Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Yóò Ṣe Rí?
BÍ ỌLỌ́RUN Olódùmarè bá mọ ohun gbogbo, tí ó mọ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá, ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, àti èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la, ko ha jẹ́ pé a ti kádàrá pé kí ohun gbogbo ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti rí i tẹ́lẹ̀ bí? Bí Ọlọ́run bá ti rí ìgbésẹ̀ àti àtúbọ̀tán gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tẹ́lẹ̀, tí ó sì fàṣẹ sí i pé kí ó rí bẹ́ẹ̀, a ha lè sọ ní tòótọ́ pé a lómìnira láti yan ọ̀nà ìgbésí ayé wa, ọjọ́ ọ̀la wa bí?
A ti jiyàn lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Awuyewuye náà ṣì ń dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ìsìn pàtàkì pàtàkì. A ha lè mú èrò pé Ọlọ́run ní agbára láti mọ ọjọ́ ọ̀la bá èrò pé ẹ̀dá ènìyàn ní òmìnira ìfẹ́ inú mu bí? Ibo ni ó yẹ kí a yíjú sí fún ìdáhùn?
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yíká ayé ni yóò gbà pé Ọlọ́run ti bá aráyé sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, tí àwọn agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀, àwọn wòlíì, ti fi jíṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Kùránì fi hàn pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ìṣípayá ti wá: Ataora (Tórà, Òfin, tàbí ìwé márùn-ún ti Mósè), Zabūr (Sáàmù), àti Injila (Ìhìn Rere, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tàbí “Májẹ̀mú Tuntun”), àti ohun tí a ṣí payá fún àwọn wòlíì Ísírẹ́lì.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a kà pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Ó ṣe kedere pé, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ìtọ́sọ́nà tàbí ìlàlóye èyíkéyìí tí a rí gbà ti ní láti wá. Kò ha ní bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àwọn wòlíì Ọlọ́run ní ìjímìjí? Kí ni wọ́n ṣí payá nípa ọjọ́ ọ̀la wa?
Ọjọ́ Ọ̀la Tí Ó Ní Àkọọ́lẹ̀
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ka Ìwé Mímọ́ yóò mọ̀ pé wọ́n kún fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ní ti gidi. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé bí ìṣubú Bábílónì ìgbàanì, àtúnkọ́ Jerúsálẹ́mù (ọ̀rúndún kẹfà sí ìkarùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa), ìdìde àti ìṣubú àwọn ọba ìgbàanì ti Mídíà òun Páṣíà àti ti Gíríìsì, gbogbo wọn pátá ni a sọ tẹ́lẹ̀ ní kúlẹ̀kúlẹ̀. (Aísáyà 13:17-19; 44:24–45:1; Dáníẹ́lì 8:1-7, 20-22) Ìmúṣẹ irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí lílágbára jù lọ pé Ìwé Mímọ́ ní tòótọ́ jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó ní agbára láti rí ohun kan tẹ́lẹ̀ àti láti pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Lọ́nà yìí, Ìwé Mímọ́ ní tòótọ́ ní àkọọ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la.
Ọlọ́run fúnra rẹ̀ polongo pé: “Èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi; Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tí ì ṣe; Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe’ . . . Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:9-11; 55:10, 11) Orúkọ náà gan-an tí Ọlọ́run pe ara rẹ̀ fún àwọn wòlíì ìgbàanì ni Jèhófà, tí ó túmọ̀ ní ṣangiliti sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.”a (Jẹ́nẹ́sísì 12:7, 8; Ẹ́kísódù 3:13-15; Sáàmù 83:18) Ọlọ́run ṣí ara rẹ̀ payá gẹ́gẹ́ bí Ẹni náà tí ń di Olùmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, Ẹni náà tí ń mú ète rẹ̀ ṣẹ nígbà gbogbo.
Nípa báyìí, Ọlọ́run ń lo agbára mímọ nǹkan tẹ́lẹ̀ tí ó ní láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Ó ti lò ó lọ́pọ̀ ìgbà láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn burúkú nípa ìdájọ́ tí ń bọ̀ àti láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìrètí fún ìgbàlà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ha ń lo agbára yìí lọ́nà tí kò láàlà bí? Ẹ̀rí èyíkéyìí ha wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run yàn láti má ṣe mọ̀ kí ó tó ṣẹlẹ̀ bí?
Gbogbo Nǹkan Ha Ni Ọlọ́run Ń Mọ̀ Kí Ó Tó Ṣẹlẹ̀ Bí?
Gbogbo ìjiyàn tí ó ti kádàrá lẹ́yìn ni a gbé karí èrò náà pé níwọ̀n bí kò ti sí àní-àní pé Ọlọ́run ní agbára láti mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀, tí ó sì lè pinnu wọn, ó ní láti mọ ohun gbogbo ṣáájú kí ó tó ṣẹlẹ̀, títí kan àwọn ìgbésẹ̀ ọjọ́ ọ̀la ti gbogbo olúkúlùkù. Ṣùgbọ́n, èrò yìí ha múná dóko bí? Ohun tí Ọlọ́run ṣí payá nínú Ìwé Mímọ́ rẹ̀ tọ́ka sí ohun tí ó yàtọ̀.
Fún àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ sọ pé “Ọlọ́run . . . dán Ábúráhámù wò” nípa pípàṣẹ fún un láti fi ọmọkùnrin rẹ̀, Ísákì, rúbọ sí òun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun. Nígbà tí Ábúráhámù fẹ́ fi Ísákì rúbọ, Ọlọ́run dá a dúró, ó sì wí pé: “Nísinsìnyí ni mo mọ̀ pé olùbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìwọ ní ti pé ìwọ kò fawọ́ ọmọkùnrin rẹ, ọ̀kan ṣoṣo tí o ní, sẹ́yìn fún mi.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:1-12) Bí Ọlọ́run bá ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Ábúráhámù yóò ṣègbọràn sí òun, òun yóò ha tún sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ bí? Yóò ha ti jẹ́ ìdánwò tí kò lábòsí nínú bí?
Ní àfikún sí i, àwọn wòlíì ìgbàanì ròyìn pé Ọlọ́run sọ̀rọ̀ léraléra nípa ara rẹ̀ pé ‘òun kẹ́dùn’ lórí ohun kan tí òun ti ṣe tàbí tí òun ń ronú láti ṣe. Fún àpẹẹrẹ, Ọlọ́run wí pé òun “kẹ́dùn [láti inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, na·chamʹ] pé òun ti fi Sọ́ọ̀lù jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì.” (1 Sámúẹ́lì 15:11, 35; fi wé Jeremáyà 18:7-10; Jónà 3:10.) Nítorí Ọlọ́run jẹ́ ẹni pípé, àwọn ẹsẹ wọ̀nyí kò lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ṣàṣìṣe fún yíyan Sọ́ọ̀lù láti jẹ́ ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti fi hàn pé ó ṣe Ọlọ́run láàánú pé Sọ́ọ̀lù yí padà di aláìṣòótọ́ àti aláìgbọràn. Lílò tí Ọlọ́run lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ fún ara rẹ̀ kò ní nítumọ̀ bí ó bá jẹ́ pé ó ti mọ ìgbésẹ̀ tí Sọ́ọ̀lù yóò gbé tẹ́lẹ̀.
Ọ̀rọ̀ kan náà fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ tí ọjọ́ rẹ̀ tí ì pẹ́ jù lọ, níbi tí, ní títọ́ka sí àwọn ọjọ́ Nóà, ó wí pé: “Jèhófà . . . kẹ́dùn pé òun dá àwọn ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì dùn ún ní ọkàn-àyà rẹ̀. Nítorí náà, Jèhófà wí pé: ‘Èmi yóò nu àwọn ènìyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀, . . . nítorí tí mo kẹ́dùn pé mo dá w[ọ]n.’” (Jẹ́nẹ́sísì 6:6, 7) Níhìn-ín pẹ̀lú, èyí fi hàn pé Ọlọ́run kò kádàrá ìgbésẹ̀ ènìyàn. Ọlọ́run kẹ́dùn, ó dùn ún gan-an, ó tilẹ̀ bà á nínú jẹ́, kì í ṣe nítorí pé ó ṣe àṣìṣe, ṣùgbọ́n nítorí tí ìwà burúkú ènìyàn ń pọ̀ sí i. Ẹlẹ́dàá kẹ́dùn pé ó ti wá pọndandan láti pa gbogbo aráyé run, àyàfi Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan. Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí ikú ẹni burúkú.”—Ìsíkíẹ́lì 33:11; fi wé Diutarónómì 32:4, 5.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ha ti mọ̀ pé Ádámù yóò ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ títí kan àwọn àbájáde oníyọnu tí èyí yóò mú wá fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, tí ó sì ti ṣàkọọ́lẹ̀ rẹ̀ pàápàá bí? Ohun tí a ti gbé yẹ̀ wò fi hàn pé èyí kò lè jẹ́ òtítọ́. Ìyẹn nìkan kọ́, bí Ọlọ́run bá ti mọ gbogbo èyí tẹ́lẹ̀, a jẹ́ pé òun ni orísun ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí ó dá ènìyàn, òun ni ì bá sì lẹ̀bi gbogbo ìwà burúkú àti ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. Ó ṣe kedere pé, a kò lè mú èrò yìí bá ohun tí Ọlọ́run ṣí payá nípa ara rẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ mu. Òun jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo tí ó kórìíra ìwà burúkú.—Sáàmù 33:5; Òwe 15:9; 1 Jòhánù 4:8.
Kádàrá Méjì Tí Ènìyàn Ní
Ìwé Mímọ́ kò ṣí i payá pé Ọlọ́run ti pinnu ọjọ́ ọ̀la ẹnì kọ̀ọ̀kan tẹ́lẹ̀ tàbí ti kádàrá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ó ṣí payá ni pé Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa kádàrá méjì tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ti ènìyàn. Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ni òmìnira ìfẹ́ inú láti yan kádàrá tí yóò jẹ́ tirẹ̀. Wòlíì Mósè ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn polongo fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, . . . kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn; nítorí òun ni ìyè rẹ àti gígùn ọjọ́ rẹ.” (Diutarónómì 30:19, 20) Jésù, wòlíì Ọlọ́run, kìlọ̀ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Ọ̀nà méjì, kádàrá méjì. Ọjọ́ ọ̀la wa sinmi lórí ìgbésẹ̀ wa. Ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run túmọ̀ sí ìyè, ṣíṣàìgbọràn sí i yóò túmọ̀ sí ikú.—Róòmù 6:23.
Ọlọ́run “ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà. Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo.” (Ìṣe 17:30, 31) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé ní ọjọ́ Nóà ti yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tí a sì pa wọ́n run, bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ kò ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Síbẹ̀, Ọlọ́run kò tí ì pinnu àwọn tí yóò parun àti àwọn tí yóò rí ìgbàlà. Ní tòótọ́, Ọlọ́run sọ pé òun “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Àní àwọn ènìyàn burúkú paraku pàápàá lè ronú pìwà dà, kí wọ́n di onígbọràn, kí wọ́n sì ṣe ìyípadà tí ó bá pọndandan láti jèrè ojú rere Ọlọ́run.—Aísáyà 1:18-20; 55:6, 7; Ìsíkíẹ́lì 33:14-16; Róòmù 2:4-8.
Fún àwọn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn, Ọlọ́run ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè alálàáfíà, ilẹ̀ ayé tí a fọ gbogbo ìwà burúkú, ìwà ipá, àti ogun mọ́ kúrò nínú rẹ̀, ayé kan tí kò ní sí ebi, ìjìyà, àìsàn, àti ikú mọ́. (Sáàmù 37:9-11; 46:9; Aísáyà 2:4; 11:6-9; 25:6-8; 35:5, 6; Ìṣípayá 21:4) Àní a óò jí àwọn òkú pàápàá dìde, a óò sì fún wọn ní àǹfààní láti sin Ọlọ́run.—Dáníẹ́lì 12:2; Jòhánù 5:28, 29.
Onísáàmù náà wí pé: “Máa ṣọ́ aláìlẹ́bi, kí o sì máa wo adúróṣánṣán, nítorí pé ọjọ́ ọ̀la ẹni yẹn yóò kún fún àlàáfíà. Ṣùgbọ́n ó dájú pé a ó pa àwọn olùrélànàkọjá rẹ́ ráúráú lápapọ̀; ọjọ́ ọ̀la àwọn ènìyàn burúkú ni a óò ké kúrò ní tòótọ́.” (Sáàmù 37:37, 38) Báwo ni ọjọ́ ọ̀la rẹ yóò ṣe rí? Ọwọ́ rẹ ni ó kù sí. Àwọn tí ó ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde yóò láyọ̀ láti fún ọ ní ìsọfúnni síwájú sí i láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i dájú pé o ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀, alálàáfíà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ náà Jèhófà fara hàn ní ìgbà tí ó lé ní 7,000 nínú Ìwé Mímọ́; wo ìwé àṣàrò kúkúrú náà The Greatest Name, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde ní ọdún 1995.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ọlọ́run ń lo agbára mímọ nǹkan tẹ́lẹ̀ tí ó ní láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ọlọ́run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí Ọlọ́run bá mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Ábúráhámù yóò ṣe tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, ìyẹn yóò ha jẹ́ ìdánwò tí kò lábòsí nínú bí?