ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Àpẹẹrẹ Àwọn Ẹni Tẹ̀mí Mú Kí N Fayé Mi Sin Jèhófà
NÍ Ọ̀GÀNJỌ́ òru ọjọ́ kan, a bá ara wa létí odò ọya, ìyẹn River Niger. Wọ́n ń ja ogun abẹ́lé ní Nàìjíríà nígbà yẹn, torí náà ó léwu gan-an téèyàn bá lóun máa sọdá odò yẹn. Síbẹ̀, a mà sọdá o, kódà a ṣe bẹ́ẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ. Kí ló gbé mi débẹ̀? Ẹ jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé mi látọ̀dọ̀ àwọn òbí mi.
Lọ́dún 1913, dádì mi tó ń jẹ́ John Mills ṣèrìbọmi nílùú New York City lẹ́ni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25), Arákùnrin Russell ló sì sọ àsọyé ìrìbọmi wọn. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Dádì lọ sí orílẹ̀-èdè Trinidad, wọ́n sì fẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara kan níbẹ̀ tó ń jẹ́ Constance Farmer. Dádì máa ń ran William R. Brown lọ́wọ́ láti fi fídíò “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá” han àwọn èèyàn títí dọdún 1923 nígbà tí ètò Ọlọ́run rán ìdílé Brown lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Bó ṣe di pé Dádì àti Mọ́mì ń báṣẹ́ lọ ní Trinidad nìyẹn o, ẹni àmì òróró sì làwọn méjèèjì.
ÀWỌN ÒBÍ WA NÍFẸ̀Ẹ́ WA
Ọmọ mẹ́sàn-án làwọn òbí mi bí. Rutherford ni wọ́n sọ àkọ́bí, ìyẹn orúkọ tí ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society ń jẹ́. Nígbà tí wọ́n bí mi ní December 30, 1922, wọ́n sọ mí ní Woodworth torí pé Clayton J. Woodworth ni orúkọ olóòtú ìwé ìròyìn The Golden Age (tá a mọ̀ sí Jí! báyìí). Àwọn òbí wa rán gbogbo wa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àmọ́ nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n tẹ̀ mọ́ wa lọ́kàn jù. Màmá mi mọ bí wọ́n ṣe ń fi Ìwé Mímọ́ yíni lérò pa dà. Dádì ní tiwọn fẹ́ràn kí wọ́n máa sọ ìtàn Bíbélì fún wa, kódà gbogbo ara ni wọ́n máa ń lò kó lè dà bíi pé àwa náà wà níbẹ̀.
Gbogbo ìsapá wọn ló sèso rere. Mẹ́ta nínú àwa ọmọkùnrin márùn-ún ló lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Mẹ́ta lára àwọn àbúrò mi obìnrin sì ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè Trinidad àti Tobago. Àwọn òbí wa kọ́ wa, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa, wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ‘gbìn wá sínú ilé Jèhófà.’ Ìṣírí tí wọ́n fún wa mú ká sọ òtítọ́ di tiwa ká sì máa sin Jèhófà nìṣó.—Sm. 92:13.
Ilé wa ni wọ́n ti sábà máa ń pàdé fún òde ẹ̀rí, ibẹ̀ sì lọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà sábà máa ń darí sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí Arákùnrin George Young. Orílẹ̀-èdè Kánádà ló ti wá, míṣọ́nnárì sì ni nígbà tó ṣèbẹ̀wò sí Trinidad. Bákan náà, inú àwọn òbí mi máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìdílé Brown tí wọ́n jọ ń wàásù tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọ́n ti wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Gbogbo ìtàn tí mo gbọ́ yìí ló mú kí èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lọ́mọ ọdún mẹ́wàá.
ÌBẸ̀RẸ̀ ÌGBÉSÍ AYÉ MI
Àwọn ìwé ìròyìn wa máa ń sọjú abẹ níkòó gan-an. Wọ́n máa ń tú àṣírí ìsìn èké, àwọn jẹgúdújẹrá olóṣèlú àtàwọn oníṣòwò oníjẹkújẹ. Torí náà, nígbà tó dọdún 1936, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì mú kí gómìnà Trinidad fòfin de gbogbo ìwé Watch Tower. A tọ́jú àwọn ìwé náà, a sì ń lò wọ́n títí a fi lo gbogbo èyí tó wà lọ́wọ́ wa tán. A máa ń yan kiri ìlú, a sì máa ń lo kẹ̀kẹ́ láti gbé àkọlé gàdàgbà kiri, a tún máa ń pín àwọn ìwé ìléwọ́ fáwọn èèyàn. Àwa àtàwọn ará tó ń lo mọ́tò tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ láti ìlú Tunapuna máa ń lọ wàásù títí dé àwọn ìgbèríko Trinidad. Mánigbàgbé làwọn ọdún yẹn. Àwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí ló mú kí n ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16).
Ọwọ́ tí ìdílé wa fi mú ìjọsìn Ọlọ́run àtàwọn ìrírí tí mò ń gbọ́ mú kí n pinnu pé èmi náà máa di míṣọ́nnárì. Ohun tó wà lọ́kàn mi nìyẹn tó fi jẹ́ pé lọ́dún 1944, mo lọ dara pọ̀ mọ́ Arákùnrin Edmund W. Cummings tó ń sìn ní erékùṣù Aruba. Inú wa dùn gan-an nígbà táwọn mẹ́wàá pé jọ síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 1945. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní erékùṣù yẹn.
Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo wàásù fún obìnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Oris Williams lorúkọ ẹ̀. Oris máa ń bá mi jiyàn gan-an torí àwọn ohun tó ti kọ́ nínú ẹ̀sìn ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi tó fi ṣèrìbọmi ní January 5, 1947. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra, a sì ṣègbéyàwó. November 1950 ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Oris sì ti mú kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ ládùn.
A GBÁDÙN IṢẸ́ ÌSÌN WA NÍ NÀÌJÍRÍÀ
Ètò Ọlọ́run pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1955. Nígbà tá à ń múra ìrìn àjò yẹn, èmi àti Oris fiṣẹ́ wa sílẹ̀, a ta ilé wa àtàwọn nǹkan míì tá a ní, a sì dágbére fáwọn ọ̀rẹ́ wa ní Aruba. Ní July 29, 1956, a kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹtàdínlọ́gbọ̀n ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì rán wa lọ sí Nàìjíríà.
Oris sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà máa ń jẹ́ kéèyàn kojú ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Àtilẹ̀ lọkọ mi ti pinnu pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì lòun máa ṣe, àmọ́ ní tèmi, ohun tó wù mí ni pé kí n wà nílé ara mi kí n sì bímọ. Àmọ́, mo yí èrò mi pa dà nígbà tí mo rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ kánjúkánjú. Nígbà tá a fi máa parí ní Gílíádì, mo ti ṣe tán láti di míṣọ́nnárì, kí n sì lọ wàásù. Àmọ́, nǹkan kan ṣẹlẹ̀, bá a ṣe fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú omi Queen Mary. Arákùnrin Worth Thornton tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì Arákùnrin Knorr kí wa pé ó dìgbà kan ná o, ó wá sọ fún wa pé Bẹ́tẹ́lì là ń lọ. Mo ní: ‘Rárá o!’ Síbẹ̀, kò pẹ́ tí mo fi fẹ́ràn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni mo sì ṣe níbẹ̀. Iṣẹ́ tí mo gbádùn jù ni iṣẹ́ ìgbàlejò. Torí pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, iṣẹ́ náà jẹ́ kí n mọ ọ̀pọ̀ àwọn ará ní Nàìjíríà. Tí púpọ̀ nínú wọn bá dé, eruku á ti bò wọ́n, á ti rẹ̀ wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ebi á máa pa wọ́n tí òǹgbẹ á sì máa gbẹ wọ́n. Inú mi máa ń dùn láti tọ́jú wọn, ara sì máa ń tù wọ́n gan-an. Mo gbà pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni gbogbo ẹ̀, ohun tó sì fún mi láyọ̀ nìyẹn.” Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa ló mú ká túbọ̀ mọyì iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Nígbà àpèjẹ kan tí ìdílé wa ṣe ní Trinidad lọ́dún 1961, Arákùnrin Brown sọ àwọn ìrírí amóríyá tí wọ́n ní nílẹ̀ Áfíríkà, èmi náà sì sọ àwọn ìbísí tó ń wáyé ní Nàìjíríà. Arákùnrin Brown wá gbọ́wọ́ lé èjìká dádì mi, wọ́n sì sọ pé: “Johnny, o ò láǹfààní àtilọ sí Áfíríkà, àmọ́, Woodworth ti lọ!” Dádì sọ pé: “Ọmọ àmúyangàn ni ẹ́ Worth, máa tẹ̀ síwájú!” Àwọn ìṣírí tí mo rí lọ́dọ̀ àwọn ẹni tẹ̀mí yìí ló mú kí n túbọ̀ pinnu pé màá ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi ní kíkún.
Lọ́dún 1962, mo tún láǹfààní láti lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Gílíádì, ìyẹn ní kíláàsì kẹtàdínlógójì (37), oṣù mẹ́wàá gbáko la sì lò níbẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, Arákùnrin Wilfred Gooch tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ní Nàìjíríà nígbà yẹn náà lọ sí kíláàsì kejìdínlógójì (38), wọ́n sì rán wọn lọ sí orílẹ̀-èdè England. Bí iṣẹ́ àbójútó ẹ̀ka ṣe já lé mi léjìká nìyẹn o. Bíi ti Arákùnrin Brown, èmi náà rìnrìn àjò gan-an, mo sì sapá láti mọ àwọn ará wa ní Nàìjíríà dáadáa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn nǹkan amáyédẹrùn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, síbẹ̀ ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n ní fi hàn pé kì í ṣe owó tàbí àwọn ohun ìní tara ló ń jẹ́ kéèyàn ní ayọ̀ tòótọ́. Láìka bí ipò wọn ṣe rí sí, wọ́n máa ń múra dáadáa, wọ́n á mọ́ tónítóní, wọ́n sì máa ń wà létòletò tí wọ́n bá ń bọ̀ nípàdé. Ọkọ̀ akẹ́rù tàbí bọ́lẹ̀kájàa ni wọ́n máa ń wọ̀ wá sáwọn àpéjọ àgbègbè. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n sábà máa ń kọ oríṣiríṣi nǹkan sára àwọn ọkọ̀ náà. Ọ̀kan tí mo rántí dáadáa ni: “Ìsun térétéré ló ń dodò.”
Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yẹn tá a bá wo bíṣẹ́ ìwàásù ṣe tẹ̀ síwájú lórílẹ̀-èdè yìí! Ìsapá gbogbo àwọn ará ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, àwa náà sì fi tiwa kún un. Nígbà tó fi máa di 1974, Nàìjíríà nìkan ni orílẹ̀-èdè tó ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún akéde (100,000) yàtọ̀ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ náà ti gbèrú gan-an!
Bí iṣẹ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí i, ogun abẹ́lé jà ní Nàìjíríà lọ́dún 1967 sí 1970. Ọ̀pọ̀ oṣù làwọn ará tó wà lápá Biafra ò fi lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ó di dandan ká wá bá a ṣe máa gbé oúnjẹ tẹ̀mí lọ fún wọn. Bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, àdúrà àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà la sì sọdá odò náà.
Mi ò lè gbàgbé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láwọn ìgbà tá a sọdá odò yẹn. A ò bẹ̀rù pé àwọn sójà afẹ̀míṣòfò lè pa wá dà nù àti pé a lè kó àìsàn tàbí ká kó sínú ewu míì. Kò rọrùn rárá láti kọjá ibi táwọn ọmọ ogun ìjọba wà, àmọ́ àtikọjá ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun Biafra tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Alẹ́ ọjọ́ kan wà tí mo wọ ọkọ̀ ojú omi sọdá odò yẹn láti Asaba dé Onitsha, kí n lè lọ fún àwọn alàgbà tó wà ní Enugu níṣìírí. Nígbà míì tá a tún lọ, a gbé àwọn alàgbà tó wà nílùú Aba ró, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọgbọ níbẹ̀. Lọ́jọ́ kan tá à ń ṣèpàdé ní Port Harcourt, ṣe la sáré fi àdúrà parí ìpàdé náà torí pé àwọn ọmọ ogun ìjọba ti mú àwọn ọmọ ogun Biafra balẹ̀, wọ́n sì ti ń bọ̀ nínú ìlú.
Àwọn ìpàdé yẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá àwọn ará lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, a sì tún fìyẹn rán wọn létí pé wọn ò gbọ́dọ̀ dá sí rògbòdìyàn náà, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ni kí wọ́n sapá láti túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ò jẹ́ kí ogun yẹn fa ìpínyà láàárín wọn. Wọ́n fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn láìka ẹ̀tanú àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó gbòde kan, wọ́n sì ṣe ara wọn lọ́kan. Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún mi pé mo lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn àsìkò tí nǹkan nira yẹn.
Lọ́dún 1969, Arákùnrin Milton G. Henschel ṣe alága Àpéjọ Àgbáyé “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” ní Yankee Stadium, nílùú New York, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ gan-an torí èmi ni mo ràn án lọ́wọ́. Àpéjọ yẹn bọ́ sásìkò torí pé lọ́dún 1970, a ṣe Àpéjọ Àgbáyé “Àwọn Èèyàn Onífẹ̀ẹ́ Rere” nílùú Èkó. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló jẹ́ kí àpéjọ yìí kẹ́sẹ járí torí pé kété lẹ́yìn ogun yẹn la ṣe é. Èdè mẹ́tàdínlógún (17) la sọ níbẹ̀, àwọn 121,128 ló sì pésẹ̀. Lẹ́yìn ti Pẹ́ńtíkọ́sì, àpéjọ yìí làwọn tó tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ti ṣèrìbọmi, kódà 3,775 làwọn tó ṣèrìbọmi. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún Arákùnrin Knorr, Arákùnrin Henschel àtàwọn míì tó wá láti Amẹ́ríkà àti England. Ìgbà tá à ń ṣètò àpéjọ yẹn ni ọwọ́ mi tíì dí jù. Ìbísí tó wáyé kọjá bẹ́ẹ̀, ó kà màmà!
Láàárín ọgbọ̀n (30) ọdún tí mo lò ní Nàìjíríà, mo gbádùn iṣẹ́ arìnrìn-àjò, mo sì tún máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ará tó wà láwọn orílẹ̀-èdè míì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Àwọn míṣọ́nnárì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yẹn máa ń mọyì ìṣírí tá a máa ń fún wọn àti àkókò tá a máa ń lò lọ́dọ̀ wọn. Mo máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ètò Ọlọ́run ò gbàgbé wọn, àkókò aláyọ̀ ló sì máa ń jẹ́ fún gbogbo wa. Iṣẹ́ yìí ti jẹ́ kí n rí i pé téèyàn bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ìyẹn gan-an ló máa jẹ́ kí wọ́n rókun gbà kí wọ́n sì máa pa ìṣọ̀kan àárín wa mọ́.
Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà ni ò jẹ́ ká bógun yẹn lọ tí kò sì jẹ́ kí àìsàn gbẹ̀mí wa. Kò sígbà tá à kì í rí ìbùkún Jèhófà láyé wa. Oris sọ pé:
“Ọ̀pọ̀ ìgbà làwa méjèèjì ní àìsàn ibà. Nígbà kan, ọkọ mi dákú lọ gbári. Nígbà tá a gbé e délé ìwòsàn kan nílùú Èkó, wọ́n sọ fún mi pé kò lè yè é, àmọ́ Jèhófà kó o yọ! Nígbà tó lajú, ó wàásù fún nọ́ọ̀sì tó ń tọ́jú rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, èmi àti ẹ̀ lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọkùnrin nọ́ọ̀sì yẹn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nwambiwe. Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì di alàgbà nílùú Aba nígbà tó yá. Èmi náà ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ títí kan àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí paraku, wọ́n sì wá sin Jèhófà. Ohun míì tó tún fún wa láyọ̀ ni bá a ṣe mọ àwọn ará wa ní Nàìjíríà, tá a mọ àṣà ìbílẹ̀ wọn àti èdè wọn.”
Ẹ̀kọ́ míì tí mo tún kọ́ ni pé táwa tá à ń sìn nílẹ̀ òkèèrè bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ wa láṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin láìka ti pé àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa.
A NÍ ÀǸFÀÀNÍ IṢẸ́ ÌSÌN MÍÌ
Lẹ́yìn tá a ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní Nàìjíríà, ètò Ọlọ́run rán wa lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní erékùṣù St. Lucia ní Caribbean, ibẹ̀ sì rẹwà gan-an. A gbádùn iṣẹ́ wa níbẹ̀, àmọ́ ibẹ̀ náà ní àwọn ìṣòro tiẹ̀. Nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ìyàwó púpọ̀, àmọ́ ní St. Lucia, ìṣòro wọn ni pé tọkọtaya máa ń gbé pọ̀ láì fẹ́ra wọn níṣu lọ́kà. Bó ti wù kó rí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí púpọ̀ lára àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.
Bá a ṣe ń dàgbà sí i bẹ́ẹ̀ lagbára wa ń dín kù. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní ká máa bọ̀ ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, lọ́dún 2005. Kò sígbà tí mi ò kì í dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí Oris. Ó dùn mí pé ó sùn nínú ikú lọ́dún 2015, mi ò sì lè ṣàlàyé bó ṣe rí lára mi. Ìyàwó tó dáńgájíá ni, ó fẹ́ràn mi gan-an, èmi náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) tá a fi jọ wà. A ti rí i pé téèyàn bá máa láyọ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ, ó gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń múpò iwájú, kó máa dárí jini fàlàlà, kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó sì máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù.
Láwọn ìgbà tá a ní ìjákulẹ̀ tàbí tí nǹkan ò lọ bá a ṣe fẹ́, a máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ kí gbogbo ìsapá wa má bàa já sí pàbó. Báwa náà ṣe ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, à ń rí i pé ṣe ni nǹkan ń dáa sí i. Síbẹ̀, ọjọ́ ológo ńbẹ níwájú!—Aísá. 60:17; 2 Kọ́r. 13:11.
Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ táwọn òbí mi àtàwọn míì ṣe ní Trinidad àti Tobago gan-an. Kódà, ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé àwọn tó ń sin Jèhófà níbẹ̀ báyìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (9,892). Ní Aruba, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti ṣe gudugudu méje láti fún ìjọ tí mo wà tẹ́lẹ̀ lókun. Ní báyìí, odindi ìjọ mẹ́rìnlá (14) ló wà ní erékùṣù yẹn. Ní ti Nàìjíríà, àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (381,398). Ní St. Lucia, ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàlélọ́gọ́rin (783) làwọn akéde tó ń wàásù níbẹ̀.
Mo ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún báyìí. Sáàmù 92:14 sì sọ nípa àwọn tá a gbìn sínú ilé Jèhófà pé: “Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú, wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjà yọ̀yọ̀.” Inú mi dùn pé Jèhófà ni mo fayé mi sìn. Àpẹẹrẹ àwọn òbí mi fún mi ní ìṣírí láti sin Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí n máa “yọ ìtànná” nínú ilé rẹ̀.—Sm. 92:13.
a Wo Jí! March 8, 1972, ojú ìwé 24 sí 26 lédè Gẹ̀ẹ́sì.