ÌBÉÈRÈ LÁTI ỌWỌ́ ÀWỌN ÒǸKÀWÉ
Ìgbà wo ni Bábílónì Ńlá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn?
Ní àkókò kan lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ni, ó sì dópin lọ́dún 1919. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní tẹ́lẹ̀?
Ó ṣe kedere ní gbogbo ọ̀nà pé lọ́dún 1919, Ọlọ́run dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀ kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá, ó sì kó wọn jọ sínú ìjọ tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Ronú nípa èyí ná: Kété lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run lọ́dún 1914, a dán àwọn èèyàn Ọlọ́run wò, a sì wá tipa bẹ́ẹ̀ yọ́ wọn mọ́ kúrò nínú ìsìn èké.a (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (Málákì 3:1-4) Lẹ́yìn náà, lọ́dún 1919, Jésù yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sípò láti máa fún àwọn èèyàn Ọlọ́run tí a ti yọ́ mọ́ ní ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ (Mátíù 24:45-47) Lọ́dún yẹn kan náà, Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Ìṣípayá 18:4) Àmọ́ ìgbà wo ni Bábílónì Ńlá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn?
Àlàyé tá a máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni pé Bábílónì Ńlá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn lọ́dún 1918. Àlàyé kan nínú Ilé-Ìṣọ́nà March 15, 1992, sọ pé bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lọ sígbèkùn ní Bábílónì ayé ọjọ́un, bẹ́ẹ̀ náà ni Bábílónì Ńlá ṣe mú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nígbèkùn lọ́dún 1918. Àmọ́ ìwádìí tá a ṣe síwájú sí i fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ti wà nígbèkùn ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ọdún 1918.
Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:1-14 fi hàn pé wọ́n máa kó àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn, tó bá sì yá wọ́n á dá wọn sílẹ̀ lómìnira. Nínú ìran, Ìsíkíẹ́lì rí àfonífojì kan tó kún fún egungun. Jèhófà sọ pé: “Ní ti egungun wọ̀nyí, gbogbo ilé Ísírẹ́lì ni wọ́n.” (Ẹsẹ 11) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni èyí tọ́ka sí, ó sì tún wá tọ́ka sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró. (Gálátíà 6:16; Ìṣe 3:21) Nínú ìran náà, àwọn egungun náà wá sí ìyè, wọ́n sì di ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá. Èyí ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbèkùn Bábílónì Ńlá lọ́dún 1919. Àmọ́ báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe fi hàn pé àkókò gígùn làwọn èèyàn Ọlọ́run lò nígbèkùn?
Lákọ̀ọ́kọ́, Ìsíkíẹ́lì kíyè sí i pé egungun àwọn òkú náà “gbẹ gidigidi.” (Ìsíkíẹ́lì 37:2, 11) Èyí fi hàn pé ó ti pẹ́ táwọn èèyàn náà ti kú. Yàtọ̀ síyẹn, Ìsíkíẹ́lì rí i pé díẹ̀díẹ̀ làwọn òkú náà ń wá sí ìyè, wọ́n ò ta gìrì dìde lẹ́ẹ̀kan náà. Ó gbọ́ ìró kan, “dídún kan sì wà, àwọn egungun sì bẹ̀rẹ̀ sí sún mọ́ra, egungun mọ́ egungun.” Ó wá rí i tí “àwọn fọ́nrán iṣan àti ẹran ara wá sára wọn.” Lẹ́yìn ìyẹn, awọ bo àwọn ẹran ara náà. Nígbà tó yá, ‘èémí wá sínú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wà láàyè.’ Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nígbà tí àwọn èèyàn náà pa dà wá sí ìyè, Jèhófà fi ilẹ̀ wọn fún wọn kí wọ́n lè máa gbé ibẹ̀. Gbogbo èyí á gba àkókò.—Ìsíkíẹ́lì 37:7-10, 14.
Bá a ṣe rí i nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò nígbèkùn. Ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ́kọ́ kó wọn lọ sígbèkùn, ìyẹn ìgbà tí wọ́n fipá mú ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, tó wà ní àríwá kúrò ní ilẹ̀ wọn. Nígbà tó sì di ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n sì fipá mú ẹ̀yà méjì ti Júdà tó wà ní gúúsù kúrò ní ilẹ̀ wọn. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n dá wọn sílẹ̀, àwọn díẹ̀ lára àwọn Júù sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè tún tẹ́ńpìlì kọ́ kí wọ́n sì tún máa jọ́sìn Jèhófà.
Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé yìí fi hàn pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ní láti wà nígbèkùn Bábílónì Ńlá fún ìgbà pípẹ́, kì í wulẹ̀ ṣe láti ọdún 1918 sí ọdún 1919. Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa àkókò gígùn yìí nígbà tó sọ pé àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́, ìyẹn àwọn èpò, á máa dàgbà pa pọ̀ pẹ̀lú “àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn àlìkámà. (Mátíù 13:36-43) Àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà láàárín àkókò yẹn ò tó nǹkan. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pera wọn ní Kristẹni gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́, wọ́n sì di apẹ̀yìndà. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé Bábílónì Ńlá kó ìjọ Kristẹni nígbèkùn. Èyí sì bẹ̀rẹ̀ ní àkókò kan lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní títí dìgbà tí Jésù fi fọ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí mọ́ ní àkókò òpin.—Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:3, 6; 1 Jòhánù 2:18, 19.
Ní gbogbo ọdún yẹn, àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn olóṣèlú fẹ́ máa jẹ gàba lé àwọn èèyàn lórí. Bí àpẹẹrẹ, wọn ò gbà káwọn èèyàn ní Bíbélì lọ́wọ́, wọn ò sì jẹ́ kí wọ́n rí i kà lédè tó yé wọn. Wọ́n tiẹ̀ dáná sun àwọn tó ń ká Bíbélì, wọ́n sì fi dẹndẹ ìyà jẹ àwọn tí ò fara mọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí kó fi kọ́ àwọn ẹlòmíì.
Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí tún jẹ́ ká mọ̀ pé ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn Ọlọ́run pa dà wá sí ìyè, wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìsìn èké. Ìgbà wo lèyí bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀? Ìsíkíẹ́lì tún sọ pé òun gbọ́ ìró “dídún kan.” Èyí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan ṣáájú àkókò òpin. Láwọn ọdún yẹn, àwọn olóòótọ́ èèyàn mélòó kan wà tí wọ́n fẹ́ mọ òtítọ́ tí wọ́n sì fẹ́ máa sin Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké làwọn aṣáájú ìsìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn nígbà yẹn. Wọ́n ka Bíbélì, wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n ń kọ́ fáwọn èèyàn. Àwọn míì nínú wọn ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì sí èdè tó yé àwọn èèyàn.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1870, àfi bíi pé ẹran ara àti awọ ń bo àwọn egungun náà. Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ṣàwárí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì kí wọ́n sì sin Jèhófà. Wọ́n tún fi ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower àtàwọn ìtẹ̀jáde míì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́. Nígbà tó yá, àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá ìyẹn “Photo-Drama of Creation” tí wọ́n ṣe lọ́dún 1914 àti ìwé The Finished Mystery tí wọ́n ṣe lọ́dún 1917 mú kí ìgbàgbọ́ táwọn èèyàn Jèhófà ní lágbára. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn lọ́dún 1919, ńṣe ló dà bíi pé àwọn èèyàn Jèhófà wá sí ìyè, tí Jèhófà sì fún wọn ní ilẹ̀ tuntun. Látìgbà yẹn ni àwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró. Gbogbo wọn jùmọ̀ ń sin Jèhófà, wọ́n sì wá di “ẹgbẹ́ ológun ńláǹlà.”—Ìsíkíẹ́lì 37:10; Sekaráyà 8:20-23.b—Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Torí náà, ó ṣe kedere pé lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Bábílónì Ńlá mú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbèkùn. Àkókò yìí ni ọ̀pọ̀ èèyàn di apẹ̀yìndà nígbà tí wọ́n gba àwọn ẹ̀kọ́ èké gbọ́ tí wọ́n sì kọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ sílẹ̀. Ní gbogbo ọdún yẹn, ó ṣòro gan-an fáwọn èèyàn láti sin Jèhófà bó ṣe ṣòro fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà láti sin Jèhófà nígbà tí wọ́n wà lóko ẹrú. Àmọ́ lónìí, à ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. A mà dúpẹ́ o, pé à ń gbé ní àkókò tí ‘àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò máa tàn yòò!’ Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn lè “wẹ ara wọn mọ́,” kí a “yọ́ wọn mọ́,” kí wọ́n sì máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́!—Dáníẹ́lì 12:3, 10.
Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, ṣé tẹ́ńpìlì gangan ló mú Jésù lọ àbí ṣe ló fi tẹ́ńpìlì hàn án nínú ìran?
A ò mọ̀ dájú bóyá Sátánì mú Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì ni o àbí ó fi hàn án nínú ìran.
Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì náà Mátíù àti Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀. Mátíù sọ pé ‘Èṣù mú’ Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù ó sì “mú un dúró lórí odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì,” ìyẹn ibi tó ga jù lọ ní tẹ́ńpìlì. (Mátíù 4:5) Lúùkù sọ pé Èṣù “mú un lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì mú un dúró lórí odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì.”—Lúùkù 4:9.
Tẹ́lẹ̀, àwọn ìtẹ̀jáde wa sọ pé ó lè máà jẹ́ tẹ́ńpìlì gangan ni Sátánì mú Jésù lọ nígbà tó dán an wò. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1961 sọ pé ṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tí Bíbélì sọ pé Sátánì dán Jésù wò nípa fífi gbogbo ìjọba ayé hàn án láti orí òkè ńlá kan. Ó sọ pé kò sí òkè tó ga débi pé téèyàn bá dúró sórí rẹ̀ yóò máa rí gbogbo ìjọba ayé. Ilé Ìṣọ́ náà wá sọ pé, bákan náà, kò dájú pé tẹ́ńpìlì gangan ni Sátánì mú Jésù lọ. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn àpilẹ̀kọ tá a tẹ̀ jáde nínú Ilé Ìṣọ́ lẹ́yìn náà sọ pé Jésù ì bá ti kù ká ní ó bẹ́ sílẹ̀ látorí tẹ́ńpìlì náà ni.
Àwọn kan sọ pé nígbà tó jẹ́ pé Jésù kì í ṣe ọmọ Léfì, wọn ò lè jẹ́ kò dúró sórí ibùjọsìn tẹ́ńpìlì. Torí náà, wọ́n sọ pé ó ní láti jẹ́ pé inú ìran ni Sátánì ti dán Jésù wò. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, Ọlọ́run mú Ìsíkíẹ́lì lọ sínú tẹ́ńpìlì nínú ìran.—Ìsíkíẹ́lì 8:3, 7-10; 11:1, 24; 37:1, 2.
Àmọ́, tó bá jẹ́ pé inú ìran ni Èṣù ti mú Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, àwọn kan lè béèrè pé:
Ṣó tiẹ̀ máa wu Jésù láti bẹ́ sílẹ̀ láti orí òrùlé tẹ́ńpìlì náà?
Láwọn ìgbà míì tí Sátánì dán Jésù wò, ó ní kí Jésù sọ òkúta di ìṣù búrẹ́dì gangan, ó sì fẹ́ kí Jésù jọ́sìn òun. Torí náà, ṣé ó lè jẹ́ pé látorí tẹ́ńpìlì gangan ni Sátánì ti fẹ́ kí Jésù bẹ́ sílẹ̀?
Àmọ́ tó bá jẹ́ pé tẹ́ńpìlì gangan ni Sátánì mú Jésù lọ, àwọn kan lè máa béèrè pé:
Ṣé Jésù rú Òfin torí pé ó dúró sórí ibùjọsìn tẹ́ńpìlì?
Láti inú aginjù tí Jésù wà, báwo ló ṣe dé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù?
Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó kan táá mú ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè méjì tó gbẹ̀yìn yìí.
Nínú ìwé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n D. A. Carson kọ, ó sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “tẹ́ńpìlì” nínú ìwé Mátíù àti Lúùkù túmọ̀ sí gbogbo tẹ́ńpìlì náà àti àyíká rẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe ibùjọsìn tẹ́ńpìlì nìkan, tó jẹ́ pé àwọn ọmọ Léfì nìkan ni wọ́n máa ń lọ síbẹ̀. Apá gúúsù tẹ́ńpìlì náà níbi tó ti dojú kọ ìlà oòrùn, ní òrùlé pẹrẹsẹ kan, ibẹ̀ ló sì ga jù ní tẹ́ńpìlì náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni Sátánì mú Jésù lọ. Orí òkè yẹn sí Àfonífojì Kídírónì ga tó ilé alájà mẹ́rìnlélógójì [44]. Òpìtàn Josephus sọ pé òkè yẹn ga débi pé téèyàn bá dúró síbẹ̀ tó sì wolẹ̀, “òòyì lè kọ́ ọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kì í ṣe ọmọ Léfì, ó lè dúró sórí òkè náà láìsí ẹni tó máa yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.
Àmọ́, láti ibi tí Jésù wà ní aginjù, báwo ló ṣe dé tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù? A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé báyìí ló ṣe ṣẹlẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé Sátánì mú Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù. Kò sọ bí ibi tí Jésù wà ṣe jìnnà sí Jerúsálẹ́mù tó tàbí bó ṣe pẹ́ tó tí Sátánì fi dán an wò. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Jésù fẹsẹ̀ ara rẹ̀ rìn lọ sí Jerúsálẹ́mù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè pẹ́ kó tó débẹ̀.
Nígbà tí Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé” han Jésù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìran ló ti fi hàn án torí kò sí òkè téèyàn lè gùn táá fi rí gbogbo ìjọba ayé yìí tán. A lè fi èyí wé bá a ṣe lè fi fọ́tò àwọn apá ibòmíì lágbàáyé han ẹnì kan. Sátánì fi gbogbo ìjọba ayé yìí han Jésù nínú ìran, àmọ́ ó fẹ́ kí Jésù forí balẹ̀ fún òun kó sì jọ́sìn òun. (Mátíù 4:8, 9) Torí náà, nígbà tí Sátánì mú Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ló fẹ́ kí Jésù bẹ́ sílẹ̀ látorí tẹ́ńpìlì, kí Jésù lè fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu. Àmọ́, Jésù kọ̀ jálẹ̀. Èyí gan-an la lè pè ní ìdánwò, ó kọjá kéèyàn kàn fi nǹkan han èèyàn nínú ìran!
Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó sì dúró sórí ibi tó ga jù ní tẹ́ńpìlì náà. Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a ò mọ̀ dájú bóyá tẹ́ńpìlì gangan ni Sátánì mú Jésù lọ tàbí ó fi hàn án nínú ìran. Àmọ́, a mọ̀ pé Sátánì ṣáà ń gbìyànjú láti mú kí Jésù ṣe ohun tí kò tọ́, síbẹ̀ Jésù kọ̀ jálẹ̀.
b Ìwé Ìsíkíẹ́lì 37:1-14 àti Ìṣípayá 11:7-12 sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìsíkíẹ́lì 37:1-14 sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe pa dà fìdí ìjọsìn tòótọ́ múlẹ̀ lọ́dún 1919 lẹ́yìn tí wọ́n ti wà nígbèkùn fún ìgbà pípẹ́. Ìwé Ìṣípayá 11:7-12 ní tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bí àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe sọ jí pa dà lọ́dún 1919. Kò ṣeé ṣe fún àwọn arákùnrin yìí láti ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ láàárín àwọn àkókò kan.