Ilẹ-Ọba tí Ó Pòórá tí Ó Rú Awọn Aṣelámèyítọ́ Bibeli Lójú
“Tẹlẹri ìtàn ilẹ-ọba Assiria jẹ́ ọ̀kan lara awọn akori ìtàn fifarasin julọ ninu awọn akọsilẹ ọ̀rọ̀-ìtàn ayé.” “Gbogbo ohun ti a mọ̀ nipa Ninefe igbaani ni ó parapọ wà ninu awọn ìsọ̀rọ̀bá ati asọtẹlẹ tí ó sọrọ bá a ninu Bibeli, ati awọn àjákù akiyesi ìtàn afẹnusọ Assiria ninu Diodorus Siculus . . . ati awọn miiran.”—Cyclopædia of Biblical Literature, Idipọ 1 ati 3, 1862.
OPITAN Griki naa Diodorus Siculus gbé ni 2,000 ọdun sẹhin. Ó fi idaniloju sọ pe, Ninefe jẹ́ ilu-nla onigun-mẹrin; awọn ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin rẹ̀ papọ jẹ́ pápá iṣere 480 ni gigun. Iyẹn jẹ́ 60 ibusọ! Bibeli funni ni aworan ti o farajọra, ni ṣiṣapejuwe Ninefe gẹgẹ bi ilu-nla ‘ti o tó irin ọjọ mẹta.’—Jona 3:3.
Awọn aṣelámèyítọ́ Bibeli ti ọrundun kọkandinlogun kọ̀ lati gbà pe ilu-nla ayé igbaani kan ti a kò mọ̀ ti lè tobi tobẹẹ rí. Wọn tun sọ pẹlu pe bi Ninefe bá ti wà rí, o ti gbọdọ jẹ́ apakan ọlaju igbaani ti ó ṣaaju Babiloni.
Oju-iwoye yii lodi si Genesisi ori 10, eyi ti o sọ pe ọmọ-ọmọ ńlá Noa, Nimrodu, fi idi ipinlẹ oṣelu akọkọ mulẹ ni ẹkun Babeli, tabi Babiloni. “Lati ilẹ̀ yẹn,” ni Bibeli ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, “ó jade lọ si Assiria ó sì bẹrẹ sii kọ́ Ninefe ati Rehoboti ati Kala ati Reseni lagbedemeji Ninefe oun Kala: eyi ni ilu nla naa.” (Genesisi 10:8-12, NW) Ṣakiyesi pe, iwe mimọ ṣapejuwe awọn ilu-nla Assiria titun mẹrin naa pé wọn jẹ́ “ilu nla” kan.
Ni 1843 awalẹpitan ọmọ ilẹ Faranse kan, Paul-Émile Botta, ṣawari awọn àwókù ààfin kan ti ó jẹ́ apakan ilu-nla Assiria kan. Nigba ti irohin awari yii dé etígbọ̀ọ́ awọn ara-ilu, o fa ayọ ńláǹlà. “Ọkàn-ìfẹ́ awọn ara-ilu ga sii,” ni Alan Millard ṣalaye ninu iwe rẹ̀ Treasures From Bible Times, “nigba ti a fẹ̀rí rẹ̀ hàn pe ààfin naa jẹ́ ti Sargoni, ọba Assiria ti a darukọ ni Isaiah 20:1, ẹni ti a ti ṣiyemeji wíwà rẹ̀ nitori pe a kò fi bẹẹ mọ̀.”
Laaarin àfo akoko yii, awalẹpitan miiran, Austen Henry Layard, bẹrẹ sii hú awọn àwókù jade ni ibikan ti a pe ni Nimrud ni nǹkan bii kilomita 42 ni apa-iha guusu-iwọ-oorun Khorsabad. Àwókù naa wá di Kala—ọ̀kan lara awọn ilu-nla Assiria mẹrin ti a mẹnukan ni Genesisi 10:11. Lẹhin naa, ni 1849, Layard hú àwókù ààfin gàgàrà kan jade ni ibikan ti a pe ni Kuyunjik, lagbedemeji Kala ati Khorsabad. Ààfin naa ni ẹ̀rí fihàn pé ó jẹ́ apakan Ninefe. Lagbedemeji Khorsabad oun Kala ni àwókù awọn ibi ti a tẹ̀dó miiran wà, ti ó ní okiti kan ti a pe ni Karamles ninu. “Bi a bá mú awọn okiti ńlá mẹrin Nimrúd [Kala], Koyunjik [Ninefe], Khorsabad, ati Karamles, gẹgẹ bi kọ̀rọ̀ igun-mẹrin kan,” ni Layard ṣakiyesi, “a o rí i pe awọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹrin baradọgba lọna pípéye pẹlu awọn pápá iṣere 480 tabi 60 ibusọ ti onimọ irisi-ilẹ, eyi ti o di irin ọjọ mẹta ti wolii [Jona].”
Ni kedere, nigba naa, Jona fi gbogbo awọn ibi ti a tẹ̀dó wọnyi kun un gẹgẹ bi “ilu nla” kan, ni pípè wọn ni orukọ ilu-nla ti a kọkọ kọsilẹ ni Genesisi 10:11, ti ń jẹ́, Ninefe. Ohun kan-naa ni a ń ṣe lonii. Fun apẹẹrẹ, iyatọ wà laaarin ilu-nla London ipilẹṣẹ ati ayika rẹ̀, ti o papọ jẹ́ eyi ti a ń pè ni “London Titobi Ju” nigba miiran.
Ọba Assiria Agberaga Kan
Ààfin ti ó wà ni Ninefe ní iye ti o ju 70 yàra ninu, ó sì ní ohun ti o fẹrẹẹ tó ogiri oni-kilomita mẹta. Lori awọn ogiri wọnyi ni àjókù awọn igi gbígbẹ́ ti ń rannileti ijagunmolu ologun ati awọn aṣeyọri miiran wà. Ọpọ julọ ninu wọn ni ó ti bajẹ gidigidi. Ni apa ipari diduro nibẹ rẹ̀, bi o ti wu ki o ri, Layard ṣawari ìyẹ̀wù kan ni ipo itọjupamọ pipẹtẹri kan. Lara awọn ogiri ni aworan kan ti ń fi ìkólẹ́rú ilu olódi ńláǹlà kan hàn wà, pẹlu awọn igbekun ti a tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ niwaju ọba ti o gbogun tì í naa, ẹni ti o jokoo lori ìtẹ́ ni òde ilu-nla naa. Lókè ọba naa ni ohun kan ti a kọ wà ti awọn ogbontagi ninu ikọwe awọn ara Assiria tumọ gẹgẹ bi o ti tẹlee yii: “Sennakeribu, ọba ayé, ọba Assiria, jokoo lori ìtẹ́ nimedu ti ó sì ń ṣayẹwo ìkógun (ti o gbà) lati ọ̀dọ̀ Lakiṣi (La-ki-su).”
Lonii aworan ati ikọwe yii ni a lè wò ninu Ile Àkójọ-Ohun-Ìṣẹ̀m̀báyé ti Britain. Ó bá iṣẹlẹ ọlọ́rọ̀-ìtàn ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Bibeli ninu 2 Ọba 18:13, 14 mu pe: “Ni ọdun kẹrinla Hesekiah ọba, ni Sennakeribu ọba Assiria goke wá si gbogbo awọn ilu olódi Juda, ó sì kó wọn. Hesekiah ọba Juda sì ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wi pe, Mo ti ṣẹ̀; pada lẹhin mi; eyi ti iwọ bá bù fun mi ni emi ó rù. Ọba Assiria sì bu ọọdunrun talenti fadaka, ati ọgbọn talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.”
Awọn ikọwe miiran ni a rí laaarin awọn àwókù Ninefe ti ń fi afikun awọn kulẹkulẹ nipa gbígbóguntì tí Sennakeribu gbógun ti Juda ati ìṣákọ́lẹ̀ ti Hesekiah san hàn. “Boya ọ̀kan lara awọn ìṣèèṣì baradọgba pipẹtẹri julọ nipa ẹ̀rí ti ó wà ninu akọsilẹ ni, iye iṣura ninu wura ti a gbà lọwọ Hesekiah, ọgbọ̀n talenti, baramu ninu awọn akọsilẹ ọtọọtọ patapata meji,” ni Layard kọwe. Ọ̀gbẹ́ni Henry Rawlinson, ti ó ṣeranwọ lati dá ikọwe Assiria mọ̀, kede pe awọn ikọwe wọnyi “gbé àmì idanimọ onítàn [ti Sennakeribu] kọja ayika iyàn jíjà.” Siwaju sii, Layard beere ninu iwe rẹ̀ Nineveh and Babylon pe: “Ta ni ìbá ti gbà á gbọ́ ní boya tabi pe ó ṣeeṣe, ṣaaju ki a tó ṣe awọn awari wọnyi, pe nisalẹ okiti iyẹ̀pẹ̀ ati pantiri ti o sami si ọgangan Ninefe, a o rí ìtàn awọn ogun laaarin Hesekiah ati Sennakeribu, ti a kọ lati ọwọ́ Sennakeribu funraarẹ ni akoko naa gan-an ti wọn ṣẹlẹ, ti ó sì ń jẹrii si awọn kulẹkulẹ ti o kéré gan-an ninu akọsilẹ Bibeli paapaa?”
Dajudaju, awọn kulẹkulẹ kan nipa akọsilẹ Sennakeribu kò baramu pẹlu Bibeli. Fun apẹẹrẹ, awalẹpitan Alan Millard ṣakiyesi pe: “Otitọ ti ó gbani lafiyesi julọ wà ni opin [akọsilẹ Sennakeribu]. Hesekiah rán ońṣẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ìṣákọ́lẹ̀, si Sennakeribu ‘lẹhin naa, si Ninefe’. Ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Assiria kò gbé wọn lọ sile ninu ayọ-iṣẹgun ni ọ̀nà ti ó sábà maa ń gbà jẹ́.” Bibeli sọ pe ìṣákọ́lẹ̀ naa ni a san ṣaaju ki ọba Assiria tó pada si Ninefe. (2 Ọba 18:15-17) Ki ni o fa iyatọ naa? Eesitiṣe ti Sennakeribu kò fi lè fọ́nnu nipa ṣiṣẹgun Jerusalemu, olu-ilu Judea, ni ọ̀nà ti ó gbà fọ́nnú nipa ijagunmolu rẹ̀ lori odi-agbara Judea, Lakiṣi? Awọn onkọwe Bibeli mẹta funni ni idahun naa. Ọ̀kan ninu wọn, ti ó jẹ́ ẹni ti ọ̀ràn ṣoju rẹ̀, kọwe pe: “Angẹli Oluwa sì jade lọ, ó sì pa ọkẹ mẹsan-an ó lé ẹgbẹẹdọgbọn ni ibùdó awọn ará Assiria; nigba ti wọn sì dide lowurọ kutukutu, kiyesi i, gbogbo wọn jẹ oku. Bẹẹ ni Sennakeribu ọba Assiria mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó sì lọ, ó sì pada, ó sì ń gbé Ninefe.”—Isaiah 37:36, 37; 2 Ọba 19:35; 2 Kronika 32:21.
Ninu iwe rẹ̀ Treasures From Bible Times, Millard pari-ero pe: “Kò sí idi rere lati ṣiyemeji nipa irohin yii . . . Lọna ti ó yeni, Sennakeribu kò ni ṣakọsilẹ iru ìjábá bẹẹ fun awọn agbapò rẹ̀ lati kà, nitori pe yoo tẹ́ ẹ lógo.” Kaka bẹẹ, Sennakeribu gbiyanju lati muni lero pe igbogunti Judea ti kẹsẹjari ati pe Hesekiah ń baa lọ ni jijuwọsilẹ, ni fifi ìṣákọ́lẹ̀ ranṣẹ si Ninefe.
A Fìdíi Ipilẹṣẹ Assiria Múlẹ̀
Awọn ibi-àkójọ-ìwé-kíkà ti wọn ní ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa-mẹwaa awọn wàláà alámọ̀ ni a tun ṣawari ni Ninefe. Awọn ohun eelo ikọwe wọnyi fẹ̀rí hàn pe Ilẹ-ọba Assiria ní gbongbo rẹ̀ ni guusu ni Babiloni, gan-an gẹgẹ bi Genesisi 10:11 ti fihàn. Ní titẹle isọfunni yii, awọn awalẹpitan bẹrẹ sii kó awọn isapa wọn jọ jinna sii si guusu. Iwe gbedegbẹyọ Encyclopædia Biblica ṣalaye pe: “Gbogbo ohun ti ó ṣẹku nipa Assiria fihàn pe Babiloni ni orírun wọn. Èdè ati ọ̀nà ìgbàkọ̀wé wọn, gbogbo iwe wọn, isin wọn, ati imọ-ijinlẹ wọn ni wọn múwá lati ọ̀dọ̀ awọn aladuugbo wọn apa-iha guusu pẹlu iwọn atunṣe kekere.”
Awọn awari bii ti oke yii ti fipa mú awọn aṣelámèyítọ́ Bibeli lati mú oju-iwoye wọn wà deedee. Nitootọ, ayẹwo ti a fi otitọ-inu ṣe nipa Bibeli fihàn pe a kọ ọ́ nipasẹ awọn onkọwe oniṣọọra, alailabosi. Olori onidaajọ Ile-ẹjọ Giga Julọ United States tẹlẹri, Salmon P. Chase, sọ lẹhin ti o ṣayẹwo Bibeli pe: “Ó jẹ́ ikẹkọọ ti o gba akoko gigun kan, ti ó ṣe pataki, ti ó sì jinlẹ: ati ni lílo awọn ilana ẹ̀rí kan-naa ninu koko-ẹkọ isin yii gẹgẹ bi mo ti sábà maa ń ṣe ninu awọn koko-ẹkọ ti ayé, mo ti wá dori ipinnu naa pe Bibeli jẹ́ iwe aramanda-ọtọ kan, pe ó wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.”—The Book of Books: An Introduction.
Nitootọ, Bibeli fi pupọpupọ ju ìtàn pípéye lọ. Ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a mísí, ẹbun kan fun anfaani araye. (2 Timoteu 3:16) Ẹ̀rí eyi ni a lè rí nipa ṣiṣayẹwo irisi oju-ilẹ Bibeli. Eyi ni a o jiroro ninu itẹjade ti ń bọ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Loke: Awọn kulẹkulẹ mẹta ti a kọ lati ara aworan ogiri
Nisalẹ: Aworan yíyà ti aworan ogiri Assiria ti ń fi isagati Lakiṣi hàn
[Àwọn Credit Line]
(Iyọọda oninuure ti The British Museum)
(Lati inu The Bible in the British Museum, ti a tẹjade nipasẹ British Museum Press)
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Iyọọda Oninuure ti Trustees of The British Museum