“Ta Ni Ó Wà ní Ìhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà?”
“Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o bẹ̀rù. Òun ni kí o máa sìn, òun ni kí o sì rọ̀ mọ́.”—DIU. 10:20.
1, 2. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká wà lọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
KÒ SÍ àní-àní pé ti Jèhófà ló yẹ ká ṣe. Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó lágbára, tó gbọ́n, tó sì nífẹ̀ẹ́ tó Ọlọ́run wa! Ó dájú pé kò sẹ́ni tí kò ní fẹ́ wà lọ́dọ̀ Jèhófà. (Sm. 96:4-6) Síbẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan wà tó fi Jèhófà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n kojú àdánwò.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àpẹẹrẹ àwọn kan tó sọ pé ti Jèhófà làwọn ń ṣe, àmọ́ tó jẹ́ pé nǹkan tí Jèhófà kórìíra ni wọ́n ń lọ́wọ́ sí. Bá a ṣe ń gbé àpẹẹrẹ wọn yẹ̀ wò, a máa rí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa mú ká pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà lábẹ́ ipòkípò.
JÈHÓFÀ MÁA Ń YẸ ỌKÀN WA WÒ
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi kìlọ̀ fún Kéènì, kí ni Jèhófà sọ fún un?
3 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Kéènì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kéènì sọ pé òun ń sin Jèhófà, síbẹ̀ Jèhófà ò fojúure wo ìjọsìn Kéènì. Ìdí sì ni pé ìkórìíra ti ń jọba lọ́kàn rẹ̀. (1 Jòh. 3:12) Jèhófà wá kìlọ̀ fún Kéènì pé: “Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?” (Jẹ́n. 4:6, 7) Ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún Kéènì pé, “Tó o bá ronú pìwà dà, tó o sì dúró sọ́dọ̀ mi, èmi náà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀.”
4. Kí ni Kéènì ṣe nígbà tí Jèhófà fún un nímọ̀ràn?
4 Jèhófà máa fojúure hàn sí Kéènì tó bá lè fa èrò burúkú tó wà lọ́kàn rẹ̀ tu. Àmọ́ Kéènì ò gba ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, èrò burúkú tó wà lọ́kàn rẹ̀ àti ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tó ní mú kó hùwà burúkú. (Ják. 1:14, 15) Nígbà tí Kéènì wà lọ́dọ̀ọ́, ó ṣeé ṣe kó má ronú ẹ̀ rí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun máa fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, Kéènì hùwà burúkú, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì pa àbúrò rẹ̀!
5. Irú èrò wo ló lè mú ká pàdánù ojú rere Jèhófà?
5 Bíi ti Kéènì, àwọn Kristẹni kan lónìí sọ pé àwọn ń sin Jèhófà, àmọ́ wọ́n tún ń lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. (Júúdà 11) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè máa lọ sípàdé déédéé, kó sì máa kópa tó jọjú lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, èròkérò lè ti gba ẹni yẹn lọ́kàn tàbí kó jẹ́ pé ìrònú bó ṣe máa ní tibí ní tọ̀hún ló gbà á lọ́kàn tàbí kó tiẹ̀ kórìíra arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ̀. (1 Jòh. 2:15-17; 3:15) Irú àwọn èrò burúkú bẹ́ẹ̀ lè mú kó hùwàkiwà. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lè má mọ ohun tá à ń rò tàbí ohun tá à ń ṣe. Àmọ́ ká rántí pé Jèhófà rí ohun gbogbo, ó sì máa mọ̀ tá ò bá sìn ín tọkàntọkàn.—Ka Jeremáyà 17:9, 10.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè “kápá” èrò òdì?
6 Tá a bá ṣàṣìṣe, Jèhófà ṣì máa ń mú sùúrù fún wa. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fìfẹ́ rọ àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.” (Mál. 3:7) Jèhófà mọ̀ pé a láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá à ń bá yí, síbẹ̀ ó fẹ́ ká sapá ká lè borí wọn. (Aísá. 55:7) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà náà máa dúró tì wá, á sì fún wa ní okun tá a nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí ká lè “kápá” èrò òdì.—Jẹ́n. 4:7.
“KÍ A MÁ ṢÌ YÍN LỌ́NÀ”
7. Kí ló mú kí Sólómọ́nì pàdánù ojú rere Jèhófà?
7 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sólómọ́nì. Nígbà tí Sólómọ́nì wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà. Jèhófà wá fún un ní ọgbọ́n tó tayọ, ó sì fún un láǹfààní láti kọ́ tẹ́ńpìlì rèǹtèrente tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀, Sólómọ́nì pàdánù ojú rere Jèhófà. (1 Ọba 3:12; 11:1, 2) Kí nìdí? Jèhófà dìídì pàṣẹ fáwọn Ọba Ísírẹ́lì pé wọn ò “gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara [wọn], kí ọkàn-àyà [wọn] má bàa yà kúrò” lọ́dọ̀ Jèhófà. (Diu. 17:17) Àmọ́ Sólómọ́nì ṣàìgbọràn, ó sì fẹ́ ọgọ́rùn-ún méje [700] ìyàwó, kódà ó tún ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] wáhàrì. (1 Ọba 11:3) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nínú àwọn obìnrin yìí ni kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì máa ń bọ̀rìṣà. Èyí fi hàn pé Sólómọ́nì tún rú òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.—Diu. 7:3, 4.
8. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ tí Sólómọ́nì dá ṣe burú tó?
8 Díẹ̀díẹ̀ ni Sólómọ́nì ń fọwọ́ rọ́ àwọn òfin Jèhófà sẹ́gbẹ̀ẹ́. Èyí sì mú kó hu àwọn ìwà tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì kọ́ pẹpẹ kan fún òrìṣà Áṣítórétì, ó sì tún kọ́ òmíì fún òrìṣà Kémóṣì. Ibẹ̀ sì lòun àtàwọn ìyàwó rẹ̀ ti ń bọ̀rìṣà. Ibi tó wá burú sí ni pé orí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù níbi tí tẹ́ńpìlì Jèhófà wà ló kọ́ àwọn pẹpẹ yẹn sí! (1 Ọba 11:5-8; 2 Ọba 23:13) Ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì máa tan ara rẹ̀ jẹ pé Jèhófà máa gbójú fo ìwà burúkú tóun hù tóun bá ṣáà ti ń rúbọ sí Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì.
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì kọtí ikún sí ìkìlọ̀ Jèhófà?
9 Òótọ́ kan tó yẹ ká fi sọ́kàn ni pé Jèhófà kì í gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan dá. Bíbélì sọ pé: “Ìbínú Jèhófà sì wá ru sí Sólómọ́nì, nítorí pé ọkàn-àyà rẹ̀ ti tẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà . . . , ẹni tí ó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì. Nípa ohun yìí sì ni ó pàṣẹ fún un pé kí ó má tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn,” ṣùgbọ́n kò pa àṣẹ Jèhófà mọ́. Torí náà, Jèhófà pa dà lẹ́yìn Sólómọ́nì, ó sì pàdánù ojúure Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì kú, ìjọba Ísírẹ́lì pín sí méjì, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ sì kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro.—1 Ọba 11:9-13.
10. Kí ló lè ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́?
10 Bíi ti Sólómọ́nì, tá a bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí kò ka àwọn ìlànà Jèhófà sí, àjọṣe àwa àti Jèhófà lè bà jẹ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè wà nínú ìjọ àmọ́ kó jẹ́ pé wọ́n ò ka nǹkan tẹ̀mí sí pàtàkì. Ó sì lè jẹ́ àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà bí àwọn mọ̀lẹ́bí wa, àwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ iléèwé wa. Ẹni yòówù kó jẹ́, tí àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ò bá ka àwọn ìlànà Jèhófà sí, bópẹ́ bóyá wọ́n lè mú ká pàdánù ojúure Jèhófà.
11. Kí ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o yẹra fẹ́nì kan tó ò ń bá kẹ́gbẹ́?
11 Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló láwọn ànímọ́ kan tó dáa, kódà ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kì í hùwàkiwà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o lè máa bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kẹ́gbẹ́? Ó yẹ kó o ronú lórí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà tó o bá ń bá wọn rìn. Ṣé wọ́n lè mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Kí ló máa ń jẹ wọ́n lọ́kàn? Bí àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣọ̀rọ̀ aṣọ, owó, àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, bí wọ́n á ṣe gbafẹ́ àti bí wọ́n á ṣe kó nǹkan tara jọ ni wọ́n máa ń sọ ní gbogbo ìgbà? Ṣé wọ́n sábà máa ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn míì, kí wọ́n sì máa sọ̀rọ̀ rírùn? Jésù kìlọ̀ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Tó o bá rí i pé àwọn tó ò ń bá rìn lè ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́, ó yẹ kó o gbé ìgbésẹ̀ kíá, kó o dín wọléwọ̀de rẹ pẹ̀lú wọn kù tàbí kó o tiẹ̀ yẹra fún wọn pátápátá.—Òwe 13:20.
JÈHÓFÀ FẸ́ KÁ JỌ́SÌN ÒUN NÌKAN
12. (a) Kí ni Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì? (b) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ nígbà tí Jèhófà sọ pé kí wọ́n dúró sọ́dọ̀ òun?
12 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Àwọn èèyàn náà pé jọ síwájú Òkè Sínáì. Níbẹ̀, Jèhófà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun wà láàárín wọn. Jèhófà jẹ́ kí àwọsánmà tó dúdú bo orí òkè náà, ààrá ń sán, mànàmáná ń bù yẹ̀rì, bẹ́ẹ̀ ni èéfín ń rú yọ, ìró ìwo tó ń dún láìdáwọ́dúró sì ń ròkè lálá. (Ẹ́kís. 19:16-19) Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ lọ́jọ́ yẹn pé òun jẹ́ “Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” Ó wá mú un dá wọn lójú pé òun máa dúró ti àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òun tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ òun mọ́. (Ka Ẹ́kísódù 20:1-6.) Lédè míì, ṣe ni Jèhófà ń sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé, “Màá dúró tì yín tẹ́ ẹ bá dúró sọ́dọ̀ mi.” Ká sọ pé ìwọ náà wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, báwo lohun tí Jèhófà sọ ṣe máa rí lára rẹ? Ó dájú pé ìwọ náà á dáhùn bíi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bíbélì sọ pé wọ́n “dáhùn ní ohùn kan, wọ́n sì wí pé: ‘Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ ni àwa múra tán láti ṣe.’ ” (Ẹ́kís. 24:3) Àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn lohun kan ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà.
13. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fi hàn pé wọn kì í ṣe adúróṣinṣin?
13 Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí àwọsánmà dúdú tó bolẹ̀, mànàmáná tó ń bù yẹ̀rì àtàwọn nǹkan àrà míì tí Ọlọ́run ṣe. Wọ́n wá bẹ Mósè pé kó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn lọ́dọ̀ Jèhófà lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kís. 20:18-21) Mósè gòkè lọ, ó sì pẹ́ gan-an lórí òkè náà. Làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Ó jọ pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́ torí pé wọn ò rí Mósè tó jẹ́ aṣáájú wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ti gbára lé Mósè jù, tó fi jẹ́ pé tí wọ́n ò bá rí i, àtisin Jèhófà máa dìṣòro fún wọn. Wọ́n wá sọ fún Áárónì pé: “Ṣe ọlọ́run kan fún wa tí yóò máa ṣáájú wa, nítorí, ní ti Mósè yìí, ẹni tí ó mú wa gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, dájúdájú, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”—Ẹ́kís. 32:1, 2.
14. Èrò òdì wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní, báwo lohun tí wọ́n ṣe ṣe rí lára Jèhófà?
14 Àwọn èèyàn náà mọ̀ dáadáa pé Jèhófà kórìíra ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-5) Àmọ́ kò pẹ́ tí Jèhófà fún wọn lófin yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà! Ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn tan ara wọn jẹ, wọ́n rò pé àwọn ṣì ń ṣe ti Jèhófà. Kódà, Áárónì sọ fún wọn pé “Àjọyọ̀ fún Jèhófà” ni wọ́n ń ṣe. Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe rí lára Jèhófà? Ó dùn ún gan-an, ó sì sọ fún Mósè pé wọ́n ti “gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun,” wọ́n sì “ti yà kúrò ní ọ̀nà tí [òun] pa láṣẹ fún wọn láti máa rìn.” Èyí mú kí ‘ìbínú Jèhófà ru’ débi pé ó ronú àtipa wọ́n run.—Ẹ́kís. 32:5-10.
15, 16. Báwo ni Mósè àti Áárónì ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
15 Torí pé aláàánú ni Jèhófà, ó pinnu pé òun ò ní pa gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run. Ó wá fún àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ láǹfààní láti fi hàn pé adúróṣinṣin ni wọ́n. (Ẹ́kís. 32:14) Nígbà tí Mósè rí báwọn èèyàn náà ṣe ń pariwo, tí wọ́n ń kọrin, tí wọ́n sì ń jó níwájú ère náà, ṣe ló fọ́ ère náà mọ́lẹ̀, ó sì lọ̀ ọ́ títí tó fi di lẹ́búlẹ́bú. Lẹ́yìn náà, Mósè kéde pé: “ ‘Ta ni ó wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà? Kí ó wá sọ́dọ̀ mi!’ Gbogbo àwọn ọmọ Léfì sì bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ sọ́dọ̀” Mósè.—Ẹ́kís. 32:17-20, 26.
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áárónì ló bá wọn ṣe ère náà, síbẹ̀ ó ronú pìwà dà, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Kì í ṣe pé àwọn olóòótọ́ yìí jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nìkan, ṣe ni wọ́n tún ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn aláìṣòótọ́. Ìpinnu tó dáa ni wọ́n ṣe yìí torí pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́jọ́ yẹn torí ìbọ̀rìṣà. Àmọ́, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ adúróṣinṣin.—Ẹ́kís. 32:27-29.
17. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó kìlọ̀ pé: ‘Nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má bàa di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe. A sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá. Nítorí náà, kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.’ (1 Kọ́r. 10:6, 7, 11, 12) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó ń sin Jèhófà lè bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìwà burúkú tí wọ́n ò bá ṣọ́ra. Ẹni tó lọ́wọ́ sí ìwà burúkú lè máa ronú pé òun ṣì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àmọ́ ká fi sọ́kàn pé, ó lè máa wu ẹnì kan láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà tàbí kó ronú pé òun jẹ́ adúróṣinṣin, síbẹ̀ kí inú Jèhófà má dùn sẹ́ni náà.—1 Kọ́r. 10:1-5.
18. Kí ló lè mú kẹ́nì kan fi Jèhófà sílẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀?
18 Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń ṣàníyàn torí pé Mósè pẹ́ lórí Òkè Sínáì, àwa Kristẹni lónìí náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti ń pẹ́ jù, ká sì máa ronú pé ìgbà wo ni ayé tuntun máa dé. Ó lè jọ pé àwọn ìlérí Jèhófà ti ń pẹ́ jù lójú wa tàbí pé wọ́n dà bí àlá tí kò lè ṣẹ. Tá ò bá tún èrò wa ṣe, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan tara, ká sì pa ìjọsìn Jèhófà tì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àá fi Jèhófà sílẹ̀, àá sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sáwọn ìwà burúkú tá ò lérò pé a lè lọ́wọ́ sí tẹ́lẹ̀.
19. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo, kí sì nìdí?
19 Ó yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé Jèhófà fẹ́ ká máa ṣègbọràn sí òun látọkànwá, ká sì jọ́sìn òun nìkan. (Ẹ́kís. 20:5) Tá a bá ṣe ohunkóhun tó yàtọ̀ sí ìfẹ́ Jèhófà, á jẹ́ pé ìfẹ́ Sátánì la ṣe yẹn, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ ò sì ní dáa. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ẹ kò lè máa mu ife Jèhófà àti ife àwọn ẹ̀mí èṣù; ẹ kò lè máa ṣalábàápín ‘tábìlì Jèhófà’ àti tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.”—1 Kọ́r. 10:21.
RỌ̀ MỌ́ JÈHÓFÀ!
20. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ṣàṣìṣe?
20 Ohun kan jọra nínú ìtàn Kéènì, Sólómọ́nì àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkè Sínáì. Gbogbo wọn ló láǹfààní láti ‘ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí padà.’ (Ìṣe 3:19) Èyí fi hàn pé Jèhófà máa ń mú sùúrù fáwọn tó bá ṣàṣìṣe. Àpẹẹrẹ Áárónì jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà. Bákan náà lónìí, Jèhófà máa ń lo àwọn ìtàn inú Bíbélì, àwọn ìtẹ̀jáde tàbí ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Kristẹni kan láti kìlọ̀ fún wa ká má bàa ṣàṣìṣe. Tá a bá fi àwọn ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sí wa.
21. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa tá a bá kojú àdánwò tó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀?
21 Ó nìdí tí Jèhófà fi ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wa. (2 Kọ́r. 6:1) Inú rere yìí máa ń jẹ́ ká lè “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé.” (Ka Títù 2:11-14.) Ohun kan ni pé tá a bá ṣì ń gbé “nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí,” àá máa kojú àwọn àdánwò tó lè mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé bíná ń jó, bíjì ń jà, ọ̀dọ̀ Jèhófà la máa wà torí pé ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ló yẹ ká bẹ̀rù. Òun ló yẹ ká máa sìn, òun ló sì yẹ ká rọ̀ mọ́’!—Diu. 10:20.