Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
“Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:19.
1, 2. (a) Àwọn èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mélòó ló wà nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú? (b) Kí ló yẹ ká ṣàyẹ̀wò kí a lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ọkàn?
NIKHILANANDA, ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ẹ̀sìn Híńdù ṣàkíyèsí pé: “Àbá èrò orí ti ìjìyà àìnípẹ̀kun kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ó dá. . . . Láti gbà gbọ́ pé ìjìyà ayérayé ń bẹ fún ọkàn tìtorí àwọn àṣìṣe ọdún mélòó kan, láìní fún un ní àyè láti ṣàtúnṣe, lòdì sí gbogbo ìrònú tí ó bọ́gbọ́n mu.”
2 Gẹ́gẹ́ bíi ti Nikhilananda, ọ̀pọ̀ lónìí ni ẹ̀kọ́ ìdálóró ayérayé kò bá lára dé. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ṣe ṣòro fún àwọn mìíràn láti lóye èrò dídé Nirvana, tí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà gbà sí ipò ìdẹ̀ra, àti èrò wíwà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Adẹ́dàá. Kódà láàárín àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn gbé ìgbàgbọ́ àwọn karí Bíbélì pàápàá, èrò wọn nípa ọkàn àti ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó bá kú, kò bára mu. Ṣùgbọ́n, kí ni Bíbélì kọ́ wa gan-an nípa ọkàn? Láti rí ìdáhùn sí i, ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣàyẹ̀wò ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà tí a tú sí “ọkàn” nínú Bíbélì.
Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Lò Ó
3. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni a tú sí “ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kí sì ni ìtumọ̀ rẹ̀ gan-an? (b) Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 2:7 ṣe jẹ́rìí sí i pé ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” lè túmọ̀ sí odindi ènìyàn?
3 Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a tú sí “ọkàn” ni neʹphesh, ìgbà mẹ́rìnléláàádọ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [754] ló sì fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Kí ni neʹphesh túmọ̀ sí? Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Dictionary of Bible and Religion ṣe wí, ó “sábà máa ń tọ́ka sí ẹ̀dá alààyè náà látòkè délẹ̀, ẹni náà lódindi.” Ọ̀nà tí Bíbélì gbà ṣàpèjúwe ọkàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:7 ti èyí lẹ́yìn: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ṣàkíyèsí pé ọkùnrin àkọ́kọ́ “wá di” ọkàn. Ìyẹn ni pé, Ádámù kò ní ọkàn; òun ni ọkàn—gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tí ó di dókítà ṣe jẹ́ dókítà. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” níhìn-ín ń tọ́ka sí ènìyàn lódindi.
4. Ọ̀rọ̀ wo ni a tú sí “ọkàn” nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, kí sì ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà gan-an?
4 Ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọkàn” (psy·kheʹ) fara hàn níye ìgbà tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Gẹ́gẹ́ bí neʹphesh, ọ̀rọ̀ yìí sábà máa ń tọ́ka sí ènìyàn lódindi. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí: “Ọkàn mi dààmú.” (Jòhánù 12:27) “Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba olúkúlùkù ọkàn.” (Ìṣe 2:43) “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) “A gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20) Bí ti neʹphesh, ó ṣe kedere pé psy·kheʹ pẹ̀lú ń tọ́ka sí ènìyàn lódindi. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Nigel Turner, ṣe wí, ọ̀rọ̀ yìí “dúró fún gbogbo ànímọ́ tí a fi ń peni ní ènìyàn, ẹni náà fúnra rẹ̀, ara ìyára tí Ọlọ́run mí rûaḥ [ẹ̀mí] sí nínú. . . . Ẹni náà lódindi ni a tẹnu mọ́.”
5. Ǹjẹ́ ọkàn ni àwọn ẹranko? Ṣàlàyé.
5 Ó dùn mọ́ni pé, nínú Bíbélì, ènìyàn nìkan kọ́ ni a lo ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” fún, a tún ń lò ó fún àwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jẹ́nẹ́sísì 1:20 ń ṣàpèjúwe bí a ṣe dá àwọn ẹ̀dá inú òkun, ó sọ pé Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Kí omi mú àwọn alààyè ọkàn agbáyìn-ìn máa gbá yìn-ìn.” Ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá tí ó tẹ̀ lé e, Ọlọ́run sọ pé: “Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹran tí ń rìn ká àti ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:24; fi wé Númérì 31:28.
6. Kí ni a lè sọ nípa ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn”?
6 Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” bí a ti lò ó nínú Bíbélì, tọ́ka sí ẹnì kan tàbí ẹran tàbí ìwàláàyè tí ènìyàn tàbí ẹran ní. (Wo àpótí tó wà lókè.) Ìtumọ̀ tí Bíbélì fún ọkàn rọrùn, ó bára mu délẹ̀, àwọn ọgbọ́n èrò orí àti ìgbàgbọ́ asán àwọn ènìyàn kò lè mú kí ìtumọ̀ náà dojú rú. Bí ọ̀ràn ṣe wá rí yìí, ìbéèrè gbankọ-gbì tí a wá lè béèrè ni pé, Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà tí a bá kú?
Àwọn Òkú Kò Mọ Ohunkóhun
7, 8. (a) Kí ni Ìwé Mímọ́ ṣí payá nípa ipò tí àwọn òkú wà? (b) Fúnni ni àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó fi hàn pé ọkàn lè kú.
7 A mú ipò tí àwọn òkú wà ṣe kedere nínú Oníwàásù 9:5, 10, níbi tí a ti kà pé: “Òkú kò mọ nǹkan kan . . . Kò sí ìlépa ohunkóhun, kò sí ìpète, kò sí ìmọ̀ tàbí làákàyè kankan nínú ibojì.” (Moffatt) Nítorí náà, ikú jẹ́ ṣíṣàìsí. Onísáàmù náà kọ̀wé pé nígbà tí ènìyàn bá kú, “ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:4) Àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, wọn kò lè ṣe ohunkóhun.
8 Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣèdájọ́ Ádámù, ó sọ pé: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ádámù kò sí níbikíbi kí Ọlọ́run tó ṣèdá rẹ̀ láti inú ekuru ilẹ̀, tí ó sì fún un ní ìwàláàyè. Nígbà tí Ádámù sì kú, ipò yẹn náà ló padà sí. Ikú ni ìyà ẹ̀sẹ̀ rẹ̀—kì í ṣe ìpapòdà sí àgbègbè mìíràn. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí ọkàn rẹ̀? Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” sábà máa ń wulẹ̀ tọ́ka sí ènìyàn, nígbà táa sọ pé Ádámù kú, ohun tí a ń sọ ni pé ọkàn náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ádámù, ti kú. Èyí lè ṣàjèjì sí ẹni tí ó bá gba àìleèkú ọkàn gbọ́. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Léfítíkù 21:1 sọ nípa “ọkàn tí ó ti di olóògbé” (“òkú,” ìtumọ̀ ti The Jerusalem Bible). A sì sọ fún àwọn Násírì pé wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ “òkú ọkàn èyíkéyìí” (“òkú,” Lamsa).—Númérì 6:6.
9. Kí ni Bíbélì ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé “ọkàn” Rákélì “ń jáde lọ”?
9 Ó dáa, gbólóhùn tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 35:18 tó sọ nípa ikú òjijì tí Rákélì kú, èyí tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó ń bí ọmọ rẹ̀ kejì, ńkọ́? A kà níbẹ̀ pé: “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń jáde lọ (nítorí pé ó kú) ó pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ónì; ṣùgbọ́n baba rẹ̀ pè é ní Bẹ́ńjámínì.” Ṣé ohun tí àyọkà yìí ń sọ ni pé ẹ̀dá kan wà nínú Rákélì, tí ó jáde lọ nígbà tó kú? Rárá o. Rántí pé, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn,” tún lè tọ́ka sí ìwàláàyè tí ènìyàn ní. Nítorí náà, nínú ọ̀ràn yìí, “ọkàn” Rákélì wulẹ̀ túmọ̀ sí “ìwàláàyè” rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwọn Bíbélì mìíràn fi tú gbólóhùn náà “ọkàn rẹ̀ . . . ń jáde lọ” sí “ìwàláàyè rẹ̀ ń tán lọ” (Knox), “ó mí èémí àmíkẹ́yìn” (JB), àti “ìwàláàyè rẹ̀ kúrò lára rẹ̀” (Bible in Basic English). Kò sí ohun tí ó fi hàn pé ohun àràmàǹdà kan wà nínú Rákélì tí ó ṣì wà láàyè lẹ́yìn tí òun alára ti kú.
10. Ọ̀nà wo ni ọkàn ọmọ opó tí a jí dìde náà gbà “padà sínú rẹ̀”?
10 Bákan náà ló rí pẹ̀lú àjíǹde ọmọ opó kan, tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú 1 Àwọn Ọba orí 17. Ní ẹsẹ kejìlélógún, a kà á pé bí Èlíjà ti ń gbàdúrà lé ọ̀dọ́mọkùnrin náà lórí, “Jèhófà fetí sí ohùn Èlíjà, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ náà padà sínú rẹ̀, ó sì wá sí ìyè.” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” túmọ̀ sí “ìyè.” Nípa báyìí, ìtumọ̀ ti New American Standard Bible kà pé: “Ìwàláàyè ọmọ náà padà sínú rẹ̀ ó sì sọjí.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìwàláàyè ni ó padà sínú ọmọkùnrin náà, kì í ṣe ohun kan tí ó dà bí òjìji. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Èlíjà sọ fún ìyá ọmọ náà, pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ [ọmọ náà lódindi] yè.”—1 Àwọn Ọba 17:23.
Kí Ni Ẹ̀mí?
11. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí,” kò fi lè tọ́ka sí ohun kan tí ó jáde kúrò lára ènìyàn, tí ó sì la ikú já?
11 Bíbélì sọ pé, nígbà tí ènìyàn bá kú, “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀.” (Sáàmù 146:4) Èyí ha túmọ̀ sí pé ṣe ni ẹ̀mí kan tí ó bọ́ agọ̀ ara sílẹ̀ jáde lọ ní ti gidi tí ó sì ń bá a lọ láti wà láàyè lẹ́yìn ikú ènìyàn bí? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí onísáàmù náà sọ tẹ̀ lé èyí pé: “Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé” (“gbogbo ìrònú rẹ̀ dópin,” ìtumọ̀ ti The New English Bible). Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀mí, báwo sì ni ó ṣe ń “jáde lọ” kúrò lára ènìyàn nígbà tí onítọ̀hún bá kú?
12. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ náà tí a tú sí “ẹ̀mí” nínú Bíbélì túmọ̀ sí ní èdè Hébérù àti Gíríìkì?
12 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà tí a tú sí “ẹ̀mí” (lédè Hébérù, ruʹach; lédè Gíríìkì, pneuʹma) wulẹ̀ túmọ̀ sí “èémí.” Nípa báyìí, dípò “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ,” ìtumọ̀ ti R. A. Knox lo gbólóhùn náà, “èémí rẹ̀ kúrò lára rẹ̀.” (Sáàmù 145:4) Àmọ́ o, ohun tí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ju kìkì ọ̀ràn mímí lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jẹ́nẹ́sísì 7:22 ń ṣàlàyé bí ìwàláàyè ènìyàn àti tàwọn ẹranko ṣe pa run nígbà Àkúnya kárí ayé, ó sọ pé: “Ohun gbogbo tí èémí ipá [tàbí ẹ̀mí; lédè Hébérù a pè é ní, ruʹach] ìwàláàyè ń ṣiṣẹ́ ní ihò imú rẹ̀ kú, èyíinì ni, gbogbo ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” Nítorí náà, “ẹ̀mí” lè tọ́ka sí agbára ìwàláàyè tí ń ṣiṣẹ́ nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè, àtènìyàn àtẹranko, èyí tí mímí tí a ń mí sì gbé ró.
13. Báwo ni ẹ̀mí ṣe ń padà lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí ẹnì kan bá kú?
13 Nígbà náà, kí ló túmọ̀ sí, nígbà tí Oníwàásù 12:7 sọ pé nígbà tí ènìyàn bá kú, “ẹ̀mí . . . yóò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni”? Èyí ha túmọ̀ sí pé ṣe ni ẹ̀mí náà máa ń gba òfuurufú lọ bá Ọlọ́run ní ti gidi bí? Ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí kọ́ nìyẹn. Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé ẹ̀mí ni agbára ìwàláàyè, ó “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́” ní ti pé, láti ìgbà náà lọ, ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí èyíkéyìí tí onítọ̀hún ní fún ọjọ́ ọ̀la wà. Ọlọ́run nìkan ṣoso ló lè dá ẹ̀mí, tàbí agbára ìwàláàyè náà padà, kí ó sì mú kí ẹni náà padà wà láàyè. (Sáàmù 104:30) Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ha pète láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
“Yóò Dìde”
14. Kí ni Jésù sọ, tí ó sì ṣe láti tu àwọn arábìnrin Lásárù nínú, lẹ́yìn tí wọ́n ti pàdánù arákùnrin wọn?
14 Ní ìletò kan nítòsí Bẹ́tánì, ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́ta sí ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù, Màríà àti Màtá ń ṣọ̀fọ̀ ikú àìtọ́jọ́ tó pa Lásárù, arákùnrin wọn. Jésù pẹ̀lú bá wọn dárò, nítorí ó fẹ́ràn Lásárù àti àwọn arábìnrin rẹ̀ gan-an ni. Báwo wá ni Jésù yóò ṣe tu àwọn arábìnrin wọ̀nyí nínú? Kì í ṣe nípa fífi àtamọ́ mátamọ̀, ṣùgbọ́n nípa bíbá wọn sọ òótọ́ gan-an. Jésù wulẹ̀ sọ pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Lẹ́yìn náà, Jésù lọ sí ibojì náà, ó sì jí Lásárù dìde—ó dá ìwàláàyè padà sínú ọkùnrin náà tí ó ti kú fún odindi ọjọ́ mẹ́rin!—Jòhánù 11:18-23, 38-44.
15. Báwo ni Màtá ṣe fèsì sí ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe?
15 Gbólóhùn Jésù náà pé Lásárù yóò “dìde” ha ya Màtá lẹ́nu bí? Rárá o, nítorí ó fèsì pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Ó ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí àjíǹde tẹ́lẹ̀. Jésù wá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòhánù 11:23-25) Iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láti dá ìwàláàyè Lásárù padà tún mú kí ìgbàgbọ́ Màtá lágbára sí i, ó sì mú kí àwọn ẹlòmíràn nígbàgbọ́. (Jòhánù 11:45) Ṣùgbọ́n, kí tilẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde” túmọ̀ sí gan-an?
16. Kí ni ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” túmọ̀ sí?
16 Ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” ni a tú láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·naʹsta·sis, ní sáńgílítí tí ó túmọ̀ sí “dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Àwọn Hébérù olùtúmọ̀ èdè Gíríìkì túmọ̀ a·naʹsta·sis sí “mímú òkú sọ jí” (lédè Hébérù a pè é ní, techi·yathʹ ham·me·thimʹ)a Nípa báyìí, gbígbé ènìyàn dìde kúrò nínú ipò òkú—dídá ẹ̀mí ònítọ̀hún àti ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ padà sí i nínú—ni àjíǹde.
17. (a) Èé ṣe tí jíjí àwọn ènìyàn dìde kò fi ní jẹ́ ìṣòro fún Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi? (b) Ìlérí wo ni Jésù ṣe nípa àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí?
17 Ó rọrùn fún Jèhófà Ọlọ́run láti jí ènìyàn dìde, níwọ̀n bí ọgbọ́n rẹ̀ kò ti lópin, tí agbára ìrántí rẹ̀ sì jẹ́ pípé. Rírántí ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn tí ó ti kú—ìṣarasíhùwà wọn, ìtàn ìgbésí ayé wọn, àti gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdánimọ̀ wọn—kì í ṣe ìṣòro fún un. (Jóòbù 12:13; fi wé Aísáyà 40:26.) Ní àfikún sí i, gẹ́gẹ́ bí ìrírí Lásárù ti fi hàn, Jésù Kristi lè jí àwọn òkú dìde, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Fi wé Lúùkù 7:11-17; 8:40-56) Àní, Jésù Kristi wí pé: “Nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [ohùn Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Jèhófà ni yóò ní àjíǹde. Ó ṣe kedere pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọkàn ń kú, àjíǹde sì ni oògùn ikú. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn ló ti wà láàyè rí, tó sì ti kú. Mélòó nínú wọn ló wà nínú ìrántí Ọlọ́run, mélòó nínú wọn ni ìrètí wà pé yóò jíǹde?
18. Àwọn wo ni a óò jí dìde?
18 A óò jí àwọn tí wọ́n ti rìn ní ipa ọ̀nà òdodo gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà dìde. Ṣùgbọ́n, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn mìíràn ni wọ́n ti kú tí wọn kò sì fi hàn bóyá àwọn yóò gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òdodo Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé wọn kò mọ ohun tí Jèhófà ń béèrè tàbí pé àkókò kò tó fún wọn láti ṣe àwọn àyípadà tí ó yẹ kí wọ́n ṣe. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú wà nínú ìrántí Ọlọ́run, nípa bẹ́ẹ̀ a óò jí wọn dìde, nítorí Bíbélì ṣèlérí pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
19. (a) Ìran wo ni àpọ́sítélì Jòhánù rí gbà nípa àjíǹde? (b) Kí ni a fi “sọ̀kò sínú adágún iná,” kí sì ni gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí?
19 Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran amọ́kànyọ̀ kan pé àwọn tí a jí dìde, dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run. Nígbà tó ń ṣàpèjúwe rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:12-14) Ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná! A óò tú gbogbo òkú tí ó wà nínú ìrántí Ọlọ́run sílẹ̀ kúrò nínú Hédíìsì, tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, sàréè gbogbo aráyé. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:31) Lẹ́yìn náà, a óò sọ “ikú àti Hédíìsì” sínú ohun tí a pè ní “adágún iná,” tí ó ṣàpẹẹrẹ ìparun yán-án-yán. Kò ní sí sàréè gbogbo aráyé mọ́.
Ìrètí Àrà Ọ̀tọ̀!
20. Irú àyíká wo ni a óò jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ti kú nísinsìnyí dìde sí?
20 Nígbà tí a bá jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn dìde nígbà àjíǹde, ayé tí ó ṣófo kọ́ ni a máa mú wọn padà wá gbé. (Aísáyà 45:18) Wọn yóò jí sí àyíká ẹlẹ́wà tí a ti mú sunwọ̀n sí i, wọn yóò sì rí i pé a ti pèsè ibùgbé, aṣọ àti ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ dè wọ́n. (Sáàmù 67:6; 72:16; Aísáyà 65:21, 22) Ta ni yóò ṣe gbogbo ìwọ̀nyí sílẹ̀? Dájúdájú, àwọn ènìyàn yóò ti máa gbé nínú ayé tuntun kí àjíǹde ti ilẹ̀ ayé tó bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn wo ni?
21, 22. Ìrètí àrà ọ̀tọ̀ wo ni ó wà níwájú fún àwọn tí ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?
21 Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan yìí.b (2 Tímótì 3:1) Láìpẹ́ sígbà tí a wà yìí, Jèhófà Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn aráyé, yóò sì mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:10, 11; Òwe 2:21, 22) Nígbà yẹn, kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń fi tòótọ́tòótọ́ sin Ọlọ́run?
22 Jèhófà kò ní pa olódodo run pọ̀ mọ́ ẹni burúkú. (Sáàmù 145:20) Kò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ṣe é nígbà tí ó bá fọ ìwà ibi kúrò nínú ayé. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 18:22, 23, 26.) Àní, ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” tí ó jáde wá láti inú “ìpọ́njú ńlá.” (Ìṣípayá 7:9-14) Bẹ́ẹ̀ ni, ògìdìgbó ńláǹlà yóò la ìpọ́njú ńlá já, nínú èyí tí ayé burúkú ìsinsìnyí yóò ti dópin, wọn yóò sì wọnú ayé tuntun Ọlọ́run. Níbẹ̀, aráyé onígbọràn yóò lè jàǹfààní ní kíkún nínú ìpèsè àgbàyanu Ọlọ́run tí yóò tú aráyé sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ìṣípayá 22:1, 2) Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe dandan pé kí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” kú. Ìrètí àrà ọ̀tọ̀ mà lèyí o!
Ìwàláàyè Láìsí Ikú
23, 24. Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe bí o bá fẹ́ gbádùn ìwàláàyè láìkú, nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé?
23 Ìrètí àgbàyanu yìí ha ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé bí? Dájúdájú! Jésù Kristi fúnra rẹ̀ fi hàn pé ìgbà kan yóò wà tí àwọn ènìyàn yóò máa wà láàyè láìní kú láé. Kété kí Jésù tó jí Lásárù, ọ̀rẹ́ rẹ̀, dìde, ó sọ fún Màtá pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.”—Jòhánù 11:26.
24 O ha fẹ́ láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé bí? Ó ha ń yán hànhàn fún pípadà rí àwọn tí o fẹ́ràn lẹ́ẹ̀kan sí i bí? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Àkókò gan-an nìyí fún ọ láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, kí o sì pinnu láti máa ṣe é. Nígbà náà, ìwọ, àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn tí ó ti ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, yóò lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” kò fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kedere ni a sọ ìrètí àjíǹde nínú Jóòbù 14:13, Dáníẹ́lì 12:13, àti Hóséà 13:14.
b Wo Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 98 sí 107, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà gan-an tí a tú sí “ọkàn”?
◻ Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn nígbà ikú?
◻ Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, kí ni oògùn ikú?
◻ Ìrètí àrà ọ̀tọ̀ wo ló ń dúró de àwọn olóòótọ́ lónìí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]
“Ọkàn” Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀mí Ẹ̀dá
Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” lè tọ́ka sí ẹ̀mí tí ènìyàn tàbí ẹranko ní. Èyí kò mú ìyípadà bá ohun tí Bíbélì sọ pé ọkàn jẹ́, ìyẹn ni ènìyàn kan tàbí ẹranko kan. Láti ṣàpèjúwe rẹ̀: A lè sọ pé ẹnì kan wà láàyè, tí ó túmọ̀ sí pé ó jẹ́ alààyè. A sì tún lè sọ pé ẹ̀mí wà nínú rẹ̀. Lọ́nà kan náà, alààyè jẹ́ ọkàn. Síbẹ̀, nígbà tí ó bá wà láàyè, a lè sọ̀rọ̀ nípa “ọkàn” gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó wà nínú rẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Gbogbo ènìyàn tí ń dọdẹ ọkàn rẹ ti kú.” Ní kedere, ṣe ni àwọn ọ̀tá Mósè fẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. (Ẹ́kísódù 4:19; fi wé Jóṣúà 9:24; Òwe 12:10.) Jésù lo ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ó jọra, nígbà tí ó wí pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, . . . kí ó [lè] fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28; fi wé 10:28.) Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” túmọ̀ sí “ẹ̀mí ẹ̀dá.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọkàn ni gbogbo wọn pátá
[Credit Line]
Ẹyẹ akùnyùnmù: U.S. Fish and Wildlife Service, Washington, D.C./Dean Biggins
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jésù fi hàn pé àjíǹde ni oògùn ikú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“Olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè, tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, kì yóò kú láé.” —Jòhánù 11:26