Ẹ̀KỌ́ 26
Kí Nìdí Tí Nǹkan Burúkú Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Tá A sì Ń Jìyà?
Tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè pé, “Kí nìdí tírú èyí fi ń ṣẹlẹ̀?” Inú wa dùn gan-an pé Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí!
1. Kí ni Sátánì ṣe tí ìwà ibi fi bẹ̀rẹ̀ ní ayé?
Sátánì Èṣù ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, torí pé ó wù ú láti máa ṣàkóso àwa èèyàn. Torí náà, ó mú kí Ádámù àti Éfà kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, àwọn náà sì di ọlọ̀tẹ̀. Ọ̀nà tí Sátánì gbà ṣe é ni pé ó parọ́ fún Éfà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Sátánì mú kí Éfà rò pé àwọn nǹkan rere kan wà tí Ọlọ́run ò fẹ́ kó ní. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé kò dìgbà táwa èèyàn bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká tó lè láyọ̀. Sátánì parọ́ fún Éfà pé kò ní kú. Bó ṣe di pé òun lẹni àkọ́kọ́ tó parọ́ nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Sátánì ní ‘òpùrọ́ àti baba irọ́.’—Jòhánù 8:44.
2. Kí ni Ádámù àti Éfà pinnu láti ṣe?
Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ní gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ní. Ó sọ fún wọn pé wọ́n lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì, àmọ́ igi kan wà níbẹ̀ tó ní kí wọ́n má jẹ èso ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Ṣùgbọ́n, ńṣe ni wọ́n jẹ èso igi tí Ọlọ́run ní kí wọ́n má jẹ. Éfà “mú lára èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Lẹ́yìn náà, Ádámù “jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Bí àwọn méjèèjì ṣe ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nìyẹn. Àmọ́, ohun tó tọ́ ló yẹ kí Ádámù àti Éfà ṣe torí pé ẹni pípé ni wọ́n. Torí náà, bí wọ́n ṣe mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run fi hàn pé wọn ò fẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn, wọ́n sì di ẹlẹ́ṣẹ̀. Ìpinnu tí wọ́n ṣe yẹn fi baba ńlá ìyà jẹ wọ́n.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19.
3. Àkóbá wo ni ìpinnu Ádámù àti Éfà ṣe fún wa?
Nígbà tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ wọ́n di aláìpé, èyí mú kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn jogún àìpé. Bíbélì sọ nípa Ádámù pé: “Bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe tipasẹ̀ ẹnì kan wọ ayé, tí ikú sì wá nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ikú ṣe tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.”—Róòmù 5:12.
Oríṣiríṣi nǹkan ló fà á tá a fi ń jìyà. Ìyà lè jẹ wá torí pé a ṣe ìpinnu tí kò dáa, ìpinnu tí kò dáa táwọn ẹlòmíì ṣe sì lè kó ìyà jẹ wá. Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé èèyàn máa ń jìyà torí pé ó ṣe kòńgẹ́ aburú.—Ka Oníwàásù 9:11.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Jẹ́ ká wo ohun tó fi hàn pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń fìyà jẹ aráyé àti bó ṣe máa ń rí lara Ọlọ́run tá a bá ń jìyà
4. Ẹni tó fa ìyà tó ń jẹ wá
Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ayé. Ṣé òótọ́ ni? Wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Jémíìsì 1:13 àti 1 Jòhánù 5:19, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ṣé Ọlọ́run ló ń fa àwọn nǹkan burúkú tó ń fìyà jẹ aráyé?
5. Àwọn nǹkan tí àkóso Sátánì ti fà
Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Irọ́ wo ni Sátánì pa?—Wo ẹsẹ 4 àti 5.
Báwo ni Sátánì ṣe dọ́gbọ́n sọ pé àwọn nǹkan rere kan wà tí Ọlọ́run ò fẹ́ káwa èèyàn ní?
Sátánì sọ pé kò dìgbà tí Jèhófà bá jẹ́ Alákòóso wa ká tó lè láyọ̀, ṣé òótọ́ lohun tó sọ yẹn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ka Oníwàásù 8:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ torí pé Jèhófà kọ́ ló ń ṣàkóso ayé?
A. Ẹni pípé ni Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n wà nínú Párádísè. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n tẹ̀ lé ohun tí Sátánì sọ, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà
B. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ń jìyà, wọ́n sì ń kú
D. Láìpẹ́, Jèhófà máa fòpin sí ẹ̀ṣẹ̀, ìyà àti ikú. Àwa èèyàn á wá di pípé, a ó sì máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé
6. Jèhófà ò fẹ́ ká máa jìyà
Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tá a bá ń jìyà? Wo ohun tí Ọba Dáfídì àti àpọ́sítélì Pétérù sọ. Ka Sáàmù 31:7 àti 1 Pétérù 5:7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà rí ìyà tó ń jẹ ọ́, ọ̀rọ̀ rẹ sì ká a lára?
7. Ọlọ́run máa mú gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé kúrò
Ka Àìsáyà 65:17 àti Ìfihàn 21:3, 4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ṣé ara tù ẹ́ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa mú gbogbo ìyà tó ń jẹ wá kúrò? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Nígbà tí Sátánì pa irọ́ àkọ́kọ́, ńṣe ló ba Jèhófà lórúkọ jẹ́. Torí pé ó fẹ́ ká gbà pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí àti pé ìkà ni. Tí Jèhófà bá mú gbogbo ìyà tó ń jẹ wá kúrò lọ́jọ́ iwájú, ó máa dá ara rẹ̀ láre. Ìyẹn ni pé ó máa fi hàn pé àkóso rẹ̀ ló dáa jù lọ. Bí Jèhófà ṣe máa dá ara rẹ̀ láre ni ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run.—Mátíù 6:9, 10.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àtọjọ́ táláyé ti dáyé làwọn èèyàn ti ń jìyà, gbogbo ẹ̀ ò sì ṣẹ̀yìn Ọlọ́run.”
Kí lèrò tìẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Sátánì Èṣù pẹ̀lú Ádámù àti Éfà ló fa àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Inú Jèhófà ò dùn rárá sí ìyà tó ń jẹ wá, ó sì máa fòpin sí i láìpẹ́.
Kí lo rí kọ́?
Irọ́ wo ni Sátánì Èṣù pa fún Éfà?
Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, àkóbá wo nìyẹn ṣe fún wa?
Báwo la ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀.
Ka ìwé yìí ko o lè mọ púpọ̀ sí i nípa bí Sátánì Èṣù ṣe ta ko Ọlọ́run ní ọgbà Édẹ́nì.
“Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2014)
Ka ìwé yìí kó o lè rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì kan.
“Kí Nìdí Tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Fi Ṣẹlẹ̀? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Ṣe Fòpin Sí I?” (Àpilèkọ orí ìkànnì)
Wo fídíò yìí kó o lè rí ẹ̀kọ́ tí ọkùnrin kan kọ́ nígbà tó rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn lágbègbè rẹ̀.