Ìdí Tí Jèhófà Tó Jẹ́ Alákòóso Tún Fi Gbé Ìjọba Kan Kalẹ̀
“Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì . . . Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà.”—1 KÍRÓNÍKÀ 29:11.
1. Kí nìdí tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Alákòóso láyé àtọ̀run?
“JÈHÓFÀ tìkára rẹ̀ ti fìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in ní ọ̀run gan-an; àkóso rẹ̀ sì ń jọba lórí ohun gbogbo.” (Sáàmù 103:19) Ọ̀rọ̀ tẹ́ni tó kọ sáàmù yìí sọ jẹ́ ká rí ohun tí ìṣàkóso túmọ̀ sí ní ti gidi. Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Alákòóso láyé àtọ̀run.
2. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe ibi táwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé tí Jèhófà ti ń ṣàkóso?
2 Ó dájú pé ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ alákòóso, ó gbọ́dọ̀ láwọn tó ń ṣàkóso lé lórí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà ti ń ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó dá. Àkọ́kọ́ lára wọn ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹ̀yìn náà ló wá kan ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì. (Kólósè 1:15-17) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn èyí ni Ọlọ́run fi ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run han Dáníẹ́lì. Ó wá kọ̀wé pé: “Mo ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé sì jókòó. . . . Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.” (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Àìmọye ọdún ni Jèhófà tó jẹ́ “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé” ti ń ṣàkóso lórí ìdílé rẹ̀ tó tóbi lọ́nà kíkàmàmà tó sì wà létòlétò gan-an, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí í ṣe ọmọ rẹ̀, tí wọ́n ń sìn gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́” tó ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 103:20, 21.
3. Báwo ni ìṣàkóso Jèhófà ṣe nasẹ̀ dé ọ̀run tó fẹ̀ lọ salalu, títí kan ilẹ̀ ayé?
3 Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà mú kí ibi tóun ń ṣàkóso lé lórí gbòòrò sí i nípa dídá ọ̀run tó fẹ̀ lọ salalu tó sì jẹ́ àgbàyanu, títí kan ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:4, 7) Téèyàn bá ń wo oòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run látorí ilẹ̀ ayé, wọ́n wà létòlétò gan-an wọ́n sì ń báṣẹ́ lọ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí débi pé, ńṣe ló dà bíi pé wọn ò nílò ẹnì kankan láti máa darí wọn tàbí láti máa ṣàkóso wọn. Síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù sọ pé: “[Jèhófà] fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn. Ó sì mú kí wọ́n dúró títí láé, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ó ti fún wọn ní ìlànà, èyí tí kì yóò sì ré kọjá.” (Sáàmù 148:5, 6) Kò sígbà kan tí Jèhófà kì í ṣe alákòóso. Ó ń darí ohun tó ń lọ níbi táwọn ẹni ẹ̀mí ń gbé, àti ní ọ̀run tó fẹ̀ lọ salalu, títí kan ilẹ̀ ayé níbi, ó ń fún wọn ní ìlànà, ó sì ń ṣàkóso wọn.—Nehemáyà 9:6.
4. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń ṣàkóso lórí ẹ̀dá èèyàn?
4 Nígbà tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó fi ọ̀nà mìíràn tóun ń gbà ṣàkóso hàn. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà pèsè gbogbo ohun tí ẹ̀dá èèyàn nílò fún wọn kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé tó dára gan-an tó sì dùn bí oyin, ó tún fún wọn láṣẹ láti máa ṣàkóso lórí àwọn ẹ̀dá tó rẹlẹ̀ sí wọn lórí ilẹ̀ ayé, tó túmọ̀ sí pé ó fún àwọn náà lágbára lórí àwọn nǹkan kan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:8, 9) Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé yàtọ̀ sí pé ìṣàkóso Ọlọ́run dára ó sì ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní, ó tún ń buyì kún àwọn tó ń jọba lé lórí. Ká ní pé Ádámù àti Éfà jẹ́ kí Jèhófà máa ṣàkóso àwọn lọ ni, wọn ì bá máa gbé lórí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ Párádísè títí láé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17.
5. Kí la lè sọ nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso?
5 Kí la lè fà yọ nínú gbogbo ohun tá a ti sọ yìí? Ohun àkọ́kọ́ ni pé, kò sígbà kan tí Jèhófà kì í ṣe alákòóso lórí gbogbo ohun tó dá. Èkejì ni pé, ọ̀nà tó dára gan-an ni Ọlọ́run ń gbà ṣàkóso, ìṣàkóso rẹ̀ sì ń buyì kún àwọn tó ń jọba lé lórí. Ẹ̀kẹta sì ni pé, tá a bá gbà kí Ọlọ́run máa ṣàkóso wa tá a sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀, a ó láyọ̀ títí ayé. Abájọ tí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fi sọ pé: “Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì; nítorí ohun gbogbo tí ó wà ní ọ̀run àti ní ilẹ̀ ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo.”—1 Kíróníkà 29:11.
Kí Nìdí Tá A Tún Fi Nílò Ìjọba Ọlọ́run?
6. Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ alákòóso, kí nìdí tó tún fi gbé Ìjọba kan kalẹ̀?
6 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sígbà kan tí Jèhófà, Alákòóso Ayé Àtọ̀run, kò lo agbára rẹ̀ láti ṣàkóso àwọn ohun tó dá, kí nìdí tá a tún fi nílò Ìjọba Ọlọ́run? Àwọn ọba sábà máa ń lẹ́ni tó ń ṣojú fún wọn lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ń jọba lé lórí. Nítorí náà, Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ń lò láti fi hàn pé òun ni alákòóso lórí àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ láyé àtọ̀run.
7. Kí nìdí tí Jèhófà fi gbé ọ̀nà tuntun kalẹ̀ láti fi máa ṣàkóso?
7 Jèhófà ti lo onírúurú ọ̀nà tó yàtọ̀ síra láti ṣàkóso láwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó tún wá gbé ọ̀nà tuntun kan kálẹ̀ nítorí ohun kan tó ṣẹlẹ̀. Èyí wáyé nígbà tí ọmọ Ọlọ́run kan tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí, ìyẹn Sátánì, di ọlọ̀tẹ̀ tó sì mú kí Ádámù àti Éfà kọ ìṣàkóso Jèhófà sílẹ̀. Ọ̀tẹ̀ yìí fi hàn pé wọ́n ta ko ìṣàkóso Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Nígbà tí Sátánì sọ fún Éfà pé kì ‘yóò kú’ tó bá jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé Jèhófà kò sọ òótọ́ fún Éfà, pé Jèhófà kì í ṣe ẹni tí wọ́n lè fọkàn tán. Sátánì tún sọ fún Éfà pé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Sátánì ń tipa báyìí sọ fún Ádámù àti Éfà pé nǹkan á túbọ̀ dára fún wọn tí wọn ò bá tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń dá ṣèpinnu fúnra wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ìyẹn fi hàn pé ó dìídì ta ko ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso. Kí ni Jèhófà wá ṣe?
8, 9. (a) Ọ̀nà wo ni ọba kan tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn yóò gbà yanjú ọ̀tẹ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ níbi tó ń ṣàkóso lé lórí? (b) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí ọ̀tẹ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì?
8 Kí la retí pé ọba kan yóò ṣe táwọn kan bá mọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí àṣẹ rẹ̀ lágbègbè tó ń ṣàkóso lé lórí? Àwọn tó mọ ìtàn dáadáa yóò rántí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Dípò kí ọba náà fojú pa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rẹ́, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ ọba rere, lọ́pọ̀ ìgbà ohun tí yóò ṣe ni pé, yóò ṣèdájọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pé wọ́n jẹ̀bi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀-síjọba. Ọba náà lè wá yan ẹnì kan, kó fún un láṣẹ láti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, kó sì mú kí àlàáfíà padà wà lágbègbè náà. Irú ohun tí Jèhófà ṣe nìyí láti fi hàn pé òun lágbára láti kápá ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì nígbà tó yára gbé ìgbésẹ̀ tó sì ṣèdájọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà. Ó sọ pé Ádámù àti Éfà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì lé wọn kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19, 22-24.
9 Nígbà tí Jèhófà ṣèdájọ́ fún Sátánì, ó mẹ́nu kan ọ̀nà tuntun tóun máa gbà ṣàkóso, ìyẹn ọ̀nà tó máa gbà dá àlàáfíà padà sí gbogbo ibi tó ń ṣàkóso lé lórí. Ọlọ́run sọ fún Sátánì pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Jèhófà tipa báyìí fi hàn pé òun yóò fún “irú ọmọ” kan lágbára láti pa Sátánì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run, òun á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ìṣàkóso òun ló tọ̀nà.—Sáàmù 2:7-9; 110:1, 2.
10. (a) Ta ni “irú-ọmọ” náà wá jẹ́? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́?
10 Jésù Kristi ló wá di “irú-ọmọ” yẹn, pẹ̀lú àwọn kan tí Ọlọ́run yà sọ́tọ̀ tí wọn yóò bá Jésù ṣàkóso. Gbogbo wọn para pọ̀ jẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Mèsáyà yóò ṣàkóso. (Dáníẹ́lì 7:13, 14, 27; Mátíù 19:28; Lúùkù 12:32; 22:28-30) Àmọ́ Ọlọ́run kò ṣí gbogbo nǹkan wọ̀nyí payá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kódà “àṣírí ọlọ́wọ̀ tí a ti pa mọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tipẹ́tipẹ́” ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ yìí jẹ́. (Róòmù 16:25) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn ọkùnrin tí wọ́n nígbàgbọ́ gan-an fi ń retí ìgbà tí Ọlọ́run yóò ṣí “àṣírí ọlọ́wọ̀” yìí payá tí àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ yẹn yóò sì nímùúṣẹ, èyí tó máa fi hàn pé lóòótọ́, Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso.—Róòmù 8:19-21.
Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣí “Àṣírí Ọlọ́wọ̀” Náà Payá Díẹ̀díẹ̀
11. Kí ni Jèhófà ṣí payá fún Ábúráhámù?
11 Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ káwọn èèyàn mọ onírúurú ohun tó so mọ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba Ọlọ́run.” (Máàkù 4:11) Lára àwọn tí Jèhófà sọ ọ́ di mímọ̀ fún ni Ábúráhámù, tí Bíbélì pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Jákọ́bù 2:23) Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun yóò sọ ọ́ di “orílẹ̀-èdè ńlá.” Nígbà tó yá, Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Àwọn ọba yóò sì ti inú rẹ jáde wá” àti pé “nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:2, 3; 17:6; 22:17, 18.
12. Báwo ni irú-ọmọ Sátánì ṣe fi ara rẹ̀ hàn lẹ́yìn Ìkún-omi?
12 Nígbà ayé Ábúráhámù, àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá ọ̀nà tí wọ́n á fi máa ṣàkóso ara wọn tí wọ́n á sì máa jẹ gàba lé ara wọn lórí. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Bíbélì sọ nípa Nímírọ́dù tí ọmọ ọmọ Nóà bí ni pé: “Òun ni ó bẹ̀rẹ̀ dídi alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé. Ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:8, 9) Èyí fi hàn wá kedere pé irinṣẹ́ Èṣù ni Nímírọ́dù àtàwọn mìíràn tí wọ́n sọra wọn di alákòóso. Àwọn pẹ̀lú àwọn alátìlẹyìn wọn di apá kan irú-ọmọ Sátánì.—1 Jòhánù 5:19.
13. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà sọ nípasẹ̀ Jékọ́bù?
13 Pẹ̀lú gbogbo bí Sátánì ṣe ń sapá láti máa sọ àwọn èèyàn di alákòóso, Jèhófà kò dáwọ́ ohun tó pinnu láti ṣe dúró. Jèhófà tipasẹ̀ Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ọmọ Ábúráhámù sọ pé: “Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 49:10) Ọ̀rọ̀ náà, “Ṣílò” túmọ̀ sí “Oní-ǹkan tàbí Ẹni Tó Tọ́ Sí.” Nípa báyìí, àwọn gbólóhùn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi hàn pé ẹnì kan yóò dé tí yóò ní ẹ̀tọ́ láti gba “ọ̀pá aládé” tàbí ìṣàkóso, àti “ọ̀pá àṣẹ” tàbí ìjọba, lórí “àwọn ènìyàn” tàbí gbogbo ayé. Tá ni Ẹni yẹn yóò jẹ́?
“Títí Ṣílò Yóò Fi Dé”
14. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Dáfídì dá?
14 Nínú gbogbo àtọmọdọ́mọ Júdà, ẹni àkọ́kọ́ tí Jèhófà yàn láti jẹ́ ọba lórí àwọn èèyàn rẹ̀ ni Dáfídì tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó sì jẹ́ ọmọ Jésè.a (1 Sámúẹ́lì 16:1-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tó sì ṣàṣìṣe, ó rí ojú rere Jèhófà nítorí pé ó ti ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn. Jèhófà jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó sọ lọ́gbà Édẹ́nì túbọ̀ ṣe kedere nígbà tó bá Dáfídì dá Májẹ̀mú. Ó sọ fún un pé: “Èmi yóò gbé irú-ọmọ rẹ dìde lẹ́yìn rẹ dájúdájú, tí yóò jáde wá láti ìhà inú rẹ; ní tòótọ́, èmi yóò fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” Èyí kò mọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì tó gorí ìtẹ́ lẹ́yìn rẹ̀, nítorí pé májẹ̀mú náà sọ pé: “Èmi yóò fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá fi hàn kedere pé “irú-ọmọ” tó ṣèlérí pé yóò jẹ́ alákòóso Ìjọba náà yóò wá látinú ìran Dáfídì nígbà tí àkókò bá tó.—2 Sámúẹ́lì 7:12, 13.
15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìjọba Júdà ń ṣàpẹẹrẹ Ìjọba Ọlọ́run?
15 Dáfídì lẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ọba tí olórí àlùfáà fàmì òróró yàn. Ìdí èyí la fi lè pe àwọn ọba wọ̀nyí ní àwọn ẹni àmì òróró tàbí mèsáyà. (1 Sámúẹ́lì 16:13; 2 Sámúẹ́lì 2:4; 5:3; 1 Àwọn Ọba 1:39) Bíbélì sọ pé wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Jèhófà wọ́n sì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. (2 Kíróníkà 9:8) Lọ́nà yìí, ìjọba Júdà ṣojú fún Ìjọba Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ṣàkóso.
16. Kí ló jẹ́ àbájáde ìṣàkóso àwọn ọba ilẹ̀ Júdà?
16 Nígbà táwọn ọba àtàwọn èèyàn wọ̀nyẹn bá fara mọ́ ìṣàkóso Jèhófà, wọ́n máa ń rí ààbò rẹ̀ àti ìbùkún rẹ̀. Ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ni àlàáfíà àti aásìkí tiẹ̀ pọ̀ kọjá sísọ, èyí sì jẹ́ àpẹẹrẹ bí nǹkan ṣe máa rí lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí Sátánì kò ní lè ṣe ohunkóhun mọ́, táá sì hàn gbangba pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso. (1 Àwọn Ọba 4:20, 25) Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó jẹ́ ọba ní ìran Dáfídì ni kò ṣe ohun tí Jèhófà sọ, àwọn èèyàn wọn sì di abọ̀rìṣà àti oníṣekúṣe. Níkẹyìn, Jèhófà jẹ́ káwọn ará Bábílónì pa ìjọba náà run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó wá dà bíi pé gbogbo ìsapá Sátánì láti fi hàn pé ìṣàkóso Jèhófà kò dára rárá ti kẹ́sẹ járí.
17. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá pa ìjọba Dáfídì run, kí ló fi hàn pé Jèhófà ló ṣì ń ṣàkóso?
17 Pípa tí wọ́n pa ìjọba Dáfídì run, tí ìjọba àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì sì ti kọ́kọ́ pa run ṣáájú ìgbà yẹn, kì í ṣe ẹ̀rí pé ìṣàkóso Jèhófà kùnà tàbí pé kò kúnjú ìwọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi hàn pé ohun búburú ló jẹ́ àbájáde ipa tí Sátánì ní lórí àwọn èèyàn àti kíkọ̀ táwọn èèyàn kọ̀ láti jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí wọn. (Òwe 16:25; Jeremáyà 10:23) Láti fi hàn pé Jèhófà ṣì ń ṣàkóso, ó kéde nípasẹ̀ wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé: “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò. . . . Rírun, rírun, rírun ni èmi yóò run ún. Ní ti èyí pẹ̀lú, dájúdájú, kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.” (Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí, ìyẹn Ẹni “tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
18. Kí ni áńgẹ́lì tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà?
18 Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì sí Màríà wúńdíá tó ń gbé ní Násárétì tó jẹ́ ìlú kan ní Gálílì, tó wà ní àríwá ilẹ̀ Palẹ́sìnì. Áńgẹ́lì yìí sọ fún Màríà pé: “Wò ó! ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Lúùkù 1:31-33.
19. Àkókò ohun àgbàyanu wo ló sún mọ́lé?
19 Níkẹyìn, àkókò tí Ọlọ́run máa ṣí “àṣírí ọlọ́wọ̀” yẹn payá wá sún mọ́lé. Ẹni tó jẹ́ olórí lára “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn kò ní pẹ́ fara hàn mọ́. (Gálátíà 4:4; 1 Tímótì 3:16) Sátánì yóò pa á ní gìgísẹ̀. Àmọ́ “irú ọmọ” yẹn yóò pa Sátánì ní orí nípa mímú òun àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ kúrò. Yóò tún jẹ́rìí pé Ìjọba Ọlọ́run ni Ọlọ́run yóò lò láti mú gbogbo aburú tí Sátánì ti dá sílẹ̀ kúrò yóò sì jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso. (Hébérù 2:14; 1 Jòhánù 3:8) Ọ̀nà wo ni Jésù yóò gbà ṣe èyí? Àpẹẹrẹ wo ló fi lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé? A ó rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Látinú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni Sọ́ọ̀lù, ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ yàn láti ṣàkóso lórí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti wá.—1 Sámúẹ́lì 9:15, 16; 10:1.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Alákòóso láyé àtọ̀run?
• Kí nìdí tí Jèhófà fi pinnu láti gbé Ìjọba kan kalẹ̀?
• Báwo ni Jèhófà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí “àṣírí ọlọ́wọ̀” náà payá díẹ̀díẹ̀?
• Kí ló fi hàn pé Jèhófà ló ṣì ń ṣàkóso bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá pa ìjọba Dáfídì run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jèhófà sọ nípasẹ̀ Ábúráhámù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kí nìdí tí pípa táwọn ọ̀tá pa ìjọba Dáfídì run kò fi túmọ̀ sí pé ìṣàkóso Jèhófà kùnà?