Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
OCTOBER 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 31-32
“Ẹ Sá fún Ìbọ̀rìṣà”
Máa Tẹ̀ Síwájú Sí Ìdàgbàdénú Torí Pé “Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé”
Ó lè ṣòro láti fi ohun tá a kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ sílò, ní pàtàkì jù lọ tí ipò nǹkan bá le. Bí àpẹẹrẹ, kò pẹ́ tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko òǹdè àwọn ará Íjíbítì, tí wọ́n fi “bẹ̀rẹ̀ sí bá Mósè ṣe aáwọ̀” wọ́n sì ń bá a nìṣó “ní dídán Jèhófà wò.” Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn kò rí omi mu. (Ẹ́kís. 17:1-4) Kò tíì pé oṣù méjì lẹ́yìn tí wọ́n wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n sọ pé àwọn á ṣe “gbogbo [ohun] tí Jèhófà sọ” tí wọ́n fi rú òfin Ọlọ́run lórí ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 24:3, 12-18; 32:1, 2, 7-9) Ṣé ó lè jẹ́ pípẹ́ tí Mósè pẹ́ nígbà tí Ọlọ́run ń fún un ní ìtọ́ni lórí Òkè Hórébù ló bà wọ́n lẹ́rù? Àbí ṣe ni wọ́n ronú pé àwọn ará Ámálékì lè gbógun dé, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì á sì wà láìní olùgbèjà torí pé Mósè tí wọ́n gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun Ámálékì nígbà kan rí kò sí nílé? (Ẹ́kís. 17:8-16) Ó lè jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, àmọ́ láìkà ohun yòówù kó jẹ́ sí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “kọ̀ láti jẹ́ onígbọràn.” (Ìṣe 7:39-41) Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé “kí a sa gbogbo ipá wa” ká má bàa “ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn” táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn nígbà tí wọ́n ń bẹ̀rù láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí.—Héb. 4: 3, 11.
Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Kí o Sì Jàǹfààní Nínú Àwọn Ìlérí Tó Fi Ìbúra Ṣe
Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ojúṣe tó jẹ́ tirẹ̀ nínú májẹ̀mú Òfin náà nípa ṣíṣètò àgọ́ ìjọsìn àti ẹgbẹ́ àlùfáà, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ kíákíá ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbàgbé pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì “ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” (Sm. 78:41) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Mósè ń gba àwọn ìsọfúnni síwájú sí i lórí Òkè Sínáì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní sùúrù mọ́, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í yingin, èrò wọn ni pé Mósè ti pa wọ́n tì. Torí náà wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà, wọ́n sì sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 32:1, 4) Lẹ́yìn náà, wọ́n wá ṣe ayẹyẹ kan tí wọ́n pè ní “àjọyọ̀ fún Jèhófà,” wọ́n tẹrí ba, wọ́n sì rúbọ sí ère tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. Nígbà tí Jèhófà rí ohun tí wọ́n ṣe yìí, ó sọ fún Mósè pé: “Ní kíákíá, wọ́n ti yà kúrò ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún wọn láti máa rìn.” (Ẹ́kís. 32:5, 6, 8) Ó dunni pé, látìgbà yẹn lọ ló ti di àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run kí wọ́n má sì mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.—Nọ́ń. 30:2.
“Ta Ni Ó Wà ní Ìhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà?”
Àwọn èèyàn náà mọ̀ dáadáa pé Jèhófà kórìíra ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-5) Àmọ́ kò pẹ́ tí Jèhófà fún wọn lófin yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà! Ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn tan ara wọn jẹ, wọ́n rò pé àwọn ṣì ń ṣe ti Jèhófà. Kódà, Áárónì sọ fún wọn pé “Àjọyọ̀ fún Jèhófà” ni wọ́n ń ṣe. Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára Jèhófà? Ó dùn ún gan-an, ó sì sọ fún Mósè pé wọ́n ti “gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun,” wọ́n sì “ti yà kúrò ní ọ̀nà tí [òun] pa láṣẹ fún wọn láti máa rìn.” Èyí mú kí ‘ìbínú Jèhófà ru’ débi pé ó ronú àtipa wọ́n run.—Ẹ́kís. 32:5-10.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ó Yẹ Ká Ní Àkókò fún Iṣẹ́ àti Ìsinmi
Ṣé bí Jèhófà àti Jésù kò ṣe fiṣẹ́ ṣeré yìí wá túmọ̀ sí pé àwa náà ò gbọ́dọ̀ sinmi? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Kì í rẹ Jèhófà, torí náà kò nílò ìsinmi báwa èèyàn ṣe máa ń sinmi. Bó ti wù kó rí, Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Jèhófà dá ọ̀run àti ayé, ‘ó sinmi, ara sì tù ú.’ (Ẹ́kís. 31:17) Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ ni pé Jèhófà dáwọ́ dúró díẹ̀ kó lè fara balẹ̀ wo àwọn nǹkan tó dá, ìyẹn sì múnú rẹ̀ dùn. Jésù náà ṣiṣẹ́ kára nígbà tó wà láyé, síbẹ̀ ó wáyè láti sinmi, òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì jọ gbádùn ara wọn.—Mát. 14:13; Lúùkù 7:34.
w87 9/1 29
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ti pé Ọlọ́run rántí ẹnì kan tó sì tẹ́wọ́ gbà á (tàbí pé wọ́n “kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé ìyè”) kò túmọ̀ sí pé ó ti di dandan kó wà láàyè títí láé, bíi pé Ọlọ́run ti kádàrá pé bó ṣe máa rí nìyẹn. Nígbà tí Mósè ń bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Tí o bá fẹ́, dárí jì wọ́n; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀ọ́, pa mí rẹ́ kúrò nínú ìwé rẹ tí o kọ.” Ọlọ́run dá a lóhùn pé: “Màá pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣẹ̀ mí rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Ẹ́kísódù 32:32, 33) Kódà tí Ọlọ́run bá ti kọ orúkọ ẹnì kan sínú “ìwé” rẹ̀, ẹni yẹn ṣì lè ṣàìgbọràn kó sí fi Jèhófà sílẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run máa “yọ orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè.”—Ìfihàn 3:5.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 33-34
“Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Tó Fani Mọ́ra”
it-2 466-467
Orúkọ
Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run wà, àmọ́ àwọn nǹkan yẹn ò sọ orúkọ Ọlọ́run fún wa. (Sm 19:1; Ro 1:20) Ti pé ẹnì kan kàn mọ orúkọ Ọlọ́run ò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún mọ Ọlọ́run dáadáa. (2Kr 6:33) Ká tó lè sọ pé ẹnì kan mọ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe, àwọn ohun tó ń ṣe àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ. (Fi wé 1Ọb 8:41-43; 9:3, 7; Ne 9:10.) Àpẹẹrẹ Mósè jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà sọ pé òun ‘fi orúkọ mọ’ Mósè, ìyẹn ni pé ó mọ̀ ọ́n dáadáa. (Ẹk 33:12) Mósè láǹfààní láti rí ògo Jèhófà, ó sì tún gbọ́ bí wọ́n ṣe ń “kéde orúkọ Jèhófà.” (Ẹk 34:5) Ìkéde yìí kì í kàn ṣe pé wọ́n ń pe orúkọ Jèhófà léraléra, ṣe ni wọ́n ń sọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini, àmọ́ tí kò ní ṣàìfi ìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀, tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá jẹ àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ ọmọ, dórí ìran kẹta àti dórí ìran kẹrin.” (Ẹk 34:6, 7) Bákan náà, nínú orin tí Mósè kọ, tó ti sọ pé “torí màá kéde orúkọ Jèhófà,” ó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sì ṣàlàyé irú ẹni tí Jèhófà jẹ́.—Di 32:3-44.
Jèhófà Ṣàpèjúwe Irú Ẹni Tóun Jẹ́
Ohun àkọ́kọ́ tí Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ ni pé òún jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” (Ẹsẹ 6) Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a tú sí “aláàánú” jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa ń “ṣàánú lọ́nà tó tuni lára, bí ìgbà tí bàbá kan ń ṣàánú àwọn ọmọ ẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tá a tú sí ‘oore ọ̀fẹ́’ sì ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣe tí wọ́n fi ń “ṣàpèjúwe ẹni tó ṣe tán láti ran aláìní lọ́wọ́ tọkàntọkàn.” Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé báwọn òbí ṣe máa ń tọ́jú àwọn ọmọ wọn lòun náà ṣe máa ń tọ́jú àwọn tó bá ń sin òun, ó fẹ́ràn wọn dénú, àwọn ohun tí wọ́n nílò sì jẹ ẹ́ lógún.—Sáàmù 103:8, 13.
Jèhófà wá sọ tẹ̀ lé e pé òun máa “ń lọ́ra láti bínú.” (Ẹsẹ 6) Kì í tètè bínú sí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ní sùúrù fún wa, ó máa ń ro ti pé a jẹ́ aláìpé mọ́ wa lára bó ṣe ń fún wa lákòókò tó pọ̀ tó láti fìwà ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀.—2 Pétérù 3:9.
Ọlọ́run tún sọ pé òún “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” (Ẹsẹ 6) Inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ àtọkànwá ni ànímọ́ àtàtà tí Jèhófà fi ń mú kí ìdè ìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ lágbára. (Diutarónómì 7:9) Jèhófà náà tún ni orísun òtítọ́ gbogbo. Kò sẹ́ni tó lè tàn án jẹ, bẹ́ẹ̀ lòun náà ò sì ní tan ẹnikẹ́ni jẹ. Torí pé òun ni “Ọlọ́run òtítọ́,” tọkàntọkàn la fi gba gbogbo ohun tó sọ gbọ́, títí kan àwọn ìlérí tó ṣe fún wa nípa ọjọ́ iwájú.—Sáàmù 31:5.
Jèhófà Ṣàpèjúwe Irú Ẹni Tóun Jẹ́
Òtítọ́ míì tó ṣe pàtàkì tí Jèhófà tún fẹ́ ká mọ̀ nípa òun ni pé òún máa “ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Ẹsẹ 7) ‘Ó ṣe tán láti dárí ji’ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. (Sáàmù 86:5) Àmọ́, Jèhófà kì í fàyè gba ìwàkiwà. Ó ṣàlàyé pé “lọ́nàkọnà” òun “kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹsẹ 7) Ọlọ́run mímọ́ tó ń ṣèdájọ́ òdodo ò ní fàwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà. Bó pẹ́ bó yá, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa jèrè iṣẹ́ burúkú ọwọ́ wọn.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
33:11, 20—Báwo ni Ọlọ́run ṣe bá Mósè sọ̀rọ̀ “ní ojúkojú”? Gbólóhùn yìí túmọ̀ sí pé kí ẹni méjì máa bá ara wọn sọ̀rọ̀. Mósè bá aṣojú Ọlọ́run sọ̀rọ̀, Jèhófà sì tipasẹ̀ aṣojú náà bá Mósè sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, Mósè ò rí Jèhófà, níwọ̀n bí ‘kò ti sí ẹni tó lè rí Ọlọ́run kó sì tún wà láàyè.’ Àní ṣẹ́, Jèhófà ò bá Mósè sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Ohun tí ìwé Gálátíà 3:19 sọ ni pé ‘a sì ta Òfin látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì láti ọwọ́ alárinà kan.’
Rí i Dájú Pé O Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú!
Ìgbà mẹ́ta lọ́dún ni a pàṣẹ fún ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì àti aláwọ̀ṣe ní ilẹ̀ náà láti fara hàn níwájú Jèhófà. Nítorí tí ọ̀pọ̀ olórí ìdílé mọ̀ pé gbogbo ìdílé náà ni yóò jàǹfààní nípa tẹ̀mí nínú irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣètò pé kí aya wọn àti àwọn ọmọ wọn bá wọn lọ. Ṣùgbọ́n ta ni yóò máa ṣọ́ ilé àti oko wọn tí àwọn ọ̀tá bá dé nígbà tí ìdílé náà ti rìnrìn àjò? Jèhófà ṣèlérí pé: “Ojú ẹnikẹ́ni kì yóò sì wọ ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ láti rí ojú Jèhófà Ọlọ́run ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún.” (Ẹ́kísódù 34:24) Ó gba ìgbàgbọ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè gbà pé bí àwọn bá fi ire tẹ̀mí ṣáájú, àwọn kò ní pàdánù ohunkóhun. Jèhófà ha mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ bí? Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́!
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 35-36
“Jèhófà Ràn Wọ́n Lọ́wọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀”
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Ní Ẹ̀mí Ìmúratán
Kì í ṣe ohun tí wọ́n mú wá ló mú inú Jèhófà dùn, bí kò ṣe ẹ̀mí ìmúratán tí wọ́n fi ń kọ́wọ́ ti ìjọsìn mímọ́. Àwọn èèyàn yìí tún yọ̀ǹda àkókò àti okun wọn. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn obìnrin . . . fi ọwọ́ wọn rànwú.” Kódà, “gbogbo obìnrin tí ọkàn-àyà wọn sún wọn ṣiṣẹ́ . . . ran irun ewúrẹ́.” Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún Bẹ́sálẹ́lì ní ‘ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.’ Ọlọ́run fi gbogbo ọgbọ́n ọnà tí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù nílò kún inú wọn kí wọ́n lè ṣe gbogbo iṣẹ́ tí ó gbé fún wọn.—Ẹ́kís. 35:25, 26, 30-35.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́ Ayé Ìgbàanì
Ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn tó gbáyé ní àkókò kan náà pẹ̀lú Mósè tó sì rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ni Bẹ́sálẹ́lì. Àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ nípa bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe lè máa darí wa. (Ka Ẹ́kísódù 35:30-35.) Jèhófà yan Bẹ́sálẹ́lì láti múpò iwájú nínú ṣíṣe àwọn ohun èlò fún àgọ́ ìjọsìn. Ṣé ó mọ̀ nípa iṣẹ́ ọnà kó tó di pé Ọlọ́run gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí lé e lọ́wọ́? Bóyá ni. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ mímọ bíríkì fáwọn ará Íjíbítì ló ṣe gbẹ̀yìn. (Ẹ́kís. 1:13, 14) Torí náà, báwo ni Bẹ́sálẹ́lì ṣe máa ṣe iṣẹ́ tó díjú tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́? Jèhófà “bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n, ti òye àti ti ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà kún inú rẹ̀ àti fún ṣíṣe iṣẹ́ ọnà àwọn nǹkan àfọgbọ́nrọ . . . láti ṣe onírúurú nǹkan tí a fi ọgbọ́n hùmọ̀.” Ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ mú kí ẹ̀bùn àbímọ́ni yòówù kí Bẹ́sálẹ́lì ní sunwọ̀n sí i. Bí ọ̀rọ̀ ti Òhólíábù náà sì ṣe rí nìyẹn. Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ti ní láti kẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, torí pé kì í wulẹ̀ ṣe pé wọ́n ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún kọ́ àwọn míì bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run fi í sí wọn lọ́kàn láti kọ́ àwọn míì.
Ẹ̀mí Ọlọ́run Darí Àwọn Olóòótọ́ Ayé Ìgbàanì
Ohun mìíràn tó fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ni pé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ṣe wà fún ìgbà pípẹ́. Àwọn èèyàn ṣì lo àwọn ohun tí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe wọ́n. (2 Kíró. 1:2-6) Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù kò dà bí àwọn tó máa ń ṣe nǹkan lóde òní tó jẹ́ pé wọ́n máa ń kọ orúkọ wọn sára ohun tí wọ́n bá ṣe tàbí kí wọ́n sàmì sí i. Jèhófà ni ọpẹ́ yẹ, torí pé òun ló mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí.—Ẹ́kís. 36:1, 2.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Mọ Àwọn Ọ̀nà Jèhófà
Máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ohun tara ṣèdíwọ́ fáwọn ohun tẹ̀mí. Wọn kò gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lépa nǹkan tara ṣáá. Jèhófà ya ọjọ́ kan tó kà sí mímọ́ sọ́tọ̀ ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kìkì àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbọ́dọ̀ máa ṣe lọ́jọ́ náà. (Ẹ́kísódù 35:1-3; Númérì 15:32-36) Lọ́dọọdún, wọ́n tún gbọ́dọ̀ fi àyè sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe àwọn àpéjọ mímọ́ kan tó jẹ́ àkànṣe. (Léfítíkù 23:4-44) Ìwọ̀nyí á jẹ́ kí wọ́n lè ráyè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ribiribi tí Jèhófà ti ṣe, wọ́n á tún rántí àwọn ọ̀nà rẹ̀, wọ́n á sì lè fi ìmoore hàn nítorí gbogbo oore rẹ̀. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe ohun wọ̀nyí nínú ìjọsìn wọn, wọ́n á túbọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un á jinlẹ̀ sí i, wọ́n á sì túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè máa rìn láwọn ọ̀nà rẹ̀. (Diutarónómì 10:12, 13) Àwọn ìlànà dáradára tó wà nínú àwọn ìtọ́ni wọ̀nyẹn ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní láǹfààní gan-an.—Hébérù 10:24, 25.
Fífi Ìwà Ọ̀làwọ́ Hàn Lọ́pọ̀ Yanturu Ń Máyọ̀ Wá
Wáá fojú inú wo bó ṣe máa rí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ìran kan tó ti jìyà gan-an níbi tí wọ́n ti ń sìnrú lọ́nà kíkorò, tí wọ́n sì fi nǹkan dù wọ́n. Wọ́n ti wá dòmìnira báyìí, wọ́n sì tún ní àwọn nǹkan ti ara lọ́pọ̀ yanturu. Báwo ni kíkó lára àwọn nǹkan ìní wọ̀nyẹn sílẹ̀ ṣe máa wá rí lára wọn? Wọ́n ti lè ronú pé ó ti di tàwọn ná, ó sì di dandan fáwọn láti fi gbọ́ tara àwọn. Àmọ́, nígbà táa pè wọ́n láti wá fowó ṣètọrẹ kí wọ́n lè kọ́wọ́ ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀—wọn ò lọ́ tìkọ̀, wọn ò sì fi ìwà ahun ṣe é! Wọn ò gbàgbé pé Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún àwọn láti ní àwọn nǹkan ìní wọ̀nyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ọ̀pọ̀ yanturu fàdákà àti wúrà àti ohun ọ̀sìn wọn tọrẹ. Wọ́n jẹ́ “ọlọ́kàn ìmúratán.” ‘Ọkàn-àyà’ wọn ‘sún wọn ṣiṣẹ́.’ ‘Ẹ̀mí wọn ru wọ́n sókè.’ Ní ti tòótọ́, “ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe . . . fún Jèhófà” ni.—Ẹ́kísódù 25:1-9; 35:4-9, 20-29; 36:3-7.
Bíbélì Kíkà
OCTOBER 26–NOVEMBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 37-38
“Ohun Tí Pẹpẹ Àgọ́ Ìjọsìn Wà Fún”
it-1 82 ¶3
Pẹpẹ
Pẹpẹ tùràrí. Igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe pẹpẹ tùràrí (wọ́n tún ń pè é ní “pẹpẹ wúrà” [Ẹk 39:38]), wọ́n sì fi wúrà bo òkè àti àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yí ká. Wọ́n ṣe ìgbátí wúrà sí òkè rẹ̀ yí ká. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì. Ó tún ní àwọn “ìwo” tó yọ jáde ní àwọn igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Wọ́n fi wúrà ṣe òrùka méjì sára rẹ̀, kí wọ́n lè máa ki àwọn ọ̀pá tí wọ́n á fi máa gbé e bọ ibẹ̀. Igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì fi wúrà bò ó. Abẹ́ ìgbátí wúrà tó wà lókè rẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn òrùka yìí sí, lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì tó wà lódìkejì ara wọn. (Ẹk 30:1-5; 37:25-28) Tùràrí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan wà tí wọ́n máa ń sun lórí pẹpẹ yìí lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́, wọ́n máa ń sun ún láàárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́. (Ẹk 30:7-9, 34-38) Àwọn ẹsẹ Bíbélì míì sọ pé wọ́n tún máa ń lo ìkóná láti fi sun tùràrí, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n máa ń lo ìkóná pọ̀ mọ́ pẹpẹ tùràrí. (Le 16:12, 13; Heb 9:4; Ifi 8:5; fi wé 2Kr 26:16, 19.) Inú àgọ́ ìjọsìn ni wọ́n máa ń gbé pẹpẹ tùràrí náà sí, níwájú aṣọ ìkélé tó bo Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé “[iwájú] àpótí Ẹ̀rí” ló wà.—Ẹk 30:1, 6; 40:5, 26, 27.
it-1 1195
Tùràrí
Àwọn ohun èlò olówó ńlá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣètọrẹ ni wọ́n fi ṣe tùràrí mímọ́ tí wọ́n máa ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn tó wà nínú aginjù. (Ẹk 25:1, 2, 6; 35:4, 5, 8, 27-29) Jèhófà ló sọ àwọn nǹkan mẹ́rin tí wọ́n máa pò pọ̀ láti fi ṣe tùràrí náà fún Mósè, ó ní: “Mú àwọn lọ́fínńdà yìí ní ìwọ̀n kan náà: àwọn ẹ̀kán sítákítè, ọ́níkà, gábánọ́mù onílọ́fínńdà àti ògidì oje igi tùràrí. Kí o fi ṣe tùràrí; kí o ro àwọn èròjà náà pọ̀ dáadáa, fi iyọ̀ sí i, kó jẹ́ ògidì, kó sì jẹ́ mímọ́. Kí o gún lára rẹ̀, kó sì kúnná, kí o wá bu lára rẹ̀ síwájú Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé, níbi tí màá ti pàdé rẹ. Kó jẹ́ mímọ́ jù lọ fún yín.” Jèhófà wá sọ ohun kan tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tùràrí yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, ó sì jẹ́ mímọ́. Ó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ṣe ohun tó jọ ọ́ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò nínú àwọn èèyàn rẹ̀.”—Ẹk 30:34-38; 37:29.
it-1 82 ¶1
Pẹpẹ
Àwọn Pẹpẹ Àgọ́ Ìjọsìn. Nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà ní kí wọ́n ṣe pẹpẹ méjì. Igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe pẹpẹ ẹbọ sísun (wọ́n tún ń pè é ní “pẹpẹ bàbà” [Ẹk 39:39]). Wọ́n ṣe é bí àpótí tó níhò láàárín, ìyẹn fi hàn pé wọn ò fi nǹkan bò ó lókè àti nísàlẹ̀. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta. “Ìwo” yọ jáde ní igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lókè. Bàbà ni wọ́n fi bò ó yí ká. Wọ́n fi bàbà ṣe àgbàyan tó rí bí àwọ̀n, wọ́n sì gbé e sí “ọwọ́ ìsàlẹ̀” etí pẹpẹ náà “níbi àárín.” Wọ́n ṣe òrùka mẹ́rin sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹpẹ náà nítòsí àgbàyan náà, ó sì jọ pé ibẹ̀ náà ni wọ́n á máa ki àwọn ọ̀pá bọ̀ láti máa fi gbé pẹpẹ náà. Méjì ni àwọn ọ̀pá yìí, igi bọn-ọ̀n-ní ni wọ́n fi ṣe é, wọ́n sì fi bàbà bò ó. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gé apá ibì kan lára pẹpẹ yìí légbẹ̀ẹ́ méjì, kí wọ́n lè máa kí àgbàyan náà bọ ibẹ̀, àwọn òrùka náà sì yọ síta lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì. Ẹnu àwọn ọ̀mọ̀wé ò kò lórí ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì gbà pé àwọn òrùka míì wà lára pẹpẹ yìí lọ́wọ́ ìta tí wọ́n máa ń ki òpá bọ̀ láti fi gbé e. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bàbà ṣe àwọn garawa àti ṣọ́bìrì láti máa fi kó eérú, wọ́n tún ṣe abọ́ láti máa fi gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran, wọ́n ṣe àmúga láti máa fi mú ẹran, wọ́n sì ṣe ìkóná.—Ẹk 27:1-8; 38:1-7, 30; Nọ 4:14.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 36
Igi Bọn-ọ̀n-ní
Igi bọn-ọ̀n-ní máa ń ní ẹ̀gún lára gan-an, àwọn ẹ̀gún yìí sì máa ń yọ ṣọọrọ-ṣọọrọ jáde látara àwọn ẹ̀ka rẹ̀ fífẹ̀. Àwọn ẹ̀ka yìí sábà máa ń so kọ́ àwọn ẹ̀ka igi bọn-ọ̀n-ní míì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn débi pé àwọn ẹ̀ka náà á ti wá lọ́jú pọ̀. Ohun tó fà á nìyí tó fi jẹ́ pé shit·timʹ tó jẹ́ ọ̀rọ̀ tó máa ń tọ́ka sí nǹkan púpọ̀ ni Bíbélì sábà máa ń lò tó bá ń dárúkọ igi yìí. Igi bọn-ọ̀n-ní máa ń ga tó mítà mẹ́fà sí mẹ́jọ, àwọn igi yìí sì máa ń sù pọ̀. Ewé rẹ̀ rí múlọ́múlọ́, ó dà bí ìyẹ́, ó sì máa ń ní òdòdó yẹ́lò tó máa ń ta sánsán. Èso rẹ̀ máa ń rí kọdọrọ, ó sì máa ń ní àwọn kóró. Èèpo ẹ̀yìn igi náà rí hárahàra, ó sì dúdú. Tá a bá ṣí èèpo yìí kúrò, a máa rí i pé igi náà le, ara ẹ̀ jọ̀lọ̀, ó sì wúwo, kódà kòkòrò ò lè bà á jẹ́. Àwọn ohun tá a sọ nípa igi yìí àti bó ṣe máa ń pọ̀ ní aṣálẹ̀ ló jẹ́ kí wọ́n lè lò ó láti fi kọ́ àgọ́ ìjọsìn àtàwọn ohun èlò rẹ̀. Òun ni wọ́n fi kọ́ àpótí májẹ̀mú (Ẹk 25:10; 37:1), tábìlì búrẹ́dì àfihàn (Ẹk 25:23; 37:10), àwọn pẹ́pẹ́ (Ẹk 27:1; 37:25; 38:1), àwọn òpó tí wọ́n fi ń gbé àwọn nǹkan yìí (Ẹk 25:13, 28; 27:6; 30:5; 37:4, 15, 28; 38:6), àwọn òpó tí wọ́n ń gbé aṣọ ìdábùú àti aṣọ ìkélé kọ́ (Ẹk 26:32, 37; 36:36), àwọn férémù àgọ́ ìjọsìn (Ẹk 26:15; 36:20) àtàwọn ọ̀pá gbọọrọ tó so wọ́n pọ̀ (Ẹk 26:26; 36:31).
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Àwọn dígí tí wọ́n ń lò láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì yàtọ̀ sí tòde òní. Nígbà yẹn, irin tí wọ́n dán dáadáa ni wọ́n fi ń ṣe dígí. Idẹ ni wọ́n sábà máa ń lò, àmọ́ wọ́n tún máa ń lo bàbà, fàdákà, wúrà tàbí fàdákà àti wúrà tí wọ́n yọ́ pọ̀. Ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa dígí ni ìgbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ìyẹn ilé àkọ́kọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò fún ìjọsìn. Àwọn obìnrin dá dígí jọ kí wọ́n lè fi ṣe bàsíà bàbà àti ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀. (Ẹ́kísódù 38:8) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi iná yọ́ àwọn dígí yìí kí wọ́n tó lè fi ṣe bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀.
Bíbélì Kíkà