Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
ÒÓTỌ́ pọ́ńbélé ni ìtàn tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù, èyí tó sọ bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn tá a mú “sìnrú lábẹ́ ìfìkà-gboni-mọ́lẹ̀” nídè. (Ẹ́kísódù 1:13) Ó sì tún jẹ́ ìtàn alárinrin nípa bí Ọlọ́run ṣe dá orílẹ̀-èdè kan sílẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀, òfin tó gbámúṣé àti kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn wà lára àwọn ohun tó ń mú kí ìwé náà fani mọ́ra. Ohun tá à ń sọ gan-an ni pé ìwọ̀nyí làwọn ohun tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù.
Wòlíì Hébérù nì, Mósè, ló kọ ìwé Ẹ́kísódù. Ìwé náà ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láàárín ọdún márùnlélógóje [145], èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà ikú Jósẹ́fù, lọ́dún 1657 ṣáájú Sànmánì Tiwa, títí dìgbà tí wọ́n parí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn lọ́dún 1512 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ náà kì í ṣe ìtàn ṣákálá kan lásán. Ara ọ̀rọ̀, tàbí ìsọfúnni tí Ọlọ́run fẹ́ kí aráyé mọ̀ ni. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ tó ‘yè tó sì ń sa agbára’ ni. (Hébérù 4:12) Fún ìdí yìí, ìwé Ẹ́kísódù ṣe pàtàkì gidigidi fún wa.
“ỌLỌ́RUN GBỌ́ ÌKÉRORA WỌN”
Kò pẹ́ rárá táwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù tó ń gbé nílẹ̀ Íjíbítì fi pọ̀ rẹpẹtẹ, èyí tó mú kí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n sọ wọ́n dẹrú kí wọ́n sì máa lò wọ́n nílò omi òjò. Àní, Fáráò tiẹ̀ pàṣẹ pé pípa ni kí wọ́n pa gbogbo ọmọkùnrin táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bí. Àmọ́ o, ọmọ oṣù mẹ́ta kan wà tí ikú yẹ̀ lórí ẹ̀, òun ni Mósè, tí ọmọbìnrin Fáráò gbà ṣọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ààfin ọba ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà, nígbà tó pé ọmọ ogójì ọdún, ó gba ìjà àwọn èèyàn rẹ̀ jà ó sì pa ọmọ Íjíbítì kan. (Ìṣe 7:23, 24) Ó di dandan pé kí Mósè sá lọ sí ilẹ̀ Mídíánì. Níbẹ̀ ló ti fẹ́yàwó, tó sì ń ṣiṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Níbi tí iná ti ń jó lára igi kékeré kan lọ́nà ìyanu, Jèhófà pàṣẹ fún Mósè pé kó padà sí Íjíbítì kó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú. Ọlọ́run yan Áárónì, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún un.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
3:1—Irú àlùfáà wo ni Jẹ́tírò? Lákòókò àwọn baba-ńlá, olórí ìdílé ló máa ń sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún ìdílé rẹ̀. Ó dájú nígbà náà pé baba-ńlá tó jẹ́ olórí ẹ̀yà àwọn ará Mídíánì kan ni Jẹ́tírò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, tí ìyàwó rẹ̀ Kétúrà bí fún un, làwọn ará Mídíánì, ìjọsìn Jèhófà lè máà fi bẹ́ẹ̀ ṣàjèjì sí wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 25:1, 2.
4:11—Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà ń ‘yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ tàbí adití àti afọ́jú’? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn kan tí Jèhófà bu ìfọ́jú lù, àtàwọn tó ti mú yadi rí, kì í ṣe òun ló ń fa gbogbo àbùkù ara o. (Jẹ́nẹ́sísì 19:11; Lúùkù 1:20-22, 62-64) Ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá ló máa ń fà á. (Jóòbù 14:4; Róòmù 5:12) Àmọ́ ṣá o, níwọ̀n bí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda kí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, ó lè sọ pé òun lòún ń “yan” ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, adití àti afọ́jú.
4:16—Lọ́nà wo ni Mósè á gbà “ṣe bí Ọlọ́run” fún Áárónì? Mósè jẹ́ aṣojú Ọlọ́run. Nítorí èyí, Mósè dà “bí Ọlọ́run” fún Áárónì tó jẹ́ agbẹnusọ rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
1:7, 14. Jèhófà ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn nígbà táwọn ará Íjíbítì ń pọ́n wọn lójú. Bákan náà ló tún ń mẹ́sẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ òde òní dúró, àní nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni gbígbóná janjan sí wọ́n pàápàá.
1:17-21. Jèhófà máa ń rántí wa “fún rere.”—Nehemáyà 13:31.
3:7-10. Jèhófà kì í dágunlá sí igbe ẹkún àwọn ènìyàn rẹ̀.
3:14. Jèhófà kì í kùnà láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Nítorí náà, ó yẹ kó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé àwọn ohun tá à ń retí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣèlérí, yóò ní ìmúṣẹ.
4:10, 13. Ẹ̀rù tó ń ba Mósè nítorí àìmọ̀rọ̀ọ́sọ rẹ̀ pọ̀ débi pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti ki í láyà pàápàá, ó ṣì bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run rán ẹlòmíràn láti lọ bá Fáráò sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, Jèhófà lo Mósè ó sì fún un ní ọgbọ́n àti agbára tó nílò láti ṣe iṣẹ́ tó gbé lé e lọ́wọ́. Dípò ká máa ronú ṣáá nípa ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí, ẹ jẹ́ ká gbára lé Jèhófà ká sì fi tòótọ́tòótọ́ ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa láṣeyege.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
ÀWỌN IṢẸ́ ÌYANU TÍTAYỌ MÚ KÍ ÌDÁǸDÈ ṢEÉ ṢE
Mósè àti Áárónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì sọ fún un pé kó yọ̀ǹda àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n lè lọ ṣayẹyẹ àjọ̀dún fún Jèhófà nínú aginjù. Alákòóso orílẹ̀-èdè Íjíbítì náà fàáké kọ́rí, kò jẹ́ kí wọ́n lọ. Jèhófà lo Mósè láti mú kí ìyọnu kíkàmàmà wáyé ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé. Ìgbà tó dorí ìyọnu kẹwàá ni Fáráò tó jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí òun àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ fi gbá yá wọn. Ṣùgbọ́n Jèhófà pèsè ọ̀nà àbáyọ fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tó mú wọn rìn gba àárín Òkun Pupa kọjá tó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n là. Àwọn ará Íjíbítì tó ń lépa wọn rì sínú òkun nígbà tí omi ya bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
6:3—Lọ́nà wo ni Ọlọ́run ò gbà sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù? Àwọn baba-ńlá yìí lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà sì ṣe ìlérí fún wọn. Síbẹ̀, wọn ò mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń mú káwọn ìlérí wọ̀nyí nímùúṣẹ, wọn ò sì rí ọ̀nà tó gbà ṣe bẹ́ẹ̀ rí.—Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 2; 15:7, 13-16; 26:24; 28:10-15.
7:1—Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi Mósè ṣe “Ọlọ́run fún Fáráò”? Ọlọ́run fún Mósè ní agbára ó sì fi í jọ̀gá lé Fáráò lórí. Nítorí náà, kò sí ìdí fún un láti bẹ̀rù ọba yẹn.
7:22—Ibo làwọn àlùfáà Íjíbítì ti rí omi tí kò tíì di ẹ̀jẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé omi tí wọ́n ti bù nínú Odò Náílì kí ìyọnu náà tó bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ń lò. Wọ́n tún lè rómi tí ò tíì di ẹ̀jẹ̀ bí wọ́n bá gbẹ́lẹ̀ nítòsí Odò Náílì.—Ẹ́kísódù 7:24.
8:26, 27—Kí nìdí tí Mósè fi sọ pé ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò rú á jẹ́ “ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn ará Íjíbítì”? Onírúurú ẹranko làwọn ará Íjíbítì ń bọ. Nítorí náà, dídá tí Mósè dárúkọ ẹbọ tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọ̀rọ̀ náà kúrò ní tàwàdà, á sì mú kí wọ́n rí ìdí tó fi ń tẹnu mọ́ ọn pé kí wọ́n yọ̀ǹda fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ rúbọ sí Jèhófà.
12:29—Àwọn wo ni wọ́n kà sí àkọ́bí? Kìkì àwọn àkọ́bí tó jẹ́ akọ nìkan ni. (Númérì 3:40-51) Àkọ́bí ni Fáráò alára, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò pa á. Ó ní agboolé tirẹ̀. Ìyọnu kẹwàá náà kò mẹ́mìí ẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí olórí agboolé yìí, àkọ́bí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ló bá a rìn.
12:40—Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbé pẹ́ tó nílẹ̀ Íjíbítì? Àkókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò “ní ilẹ̀ Íjíbítì àti ní ilẹ̀ Kénáánì” wà lára ọgbọ̀n lé nírínwó [430] ọdún tá a mẹ́nu kàn níbí. (Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin ni Ábúráhámù lákòókò tó sọdá Odò Yúfírétì lọ́dún 1943 ṣáájú Sànmánì Tiwa, nígbà tó ń lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:4) Látìgbà náà títí di àkókò tí Jékọ́bù, ẹni àádóje [130] ọdún fi wọ ilẹ̀ Íjíbítì, jẹ́ ọdún okòólénígba ó dín márùn-ún. [215] (Jẹ́nẹ́sísì 21:5; 25:26; 47:9) Èyí tó túmọ̀ sí pé lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lo iye àkókò yìí kan náà ní Íjíbítì.
15:8—Ṣé lóòótọ́ ni omi Òkun Pupa náà le gbagidi bíi yìnyín nígbà tí Bíbélì sọ pé ó “dì”? Ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “dì” túmọ̀ sí kí nǹkan sún kì tàbí ki pọ́pọ́. Nínú ìwé Jóòbù 10:10, Bíbélì lo gbólóhùn náà fún wàràkàṣì tí a mú kó dì. Nítorí náà, pé omi náà dì ò fi dandan túmọ̀ sí pé ó le gbagidi bíi yìnyín. Bó bá jẹ́ pé “ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle” tí Ẹ́kísódù 14:21 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ tutù tó láti mú kí omi náà dì, ó dájú pé Bíbélì ì bá ti mẹ́nu kàn án pé ńṣe ló tutù nini. Níwọ̀n bí kò ti sí ohunkóhun tó dí omi náà lọ́wọ́, ó wà dà bí ẹni pé ó dì, tàbí pé ó ki pọ́pọ́.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
7:14–12:30. Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá náà ò ṣàdédé ṣẹlẹ̀ o. A sàsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, wọ́n sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Dájúdájú, mímú tí Ẹlẹ́dàá mú àwọn ìyọnu mẹ́wàá náà wá fi bó ṣe ní agbára lórí omi, ìmọ́lẹ̀, àwọn kòkòrò, ẹranko àtàwọn èèyàn hàn wá kedere! Àwọn ìyọnu náà tún fi hàn pé Ọlọ́run lè mú ìyọnu wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ nìkan kó sì dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín.
11:2; 12:36. Àwọn èèyàn Jèhófà ń rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Ó ń rí i dájú pé wọ́n ń rí owó ọ̀yà tó tọ́ sí wọn gbà nítorí gbogbo làálàá wọn ní ilẹ̀ Íjíbítì. Òmìnira ni wọ́n wà nígbà tí wọ́n kó wá sí ilẹ̀ Íjíbítì, wọn kì í ṣe òǹdè tá a kó lójú ogun láti fi ṣẹrú.
14:30. Ó yẹ kó dá wa lójú pé Jèhófà lè gba àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ là nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀.—Mátíù 24:20-22; Ìṣípayá 7:9, 14.
JÈHÓFÀ ṢÈTÒ ORÍLẸ̀-ÈDÈ TÍ ÒUN FÚNRA RẸ̀ YÓÒ MÁA ṢÀKÓSO
Ní oṣù kẹta lẹ́yìn ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, wọ́n pàgọ́ sí iwájú Òkè Sínáì. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti fún wọn ní Òfin Mẹ́wàá àtàwọn òfin mìíràn, ó bá wọn dá májẹ̀mú, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè tí òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣàkóso. Mósè lo ogójì ọjọ́ lórí òkè náà, ibẹ̀ ló sì ti gba ìtọ́ni nípa ìjọsìn tòótọ́ àti bí wọn yóò ṣe kọ́ àgọ́ Jèhófà, ìyẹn tẹ́ńpìlì tó ṣeé gbé kiri. Kí Mósè tó ti orí òkè náà dé, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀. Nígbà tí Mósè ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ látorí òkè náà tó sì rí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, inú rẹ̀ ru gan-an débi pé ó fọ́ wàláà òkúta méjèèjì tí Ọlọ́run fún un mọ́lẹ̀. Lẹ́yìn táwọn aṣebi náà ti jẹ ìyà tó tọ́ sí wọn, ó tún padà sórí òkè náà ó sì gba àwọn wàláà òkúta mìíràn. Gbàrà tó padà dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àgọ́ ìjọsìn. Lọ́dún kan gbáko lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dòmìnira, wọ́n parí iṣẹ́ kíkọ́ àgọ́ kíkàmàmà náà àti ṣíṣe gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, wọ́n sì tò ó pa pọ̀. Lẹ́yìn náà ni Jèhófà fi ògo rẹ̀ kún inú àgọ́ náà.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
20:5—Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà mú “ìyà ìṣìnà àwọn baba wá” sórí àtìrandíran wọn? Lẹ́yìn tí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan bá ti dàgbà, ìwà àti ìṣe rẹ̀ ni wọ́n fi máa ń dá a lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, àtìrandíran wọn ló jìyà ohun tí wọ́n ṣe. Kódà, èyí ò yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olùṣòtítọ́ sílẹ̀. Nítorí pé ìwàkiwà tí orílẹ̀-èdè náà mú wọnú ìjọsìn mú kó ṣòro fún wọn láti pa ìwà títọ́ mọ́.
23:19; 34:26—Kí ló mú kí àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé kí wọ́n má ṣe se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀ ṣe pàtàkì? Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe sọ, síse ọmọ ẹran (ọmọ ewúrẹ́ tàbí irú ẹranko mìíràn kan) nínú wàrà ìyá rẹ̀ jẹ́ ààtò ìjọsìn tó máa ń mú kí òjò rọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé wàrà yìí ni ẹranko fi ń bọ́ ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìwà ìkà láti se ọmọ tí ẹranko kan bí nínú irú wàrà bẹ́ẹ̀. Òfin yìí kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ aláàánú.
23:20-23—Áńgẹ́lì wo là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbí, báwo sì ni orúkọ Jèhófà ṣe wà “lára rẹ̀”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù ni áńgẹ́lì náà, ṣáájú kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run lò ó láti darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (1 Kọ́ríńtì 10:1-4) Ọ̀nà tí orúkọ Jèhófà sì fi wà “lára rẹ̀” ni pé Jésù yìí ni ẹni pàtàkì tó ń gbé orúkọ Bàbá rẹ̀ lárugẹ tó sì ń yà á sí mímọ́.
32:1-8, 25-35—Kí nìdí tí Áárónì kò fi jìyà nítorí fífi tó fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù? Inú Áárónì ò dùn sí ìbọ̀rìṣà náà. Lẹ́yìn tọ́ràn náà wáyé, ńṣe ló dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Léfì yòókù láti fi hàn pé Ọlọ́run ni òun fara mọ́ kì í ṣe àwọn tó kẹ́yìn sí Mósè. Lẹ́yìn tí wọn ti pa àwọn tó jẹ̀bi tán, Mósè rán àwọn èèyàn náà létí pé wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, èyí fi hàn pé Jèhófà fi àánú hàn sí àwọn mìíràn, yàtọ̀ sí Áárónì.
33:11, 20—Báwo ni Ọlọ́run ṣe bá Mósè sọ̀rọ̀ “ní ojúkojú”? Gbólóhùn yìí túmọ̀ sí pé kí ẹni méjì máa bá ara wọn sọ̀rọ̀. Mósè bá aṣojú Ọlọ́run sọ̀rọ̀, Jèhófà sì tipasẹ̀ aṣojú náà bá Mósè sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, Mósè ò rí Jèhófà, níwọ̀n bí ‘kò ti sí ẹni tó lè rí Ọlọ́run kó sì tún wà láàyè.’ Àní ṣẹ́, Jèhófà ò bá Mósè sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Ohun tí ìwé Gálátíà 3:19 sọ ni pé ‘a sì ta Òfin látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì láti ọwọ́ alárinà kan.’
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
15:25; 16:12. Jèhófà máa ń pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀.
18:21. Lọ́nà kan náà, àwọn ọkùnrin tí à ń yàn sípò nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó dáńgájíá, olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ẹni tó ṣeé gbíyè lé àti aláìmọtara-ẹni-nìkan.
20:1–23:33. Jèhófà ni Olùfúnnilófin gíga jù lọ. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti fayọ̀ sìn ín lọ́nà tó wà létòlétò. Jèhófà ní ètò kan tí òun fúnra rẹ̀ ń darí lónìí. Fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò náà á mú ká láyọ̀, a ó sì máa gbé láìséwu.
Ó Ṣe Pàtàkì Gidigidi fún Wa
Kí ni ìwé Ẹ́kísódù jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà? Ó jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ Olùfìfẹ́pèsè, Gbanigbani tí ò láfiwé àti Olùmú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ. Òun ni Ọlọ́run tó ń ṣàkóso ètò rẹ̀.
Ó dájú pé bẹ́ ẹ bá ń ka Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi múra sílẹ̀ fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ohun tẹ́ ẹ ti rí kọ́ látinú ìwé Ẹ́kísódù á ru yín sókè gan-an ni. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń yẹ ohun tó wà lábẹ́ ẹ̀ka “Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́” wò, ẹ óò lè ní òye púpọ̀ sí i nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtó kan. Àlàyé tá a ṣe lábẹ́ “Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa” yóò jẹ́ kẹ́ ẹ mọ bẹ́ ẹ ṣe lè jàǹfààní látinú Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Jèhófà pàṣẹ fún ọkùnrin onínú-tútù náà, Mósè, pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá náà jẹ́ ká rí agbára tí Ẹlẹ́dàá ní lórí omi, ìmọ́lẹ̀, àwọn kòkòrò, ẹranko àtàwọn èèyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Jèhófà lo Mósè láti sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè kan tí òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣàkóso