TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓSẸ́FÙ
‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
OJÚ inú wo Jósẹ́fù bí àwọn oníṣòwò ilẹ̀ Mídíà táwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á fún ṣe ń mú un lọ. Ẹ̀bá àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí omi ti ya wọnú odò Náílì ni wọ́n gun àwọn ràkúnmí wọn gbà, wọ́n sì tibẹ̀ kọrí sí ọ̀nà Íjíbítì. Bí wọ́n ṣe ń lọ lọ́nà, afẹ́fẹ́ rọra ń fẹ́ yẹ́ẹ́, àwọn ẹyẹ àkọ̀ àtàwọn ẹyẹ yọnja-yọnja wà létí odò, òórùn àwọn òdòdó sì gba gbogbo inú afẹ́fẹ́. Bí Jósẹ́fù ṣe ń wòye àwọn nǹkan yìí lọ, ọkàn rẹ̀ tún fà sílé. Ó lè máa rántí àwọn ilẹ̀ olókè tó ń bẹ ní Hébúrónì ìlú rẹ̀, àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti rin ọgọ́rọ̀ọ̀rún máìlì kọjá ibẹ̀, wọn sì ti wà ní ìlú míì.
Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jósẹ́fù rí lọ́nà, ó rí àwọn ọ̀bọ tó ń ṣeré lórí igi ọ̀pẹ déètì àtàwọn igi ọ̀pọ̀tọ́. Ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tó ń kọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ èdè wọ́n ṣàjèjì sí i. Ó lè máa gbìyànjú kó lè lóye gbólóhùn bí mélòó kan nínú ohun tí wọ́n ń sọ tàbí kí òun kọ́ èdè wọn. Gbogbo èrò yìí jẹ́ kó rí i pé á ṣòro láti pa dà sílùú òun, ìyẹn tún di ọjọ́ míì ọjọ́ ire.
Jósẹ́fù ò ju ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún tàbí méjìdínlógún lọ lákòókò yìí, síbẹ̀ àgbàlagbà míì ò lè fara da ohun tójú ẹ̀ rí. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń jowú pé Jósẹ́fù ni bàbá àwọn fẹ́ràn jù, wọ́n sì gbìmọ̀ láti pa á. Ọlọ́run ló kó o yọ tí wọ́n fi tà á fáwọn oníṣòwò kan. (Jẹ́nẹ́sísì 37:2, 5, 18-28) Àtìgbà táwọn oníṣòwò náà ti ra Jósẹ́fù ni òun náà ti kò mọ́ ìrìn àjò ọlọ́jọ́ gbọọrọ pẹ̀lú wọn. Ní báyìí tí wọ́n ti sún mọ́ ibi tí wọ́n ń lọ, ó dájú pé àwọn oníṣòwò náà á máa dánú dùn pé àwọn á rí owó gidi táwọn bá ta Jósẹ́fù àtàwọn ẹrù míì táwọn dì dání. Kí ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ tí ìrẹ̀wẹ̀sì ò fi jẹ́ kó kárísọ? Bawo làwa náà ṣe lè ṣe é tí ìdààmú àti ìjákulẹ̀ kò fi ní mú wa rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́? Ẹ jẹ́ ká jọ gbé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù yẹ̀ wò.
“JÈHÓFÀ WÀ PẸ̀LÚ JÓSẸ́FÙ”
Bíbélì sọ pé: “Ní ti Jósẹ́fù, a mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí Íjíbítì, Pọ́tífárì, olórí ẹ̀ṣọ́, òṣìṣẹ́ kan láàfin Fáráò, ará Íjíbítì, sì rà á lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì tí ó mú un sọ̀ kalẹ̀ wá sí ibẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:1) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé wọ́n wọ́ Jósẹ́fù nílẹ̀ gan-an, ńṣe ni wọ́n sọ ọ́ di ọjà àràtúntà! Ní báyìí, ará Íjíbítì tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin Fáráò, ti di ọ̀gá rẹ̀ tuntun. Kò sí ohun tí Jósẹ́fù lè ṣe sí i àfi kó máa bá a lọ sílé.
Ilé tí wọ́n ń mú Jósẹ́fù lọ yàtọ̀ pátápátá sí irú ilé tó ń gbé tẹ́lẹ̀. Ìdílé darandaran ni Jósẹ́fù ti wá, inú àgọ́ sì ni wọ́n máa ń gbé torí wọ́n máa ń ṣí káàkiri ni. Àmọ́ nílẹ̀ Íjíbítì, ilé táwọn ọlọ́lá bíi ti Pọ́tífárì ń gbé sábà máa ń rí rèǹtè-rente. Àwọn awalẹ̀pìtàn sọ pé àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì máa ń ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n á ní ọgbà nínú ilé, wọ́n á tún gbin igi tí wọ́n lè gba atẹ́gùn lábẹ́ rẹ̀, wọ́n máa ń ní odò, wọ́n á sì gbin àwọn ewéko bí òrépèté àti òṣíbàtà sí etí rẹ̀. Àárín ọgbà ni wọ́n ń kọ́ àwọn ilé míì sí, wọ́n á sì ṣe gọ̀bì sí i kí wọ́n lè máa gba atẹ́gùn. Fèrèsé ilé wọn máa ń ga kí atẹ́gùn lè wọlé, wọ́n tún máa ń kọ́ ilé ìjẹun ńlá síbẹ̀, wọ́n á sì yọ yàrá ọ̀tọ̀ fáwọn ìránṣẹ́.
Ǹjẹ́ àwọn ilé arabaríbí yìí jọ Jósẹ́fù lójú bí? Kò jọ bẹ́ẹ̀, torí kò sóhun tó dà bí ilé ẹni àti pé Jósẹ́fù ò rẹ́ni fojú jọ nílùú náà. Ohun gbogbo ló ṣàjèjì sí i, èdè wọn, ìwọṣọ wọn, ìmúra wọn, ẹ̀sìn wọn pàápàá ṣàjèjì sí i. Àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ wọn pọ̀ lọ jàra, wọ́n ń ṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn, wọ́n n pidán, wọ́n ń bá òkú sọ́rọ̀, wọ́n tún ní ìgbàgbọ́ pé èèyàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Àmọ́ Jósẹ́fù ò jẹ́ kí gbogbo èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Bíbélì sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti borí ìdánìkanwà, ó ní: “Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:2) Ó dájú pé nígbà yẹn, Jósẹ́fù ò dákẹ́ àdúrà, gbogbo ìgbà lò ń sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run. Ó ṣe tán, Bíbélì ní: “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.” (Sáàmù 145:18) Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà míì wo ni Jósẹ́fù gbà sún mọ́ Ọlọ́run?
Bí àníyàn Jósẹ́fù ṣe pọ̀ tó, kò jẹ́ kí ọkàn òun pami. Ó fọkàn síṣẹ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ̀, Jèhófà sì fi ìbùkún sí i. Pọ́tífárì rí i pé Jèhófà Ọlọ́run táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń sìn ń wà pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin yìí, òjò ìbùkún rẹ̀ sì ń rọ̀ dé ilé òun. Èyí mú kí Jósẹ́fù di ààyò lójú Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi yàn án ṣe olórí ilé rẹ̀, gbogbo ohun tí ó sì jẹ́ tirẹ̀ ni ó fi lé e lọ́wọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 39:3-6.
Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jósẹ́fù jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ tó ń jọ́sìn Jèhófà lónìí. Bí àpẹẹrẹ, níléèwé, àwọn ọ̀dọ́ lè bá ara wọn ní àyíká tó ṣàjèjì sí wọn, tó kún fún àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì ń ṣayé bó ṣe wù wọ́n. Bó o bá bá ara rẹ ní irú ipò bẹ́ẹ̀, má gbàgbé pé Jèhófà tó wà pẹ̀lú Jósẹ́fù kò yí pa dà. ( Jákọ́bù 1:17) Gbágbáágbá ló máa ń wà lẹ́yìn àwọn tó ń ṣe tirẹ̀ àti gbogbo ẹni tó ń sapá láti ṣòdodo. Ó ń bù kún wọn jìngbìnnì, kò sì ní yọ ìwọ náà sílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì tá à ń bá bọ̀ sọ síwájú sí i pé, ‘Jósẹ́fù di ọkùnrin tó rẹwà, ìrísí rẹ̀ sì dùn ún wò.’ Ọmọ àná ti wá di géńdé báyìí. Àmọ́ wàhálà ńlá ni ẹwà rẹ̀ yìí ṣì ń bọ̀ wá dá sílẹ̀ fún un. Ẹ̀bùn ni ẹwà lóòótọ́, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, àtẹni tá a fẹ́ àtẹni tá ò fẹ́ ló máa ń gbá tọni lẹ́yìn nítorí ẹwà ẹni.
‘KÒ GBÀ FÚN UN RÁRÁ’
Jósẹ́fù pọ́n Pọ́tífárì ọ̀gá rẹ̀ lé gan-an àmọ́ ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ kò pọ́n ọkọ rẹ̀ lé rárá. Bíbélì sọ pé: ‘Aya ọ̀gá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fojú sí Jósẹ́fù lára, ó sì ń wí pé: “Sùn tì mí.”’ (Jẹ́nẹ́sísì 39:7) Ǹjẹ́ Jósẹ́fù gbà fún obìnrin abọ̀rìṣà tó ń fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́ yìí? Bíbélì ò kúkú sọ pé Jósẹ́fù jẹ́ aróbìnrinsá, ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ náà sì fani mọ́ra torí ẹni ọlá tí wọ́n ti fowó kẹ́ ni. Àmọ́ ṣé Jósẹ́fù lè dán irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wò kí ọ̀gá rẹ̀ má mọ̀? Ṣé ó máa tìtorí ọlá àti ìgbádùn ráńpẹ́ fara mọ́ ohun tí obìnrin náà ń fẹ́?
A lè máà mọ gbogbo ohun tí Jósẹ́fù ń rò, ṣùgbọ́n nǹkan tó wà lọ́kàn rẹ̀ hàn kedere nínu ìdáhùn tó fún aya ọ̀gá rẹ̀ yìí, ó ní: “Ọ̀gá mi kò mọ ohun tí ó wà pẹ̀lú mi nínú ilé, ohun gbogbo ni ó sì ti fi sí ọwọ́ mi. Kò sí ẹnì kankan tí ó tóbi jù mí lọ nínú ilé yìí, òun kò sì tíì fawọ́ ohunkóhun sẹ́yìn fún mi, bí kò ṣe ìwọ, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Nítorí náà, báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:8, 9) Bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló sọ yẹn. Èyí fi hàn pé kò tiẹ̀ ronú gba ibi tí aya Pọ́tífárì gbé ọ̀rọ̀ gbà, ohun ìríra ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ lójú rẹ̀.
Ìdí ni pé Jósẹ́fù ti ronú jinlẹ̀ gan-an. Ó mò pé ọ̀gá òun fọkàn tán òun ló ṣe yan òun ṣe olórí nínú ilé rẹ̀, àmọ́ kò fa ìyàwó rẹ̀ lé òun lọ́wọ́. Bí òun bá sùn ti obìnrin yìí pẹ́rẹ́, òun dalẹ̀ ọ̀gá òun nìyẹn. Kò tiẹ̀ fẹ́ gba irú èrò bẹ́ẹ̀ láyè rárá. Ṣùgbọ́n ohun míì tó tún jẹ́ kí nǹkan yẹn kó o nírìíra ni pé kò fẹ́ dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run. Ó dájú pé àwọn òbí rẹ̀ ti sọ ìlànà Ọlọ́run fún un lórí ìgbéyàwó àti ìṣòtítọ́, ó sì gbẹ̀kọ́. Jèhófà ló ṣètò ìgbéyàwó àkọ́kọ́, ó sọ bí òun ṣe fẹ́ kó rí, ó ní ọkọ á fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Díẹ̀ ló kù káwọn tó gbìyànjú láti ta ko ìlànà yìí nígbà àtijọ́ rí ìbínú Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, jàǹbá fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó fẹ́ mú ìyàwó Ábúráhámù ṣaya. Bọ́rọ̀ ṣe rí nínú ọ̀ràn ti ìyàwó Ísákì tó jẹ́ ìyá bàbá Jósẹ́fù náà nìyẹn. Sárà tó jẹ́ ìyàwó Ábúráhámù nígbà náà ni ìyá àgbà Jósẹ́fù. (Jẹ́nẹ́sísì 20:1-3; 26:7-11) Ó ṣeé ṣe kí Jósẹ́fù rántí àwọn ìtàn yẹn, kó sì ti pinnu pé ìlànà yìí ni òun á tẹ̀ lé.
Èsì tí Jósẹ́fù fún ìyàwó Pọ́tífárì yà á lẹ́nu, ọ̀rọ̀ náà sì bá a lójijì. Obìnrin náà lè máa sọ lọ́kàn rẹ̀ pé; ẹ máa wo ọmọdé yìí kẹ̀, ẹrú lásán-làsàn tóun fi kiní lọ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ lófò, tó tún pè é ní “ohun búburú,” ọmọ yìí má wọ́ òun nílẹ̀ o! Ọ̀rọ̀ náà ká a lára torí pé ó jọra rẹ̀ lójú, èyí mú kó pinnu láti mú Jósẹ́fù balẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Ó wá ń ṣe bíi ti Sátánì tó dán Jésù wò títí, tí kò rọ́nà, kàkà tí ì bá fi í lọ́rùn sílẹ̀, Èṣù tún lọ gẹ̀gùn dè é títí di “àkókò mìíràn tí ó wọ̀.” (Lúùkù 4:13) Àfi kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ dúró ṣinṣin yáa múra kó sì wà lójúfò gidigidi. Torí pé ohun tí Jósẹ́fù ṣe nìyẹn tó fi gba ara rẹ̀ sílẹ̀. ‘Ojoojúmọ́’ ni ìyàwó Pọ́tífárì ń fòòró rẹ̀, àmọ́ ‘Jósẹ́fù kò gbà fún un.’ (Jẹ́nẹ́sísì 39:10) Síbẹ̀, obìnrin elétekéte yìí kò dẹ̀yìn lẹ́yìn Jósẹ́fù rárá.
Lọ́jọ́ kan tó rí i pé àwọn èèyàn ò ní sí nílé, tó sì mọ̀ pé Jósẹ́fù máa wá ṣe àmójútó ilé, ó múra dè é. Bí Jósẹ́fù ṣe wọlé ni obìnrin yìí pa kuuru mọ́ ọn, ó dì í lẹ́wù mú, ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí i bẹ̀ ẹ́ pé: “Sùn tì mí!” Jósẹ́fù ò dẹra sílẹ̀, kíá ló já ara ẹ̀ gbà. Àmọ́ obìnrin yìí ò jáwọ́ lára ẹ̀wù Jósẹ́fù, bí Jósẹ́fù ṣe jàjà ráyè díẹ̀ báyìí, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀, ó ta kóró, ó sì fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ!—Jẹ́nẹ́sísì 39:11, 12.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí rán wa létí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Sá fún àgbèrè!” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ẹ ò rí i pé àwòkọ́ṣe ni Jósẹ́fù jẹ́ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ Kristẹni tòótọ́! Nígbà míì, nǹkan lè pa wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kò ka òfin Ọlọ́run sí, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ fi ìyẹn kẹ́wọ́ láti ṣe nǹkan tí ò yẹ. Ká yáa tètè sá kúrò níbẹ̀ láì kọ ohun tó lè yọrí sí.
Ní ti Jósẹ́fù, ìyà ló yọrí sí fún un. Ìyà tó sì jẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí ò ṣeé kó. Ìyàwó Pọ́tífárì ti kanrí Jósẹ́fù mọ́nú pé òun máa gbẹ̀san lára rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kébòòsí, ó ń pe àwọn òṣìṣẹ́ tó kù pé kí wọ́n gba òun o. Ó tún purọ́ pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun sùn lòun ṣe figbe ta. Èyí ló jẹ́ kó sá lọ láì mú ẹ̀wù rẹ̀. Obìnrin yìí ò sọ ẹ̀wù náà sílẹ̀ títí tí ọkọ̀ rẹ̀ fi dé. Nígbà tí ìyẹn dé, ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé Jósẹ́fù fẹ́ fipá bá òun sùn, ó sì dẹ́bi fún ọkọ rẹ̀ pé ká ní kò gba ẹrú burúkú yẹn sílé ni, irú ìyà àti ìwọ̀sí yìí ò ní ta lé òun. Nígbà tí Pọ́tífárì ọkọ rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, “ìbínú rẹ̀ ru”! Kò tiẹ̀ dúró gbọ́ àlàyé tó fi sọ Jósẹ́fù sẹ́wọ̀n.—Jẹ́nẹ́sísì 39:13-20.
‘WỌ́N FI ṢẸKẸ́ṢẸKẸ̀ DE ẸSẸ̀ RẸ̀’
A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí túbú wọn ṣe rí nílẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì. Àmọ́ ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n mọ àwọn ilé náà bí odi gìrìwò, ó sì ní ẹ̀wọ̀n àtàwọn àjàalẹ̀ lóríṣiríṣi. Jósẹ́fù pe túbú náà ní “ihò ẹ̀wọ̀n,” èyí tó fi hàn pé ó jẹ́ ibi tó ṣókùnkùn tó sì ṣòro láti rọ́nà sá lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 40:15) Ìwé Sáàmù tún jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n fìyà jẹ Jósẹ́fù gan-an nínú túbú yẹn, ó ní: ‘Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi irin de ọrùn rẹ̀.’ (Sáàmù 105:17, 18) Nígbà míì, àwọn ará Íjíbítì máa ń fi àwọn ìjàrá de àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́ ní àdè-sẹ́yìn ní ìgbọ̀nwọ́, àwọn míì sì rèé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ onírin ńlá tó dà bí akọ́rọ́ ni wọ́n á fi kọ́ wọn lọ́rùn pa pọ̀ mọ́ra. Ẹ ò rí i pé ìyà ńlá ni Jósẹ́fù jẹ lẹ́wọ̀n, bẹ́ẹ̀ kò mọwọ́ kò mẹsẹ̀!
Kì í ṣe ìgbà díẹ̀ ni Jósẹ́fù fi wà lẹ́wọ̀n yẹn o. Bíbélì sọ pé Jósẹ́fù “ń bá a lọ láti wà níbẹ̀ nínú ilé ẹ̀wọ̀n” náà, tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọdún ló lò nínú ẹ̀wọ̀n burúkú yẹn.a Wọn ò dá ọjọ́ tàbí ìgbà kankan fún un tí wọ́n á tú u sílẹ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọjọ́ ń gorí ọjọ́, ọ̀sẹ̀ ń yí lu ọ̀sẹ̀, oṣù ń yí lu oṣù. Síbẹ̀, Jósẹ́fù ò kárísọ, kò sì sọ̀rètí nù, báwo ló ṣe ṣe é?
Bíbélì dá wa lóhùn pé: “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:21) Ọkàn àwa ìránṣẹ́ Jèhófà náà balẹ̀ pé ì báà jẹ́ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wá mọ́ àbí inú àjàalẹ̀ lọ́hùn-ún, Jèhófà á nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí wa ṣáá ni. (Róòmù 8:38, 39) Ó dájú pé irú ìgbọ́kànlé tí Jósẹ́fù náà ní nìyẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tí ẹ̀dùn ọkàn fẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó ké gbàjarè sí Baba rẹ̀ ọ̀run nínú àdúrà, àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó ti ọ̀dọ̀ “Ọlọ́run ìtùnú” wá sì tù ú lára. (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; Fílípì 4:6, 7) Jèhófà tún ṣe nǹkan míì fún Jósẹ́fù, ó yọ̀ǹda fún Jósẹ́fù láti rí “ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n” náà.
Ṣé ẹ mọ̀ pé gbogbo ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n máa ń yanṣẹ́ fún, torí náà, Jósẹ́fù tẹra mọ́ṣẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Gbogbo ohun tí wọ́n ní kó ṣe ló ṣe, ó sì fi èyí tó kù sọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá. Kò pẹ́ rárá tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́wọ́ ìbùkún Jèhófà lára rẹ̀, nígbẹ̀yìn Jósẹ́fù di ẹni pàtàkì láàárín wọn níbẹ̀ gẹ́lẹ́ bó ṣe rí nígbà tó wà nínú ilé Pọ́tífárì. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n náà fi gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀wọ̀n lé Jósẹ́fù lọ́wọ́; gbogbo ohun tí wọ́n bá sì ń ṣe níbẹ̀, òun ni ń mú kí ó di ṣíṣe. Ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n náà kò bojú wo nǹkan kan tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ rárá, nítorí pé Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ohun tí ó sì ń ṣe ni Jèhófà ń mú kí ó yọrí sí rere.” (Jẹ́nẹ́sísì 39:22, 23) Ẹ ò rí i pé ìtùnú ńlá ni èyí jẹ́ fún Jósẹ́fù, pàápàá bí Jèhófà ṣe bójú tó o!
Nǹkan lè yí pa dà bìrí fún wa nínú ayé Èṣù yìí, àwọn èèyàn lè fọwọ́ ọlá gbá wa lójú tàbí kí wọ́n ṣe àìdáa sí wa, tá ò sí ní lè ṣe nǹkan kan sí i, àmọ́ a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù. Tá ò bá dákẹ́ àdúrà, tá à ń pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́, tá a sì ń sapá láti ṣe ohun to dáa lójú rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run wa kò ní fi wá sílẹ̀, á sì rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí wa. Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó máa jáde lọ́jọ́ iwájú, a máa rí bí Jèhófà ṣe bù kún Jósẹ́fù lọ́nà tó gadabú.
a Bíbélì jẹ́ ká mò pé Jósẹ́fù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tàbí méjìdínlógún [18] nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé lọ́dọ̀ Pọ́tífárì, ibẹ̀ ló wà fúngbà díẹ̀ tó fi dàgbà. Àmọ́ igbà tó máa fi jáde lẹ́wọ̀n, ó ti pé ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún.—Jẹ́nẹ́sísì 37:2; 39:6; 41:46
Jósẹ́fù tẹra mọ́ṣẹ́ nínú ẹ̀wọ̀n, Jèhófà sì bù kún un
[DO NOT SET]