ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9
Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nílẹ̀ Ísírẹ́lì Àtijọ́ (Apá Kìíní Nínú Mẹ́rin)
“Òun jẹ́ olùfẹ́ òdodo àti ìdájọ́ òdodo. Ilẹ̀ ayé kún fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.”—SM. 33:5.
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. (a) Kí ni gbogbo wa fẹ́? (b) Kí lohun kan tó dá wa lójú?
GBOGBO wa la fẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ kí wọ́n rẹ́ wa jẹ. Inú wa kì í dùn táwọn èèyàn ò bá rí tiwa rò tàbí tí wọ́n fọwọ́ ọlá gbá wa lójú, kódà ó lè ṣe wá bíi pé a ò wúlò.
2 Jèhófà mọ̀ pé ó máa ń wù wá pé káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa, kí wọ́n má sì fi ẹ̀tọ́ wa dù wá. (Sm. 33:5) Ohun kan tó dájú ni pé Baba wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kò sì fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ẹ̀tọ́ wa dù wá. Èèyàn á rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí téèyàn bá fara balẹ̀ wo Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè. Torí náà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sẹ́ni tó rí tìẹ rò tàbí tí ọkàn ẹ bá ń gbọgbẹ́ nítorí ìwà àìdáa táwọn èèyàn hù sí ẹ, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàyẹ̀wò Òfin Mósè,b wàá sì rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀ gan-an.
3. (a) Bí Róòmù 13:8-10 ṣe sọ, kí la máa rí kọ́ tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Òfin Mósè? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Òfin Mósè, a máa rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Ka Róòmù 13:8-10.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa ṣàyẹ̀wò mélòó kan lára àwọn òfin náà, àá sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí: Kí nìdí tá a fi sọ pé ìfẹ́ ni Òfin Mósè dá lé? Kí nìdí tá a fi sọ pé Òfin náà ń rọ àwọn èèyàn láti máa ṣèdájọ́ òdodo? Báwo ló ṣe yẹ káwọn tó wà nípò àṣẹ máa lo Òfin náà tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀rọ̀? Paríparí rẹ̀, àwọn wo gan-an ni Òfin náà dáàbò bò? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí máa tù wá nínú, á mú kí ọkàn wa balẹ̀, á sì jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́.—Ìṣe 17:27; Róòmù 15:4.
ÌFẸ́ NI ÒFIN MÓSÈ DÁ LÉ
4. (a) Kí nìdí tá a fi sọ pé ìfẹ́ ni Òfin Mósè dá lé? (b) Òfin wo ni Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì bó ṣe wà nínú Mátíù 22:36-40?
4 A lè sọ pé ìfẹ́ ni Òfin Mósè dá lé torí pé Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Bí àpẹẹrẹ, àṣẹ méjì péré ni gbogbo òfin náà rọ̀ mọ́, ìyẹn ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa. (Léf. 19:18; Diu. 6:5; ka Mátíù 22:36-40.) Torí náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òfin yẹn ló gbé ìfẹ́ Jèhófà yọ lọ́nà kan tàbí òmíì. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò.
5-6. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya ṣe, kí ló sì ń kíyè sí? Sọ àpẹẹrẹ kan.
5 Jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ, kẹ́ ẹ sì bójú tó àwọn ọmọ yín. Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya nífẹ̀ẹ́ ara wọn débi pé wọ́n á ṣera wọn lọ́kan, wọn ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun yà wọ́n. (Jẹ́n. 2:24; Mát. 19:3-6) Ìwà ìkà gbáà ni tí ẹnikẹ́ni nínú wọn bá ṣe àgbèrè, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò sì fi ìfẹ́ hàn. Abájọ tí òfin keje fi pa á láṣẹ pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè. (Diu. 5:18) Ṣe lẹni tó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ “dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run,” ọ̀dàlẹ̀ sì ni. (Jẹ́n. 39:7-9) Ẹ wo bí irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣe máa dun ẹnì kejì rẹ̀ tó. Ohun kan sì ni pé ọgbẹ́ tírú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń dá síni lọ́kàn kì í tètè jinná.
6 Jèhófà máa ń kíyè sí bí àwọn tọkọtaya ṣe ń ṣe síra wọn. Bí àpẹẹrẹ, láyé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ọkọ kò gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ìyàwó wọn. Ọkọ tó ń tẹ̀ lé Òfin Ọlọ́run máa nífẹ̀ẹ́ ìyàwó rẹ̀ dénú, kò sì ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀ torí àwọn ẹ̀sùn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. (Diu. 24:1-4; Mát. 19:3, 8) Tí ìyàwó rẹ̀ bá tiẹ̀ ṣe ohun tó burú gan-an, tó sì fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó gbọ́dọ̀ jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún un. Torí pé ó jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún un, wọn ò ní lè fẹ̀sùn kan obìnrin náà pé oníṣekúṣe ni tó bá fẹ́ ọkùnrin míì. Bákan náà, kí ọkọ kan tó lè já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún ìyàwó rẹ̀, ó máa ní láti lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà ìlú. Nípa bẹ́ẹ̀, á ṣeé ṣe fún wọn láti dá sí ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n sì bá wọn yanjú ìṣòro tí wọ́n ní. Jèhófà kì í sábà dá sí i tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà àìtọ́. Bó ti wù kó rí, Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó rí omijé obìnrin náà, ó sì mọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ lára.—Mál. 2:13-16.
7-8. (a) Kí ni Jèhófà pa láṣẹ pé kí àwọn òbí ṣe? (Wo àwòrán iwájú ìwé.) (b) Kí la rí kọ́?
7 Òfin Mósè tún jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé gan-an, kò sì fẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún àwọn òbí pé kí wọ́n pèsè ohun tí àwọn ọmọ wọn nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní Òfin Ọlọ́run, kí wọ́n sì mú káwọn ọmọ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Diu. 6:6-9; 7:13) Ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé wọ́n hùwà ìkà tí kò ṣeé gbọ́ sétí sáwọn ọmọ wọn. (Jer. 7:31, 33) Àwọn ọmọ ṣeyebíye ju dúkìá lọ, torí náà ojú gidi ni Jèhófà fẹ́ káwọn òbí fi máa wo àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì mọyì wọn torí pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n.—Sm. 127:3.
8 Ohun tá a rí kọ́: Jèhófà máa ń kíyè sí báwọn tọkọtaya ṣe ń ṣe síra wọn. Ó fẹ́ káwọn òbí nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì máa jíhìn fún Ọlọ́run tí wọn ò bá bójú tó àwọn ọmọ wọn bó ṣe yẹ.
9-11. Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò?
9 Má ṣojúkòkòrò. Òfin kẹwàá pa á láṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò, ká má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa máa fà sí nǹkan àwọn míì. (Diu. 5:21; Róòmù 7:7) Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan ni Jèhófà fi òfin yẹn kọ́ àwa èèyàn rẹ̀, ó fẹ́ ká kíyè sí ohun tá à ń rò àti ohun tí ọkàn wa ń fà sí. Ó mọ̀ pé èròkerò ló máa ń mú kéèyàn hu ìwàkiwà. (Òwe 4:23) Bí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá gba èròkerò láyè, ó ṣeé ṣe kó hùwà tó máa pa àwọn míì lára. Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe irú ẹ̀ ni Ọba Dáfídì. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé èèyàn dáadáa ni Dáfídì, àmọ́ ìgbà kan wà tó ṣojúkòkòrò ìyàwó oníyàwó. Ojúkòkòrò yẹn mú kó dẹ́ṣẹ̀, ó bá obìnrin náà ṣàgbèrè, ọ̀rọ̀ náà sì doyún. (Ják. 1:14, 15) Dáfídì wá gbìyànjú láti ti oyún náà sọ́rùn ọkọ rẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó pa ọkọ obìnrin yẹn.—2 Sám. 11:2-4; 12:7-11.
10 Jèhófà máa ń mọ̀ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ṣojúkòkòrò, ó ṣe tán Ọba arínúróde ni, ó sì mọ ohun tá à ń rò lọ́kàn. (1 Kíró. 28:9) Ṣe ni Òfin Ọlọ́run tó sọ pé ká má ṣojúkòkòrò ń mú ká yẹra fún èrò tó lè mú ká hùwàkiwà. Ó ṣe kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ọgbọ́n rẹ̀ kò sì láfiwé!
11 Ohun tá a rí kọ́: Kì í ṣe bá a ṣe rí lóde nìkan ni Jèhófà ń rí, ó tún mọ ẹni tá a jẹ́ nínú, ó sì mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. (1 Sám. 16:7) Torí náà, kò sóhun tẹ́nì kan ń rò tàbí tó ń ṣe tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Bó ti wù kó rí, ibi tá a dáa sí ni Jèhófà ń wò. Àmọ́, ó fẹ́ ká kíyè sí ibi tá a kù sí àti ohun tá à ń rò, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ àá kó sínú ẹ̀ṣẹ̀.—2 Kíró. 16:9; Mát. 5:27-30.
ÒFIN TÓ GBÉ ÌDÁJỌ́ ÒDODO LÁRUGẸ
12. Kí ni Òfin Mósè mú kó ṣe kedere?
12 Òfin Mósè tún jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. (Sm. 37:28; Aísá. 61:8) Jèhófà kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe lè máa bára wọn gbé láìsí ìrẹ́jẹ, ó sì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wọn. Tí wọ́n bá pa àwọn òfin yẹn mọ́, Jèhófà máa ń bù kún wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá tẹ ìlànà òdodo Ọlọ́run lójú, wọ́n máa ń jìyà ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì míì yẹ̀ wò nínú àwọn Òfin Mẹ́wàá náà.
13-14. Kí ni òfin méjì àkọ́kọ́ pa láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àǹfààní wo ni wọ́n máa rí tí wọ́n bá pa òfin yẹn mọ́?
13 Jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo. Òfin méjì àkọ́kọ́ sọ pé Jèhófà nìkan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn, ó sì kìlọ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ bọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-6) Kì í ṣe Jèhófà ni òfin yẹn ṣe láǹfààní, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ló máa jàǹfààní tí wọ́n bá pa òfin náà mọ́. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá pa òfin yẹn mọ́, wọ́n máa ń rí ìbùkún Ọlọ́run. Àmọ́ tí wọ́n bá bọ̀rìṣà, nǹkan máa ń burú fún wọn.
14 Àpẹẹrẹ kan ni tàwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n jẹ́ abọgi-bọ̀pẹ. Àbí kí ni ká ti gbọ́ pé èèyàn fọwọ́ ara rẹ̀ gbẹ́ igi lére, ó sì tún ń forí balẹ̀ fún un. (Sm. 115:4-8) Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn wọn ni ìṣekúṣe, wọ́n sì tún máa ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ. Ohun kan náà làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì ń bọ̀rìṣà, ìyẹn sì mú kí wọ́n hùwà ìkà sí ìdílé wọn. (2 Kíró. 28:1-4) Àwọn aṣáájú nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ fọwọ́ rọ́ ìlànà òdodo Jèhófà tì. Wọ́n ń ṣi agbára wọn lò, wọ́n ń fọwọ́ ọlá gbá àwọn aláìní lójú, wọ́n sì fojú pọ́n àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. (Ìsík. 34:1-4) Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé òun máa fìyà jẹ wọ́n tí wọ́n bá fojú pọ́n àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. (Diu. 10:17, 18; 27:19) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà máa ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n bá pa òfin rẹ̀ mọ́ tí wọ́n sì ń ṣèdájọ́ òdodo.—1 Ọba 10:4-9.
15. Kí la rí kọ́ nípa Jèhófà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo?
15 Ohun tá a rí kọ́: A ò lè dá Jèhófà lẹ́bi tí àwọn tó wà nípò àṣẹ bá ń tẹ òfin lójú, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn ọmọ abẹ́ wọn. Àmọ́ o, Jèhófà ń kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, kò fọ̀rọ̀ wa ṣeré, ó sì mọ̀ ọ́n lára tá a bá ń jìyà. Ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lọ́kàn gan-an, kódà ó ju ti abiyamọ kan tó tatí were nígbà tó gbọ́ ẹkún ọmọ rẹ̀. (Aísá. 49:15) Ó lè má dá sọ́rọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ bópẹ́ bóyá, á dá sí i, gbogbo àwọn ẹni ibi tí kò ronú pìwà dà ló sì máa jẹ iyán wọn níṣu.
BÍ WỌ́N ṢE Ń BÓJÚ TÓ ẸJỌ́
16-18. Báwo ni Òfin Mósè ṣe gbòòrò tó, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa?
16 Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo apá ìgbésí ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Òfin Mósè kàn, torí náà ó ṣe pàtàkì kí àwọn tó ń bójú tó ẹjọ́ máa lo ìlànà Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ ṣèdájọ́. Yàtọ̀ sí pé kí wọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìjọsìn, ojúṣe wọn tún ni láti bójú tó èdèkòyédè tó bá wáyé àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ mélòó kan.
17 Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá pààyàn, wọn ò kàn ní pa òun náà láìdúró gbẹ́jọ́. Àwọn àgbààgbà ìlú máa wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa kí wọ́n tó pinnu bóyá kí wọ́n pa á tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. (Diu. 19:2-7, 11-13) Onírúurú ọ̀rọ̀ làwọn àgbààgbà yẹn máa ń bójú tó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń yanjú èdèkòyédè lórí ọ̀rọ̀ ilé àti ilẹ̀, wọ́n sì tún máa ń bá àwọn tọkọtaya yanjú aáwọ̀. (Ẹ́kís. 21:35; Diu. 22:13-19) Táwọn àgbààgbà yẹn bá ń ṣèdájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà sì pa Òfin Ọlọ́run mọ́, gbogbo wọn pátá ló máa ń ṣe láǹfààní, ìyẹn sì máa ń bọlá fún Jèhófà.—Léf. 20:7, 8; Aísá. 48:17, 18.
18 Ohun tá a rí kọ́: Gbogbo apá ìgbésí ayé wa ni Jèhófà ń kíyè sí. Ó fẹ́ ká máa fìfẹ́ bá ara wa gbé, ká sì máa fi inú kan bá ara wa lò. Bákan náà, gbogbo ohun tá à ń ṣe àtohun tá à ń sọ ni Jèhófà ń kíyè sí, títí kan èyí tá à ń ṣe ní kọ̀rọ̀ inú yàrá wa.—Héb. 4:13.
19-21. (a) Báwo ló ṣe yẹ káwọn àgbààgbà àtàwọn onídàájọ́ máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run? (b) Àwọn ìlànà wo ni Jèhófà gbé kalẹ̀, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
19 Jèhófà ò fẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè tó yí àwọn èèyàn rẹ̀ ká kó èèràn ràn wọ́n. Ìdí nìyẹn tó fi pàṣẹ pé káwọn àgbààgbà àtàwọn onídàájọ́ máa tẹ̀ lé Òfin òun, kí wọ́n má sì ṣe ojúsàájú tí wọ́n bá ń dájọ́. Àmọ́ o, wọn ò gbọ́dọ̀ le koko mọ́ àwọn èèyàn náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, òdodo ló yẹ kí wọ́n fi máa ṣèdájọ́.—Diu. 1:13-17; 16:18-20.
20 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀ káwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ má bàa jìyà. Àwọn ìlànà kan wà nínú Òfin Mósè tó mú kó ṣòro láti fẹ̀sùn èké kan ẹnì kan pé ó hùwà ọ̀daràn. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn ní ẹ̀tọ́ láti ko ẹni tó fẹ̀sùn kàn án lójú. (Diu. 19:16-19; 25:1) Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò lè dá ẹnì kan lẹ́bi àyàfi tí wọ́n bá rí ẹlẹ́rìí méjì tó jẹ́rìí sí i. (Diu. 17:6; 19:15) Tẹ́nì kan bá hùwà burúkú tó sì jẹ́ pé ẹnì kan péré ló jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà ńkọ́? Ẹni náà ò gbọ́dọ̀ ronú pé òun á mú un jẹ. Ó ṣe tán, Jèhófà rí ohun tó ṣe. Nínú ìdílé, àwọn bàbá ní àṣẹ lórí ìdílé wọn, síbẹ̀ ó níbi tí àṣẹ wọn mọ. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn ọ̀rọ̀ kan bá ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé, àwọn àgbààgbà ìlú ló máa dá sí i, tí wọ́n á sì ṣèdájọ́.—Diu. 21:18-21.
21 Ohun tá a rí kọ́: Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ìgbà gbogbo ló sì máa ń ṣe ohun tó tọ́. (Sm. 9:7) Ó máa ń bù kún àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí i, àmọ́ ó máa ń fìyà jẹ àwọn tó bá ṣi agbára wọn lò. (2 Sám. 22:21-23; Ìsík. 9:9, 10) Ó lè dà bíi pé àwọn kan hùwà burúkú, wọ́n sì mú un jẹ, àmọ́ tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, gbogbo wọn ló máa fìyà jẹ. (Òwe 28:13) Tí wọn ò bá sì ronú pìwà dà, wọ́n á rí i pé ‘ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.’—Héb. 10:30, 31.
ÀWỌN TÍ ÒFIN NÁÀ DÁÀBÒ BÒ
22-24. (a) Àwọn wo gan-an ni Òfin Mósè dáàbò bò, kí nìyẹn sì kọ́ wa nípa Jèhófà? (b) Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú Ẹ́kísódù 22:22-24?
22 Òfin Mósè dìídì dáàbò bo àwọn tí kò lè dáàbò bo ara wọn, àwọn bí ọmọ tí kò ní òbí, opó àtàwọn àjèjì. Jèhófà sọ fún àwọn onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ yí ìdájọ́ àtìpó tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba po, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ fi ipá gba ẹ̀wù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.” (Diu. 24:17) Jèhófà kò fọ̀rọ̀ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ ṣeré rárá, kódà ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún gan-an. Á sì fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá fojú pọ́n wọn.—Ka Ẹ́kísódù 22:22-24.
23 Kí Jèhófà lè dáàbò bo àwọn tó wà nínú ìdílé, ó ṣòfin pé kò gbọ́dọ̀ sí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tó bá ara wọn tan. (Léf. 18:6-30) Irú ìwà yìí wọ́pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká, àmọ́ ojú tí Jèhófà fi ń wò ó ló fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ náà fi wò ó, kí wọ́n kórìíra ẹ̀ tẹ̀gbintẹ̀gbin.
24 Ohun tá a rí kọ́: Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Ó kórìíra ìfipábánilòpọ̀, bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe àtàwọn ìṣekúṣe míì. Ó fẹ́ káwọn tó ń múpò iwájú dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ní pàtàkì jù lọ àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́, kí wọ́n sì rí i pé wọ́n rí ìdájọ́ òdodo gbà.
ÒFIN JẸ́ “ÒJÌJI ÀWỌN OHUN RERE TÍ Ń BỌ̀”
25-26. (a) Kí nìdí tá a fi fi ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo wé ẹ̀mí èèyàn àti afẹ́fẹ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀?
25 A lè fi ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo wé ẹ̀mí èèyàn àti afẹ́fẹ́, ó ṣe tán a ò lè wà láàyè láìsí afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú. Tó bá dá wa lójú pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà ń gbà bá wa lò, ìfẹ́ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tá a sì mọyì àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, ìyẹn á mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ká sì máa finú kan bá wọn lò.
26 Májẹ̀mú tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá nígbà tó fún wọn ní Òfin Mósè ló mú kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà pa Òfin yẹn tì lẹ́yìn tí Jésù ti mú Òfin náà ṣẹ, ó sì fi òmíì tó dára jù ú lọ rọ́pò rẹ̀. (Róòmù 10:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Òfin Mósè ní “òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Héb. 10:1) Nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀, a máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ohun rere yẹn, àá sì rí bí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọ Kristẹni.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
a Àpilẹ̀kọ yìí ni àkọ́kọ́ lára ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ mẹ́rin táá jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Mẹ́ta yòókù máa jáde nínú Ilé Ìṣọ́ May 2019. Àkòrí wọn ni: “Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nínú Ìjọ Kristẹni,” “Máa Fi Ìfẹ́ Hàn sí Àwọn Tí Wọ́n Hùwà Ìkà Sí, Kó O sì Máa Ṣèdájọ́ Òdodo,” àti “Bá A Ṣe Lè Pèsè Ìtùnú fún Àwọn Tí Wọ́n Bá Lò Pọ̀ Nígbà Tí Wọ́n Wà Lọ́mọdé.”
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àwọn òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè la sábà máa ń pè ní “Òfin Mósè.” Tá a bá kà á ní ení èjì, wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600). Nígbà míì, wọ́n tún máa ń pe àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì sí Diutarónómì ní ìwé Òfin. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń pe àpapọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ní ìwé Òfin.
c ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Jèhófà fẹ́ kí ọkàn àwọn ọmọ balẹ̀ kí wọ́n sì láyọ̀ bí àwọn òbí ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wọn tí wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́
ÀWÒRÁN: Ìyá kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì ń bá àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń dáná. Lọ́wọ́ ẹ̀yìn lọ́hùn-ún, bàbá ń kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń tọ́jú àgùntàn.
d ÀWÒRÁN: Àwọn àgbààgbà tó wà lẹ́nu ibodè ìlú ń gba ẹjọ́ opó kan àti ọmọ rẹ̀ rò, wọ́n sì fẹ́ dá a nídè lọ́wọ́ oníṣòwò kan tó fẹ́ rẹ́ wọn jẹ.