Ipa-iṣẹ́ Oníyì Ti Àwọn Obìnrin Láàárín Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Ní Ìjímìjí
“Jehofa Ọlọrun ń báa lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa dá nìkan gbé. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’”—GENESISI 2:18, NW.
1. Báwo ni ìwé àtúmọ̀ Bibeli kan ṣe ṣàpèjúwe ipò àwọn obìnrin ní àkókò ìgbàanì?
“KÒ SÍ ibì kankan ní Mediterranean ìgbàanì tàbí ní Near East tí a ti fún àwọn obìnrin ní òmìnira tí wọ́n ń gbádùn ní àwùjọ Ìwọ̀-Oòrùn òde-òní. Ohun tí ó wọ́pọ̀ ní gbogbogbòò ni kí àwọn obìnrin wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀ sí ti àwọn ọkùnrin, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrú ṣe rẹlẹ̀ sí ẹni tí ó wà lómìnira, àti bí àwọn ọmọdé ṣe rẹlẹ̀ sí àwọn àgbàlagbà. . . . Àwọn ọmọkùnrin ni a kà sí gan-an ju àwọn ọmọbìnrin lọ, àwọn ọmọbìnrin ìkókó ni a sì máa ń fi sílẹ̀ láti kú nígbà mìíràn nítorí àìtọ́jú wọn.” Bí ìwé atúmọ̀ Bibeli kan ṣe ṣàpèjúwe ipò àwọn obìnrin ní ìgbàanì nìyẹn.
2, 3. (a) Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ti sọ, kí ni ipò ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a gbé dìde?
2 Ipò náà kò tíì dára síi ní apá ibi púpọ̀ nínú ayé lónìí. Ní 1994, fún ìgbà àkọ́kọ́, ìròyìn ọdọọdún Ẹ̀ka Orílẹ̀-Èdè ní United States nípa ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn darí àfiyèsí sórí bí a ṣe ń bá àwọn obìnrin lò. Àkórí kan nípa ìròyìn náà nínú ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ìsọfúnni láti Orílẹ̀-Èdè 193 Fi Hàn Pé Àìbánilò Lọ́gbọọgba Jẹ́ Òtítọ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Ojoojúmọ́.”
3 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tí wọ́n ní àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ipò àtilẹ̀wá tí ó yàtọ̀ síra ti darapọ̀ pẹ̀lú ìjọ àwọn ènìyàn Jehofa kárí ayé, àwọn ìbéèrè kan dìde pé: Ìbálò tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàpèjúwe rẹ̀ ha sọ irú ìpètepèrò tí Ọlọrun ní látilẹ̀wá fún àwọn obìnrin bí? Báwo ni a ṣe bá àwọn obìnrin lò láàárín àwọn olùjọsìn Jehofa ní àkókò Bibeli? Báwo sì ni ó ṣe yẹ kí a bá àwọn obìnrin lò lónìí?
“Olùrànlọ́wọ́” àti “Àṣekún”
4. Àkíyèsí wo ni Jehofa ṣe lẹ́yìn tí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà ti wà nínú ọgbà-ọ̀gbìn Edeni ní òun nìkan fún àkókò kan, kí sì ni Ọlọrun ṣe nígbà náà?
4 Lẹ́yìn tí Adamu ti dá wà nínú ọgbà-ọ̀gbìn Edeni fún àkókò kan, Jehofa kíyèsí pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa dá nìkan gbé. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Genesisi 2:18, NW) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Adamu jẹ́ ọkùnrin pípé, ohun mìíràn ṣì wà tí ó nílò kí ó baà lè mú ète Ẹlẹ́dàá ṣẹ. Láti kúnjú àìní yìí, Jehofa dá obìnrin náà ó sì ṣe ìgbéyàwó àkọ́kọ́.—Genesisi 2:21-24.
5. (a) Báwo ni àwọn òǹkọ̀wé Bibeli ṣe máa ń sábà lo ọ̀rọ̀-orúkọ Heberu náà tí a túmọ̀ sí “olùrànlọ́wọ́”? (b) Kí ni ohun tí títọ́ka tí Jehofa tọ́ka sí obìnrin àkọ́kọ́ náà gẹ́gẹ́ bí “àṣekún” túmọ̀ sí?
5 Ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún” ha fi hàn pé ipa-iṣẹ́ tí Ọlọrun yàn fún obìnrin náà jẹ́ èyí tí ń bunikù bí? Kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn òǹkọ̀wé Bibeli sábà máa ń lo ọ̀rọ̀-orúkọ Heberu náà (ʽeʹzer) tí a túmọ̀ sí “olùrànlọ́wọ́,” fún Ọlọrun. Fún àpẹẹrẹ, Jehofa fi hàn pé òun jẹ́ “olùrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.” (Orin Dafidi 33:20, NW; Eksodu 18:4; Deuteronomi 33:7) Ní Hosea 13:9 (NW), Jehofa tilẹ̀ tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùrànlọ́wọ́” Israeli. Níti ọ̀rọ̀ Heberu náà (neʹghedh) tí a túmọ̀ sí “àṣekún,” ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bibeli ṣàlàyé pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí ń wá náà kì í wulẹ̀ ṣe ìrànwọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ ojoojúmọ́ tàbí nínú bíbí àwọn ọmọ . . . ṣùgbọ́n ìtìlẹyìn fún tọ̀tún-tòsì tí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ń pèsè.”
6. Kí ni a sọ lẹ́yìn ṣíṣẹ̀dá obìnrin náà, èésìtiṣe?
6 Nípa báyìí kò sí ohun kankan tí ń bunikù nínú ṣíṣàpèjúwe tí Jehofa ṣàpèjúwe obìnrin náà gẹ́gẹ́ bí “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún.” Obìnrin náà ní àpapọ̀ ìṣẹ̀dá tirẹ̀ tí ó ṣàrà-ọ̀tọ̀ níti èrò-orí, èrò-ìmọ̀lára, àti ti ara ìyára. Ó jẹ́ alábàádọ́gba tí ó yẹ, àṣekún tí ó tẹ́nilọ́rùn fún ọkùnrin náà. Ìkọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀, síbẹ̀ ìkọ̀ọ̀kan ni a nílò láti “gbilẹ̀” ní ìbámu pẹ̀lú ète Ẹlẹ́dàá. Ó hàn gbangba pé, lẹ́yìn ìṣẹ̀dá ọkùnrin àti obìnrin náà ni “Ọlọrun . . . rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyèsí i, dáradára ni.”—Genesisi 1:28, 31.
7, 8. (a) Nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ ní Edeni, báwo ni yóò ṣe nípa lórí ipa-iṣẹ́ obìnrin? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a gbé dìde nípa ìmúṣẹ Genesisi 3:16 láàárín àwọn olùjọsìn Jehofa?
7 Nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀, nǹkan yípadà fún ọkùnrin àti obìnrin náà. Jehofa kéde ìjìyà lé àwọn méjèèjì lórí gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa àtúbọ̀tán tí ó fàyè gbà bí ẹni pé òun gan-an ni ó fà á, Jehofa sọ fún Efa pé: “Èmi óò sì sọ ìpọ́njú àti ìlóyún rẹ di púpọ̀.” Ó fikún un pé: “Ní ìroragógó ìbímọ ni ìwọ óò máa mu ọmọ jáde; lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ọkàn rẹ yóò máa fà sí, òun ni yóò sì máa jẹgàba lé ọ lórí.” (Genesisi 3:16, NW) Láti ìgbà náà wá, ọ̀pọ̀ àwọn aya ni a ti jẹgàba lé lórí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní ọ̀nà lílekoko, láti ọwọ́ àwọn ọkọ wọn. Dípò kíkà wọ́n sí olùrànlọ́wọ́ àti àṣekún, nígbà gbogbo ni a ti bá wọn lò bí ìránṣẹ́ tàbí ẹrú.
8 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìmúṣẹ Genesisi 3:16 túmọ̀ sí fún àwọn obìnrin olùjọsìn Jehofa? A ha rẹ̀ wọ́n nípò sílẹ̀ sí àyè apákúbẹ́kúbẹ́-ṣẹrú àti ìtẹ́lógo bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ṣùgbọ́n kí ni níti àkọsílẹ̀ Bibeli tí ó sọ nípa àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìṣe tí ó kan àwọn obìnrin tí ó lè dàbí èyí tí a kò tẹ́wọ́gbà ní àwọn àwùjọ kan lónìí?
Lílóye Àwọn Àṣà-Ìṣẹ̀dálẹ̀ Nínú Bibeli
9. Nígbà tí a bá ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó níí ṣe pẹ̀lú obìnrin ní àkókò Bibeli, ohun mẹ́ta wo ni a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?
9 Àwọn obìnrin ni a bálò lọ́nà tí ó dára láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní àkókò Bibeli. Nítòótọ́, ní ṣíṣàkíyèsí àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó kan àwọn obìnrin ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn, ó ṣèrànwọ́ láti fi ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan sọ́kàn. Àkọ́kọ́, nígbà tí Bibeli ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ipò tí kò báradé tí ó jẹyọ nítorí ìjẹgàba onímọtara-ẹni-nìkan ti àwọn ọkùnrin búburú, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Ọlọrun fọwọ́ sí bíbá àwọn obìnrin lò ní ọ̀nà báyìí. Èkejì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa fàyègba àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ kan láàárín àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fún àkókò kan, ó darí wọn kí ó baà lè dáàbò bo àwọn obìnrin. Ẹ̀kẹta, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a máṣe fi àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n òde-òní ṣe ìdájọ́ àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ ìgbàanì. Àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ kan tí àwọn ènìyàn tí ń gbé lónìí lè wò gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò bójúmu ni àwọn obìnrin nígbà náà lọ́hùn-ún kò fi dandan fojú wò gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń bunikù. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò.
10. Ojú wo ni Jehofa fi wo àṣà ìṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni púpọ̀, kí sì ni ó fi hàn pé òun kò pa ọ̀pá-ìdiwọ̀n rẹ̀ àtilẹ̀wá ti ọkọ-kan-aya-kan tì?
10 Àṣà ìṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni púpọ̀:a Ní ìbámu pẹ̀lú ète Jehofa látilẹ̀wá, aya kan kì yóò ṣàjọpín ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú obìnrin mìíràn. Ọlọrun dá aya kanṣoṣo fún Adamu. (Genesisi 2:21, 22) Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni, àṣà ìṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni púpọ̀ farahàn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìlà Kaini. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó di àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀, àwọn olùjọsìn Jehofa kan sì ṣàmúlò rẹ̀. (Genesisi 4:19; 16:1-3; 29:21-28) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa fàyègba àṣà ìṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni púpọ̀ tí ó sì ṣiṣẹ́ láti mú kí iye àwọn ọmọ Israeli pọ̀ síi, Jehofa fi ìgbatẹnirò hàn fún àwọn obìnrin nípa dídarí àṣà náà kí ó baà lè jẹ́ pé àwọn aya àti àwọn ọmọ wọn ni a óò dáàbò bò. (Eksodu 21:10, 11; Deuteronomi 21:15-17) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jehofa kò fìgbà kan rí pa ọ̀pá-ìdiwọ̀n rẹ̀ àtilẹ̀wá ti ọkọ-kan-aya-kan tì. Noa àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, tí a pàṣẹ náà fún gbọnmọ-gbọnmọ láti ‘máa bí síi, kí wọ́n sì kún ayé’ jẹ́ ọkọ aya kan. (Genesisi 7:7; 9:1; 2 Peteru 2:5) Ọlọrun fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ọkọ aya kan nígbà tí ó ṣàpẹẹrẹ ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Israeli. (Isaiah 54:1, 5) Lẹ́yìn náà, ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun látilẹ̀wá ti ọkọ-kan-aya-kan ni Jesu Kristi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi pẹ̀lú, tí a sì sọ dàṣà nínú ìjọ Kristian ìjímìjí.—Matteu 19:4-8; 1 Timoteu 3:2, 12.
11. Èéṣe tí a fi ń san owó-orí ìyàwó ní àkókò Bibeli, èyí ha sì dín iyì àwọn obìnrin kù bí?
11 Sísan owó-orí ìyàwó: Ìwé náà Ancient Israel—Its Life and Institutions sọ pé: “Àìgbọdọ̀máṣe yìí ti sísan iye owó kan, tàbí ohun tí ó dọ́gba pẹ̀lú rẹ̀, fún ìdílé ọmọbìnrin náà dájúdájú mú kí ìgbéyàwó àwọn ọmọ Israeli dàbíi ríra nǹkan. Ṣùgbọ́n [owó-orí ìyàwó] náà dàbí ohun tí kì í ṣe owó tí a san fún obìnrin náà bíkòṣe àsanfidípò tí a fún ìdílé náà.” (Ìtẹ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Nítorí náà sísan owó-orí ìyàwó jẹ́ àsanfidípò fún ìdílé obìnrin náà fún pípàdánù ìṣiṣẹ́sìn rẹ̀ àti fún ìsapá àti ìnáwó ti bíbójútó o tí ìdílé náà ṣe. Nígbà náà, dípò bíbu obìnrin náà kù, ó kín ìníyelórí rẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ lẹ́yìn.—Genesisi 34:11, 12; Eksodu 22:16; wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1989, ojú-ìwé 21 sí 24.
12. (a) Nígbà mìíràn, báwo ni a ṣe ń tọ́ka sí àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti gbéyàwó tàbí lọ́kọ nínú Ìwé Mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ha bí àwọn obìnrin nínú bí? (b) Kí ni ohun tí ó yẹ kí a pe àfiyèsí sí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jehofa lò ní Edeni? (Wo àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.)
12 Àwọn ọkọ gẹ́gẹ́ bí “olówó”: Ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí-ayé Abrahamu àti Sara ní nǹkan bí 1918 B.C.E. fi hàn pé ní ìgbà tiwọn ẹ̀rí tí ó dájú fi hàn pé ó ti di àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn láti fojúwo ọkùnrin tí ó ti gbéyàwó gẹ́gẹ́ bí “olówó” (Heberu, baʹʽal) àti obìnrin tí ó ti lọ́kọ gẹ́gẹ́ bí ‘ẹni tí a ni’ (Heberu, beʽu·lahʹ). (Genesisi 20:3) Lẹ́yìn náà àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ni a lò nígbà mìíràn nínú Ìwé Mímọ́, kò sì sí ìtọ́kasí kankan pé ọ̀rọ̀ náà bí àwọn obìnrin tí wọ́n wà ṣáájú àkókò Kristian nínú.b (Deuteronomi 22:22, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aya ni a kò gbọdọ̀ bálò gẹ́gẹ́ bí ohun-ìní. Ohun-ìní tàbí ọrọ̀ ni a lè rà, tà, kí a sì tilẹ̀ jogún, ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ níti ọ̀ràn aya. Òwe Bibeli kan sọ pé: “Ilé àti ọrọ̀ ni ogún àwọn bàbá: ṣùgbọ́n amòye aya, láti ọ̀dọ̀ Oluwa wá ni.”—Owe 19:14; Deuteronomi 21:14.
Ipa-Iṣẹ́ Oníyì
13. Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jehofa tí wọ́n sì ṣègbọràn sí Òfin rẹ̀, kí ni ìyọrísí rẹ̀ fún àwọn obìnrin?
13 Nígbà náà, kí ni ipa-iṣẹ́ àwọn obìnrin láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ṣáájú àkókò àwọn Kristian? Ojú wo ni a fi wò wọ́n báwo ni a sì ṣe bá wọn lò? Kí a sọ ọ́ ní ṣókí, nígbà tí àwọn ọkùnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun bá tẹ̀lé àpẹẹrẹ ti Jehofa tí wọ́n sì ṣègbọràn sí Òfin rẹ̀, àwọn obìnrin máa ń di iyì wọn mú, wọ́n sì máa ń gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ àti àǹfààní.
14, 15. Àwọn ìtọ́kasí wo ni ó wà pé àwọn obìnrin ni a bọ̀wọ̀ fún ní Israeli, èésìtiṣe tí Jehofa fi lè retí lọ́nà tí ó tọ́ pé kí àwọn ọkùnrin olùjọsìn rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn?
14 Àwọn obìnrin ni a níláti bọ̀wọ̀ fún. Òfin Ọlọrun fún Israeli pàṣẹ pé kí a bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá. (Eksodu 20:12; 21:15, 17) Lefitiku 19:3 sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín kí ó bẹ̀rù ìyá rẹ̀, àti bàbá rẹ̀.” Nínú ọ̀ràn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà tí Batṣeba tọ Solomoni ọmọkùnrin rẹ̀ lọ, “ọba sì dìde [lẹ́sẹ̀kan náà, NW] láti pàdé rẹ̀, ó sì tẹ ara rẹ̀ ba fún un” ní ọ̀nà tí ó fi ọ̀wọ̀ hàn. (1 Awọn Ọba 2:19) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica ṣàkíyèsí pé: “Fífi ìfẹ́ Ọlọrun fún Israeli wéra lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ ọkọ fún aya rẹ̀ ni a lè ṣe kìkì ní àwùjọ tí a bá ti bọ̀wọ̀ fún obìnrin.”
15 Jehofa retí pé kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ ọkùnrin bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin, nítorí pé òun bọ̀wọ̀ fún wọn. Ìtọ́kasí èyí ni a rí nínú ìwé mímọ́ níbi tí Jehofa ti lo ìrírí àwọn obìnrin ní ọ̀nà àkàwé tí ó sì fi ìmọ̀lára tirẹ̀ wé ti àwọn obìnrin. (Isaiah 42:14; 49:15; 66:13) Èyí ń ran àwọn òǹkàwé lọ́wọ́ láti lóye irú ìmọ̀lára tí Jehofa ní. Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “àánú,” tàbí “ìkáàánú,” tí Jehofa lò fún ara rẹ̀, ni ó níí ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà fún “ilé ọlẹ̀” a sì lè ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìmọ̀lára ìyá.”—Eksodu 33:19; Isaiah 54:7.
16. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fi hàn pé a ka ìmọ̀ràn àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run sí?
16 A ka ìmọ̀ràn àwọn obìnrin oníwà-bí-Ọlọ́run sí. Nínú ọ̀ràn ìṣẹ̀lẹ̀ kan nígbà tí Abrahamu olùbẹ̀rù Ọlọrun lọ́ tìkọ̀ láti gba ìmọ̀ràn Sara, aya rẹ̀, oníwà-bí-Ọlọ́run, Jehofa sọ fún un pé: “Fetísí ohùn rẹ̀.” (Genesisi 21:10-12) Àwọn aya Esau tí wọ́n jẹ́ ará Hitti jẹ́ “ìbìnújẹ́ fún Isaaki àti fún Rebeka.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Rebeka sọ wàhálà tí òun yóò ní ìrírí rẹ̀ bí Jakobu ọmọkùnrin wọn bá fẹ́ ará Hitti. Bawo ni Isaaki ṣe hùwàpadà? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Isaaki sì [pe] Jakobu, ó sì [súre] fún un, ó sì kìlọ̀ fún un, ó sì wí fún un pé, Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani.” Bẹ́ẹ̀ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Rebeka kò sọ ìmọ̀ràn náà ní tààràtà, ọkọ rẹ̀ ṣe ìpinnu tí ó gba ti ìmọ̀lára rẹ̀ rò. (Genesisi 26:34, 35; 27:46; 28:1) Ọba Dafidi yẹra fún ìtàjẹ̀sílẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín nítorí pé ó fetísí ẹ̀bẹ̀ Abigaili.—1 Samueli 25:32-35.
17. Kí ni ó fi hàn pé àwọn obìnrin ní ọlá-àṣẹ dé ìwọ̀n àyè kan nínú ìdílé?
17 Àwọn obìnrin ní ọlá-àṣẹ dé ìwọ̀n àyè kan nínú ìdílé. Àwọn ọmọ ni a rọ̀ pé: “Ọmọ mi, gbọ́ ẹ̀kọ́ bàbá rẹ, kí ìwọ kí ó má sì kọ òfin ìyá rẹ sílẹ̀.” (Owe 1:8) Àpèjúwe “aya tí ó dáńgájíá” nínú Owe orí 31 (NW) ṣípayá pé ìyàwó-ilé tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ kì í wulẹ̀ bójútó agboolé nìkan ṣùgbọ́n ó tún lè bójútó ìdúnàádúrà agbo ilé ńlá pẹ̀lú, kí ó fìdí pápá oko tí yóò mú èso wá lélẹ̀, kí ó máa darí okòwò kékeré, kí a sì mọ̀ ọ́n nítorí ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n rẹ̀. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú gbogbo rẹ̀ ni ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí obìnrin tí ìyìn yẹ fún ní fún Jehofa. Abájọ tí ìníyelórí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ fi “kọjá iyùn”! Iyùn pupa tí ó ṣeyebíye ni a kà sí ohun tí ó níyelórí gan-an láti lò fún ète ṣíṣe ara àti ilé lọ́ṣọ̀ọ́.—Owe 31:10-31.
Àwọn Obìnrin Tí Wọ́n Gba Ojúrere Àkànṣe Lọ́dọ̀ Ọlọrun
18. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a gbà fún àwọn obìnrin kan ní ojúrere àkànṣe ní àkókò Bibeli?
18 Ìdàníyànfẹ́ Jehofa fún àwọn obìnrin ni a fi hàn nínú ojúrere àkànṣe tí ó fún àwọn kan nínú wọn ní àkókò Bibeli. Hagari, Sara, àti aya Manoa ni àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jíṣẹ́ ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá bẹ̀ wò. (Genesisi 16:7-12; 18:9-15; Awọn Onidajọ 13:2-5) “Àwọn ìránṣẹ́-bìnrin” wà ní àgọ́ àwọn obìnrin akọrin sì wà nínú ilé-ẹjọ́ Solomoni.—Eksodu 38:8, NW; 1 Samueli 2:22; Oniwasu 2:8.
19. Nígbà mìíràn, ní ọ̀nà wo ni Jehofa gbà lo àwọn obìnrin láti ṣojú fún un?
19 Ní ìgbà mélòókan nínú ìtàn Israeli, Jehofa lo obìnrin láti ṣojú fún un tàbí láti gbẹnusọ fún un. Nípa Debora wòlíì obìnrin náà, a kà pé: “Àwọn ọmọ Israeli a . . . máa wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìdájọ́.” (Awọn Onidajọ 4:5) Lẹ́yìn tí Israeli ti ṣẹ́gun Jabini ọba Kenaani náà, Debora ní àǹfààní àkànṣe nítòótọ́. Ó hàn gbangba pé òun ni akórinjọ náà, ó kéré tán apákan nínú orin ìṣẹ́gun tí ó wá di apákan àkọsílẹ̀ tí Jehofa mí sí nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.c (Awọn Onidajọ, orí 5) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Ọba Josiah rán àwọn aṣojú tí ó ní nínú olórí àlùfáà sí wòlíì obìnrin náà, Hulda, láti lọ béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Jehofa. Hulda lè fi pẹ̀lú ọlá-àṣẹ dáhùn pé: “Báyìí ni Oluwa Ọlọrun Israeli wí.” (2 Awọn Ọba 22:11-15) Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ọba pàṣẹ fún àwọn aṣojú náà láti lọ bá wòlíì obìnrin kan, ṣùgbọ́n èyí ni a ṣe láti gba ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Jehofa.—Fiwé Malaki 2:7.
20. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fi àníyàn Jehofa fún ìmọ̀lára àti ire àwọn obìnrin hàn?
20 Àníyàn Jehofa fún ire àwọn obìnrin hàn gbangba nínú àwọn àpẹẹrẹ ibi tí ó ti gbégbèésẹ̀ nítorí àwọn obìnrin olùjọsìn rẹ̀ kan. Lẹ́ẹ̀mejì ni ó ti dá sí ọ̀ràn náà láti dáàbò bo aya Abrahamu tí ó rẹwà náà, Sara, kí a má baà bà á jẹ́. (Genesisi 12:14-20; 20:1-7) Ọlọrun fi ojúrere hàn sí Lea, aya Jakobu náà tí a kò nífẹ̀ẹ́ tóbẹ́ẹ̀, nípa ‘ṣíṣí inú rẹ̀’ kí ó sì bí ọmọkùnrin kan. (Genesisi 29:31, 32) Nígbà tí àwọn obìnrin agbẹ̀bí méjì tíí ṣe ará Israeli tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun fi ẹ̀mí ara wọn wewu láti dá àwọn ọmọkùnrin Heberu sí kúrò lọ́wọ́ ìkókó pípa ní ìpakúpa ní Egipti, pẹ̀lú ìmọrírì Jehofa “fún wọn ní ìdílé.” (Eksodu 1:17, 20, 21, NW) Ó tún dáhùn àdúrà onígbòóná-ọkàn Hanna. (1 Samueli 1:10, 20) Nígbà tí wòlíì opó kan sì dojúkọ onígbèsè kan tí ó ṣetán láti gba àwọn ọmọ rẹ̀ láti fi san gbèsè rẹ̀ padà, Jehofa kò pa á tì. Ní ọ̀nà onífẹ̀ẹ́, Ọlọrun mú kí ó ṣeé ṣe fún wòlíì Eliṣa láti mú òróró rẹ̀ pọ̀ síi kí ó baà lè san gbèsè náà. Nípa báyìí ó pa ìdílé rẹ̀ àti iyì rẹ̀ mọ́.—Eksodu 22:22, 23; 2 Awọn Ọba 4:1-7.
21. Àwòrán tí ó wà déédéé wo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu yà sí wa lọ́kàn nípa ipò àwọn obìnrin?
21 Kì í ṣe pé a ń fún ojú-ìwòye tí ó ṣáátá àwọn obìnrin ní ìṣírí rárá, nítorí náà, Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu fún wa ní àpèjúwe tí ó wà déédéé nípa ipò wọn láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa kò dáàbò bo àwọn olùjọsìn rẹ̀ obìnrin kúrò lọ́wọ́ ìmúṣẹ Genesisi 3:16, àwọn obìnrin ni a bálò pẹ̀lú iyì àti ọ̀wọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin oníwà-bí-Ọlọ́run tí wọ́n tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jehofa tí wọ́n sì pa Òfin rẹ̀ mọ́.
22. Nígbà tí ó fi di ìgbà tí Jesu wá sórí ilẹ̀-ayé, báwo ni ipa-iṣẹ́ àwọn obìnrin ti ṣe yípadà, àwọn ìbéèrè wo sì ni a béèrè?
22 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ó tẹ̀lé píparí Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, ipa-iṣẹ́ àwọn obìnrin yípadà láàárín àwọn Júù. Nígbà tí yóò fi di ìgbà tí Jesu wá sórí ilẹ̀-ayé, àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn rabi ti ká àwọn obìnrin lọ́wọ́ kò nínú àǹfààní ìsìn wọn àti ìgbésí-ayé ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Irú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ha nípa lórí ọ̀nà tí Jesu gbà bá àwọn obìnrin lò bí? Báwo ni a ṣe níláti bá àwọn Kristian obìnrin lò lónìí? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary, “polygamy” [àṣà ìṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni púpọ̀] tọ́ka sí “ìgbéyàwó níbi tí ẹni tí a fi ṣaya tàbí fi ṣọkọ ti lè ní alábàágbéyàwó tí ó ju ẹyọ kan lọ lẹ́ẹ̀kan náà.” Ọ̀rọ̀ kan tí ó túbọ̀ ṣe pàtó síi “polygyny” [àṣà ìkóbìnrinjọ] ni a túmọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ipò tàbí àṣà níní ju ìyàwó tàbí obìnrin alábàágbéyàwó kan lẹ́ẹ̀kan náà.”
b Jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti lọ́kọ tí wọ́n sì ti láya ni a tọ́ka sí ní ọ̀pọ̀ ìgbà gẹ́gẹ́ bí “ọkọ” (Heberu, ʼish) àti “aya” (Heberu, ʼish·shahʹ). Fún àpẹẹrẹ, ní Edeni, ọ̀rọ̀ náà tí Jehofa lò, kì í ṣe “olówó” àti ‘ẹni tí a ni,’ ṣùgbọ́n “ọkọ” àti “aya.” (Genesisi 2:24; 3:16, 17) Àsọtẹ́lẹ̀ Hosea sọ pé lẹ́yìn pípadà dé láti oko-òǹdè, Israeli yóò fi ìrònúpìwàdà pe Jehofa ní “Ọkọ mi,” kì í sì ṣe “Olówó mi” mọ́. Èyí lè dámọ̀ràn pé ọ̀rọ̀ náà “ọkọ” ní ìgbéyọsọ́kàn oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ju “olówó” lọ.—Hosea 2:16, NW.
c Lílò tí a lo ọ̀rọ̀ ẹni kìn-ínní ní títọ́ka sí Debora nínú Awọn Onidajọ 5:7, yẹ fún àfiyèsí.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” àti “àṣekún” fi hàn nípa ipa-iṣẹ́ tí Ọlọrun fún àwọn obìnrin?
◻ Nígbà tí a bá ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó kan àwọn obìnrin ní àkókò Bibeli, kí ni ohun tí a níláti fi sọ́kàn?
◻ Kí ni ó fi hàn pé àwọn obìnrin ní ipa-iṣẹ́ tí a bu iyì kún láàárín àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ìjímìjí?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa gbà fún àwọn obìnrin ní ojúrere àkànṣe ní àwọn àkókò tí ó ṣáájú ìgbà Kristian?