Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Àkókò Wa
BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú àlàáfíà àti ayọ̀ tí kò lópin wá fáráyé. (Dáníẹ́lì 2:44) Nínú Àdúrà Olúwa, tí wọ́n tún ń pè ní Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí Òkè Ólífì, ó sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó bá kù díẹ̀ kí Ìjọba náà dé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí para pọ̀ jẹ́ àmì tó máa hàn gbangba sáwọn olóòótọ́ tó bá wà lójúfò. Mélòó nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ara àmì yẹn, tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò báyìí ni ìwọ fúnra rẹ ti kíyè sí pé ó ti ń ṣẹlẹ̀?
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ń Dojú Ogun Kọ Ara Wọn. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà lọ́dún 1914, ogun abẹ́lé ló sábà máa ń jà. Yàtọ̀ sí pé Ogun Àgbáyé Kìíní kárí ibi tó pọ̀ láyé, ó tún mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í yára ṣe àwọn ohun ìjà olóró tó ń ṣọṣẹ́ ju èyíkéyìí táráyé tíì rí rí lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń lo ọkọ̀ òfúrufú tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe nígbà yẹn láti fi ju bọ́ǹbù sórí àwọn èèyàn. Bí ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ṣe ń gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìjà olóró jáde ti mú kí iye àwọn tógun ń pa túbọ̀ máa pọ̀ sí i, débi tó fi kọjá ohun tẹ́nikẹ́ni lè ronú kàn tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó tó bí ìlàjì tó kú tàbí tó ṣèṣe lára àwọn mílíọ̀nù márùndínláàádọ́rin [65,000,000] sójà tó lọ sí Ogun Àgbáyé Kìíní. Síbẹ̀, bá a ṣe ń sún mọ́ ọdún 2000, ńṣe ni iye àwọn tógun ń pa túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ òpìtàn kan, “títí láé, kò sí bá a ṣe máa mọ” iye àwọn sójà àtàwọn tí kì í ṣe sójà tó bá Ogun Àgbáyé Kejì lọ. Ogun ò sì tíì kásẹ̀ nílẹ̀ títí di bá a ṣe ń sọ yìí.
Ebi Ń Pa Tọmọdé-Tàgbà. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àìtó oúnjẹ . . . yóò sì wà.” (Mátíù 24:7) Lọ́dún 2005, ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Science, sọ pé: “Ó tó mílíọ̀nù lọ́nà ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́fà [854,000,000] èèyàn tí kì í jẹun kánú (ìyẹn sì fi hàn pé ẹnì kan nínú mẹ́wàá lára àwọn tó wà láyé ni kì í jẹun kánú).” Lọ́dún 2007, àjọ tó ń bójú tó ọ̀ràn oúnjẹ àti iṣẹ́ àgbẹ̀ lábẹ́ àsíá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè sọ pé orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] ni kò lóúnjẹ tó tó láti fi bọ́ àwọn aráàlú wọn. Kí nìdí tọ́ràn fi rí báyìí nígbà tó jẹ́ pé ńṣe loúnjẹ oníhóró táwọn àgbẹ̀ ń gbìn ń pọ̀ sí i? Ohun kan ni pé, ilẹ̀ tó yẹ kí wọ́n fi dá oko àti oúnjẹ oníhóró tó yẹ kí wọ́n fi bọ́ àwọn èèyàn ni wọ́n fi ń ṣe epo ọkọ̀. Ìwé ìròyìn kan lórílẹ̀-èdè South Africa tó ń jẹ́ The Witness sọ pé: “Oúnjẹ oníhóró tẹ́nì kan á jẹ fún odindi ọdún kan ni wọ́n máa fi ṣe ìwọ̀nba epo tó máa kún inú táǹkì ọkọ̀ ńlá kan tó lágbára láti rìn lójú ọ̀nà gbágungbàgun.” Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ọ̀pọ̀ máa ń tìtorí ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ dà á rò bóyá káwọn jẹun alẹ́ tàbí káwọn fi owó oúnjẹ náà ra àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì, irú bí oògùn.
Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ńláǹlà. Jésù sọ pé: “Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà.” (Lúùkù 21:11) Tó o bá ronú pé iye àwọn èèyàn tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ ló ń kàgbákò ìmìtìtì ilẹ̀ lónìí, èrò rẹ tọ̀nà. Ọ̀mọ̀ràn ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kan tó ń ṣèwádìí nípa ilẹ̀ ríri, Ọ̀gbẹ́ni R. K. Chadha, sọ lọ́dún 2007, pé: “Àfi bá a ṣe dédé bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ilẹ̀ ríri túbọ̀ ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ báyìí. . . . Kò sẹ́ni tọ́rọ̀ náà yé.” Síwájú sí i, bí èrò ṣe ń yára pọ̀ sí i láwọn àgbègbè tó ṣeé ṣe kí ilẹ̀ ti ri, ń jẹ́ kí iye tí àjálù yìí ń pa túbọ̀ pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Àjọ Ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tó Ń Ṣèwádìí Nípa Ohun Tó Wà Nínú Ilẹ̀ sọ, ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé lábẹ́ Òkun Íńdíà lọ́dún 2004, èyí tó fa alagbalúgbú omíyalé tí wọ́n ń pè ní sùnámì, jẹ́ kí wọ́n ka ọdún 2004 sí ọdún tó tíì “burú jù lọ, láti nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í wáyé, òun ló sì ṣìkejì èyí tó tí ì burú jù.”
Àìsàn Tí Kì Í Lọ Bọ̀rọ̀. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àjàkálẹ̀ àrùn . . . yóò sì wà.” (Lúùkù 21:11) Kárí ayé làwọn àìsàn tó ti wà tipẹ́, àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú túbọ̀ ń dá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn gúnlẹ̀, àtirí oògùn wo àwọn àìsàn náà sì wá dìṣòro. Bí àpẹẹrẹ, ìfàsẹ́yìn túbọ̀ ń bá gbogbo ìsapá àwọn orílẹ̀-èdè láti gbá àrùn ibà wọlẹ̀ torí pé apá aráyé ò fẹ́ ká àrùn náà mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn làwọn àrùn tá a ti mọ̀ tipẹ́ ń pa. Irú àrùn bẹ́ẹ̀ ni ikọ́ ẹ̀gbẹ tóun àti àrùn éèdì jọ ń ṣọṣẹ́ àtàwọn àrùn ìgbàlódé míì. Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ẹnì kan lára mẹ́ta àwọn èèyàn tó wà láyé ló ti ní kòkòrò àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ.” Àjọ náà tún sọ pé kòkòrò àrùn éèdì tún ń fa bí ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣe ń gbilẹ̀ sí i lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, ìkọ́ ẹ̀gbẹ ń mú èèyàn kọ̀ọ̀kan, àrùn yìí ò sì fẹ́ gbóògùn mọ́. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé lọ́dún 2007, ẹnì kan ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ikọ́ ẹ̀gbẹ tí “gbogbo ogun tá a lò fún un kò ràn.”
Ìwà Ọmọlúwàbí Ò Wọ́ Pọ̀ Mọ́. Jésù sọ pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) Yàtọ̀ sóhun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú kan táwọn èèyàn ò ti ní máa fọwọ́ pàtàkì mú ìwà ọmọlúwàbí, tí gbogbo nǹkan á sì fọ́jú pọ̀ láwùjọ. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ọjọ́ ìkẹyìn” lílekoko tó máa dé ṣáájú kí Ìjọba Ọlọ́run tó mú òpin dé bá àwọn èèyàn búburú. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5) Ṣéwọ náà ò ti rí i fúnra rẹ báyìí pé àwọn èèyàn ń hu irú ìwà burúkú tí Bíbélì sọ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?
Jésù àti Pọ́ọ̀lù ò sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn, láwùjọ àti lágbo òṣèlú tó fa àwọn ohun tá à ń rí báyìí. Àmọ́ wọ́n sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó pé pérépéré nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìwà tá à ń rí lónìí. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Aísáyà tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa dídé Mèsáyà, tó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, tún wá sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa yí ayé pa dà àtàwọn àǹfààní tó máa mú bá ilẹ̀ ayé. Ẹ jẹ́ ká jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn báyìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
“Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Àjàkálẹ̀ àrùn . . . yóò sì wà”
[Credit Line]
© WHO/P. Virot