Ẹ̀KỌ́ 27
Báwo Ni Ikú Jésù Ṣe Gbà Wá Là?
Ìdí tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀, tá à ń jìyà, tá a sì ń kú ni pé Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.a Àmọ́, ọ̀rọ̀ wa kò tíì kọjá àtúnṣe. Jèhófà ti ṣe ọ̀nà àbáyọ, ó rán Jésù Kristi Ọmọ ẹ̀ wá sáyé, kó lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ àti ikú. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù kú nítorí wa, ikú ẹ̀ ló sì fi san ìràpadà. Ìràpadà ni ohun tí ẹnì kan san láti gba ẹlòmíì sílẹ̀. Ohun tí Jésù san ni ẹ̀mí rẹ̀ pípé tó fi lélẹ̀. (Ka Mátíù 20:28.) Jésù ní ẹ̀tọ́ láti máa gbé ayé títí láé, àmọ́ ó fínnúfíndọ̀ kú nítorí wa ká lè rí gbogbo ohun tí Ádámù àti Éfà gbé sọ nù gbà pa dà. Ohun tí Jésù ṣe yìí tún jẹ́ ká mọ bí òun àti Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ohun tó o máa kọ́ ní orí yìí á jẹ́ kó o túbọ̀ mọyì ikú Jésù.
1. Àǹfààní wo ni ikú Jésù ń ṣe wá báyìí?
Nítorí pé a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà ò fẹ́ la máa ń ṣe. Àmọ́, tá a bá kábàámọ̀ tọkàntọkàn torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a bẹ Jèhófà nípasẹ̀ Jésù Kristi pé kó dárí jì wá, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, a máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. (1 Jòhánù 2:1) Bíbélì sọ pé: “Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀, Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún kú mọ́ láé, ó jẹ́ olódodo tó kú nítorí àwọn aláìṣòdodo, kó lè mú yín wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Pétérù 3:18.
2. Àǹfààní wo ni ikú Jésù máa ṣe wá lọ́jọ́ iwájú?
Jèhófà rán Jésù wá sáyé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ “kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú [Jésù] má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Torí ohun tí Jésù ṣe yìí, Jèhófà máa tó fòpin sí gbogbo aburú tí àìgbọràn Ádámù fà. Ìyẹn ni pé tá a bá nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, a máa láǹfààní láti gbádùn ayé títí láé nínú Párádísè!—Àìsáyà 65:21-23.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tó mú kí Jésù kú àti àǹfààní tí ikú Jésù ṣe ẹ́.
3. Ikú Jésù gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Kí ni Ádámù pàdánù nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run?
Ka Róòmù 5:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ṣe ṣàkóbá fún ẹ?
Ka Jòhánù 3:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí Jèhófà fi rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé?
Ẹni pípé ni Ádámù, àmọ́ ó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì kó aráyé sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú
Ẹni pípé ni Jésù, ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run, èyí jẹ́ kí aráyé láǹfààní láti di pípé kí wọ́n sì máa wà láàyè títí láé
4. Gbogbo èèyàn ni ikú Jésù ṣe láǹfààní
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Báwo ni ikú èèyàn kan ṣoṣo ṣe lè ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní?
Ka 1 Tímótì 2:5, 6, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ẹni pípé ni Ádámù, àmọ́ ó kó aráyé sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ẹni pípé ni Jésù náà, ṣùgbọ́n ọ̀nà wo ló gbà pèsè “ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí”?
5. Ìràpadà jẹ́ ẹ̀bùn tí Jèhófà fún ẹ
Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà máa ń wo ìràpadà bí ẹ̀bùn tí Jèhófà dìídì fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ka Gálátíà 2:20, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ka ìràpadà sí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run dìídì fún òun?
Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, òun àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ gba ìdájọ́ ikú. Àmọ́, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ láti kú nítorí rẹ, kó o lè láǹfààní láti gbé ayé títí láé.
Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà nígbà tí Ọmọ rẹ̀ ń jìyà. Ka Jòhánù 19:1-7, 16-18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Báwo ni ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún ẹ ṣe rí lára ẹ?
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Báwo ni ikú ẹnì kan ṣoṣo ṣe gba gbogbo èèyàn là?”
Báwo lo ṣe máa dáhùn?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Nítorí ikú Jésù ni Jèhófà ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ikú rẹ̀ ló sì tún jẹ́ ká nírètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tí Jésù fi kú?
Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí pípé tí Jésù fi lélẹ̀ gbà jẹ́ ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí?
Àǹfààní wo ni ikú Jésù ṣe ẹ́?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ìdí tí ẹ̀mí pípé tí Jésù fi lélẹ̀ fi jẹ́ ìràpadà.
“Báwo Ni Ẹbọ Tí Jésù Fi Ẹ̀mí Rẹ̀ Rú Ṣe Jẹ́ “Ìràpadà fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”? (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè rí ìgbàlà.
Ṣé Jèhófà lè dárí jì wá tá a bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an?
Ka ìtàn ọkùnrin kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹbọ ìràpadà Kristi, tí ìyẹn sì mú kó yí ìwà ẹ̀ pa dà.
a Kéèyàn hùwà burúkú nìkan kọ́ là ń pè ní ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ tún jẹ́ àìpé tí wọ́n bí mọ́ gbogbo wa.