwà jọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kó máa wù wá láti máa sọ ohun tó máa múnú Jèhófà dùn. Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó tuni lára nípàdé àti lóde ẹ̀rí àmọ́ tá a wá ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sáwọn tó wà nínú ìdílé wa?—1 Pét. 3:7.
6. Àǹfààní wo ni Kimberly rí nígbà tó sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dáa?
6 Tá a bá ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa, ìyẹn máa fi hàn pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá. A tún máa jẹ́ kí àwọn èèyàn tá a jọ wà ládùúgbò rí ìyàtọ̀ tó wà “láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Mál. 3:18) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Kimberly nìyẹn.b Wọ́n ní kí òun àti ọmọ kíláàsì ẹ̀ kan jọ ṣiṣẹ́ kan pa pọ̀ nílé ìwé. Lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ náà, ọmọ kíláàsì ẹ̀ yẹn kíyè sí i pé Kimberly yàtọ̀ sáwọn ọmọ kíláàsì tó kù. Ó rí i pé Kimberly kì í sọ̀rọ̀ àwọn míì láìdáa, ara ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn, kì í sì í sọ̀sọkúsọ. Ohun tí Kimberly ṣe yìí wú ọmọ kíláàsì ẹ̀ lórí gan-an débi pé ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà máa ń dùn gan-an tó bá rí i pé à ń lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa débi pé àwọn èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!
7. Kí ló wù ẹ́ kó o fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún ẹ ṣe?
7 Gbogbo wa la máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fògo fún Jèhófà, tó sì máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe tó máa jẹ́ ká lè lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa.
JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ Ẹ TUNI LÁRA TÓ O BÁ WÀ LÓDE Ẹ̀RÍ
8. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa sọ̀rọ̀ tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
8 Sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́ táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó bí ẹ nínú. Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ ìwàásù lórí ilẹ̀ ayé, àwọn èèyàn sọ pé ọ̀mùtí ni, wọ́n ní alájẹkì ni, wọ́n ní ìránṣẹ́ Èṣù ni, wọ́n ní kì í pa Sábáàtì mọ́ àti pé ó ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run. (Mát. 11:19; 26:65; Lúùkù 11:15; Jòh. 9:16) Síbẹ̀, Jésù ò sọ̀rọ̀ burúkú pa dà sí wọn. Bíi ti Jésù, táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa, kò yẹ káwa náà sọ̀rọ̀ tí kò dáa pa dà sí wọn. (1 Pét. 2:21-23) Òótọ́ ni pé kì í rọrùn láti kó ara wa níjàánu tí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ burúkú sí wa. (Jém. 3:2) Àmọ́ kí ló máa ràn wá lọ́wọ́?
9. Kí ló máa jẹ́ ká lè kó ẹnu wa níjàánu tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
9 Tẹ́nì kan bá sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa nígbà tá a wà lóde ẹ̀rí, kò yẹ ká bínú. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Sam sọ pé: “Ohun tí mo máa ń fi sọ́kàn nípa ẹni tí mo fẹ́ wàásù fún ni bó ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti pé ó ṣì lè yí pa dà.” Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ohun kan ti ṣẹlẹ̀ sí ẹni tá a fẹ́ wàásù fún ká tó débẹ̀. Tẹ́nì kan bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lucia lóde ẹ̀rí, ṣe ló máa ń rọra gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kóun kó ara òun níjàánu kóun má bàa sọ̀rọ̀ tí ò dáa sẹ́ni náà. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn.
10. Bí 1 Tímótì 4:13 ṣe sọ, kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe?
10 Túbọ̀ jẹ́ ẹni tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. Òjíṣẹ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ni Tímótì, síbẹ̀, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè sunwọ̀n sí i. (Ka 1 Tímótì 4:13.) Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń múra sílẹ̀ dáadáa. A dúpẹ́ pé a láwọn ohun èlò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi tó máa jẹ́ ká mọ̀ọ̀yàn kọ́. Wàá rí àwọn ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tó o bá wo ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni àti apá “Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù” nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. Ṣé ò ń lo àwọn ìwé yìí kó o lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́? Tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa ká tó lọ sóde ẹ̀rí, ẹ̀rù ò ní máa bà wá, ìyẹn á sì jẹ́ ká fìgboyà sọ̀rọ̀.
11. Kí làwọn ará wa kan ṣe kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́?
11 A lè túbọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́ tá a bá ń kíyè sí ọ̀nà táwọn míì nínú ìjọ ń gbà kọ́ni. Sam tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú máa ń ronú nípa ohun táwọn ará kan ṣe tí wọ́n fi dẹni tó mọ̀ọ̀yàn kọ́. Torí náà, ó kíyè sí bí wọ́n ṣe ń kọ́ni, ó sì fara wé wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Talia náà sọ pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn arákùnrin tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa tí wọ́n bá ń sọ àsọyé, ìyẹn sì ti jẹ́ kóun mọ ohun tóun máa sọ tóun bá ń dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè lóde ẹ̀rí.
JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ Ẹ TUNI LÁRA TÓ O BÁ WÀ NÍPÀDÉ
12. Kí ló máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan láti ṣe?
12 Tá a bá wà nípàdé, a lè fi hàn pé a fẹ́ káwọn ará gbádùn ìpàdé tá a bá jọ ń kọrin, tá a sì ń jẹ́ kí ìdáhùn wa gbé wọn ró. (Sm. 22:22) Ó máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan láti kọrin, kí wọ́n sì dáhùn tí wọ́n bá wà nípàdé. Ṣé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan ti nírú ìṣòro tó o ní yìí rí, wọ́n sì ti borí ẹ̀. Tó o bá mọ ohun tí wọ́n ṣe láti borí ìṣòro náà, wàá jàǹfààní gan-an.
13. Kí ló máa jẹ́ kó o lè fayọ̀ kọrin tó o bá wà nípàdé?
13 Máa fayọ̀ kọrin. Ohun tó yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run nípàdé ni pé a fẹ́ yin Jèhófà lógo. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sara máa ń wo ara ẹ̀ bíi pé òun ò lẹ́bùn orin kíkọ. Àmọ́, ó ṣì ń wù ú láti máa fi orin yin Jèhófà nípàdé. Kó lè borí ìṣòro yìí, ó máa ń múra orin tí wọ́n máa kọ nípàdé sílẹ̀ bó ṣe máa ń múra àwọn apá ìpàdé yòókù. Ó máa ń fi àwọn orin náà dánra wò kó lè mọ bí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà ṣe bá ohun tí wọ́n máa jíròrò nípàdé mu. Ó sọ pé: “Ohun tí mò ń ṣe yìí ti jẹ́ kí n lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà dípò kí n pọkàn pọ̀ sórí orin tí mi ò mọ̀ ọ́n kọ dáadáa.”
14. Kí ló máa jẹ́ kó o lè dáhùn nípàdé tẹ́rù bá ń bà ẹ́?
14 Máa dáhùn déédéé. Ká sòótọ́, kì í rọrùn fáwọn kan láti máa dáhùn nípàdé déédéé. Arábìnrin Talia tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn, ẹ̀rù máa ń bà mí torí mi kì í lè sọ̀rọ̀ bí mo ṣe fẹ́, ìyẹn sì máa ń mú kó ṣòro fún mi láti dáhùn nípàdé.” Síbẹ̀, Arábìnrin Talia ò jẹ́ kíyẹn dí òun lọ́wọ́ láti máa dáhùn nípàdé. Tó bá ń múra ìpàdé sílẹ̀, ó máa ń fi sọ́kàn pé ìdáhùn àkọ́kọ́ gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí, kó sì ṣe tààràtà. Ó sọ pé: “Ohun tó dáa ni bí ìdáhùn mi ṣe máa ń ṣe ṣókí, tí kì í lọ́jú pọ̀, tó sì máa ń ṣe tààràtà torí irú ìdáhùn yẹn ni arákùnrin tó ń darí ìpàdé fẹ́.”
15. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń dáhùn nípàdé?
15 Ó máa ń ṣòro fáwọn ará wa kan tí kì í bẹ̀rù láti dáhùn nípàdé. Kí nìdí? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Juliet sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n má dáhùn nípàdé torí mo máa ń ronú pé ìdáhùn mi ti ṣe ṣókí jù, kò sì dáa tó.” Àmọ́, ká má gbàgbé pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé ká dáhùn lọ́nà tó máa gbé àwọn ará ró.c Jèhófà máa ń mọyì ẹ̀ gan-an tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa dáhùn láwọn ìpàdé ìjọ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù lè máa bà wá.
JẸ́ KÍ Ọ̀RỌ̀ Ẹ TUNI LÁRA TÓ O BÁ Ń BÁ ÀWỌN ÈÈYÀN SỌ̀RỌ̀
16. Irú àwọn ọ̀rọ̀ wo ni kò yẹ ká máa sọ?
16 Má ṣe máa sọ “ọ̀rọ̀ èébú.” (Éfé. 4:31) Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, kò yẹ kí Kristẹni kan máa sọ̀sọkúsọ. Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ èébú kan wà tó tún yẹ ká yẹra fún tó lè dà bíi pé kò fi bẹ́ẹ̀ burú. Bí àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má máa sọ̀rọ̀ tí ò dáa sáwọn èèyàn torí pé àṣà wọn, ẹ̀yà wọn àti ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀ sí tiwa. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa sọ ọ̀rọ̀ tó máa bu àwọn ẹlòmíì kù. Arákùnrin kan sọ pé: “Ìgbà kan wà tí mo máa ń ṣe àwọn àwàdà tí mo rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ burú, àmọ́ tó jẹ́ pé ó máa ń dun ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Tí èmi àtìyàwó mi bá ti dá wà, ó máa ń sọ fún mi pé bí mo ṣe máa ń sọ̀rọ̀ sí òun àtàwọn ẹlòmíì ò dáa àti pé ọ̀rọ̀ náà máa ń dùn wọ́n gan-an.”
17. Kí ni Éfésù 4:29 sọ pé ká máa ṣe kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè gbé àwọn èèyàn ró?
17 Máa sọ ọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró. Dípò ká máa ṣàríwísí àwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká máa gbóríyìn fún wọn. (Ka Éfésù 4:29.) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fi yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Àmọ́ ṣe ni wọ́n ń kùn ṣáá. Tó bá jẹ́ gbogbo ìgbà la máa ń kùn, ó lè mú káwọn míì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kùn. Ṣé ẹ rántí pé ìròyìn tí ò dáa táwọn amí mẹ́wàá yẹn mú wá jẹ́ kí “gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . kùn sí Mósè.” (Nọ́ń. 13:31–14:4) Àmọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó ń gbé àwọn èèyàn ró, ó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀. Kò sí àní-àní pé ohun tó mú kí ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ yanjú ni pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ máa ń lọ fún un níṣìírí. (Oníd. 11:40) Sara tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn èèyàn, ṣe là ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àtàwọn ará ìjọ nífẹ̀ẹ́ wọn.” Torí náà, rí i dájú pé ò ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti máa gbóríyìn fáwọn ará látọkàn wá.
18. Bí Sáàmù 15:1, 2 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa sọ òótọ́, kí nìyẹn sì gba pé ká ṣe?
18 Máa sọ òótọ́. Tá a bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ máa sọ òótọ́. Ó kórìíra kéèyàn máa parọ́. (Òwe 6:16, 17) Lónìí, àwọn èèyàn máa ń parọ́, wọn ò sì róhun tó burú níbẹ̀. Àmọ́, kò yẹ káwa máa parọ́ torí Jèhófà kórìíra irú nǹkan bẹ́ẹ̀. (Ka Sáàmù 15:1, 2.) Yàtọ̀ sí pé kò yẹ ká máa parọ́, kò tún yẹ ká máa fi òótọ́ pa mọ́ torí pé ìyẹn lè ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.
19. Kí ló tún yẹ ká yẹra fún?
19 Má ṣe máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa. (Òwe 25:23; 2 Tẹs. 3:11) Juliet tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ ẹnì kan láìdáa, inú òun kì í dùn. Ó sọ pé: “Inú mi kì í dùn tí wọ́n bá wá ṣòfófó ẹnì kan fún mi, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí n fọkàn tán ẹni tó wá ṣòfófó náà torí mi ò mọ̀ bóyá ó máa lọ ṣòfófó tèmi náà fún ẹlòmíì.” Torí náà, tí ìwọ àti ẹnì kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ tó fẹ́ máa ṣòfófó ẹnì kan, o lè fọgbọ́n yí ọ̀rọ̀ náà pa dà, kẹ́ ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ọ̀rọ̀ tó máa gbéni ró.—Kól. 4:6.
20. Kí lo pinnu láti ṣe pẹ̀lú ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Jèhófà fún ẹ?
20 Nínú ayé tá à ń gbé lónìí, àwọn èèyàn máa ń sọ̀sọkúsọ gan-an. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká sì rí i pé ọ̀rọ̀ ẹnu wa ń múnú Jèhófà dùn. Ẹ má jẹ́ ká gbàgbé pé Jèhófà ló fún wa lẹ́bùn ọ̀rọ̀ sísọ, inú ẹ̀ sì máa dùn tá a bá lò ó lọ́nà tó dáa. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún wa tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa lo ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ wa lọ́nà tó dáa nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, nígbà tá a bá wà nípàdé àti nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tí Jèhófà bá pa ayé búburú yìí run, á túbọ̀ rọrùn fún wa láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa yìn ín lógo. (Júùdù 15) Torí náà, pinnu pé kó tó dìgbà yẹn, wàá jẹ́ kí “ọ̀rọ̀ ẹnu [rẹ]” máa múnú Jèhófà dùn.—Sm. 19:14.
ORIN 121 A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
a Jèhófà fún wa lẹ́bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ò lo ẹ̀bùn yìí bí Jèhófà ṣe fẹ́. Kí la lè ṣe kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa lè máa gbé àwọn míì ró, kó sì jẹ́ èyí táá múnú Jèhófà dùn nínú ayé burúkú tó ti bà jẹ́ bàlùmọ̀ yìí? Kí la lè ṣe tọ́rọ̀ ẹnu wa á fi máa múnú Jèhófà dùn tá a bá wà lóde ẹ̀rí, tá a bá wà nípàdé àtìgbà tá a bá ń bá àwọn míì sọ̀rọ̀? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè máa dáhùn nípàdé, wo àpilẹ̀kọ náà “Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ” nínú Ilé Ìṣọ́ January 2019.
d ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan gbaná jẹ nígbà tí ẹni tí wọ́n ń wàásù fún fìbínú sọ̀rọ̀ sí i. Arákùnrin kan ò kọrin nígbà táwọn yòókù ń kọrin nípàdé; arábìnrin kan sì ń ṣòfófó.