Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
NOVEMBER 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 39-40
“Mósè Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni Tí Jèhófà Fún Un”
Ṣé Jèhófà Mọ̀ Ẹ́?
Ìwà tí Mósè hù yàtọ̀ sí ti Kórà. Mósè “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.” (Núm. 12:3) Ó fi hàn pé òun jẹ́ oníwà-tútù àti onírẹ̀lẹ̀ torí pé ó pinnu láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Jèhófà fún un. (Ẹ́kís. 7:6; 40:16) Kò sí ohun tó fi hàn pé ńṣe ni Mósè ń kọminú ṣáá nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan tàbí kó máa bínú nítorí pé ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí Jèhófà gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà pàṣẹ fún un nípa bí wọ́n ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe fún un, tó fi mọ́ àwọ̀ àwọn òwú àgọ́ àti iye àwọn ihò kóróbójó tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe sí àwọn aṣọ àgọ́ náà. (Ẹ́kís. 26:1-6) Bí ẹnì kan tó jẹ́ alábòójútó nínú ètò Ọlọ́run bá fún ẹ ní ìtọ́ni tó dà bíi pé kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ ti pọ̀ jù, ìyẹn lè mú kí nǹkan tojú sú ẹ nígbà míì. Àmọ́, alábòójútó tó jẹ́ ẹni pípé ni Jèhófà, ó máa ń fa iṣẹ́ lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní fàlàlà, ó sì máa ń gbẹ̀rí wọn jẹ́. Bó bá ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé fún wọn, ìdí rere ní láti wà tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, má ṣe gbàgbé pé nígbà tí Jèhófà fún Mósè ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé, inú kò bí Mósè, kó wá máa rò pé ńṣe ni Jèhófà ń tẹ òun mẹ́rẹ̀ tàbí pé kò jẹ́ kóun lo ìdánúṣe tàbí òmìnira tí òun ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, Mósè rí i dájú pé àwọn òṣìṣẹ́ náà “ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́,” nípa títẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn. (Ẹ́kís. 39:32) Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Mósè mà pọ̀ o! Mósè mọ̀ pé ti Jèhófà ni iṣẹ́ náà, ó sì mọ̀ pé ńṣe ló wulẹ̀ lo òun láti rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe.
Ǹjẹ́ o Máa Ń ṣòótọ́ Nínú Gbogbo Nǹkan?
Hébérù orí kẹta ẹsẹ ìkarùn-ún sọ pé: “Mósè gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà . . . jẹ́ olùṣòtítọ́.” Kí ló mú kí Mósè wòlíì jẹ́ olùṣòtítọ́? Òun ni pé lákòókò tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, “Mósè . . . ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Ẹ́kísódù 40:16) Àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà ń fi hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́ nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run bá a ṣe ń sìn ín. Èyí tún kan jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nígbà tá a bá dojú kọ ìdánwò tàbí ìṣòro tó lékenkà. Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà tá a bá yege àwọn ìdánwò ńlá nìkan ló máa hàn pé a jẹ́ olùṣòtítọ́. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) Ó yẹ ká jẹ́ olùṣòtítọ́ kódà nínú àwọn nǹkan tó dà bíi pé kò tó nǹkan pàápàá.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 884 ¶3
Awọ Séálì
Bí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Ṣe Rí I. Tó bá jẹ́ oríṣi ẹranko kan tí wọ́n ń pè ní séálì ni ọ̀rọ̀ Hébérù náà, taʹchash ń tọ́ka sí, a lè béèrè pé báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe rí awọ séálì? Lóòótọ́, àwọn ibi tó tutù jù láyé làwọn séálì máa ń wà, àmọ́ àwọn kan máa ń fẹ́ wà níbi tí ojú ọjọ́ ti gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Lóde òní, oríṣi séálì kan tí ò létí ṣì wà lápá kan Òkun Mẹditaréníà àti láwọn òkun míì tó lọ́ wọ́ọ́rọ́. Àmọ́, láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, kò fi bẹ́ẹ̀ sí séálì mọ́, torí àwọn èèyàn máa ń pa wọ́n. Bẹ́ẹ̀ sì rèé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko yẹn pọ̀ létí Òkun Mẹditaréníà àti Òkun Pupa. Lọ́dún 1832, ìwé Calmet’s Dictionary of the Holy Bible (ojú ìwé. 139) lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn séálì máa ń wà ní èyí tó pọ̀ jù láwọn erékùṣù kéékèèké tó wà létí Òkun Pupa lágbègbè Sínáì.”—Tún wo ìwé The Tabernacle’s Typical Teaching, látọwọ́ A. J. Pollock, London, ojú ìwé 47.
Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Pé Kí Àwọn Èèyàn Rí Ohun Tó O Bá Ṣe?
Nígbà tí wọ́n parí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn náà, àwọsánmà “bẹ̀rẹ̀ sí bo àgọ́ ìpàdé, ògo Jèhófà sì kún inú àgọ́ ìjọsìn náà.” (Ẹ́kís. 40:34) Èyí fi hàn pé iṣẹ́ náà ní ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Báwo lo ṣe rò pé èyí máa rí lára Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbẹ́ orúkọ wọn sára àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe, ó dájú pé wọ́n máa ní ayọ̀ tó ti ọkàn wá torí wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ àwọn. (Òwe 10:22) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, inú wọn á ṣì máa dùn bí wọ́n ti ń rí i pé àgọ́ ìjọsìn náà ṣì wúlò fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nígbà tí Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù bá jíǹde nínú ayé tuntun, tí wọ́n wá mọ̀ pé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún lẹ́yìn náà, ni wọ́n fi lo àgọ́ ìjọsìn náà fún ìjọsìn tòótọ́, inú wọ́n máa dùn gan-an.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 1-3
“Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Mú Ọrẹ Wá”
it-2 525
Ọrẹ
Ọrẹ sísun. Tí ẹnì kan bá mú ẹran kan wá láti fi ṣe ọrẹ sísun, odindi ẹran yẹn ni wọ́n máa lò. Kò sí ìkankan lára ẹran náà tí wọ́n máa fún ẹni tó mú un wá. (Fi wé Ond 11:30, 31, 39, 40.) Wọ́n máa ń fi ọrẹ sísun bẹ Jèhófà kó lè tẹ́wọ́ gba ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n máa ń rú pẹ̀lú ọrẹ sísun náà nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù Kristi fi ara rẹ̀ rúbọ lódindi gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ sísun.”
it-2 528 ¶4
Ọrẹ
Ọrẹ ọkà. Wọ́n máa ń mú ọrẹ ọkà wá pẹ̀lú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ọrẹ sísun, ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn àkọ́so; ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń mú ọrẹ ọkà nìkan wá. (Ẹk 29:40-42; Le 23:10-13, 15-18; Nọ 15:8, 9, 22-24; 28:9, 10, 20, 26-28; orí 29) Àwọn èèyàn máa ń mú àwọn ọrẹ yìí wá láti fi dúpẹ́ oore tí Jèhófà ṣe fún wọn àti bó ṣe bù kún wọn. Wọ́n sábà máa ń mú un wá pẹ̀lú òróró àti oje igi tùràrí. Ọrẹ ọkà lè jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúnná, ọkà tí wọ́n yan, búrẹ́dì tó rí bí òrùka tàbí kó jẹ́ búrẹ́dì pẹlẹbẹ tí wọ́n yan nínú ààrò, agbada tàbí páànù. Wọ́n máa ń fi díẹ̀ lára ọrẹ ọkà rúbọ lórí pẹpẹ ọrẹ sísun, àwọn àlùfáà máa ń jẹ lára ẹ̀, tó bá sì jẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ ni, ẹni tó mú un wá máa jẹ nínú ẹ̀. (Le 6:14-23; 7:11-13; Nọ 18:8-11) Ìkankan nínú àwọn ọrẹ ọkà tí wọ́n bá fẹ́ fi rúbọ lórí pẹpẹ kò gbọ́dọ̀ ní ìwúkàrà tàbí “oyin” tó lè jẹ́ kó kan (ó jọ pé oje èso ọ̀pọ̀tọ́ tàbí omi èso ni oyin yìí túmọ̀ sí).—Le 2:1-16.
it-2 526 ¶1
Ọrẹ
Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ (tàbí ẹbọ àlàáfíà). Tí Jèhófà bá tẹ́wọ́ gba ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tẹ́nì kan mú wá, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àlàáfíà ti wà láàárín òun àti Jèhófà. Ẹni náà àti agbo ilé rẹ̀ máa jẹ lára ẹbọ náà (wọ́n á jẹ ẹ́ ní àgbàlá àgọ́ ìjọsìn, àṣà wọn nígbà yẹn ni pé wọ́n máa ń ṣe àtíbàbà sínú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn; tó bá sì jẹ́ tẹ́ńpìlì ni, inú yàrá ìjẹun ni wọ́n á ti jẹ ẹ́). Bákan náà, àlùfáà tó rú ẹbọ yẹn máa gba tiẹ̀, àwọn àlùfáà míì tó ṣiṣẹ́ níbẹ̀ náà máa gba tiwọn. Ní ti Jèhófà, ọ̀rá ẹran náà ni wọ́n á fi rúbọ sí i kó lè mú òórùn dídùn jáde. Jèhófà náà ló ni ẹ̀jẹ̀, tó dúró fún ẹ̀mí ẹran náà. Torí náà, ṣe ló dà bí ìgbà táwọn àlùfáà, àwọn tó mú ẹran wá àti Jèhófà jọ ń jẹun, ìyẹn túmọ̀ sí pé àlàáfíà wà láàárín wọn. Tí ẹnikẹ́ni tó jẹ́ aláìmọ́ (ìyẹn, tó bá ṣe ohunkóhun tó lè sọni di aláìmọ́ bí Òfin ṣe sọ) bá jẹ lára ẹbọ yìí, tàbí tẹ́nì kan jẹ ẹ́ lẹ́yìn àkókò tí Òfin sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́ (torí tó bá jẹ́ ibi tí ojú ọjọ́ ti gbóná fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ ni, ẹran náà á ti máa bà jẹ́), ṣe ni wọ́n máa pa onítọ̀hún. Ìdí ni pé ẹni náà ti ṣe ohun tó ń sọni di aláìmọ́ tàbí kó ti jẹ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ò fọwọ́ sí, tíyẹn sì ti mú kó sọ oúnjẹ náà di aláìmọ́. Ohun tẹ́ni náà ṣe fi hàn pé kò mọyì ohun mímọ́.—Le 7:16-21; 19:5-8.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Léfítíkù
2:13—Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ fi iyọ̀ sí “gbogbo ọrẹ ẹbọ”? Kì í ṣe láti lè mú kó ládùn ni wọ́n ṣe ń fi iyọ̀ sí i. Káàkiri ayé làwọn èèyàn ti má ń fi iyọ̀ sí nǹkan kó má bàa tètè bà jẹ́. Nítorí náà, ó lè jẹ́ nítorí tí iyọ̀ dúró fún nǹkan tí kì í bà jẹ́ àti nǹkan tí kì í jẹrà ni wọ́n ṣe máa ń fi sí ọrẹ ẹbọ.
it-1 813
Ọ̀rá
Ìdí tí òfin náà fi wà. Òfin tí Ọlọ́run fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú sọ pé Jèhófà nìkan ló ni ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá ẹran. Ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹran, Jèhófà nìkan ló sì lè fúnni lẹ́mìí, torí náà òun ló ni ín. (Le 17:11, 14) Ọ̀rá ni wọ́n gbà pé ó dọ́ṣọ̀ jù lára ẹran. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọ̀rá ẹran ni wọ́n máa ń fi rúbọ sí Jèhófà láti fi hàn pé ohun tó dáa jù làwọn fún un torí pé òun ló tọ́ sí, òun ló sì ń bù kún wọn. Òfin sọ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú kí ọ̀rá rú èéfín lórí pẹpẹ bí “oúnjẹ” kó lè mú “òórún dídùn jáde” fún Jèhófà, torí ṣe nìyẹn fi hàn pé ohun tó dáa jù ni wọ́n fún un. (Le 3:11, 16) Tẹ́nì kan bá wá jẹ ọ̀rá, ó ti tàpá sófin, torí pé wọ́n ti dìídì yà á sọ́tọ̀ fún Jèhófà, òun nìkan ló tọ́ sí. Ṣe ni wọ́n máa pa ẹni tó bá jẹ ọ̀rá. Àmọ́ ohun kan tí ọ̀rá fi yàtọ̀ sí ẹ̀jẹ̀ ni pé wọ́n lè lò ó fún àwọn nǹkan míì, àpẹẹrẹ kan ni tí ẹran kan bá kú fúnra ẹ̀ tàbí tí ẹranko míì pa á.—Le 7:23-25.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Léfítíkù
3:17. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rá la kà sí apá tó dára jù lára ẹran, sísọ tá á sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ́ yóò máa tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé Jèhófà ló ni apá tó dára jù yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 45:18) Èyí rán àwa náà létí pé gbogbo ọkàn ló yẹ ká máa fi sin Jèhófà.—Òwe 3:9, 10; Kólósè 3:23, 24.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
“Gbogbo Ohun Tó Ní Láti Gbé Ẹ̀mí Rẹ̀ Ró”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lúùkù 21:4
gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró: Bó ṣe wà nínú àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lk 21:2, “lẹ́pítónì méjì” ni ẹyọ owó tí opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra. Iye yìí ni alágbàṣe kan máa gbà tó bá ṣiṣẹ́ fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ẹyọ owó yìí ló kéré jù ní Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Bó ṣe wà nínú Mt 10:29, wọ́n lè fi ẹyọ owó ásáríò kan (tí ìníyelórí ẹ̀ tó lẹ́pítónì mẹ́jọ) ra ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì. Ẹyẹ yìí wà lára àwọn ẹyẹ tí kò wọ́nwó rárá táwọn èèyàn máa ń jẹ. Torí náà, ìdajì owó tí obìnrin opó yìí nílò láti ra ẹyẹ ológoṣẹ́ kan ló wà lọ́wọ́ ẹ̀, owó yẹn ò tiẹ̀ lè tó ra oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 4-5
“Ohun Tó Dáa Jù Ni Kó O Fún Jèhófà”
it-2 527 ¶9
Ọrẹ
Ọrẹ ẹ̀bi. Ẹ̀ṣẹ̀ náà ni ọrẹ ẹ̀bi wà fún, torí tí ohunkóhun bá lè mú kẹ́nì kan jẹ̀bi, ó ti dẹ́ṣẹ̀ nìyẹn. Ọrẹ ẹ̀bi wà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó lè mú kẹ́nì kan jẹ̀bi, ohun tó sì mú kó yàtọ̀ díẹ̀ sáwọn ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ yòókù ni pé, ó jọ pé wọ́n máa ń lò ó láti wá ojúure tàbí láti dá ẹ̀tọ́ tí ẹnì kan ní pa dà. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni ẹnì kan tẹ ẹ̀tọ́ Jèhófà lójú tàbí kó tẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn mímọ́ rẹ̀ lójú. Wọ́n máa wá lo ọrẹ ẹ̀bi láti wá ojúure Jèhófà torí ẹ̀tọ́ Jèhófà tẹ́ni náà tẹ̀ lójú, tàbí kí wọ́n lò ó láti fi dá ẹ̀tọ́ tẹ́ni náà ní níbàámu pẹ̀lú májẹ̀mú tó ṣe pa dà fún un. Ìyẹn á jẹ́ kó bọ́ lọ́wọ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ torí ó ti ronú pìwà dà.—Fi wé Ais 53:10.
Ó Mọbi Tágbára Wa Mọ
Òfin yẹn jẹ́ ká mọ bí àánú Jèhófà ṣe pọ̀ tó, ó ní: “Síbẹ̀síbẹ̀, bí agbára rẹ̀ kò bá ká àgùntàn, nígbà náà, kí ó mú oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.” (Ẹsẹ 7) A tún lè tún gbólóhùn tó sọ pé, “bí agbára rẹ̀ kò bá ká” sọ lọ́nà yìí, “bí owó ọwọ́ rẹ̀ kò bá ká.” Tọ́mọ Ísírẹ́lì kan bá tálákà débi pé agbára rẹ̀ ò ká àgùntàn, nígbà náà inú Ọlọ́run dùn sóhun tí owó ọwọ́ rẹ̀ bá ká, ó lè jẹ́ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.
Ó Mọbi Tágbára Wa Mọ
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò tiẹ̀ wá lágbára láti ra àwọn ẹyẹ méjì yẹn ńkọ́? Òfin náà sọ pé: “Nígbà náà, kí ó mú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà [kọ́ọ́bù mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án] ìyẹ̀fun kíkúnná fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá.” (Ẹsẹ 11) Jèhófà gba àwọn tálákà láyè lábẹ́ Òfin láti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láìlo ẹ̀jẹ̀. Torí pé ẹnì kan jẹ́ tálákà nílẹ̀ Ísírẹ́lì ò ní kó má lè rúbọ tàbí kò máà láǹfààní láti wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin
Ìwọ náà lè kọ́kọ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, kó o sì tún jẹ́ onínúure sáwọn tó sún mọ́ ẹ. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní ẹ̀rí tó dájú pé arákùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. O lè máà fẹ́ tú àṣírí rẹ̀ pàápàá tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ. Síbẹ̀, o mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, bíi ti Nátánì, ṣègbọràn sí Jèhófà kó o sì jẹ́ onínúure sí arákùnrin rẹ. Sọ fún un pé kó tètè lọ sọ ohun tó ṣe fáwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́. Tó bá kọ̀, kí ìwọ fúnra rẹ lọ sọ fáwọn alàgbà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lẹ́sẹ̀ kan náà, o ti fi inú rere hàn sí arákùnrin rẹ torí àwọn alàgbà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Àwọn alàgbà náà á sì fìfẹ́ tọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà.—Ka Léfítíkù 5:1; Gálátíà 6:1.
it-1 1130 ¶2
Ìjẹ́mímọ́
Àwọn Ẹranko àti Irè Oko. Wọ́n máa ń ya àkọ́bí àwọn màlúù, àgùntàn àti ewúré tó jẹ́ akọ sí mímọ́ fún Jèhófà, wọn kì í sì í rà wọ́n pa dà. Ṣe ni wọ́n máa ń fi rúbọ, àwọn àlùfáà tá a ti yà sọ́tọ̀ sì máa pín níbẹ̀. (Nọ 18:17-19) Ohun mímọ́ ni àwọn àkọ́so àti ìdá mẹ́wàá, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ẹbọ àti gbogbo ẹ̀bùn tá a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́. (Ẹk 28:38) Gbogbo ohun tí wọ́n bá ti yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà ló jẹ́ mímọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú un, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lò ó nílòkulò. Àpẹẹrẹ kan ni òfin ìdá mẹ́wàá. Ká sọ pé ọkùnrin kan ya ìdá mẹ́wàá àlìkámà tó kórè sọ́tọ̀, àmọ́ tí òun tàbí ẹnì kan nínú agbo ilé rẹ̀ ṣèèṣì mú níbẹ̀ tó sì sè é jẹ, ọkùnrin náà ti jẹ̀bi, ó ti rú òfin Ọlọ́run tó sọ pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ohun mímọ́. Òfin sọ pé kí ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ san àsanfidípò ìdá mẹ́wàá náà, kó tún fi ìdá márùn-ún ẹ̀ kún un, yàtọ̀ síyẹn, kó fi àgbò tí ara ẹ̀ dá ṣáṣá rúbọ. Èyí jẹ́ ká rí i pé tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ohun mímọ́ tó jẹ́ ti Jèhófà, kò yẹ ká fọwọ́ kékeré mú un rárá.—Le 5:14-16.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 6-7
“Ohun Tá A Mú Wá Láti Dúpẹ́”
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
Ẹ̀kọ́ kejì: À ń sin Jèhófà torí pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. Ká lè lóye kókó yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ ìrẹ́pọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú. Ìwé Léfítíkù jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ “láti fi ṣe ìdúpẹ́.” (Léf. 7:11-13, 16-18) Kò sí òfin tó sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan gbọ́dọ̀ rú ẹbọ yìí, òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lédè míì, ìfẹ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ní fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló mú kó fínnúfíndọ̀ rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Ẹni tó rú ẹbọ yìí, ìdílé rẹ̀ àtàwọn àlùfáà máa jẹ lára ẹran tó fi rúbọ náà. Àmọ́, àwọn apá kan wà lára ẹran náà tó jẹ́ ti Jèhófà nìkan. Apá wo nìyẹn?
Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
Ọrẹ ẹbọ àfínnúfíndọ̀ṣe mìíràn ni ẹbọ ìdàpọ̀, èyí tí ìwé Léfítíkù orí kẹta ṣàlàyé rẹ̀. A tún lè túmọ̀ orúkọ yẹn sí “àwọn ọrẹ ẹbọ àlàáfíà.” Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ náà “àlàáfíà” kì í wulẹ̀ í ṣe ọ̀ràn àìsí ogun tàbí àìsí rúkèrúdò nìkan. Ìwé Studies in the Mosaic Institutions sọ pé: “Ó ní ìtumọ̀ yìí nínú Bíbélì, àmọ́ ó tún túmọ̀ sí ipò tàbí ìdúró àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, aásìkí, ìdùnnú, àti ayọ̀.” Fún ìdí yìí, ìdí tí wọ́n fi ń rú ẹbọ ìdàpọ̀ kì í ṣe láti wá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, bíi pé nítorí kí wọ́n lè tù ú lójú, bí kò ṣe láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí láti ṣayẹyẹ ipò àlàáfíà amọ́kànyọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí tí àwọn tí ó tẹ́wọ́ gbà ń gbádùn. Àwọn àlùfáà àti ẹni tó mú ohun ẹbọ wá máa ń jẹ lára ohun ẹbọ náà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ẹ̀jẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà tán. (Léfítíkù 3:17; 7:16-21; 19:5-8) Lọ́nà tó fani mọ́ra gan-an, tó sì jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ, ṣe ni ẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá, àtàwọn àlùfáà, àti Jèhófà Ọlọ́run jọ ń jẹun pa pọ̀, tó jẹ́ àmì àjọṣe alálàáfíà tó wà láàárín wọn.
Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
Ẹni tó mú ọrẹ ẹbọ wá ńkọ́? Òfin sọ pé ẹnikẹ́ni tó bá ń bọ̀ níwájú Jèhófà gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́, láìlẹ́gbin. Ẹnì kan tó ti di ẹlẹ́gbin fún ìdí èyíkéyìí, gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ti ẹ̀bi wá, kí ó lè ní ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà kí Ó bàa lè tẹ́wọ́ gbà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ ìdàpọ̀ rẹ̀. (Léfítíkù 5:1-6, 15, 17) Nítorí náà, ǹjẹ́ a mọrírì ìjẹ́pàtàkì níní ìdúró mímọ́ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo? Bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ yára láti ṣàtúnṣe nígbàkigbà táa bá rú òfin Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ máa tètè lo ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọ́run ti pèsè fún wa—ìyẹn “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ” àti “ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,” èyíinì ni Jésù Kristi.—Jákọ́bù 5:14; 1 Jòhánù 2:1, 2.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 833 ¶1
Iná
Tó bá dọ̀rọ̀ àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì. Wọ́n máa ń lo iná ní àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì. Láràárọ̀ àti nírọ̀lẹ́, àlùfáà àgbà máa ń sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. (Ẹk 30:7, 8) Òfin Ọlọ́run sọ pé iná gbọ́dọ̀ máa jó lórí pẹpẹ ọrẹ sísun nígbà gbogbo. (Le 6:12, 13) Ohun táwọn Júù gbà gbọ́ ni pé ṣe ni Ọlọ́run máa ń mú kí iná ṣẹ́ yọ lọ́nà ara lórí pẹpẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀, a ò rí ẹ̀rí ẹ̀ nínú Bíbélì. Ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè níbẹ̀rẹ̀ ni pé, kí àwọn ọmọ Áárónì “dá iná sórí pẹpẹ, kí wọ́n sì to igi sí iná náà” kí wọ́n tó gbé ẹbọ sórí pẹpẹ. (Le 1:7, 8) Ẹ̀yìn tí wọ́n faṣẹ́ àlùfáà lé Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi ẹran rúbọ, ni iná tó bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtinú ìkùukùu tó wà lórí àgọ́ ìjọsìn ni iná náà ti bọ́, tó sì jó ẹran tó wà lórí pẹpẹ. Torí náà, kì í ṣe pé iná yẹn ṣàdédé ṣẹ́ yọ lára igi tó wà lórí pẹpẹ, àmọ́ ṣe ló “jó ẹbọ sísun àti àwọn ọ̀rá tó wà lórí pẹpẹ.” Lẹ́yìn tí ẹbọ yẹn jó tán, ó ní láti jẹ́ pé iná tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti iná tó ti wà lórí pẹpẹ tẹ́lẹ̀ ló ṣì ń jó lọ. (Le 8:14–9:24) Bákan náà, lẹ́yìn tí Sólómọ́nì gbàdúrà níbi ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì, iná bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó ẹran tí wọ́n fi rúbọ.—2Kr 7:1; tún wo Ond 6:21; 1Ọb 18:21-39; 1Kr 21:26 kó o lè rí àwọn àpẹẹrẹ míì níbi tí iná ti bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà lọ́nà àrà tó sì jó ẹbọ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rú.
si 27 ¶15
Ìwé Bíbélì Kẹta—Léfítíkù
(3) Wọ́n máa ń rú ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọn ò mọ̀ọ́mọ̀ dá. Ẹni tó bá ṣẹ̀ ló máa pinnu irú ẹran tí wọ́n máa fi ṣètùtù, ó lè jẹ́ àlùfáà, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjòyè tàbí ọmọ Ísírẹ́lì kan. Ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ pọn dandan, kò dà bí ọrẹ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ló máa ń fínnúfíndọ̀ mú un wá.—4:1-35; 6:24-30.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 30–DECEMBER 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | LÉFÍTÍKÙ 8-9
“Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Jèhófà Tẹ́wọ́ Gbà Wọ́n”
it-1 1207
Fífa Iṣẹ́ Lé Àwọn Àlùfáà Lọ́wọ́
Mósè wẹ Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀, ìyẹn Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítámárì (tàbí kó jẹ́ pé ṣe ló ní kí wọ́n lọ wẹ̀ fúnra wọn) níbi bàsíà tí wọ́n fi bàbà ṣe tó wà ní àgbàlá. Lẹ́yìn náà, ó wọ aṣọ iyì tó jẹ́ ti àlùfáà àgbà fún Áárónì. (Nọ 3:2, 3) Aṣọ tó rẹwà tí Áárónì wọ̀ yẹn fi hàn pé ipò pàtàkì ló wà, ó sì ní àwọn ojúṣe pàtàkì táá máa bójú tó. Mósè wá fòróró yan àgọ́ ìjọsìn, gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ ọrẹ sísun, bàsíà àtàwọn ohun èlò tó kù. Ohun tí Mósè ṣe yẹn ló fi yà wọ́n sí mímọ́, tó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kí wọ́n lè máa lò wọ́n fún ìjọsìn Ọlọ́run nìkan látìgbà yẹn lọ. Lẹ́yìn náà, Mósè da òróró sí Áárónì lórí láti fi yàn án.—Le 8:6-12; Ẹk 30:22-33; Sm 133:2.
it-1 1208 ¶8
Fífa Iṣẹ́ Lé Àwọn Àlùfáà Lọ́wọ́
Ní ọjọ́ kẹjọ, lẹ́yìn tí wọ́n yan àwọn àlùfáà náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn (láìsí ìrànlọ́wọ́ Mósè) fúngbà àkọ́kọ́. Wọ́n ṣe ètùtù fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́, kì í ṣe torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún nìkan, àmọ́ torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá láìpẹ́ sígbà yẹn, nígbà tí wọ́n múnú bí Jèhófà, tí wọ́n sì jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà. (Le 9:1-7; Ẹk 32:1-10) Nígbà táwọn àlùfáà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ faṣẹ́ lé lọ́wọ́ yìí parí iṣẹ́ wọn àkọ́kọ́, Jèhófà fi hàn pé òun fọwọ́ sí i, òun sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nípa bó ṣe jẹ́ kí iná bọ́ láti ọ̀run. Ó dájú pé inú ọwọ̀n ìkùukùu tó wà lórí àgọ́ ìjọsìn ni iná náà ti jáde, tó sì jó ẹbọ tó kù lórí pẹpẹ.—Le 9:23, 24.
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
Ẹ̀kọ́ kẹrin: Jèhófà ń bù kún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1512 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n to àgọ́ ìjọsìn sí ọwọ́ ìsàlẹ̀ Òkè Sínáì. (Ẹ́kís. 40:17) Mósè ló bójú tó bí wọ́n ṣe yan Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀ sípò àlùfáà. Nígbà tó di pé káwọn àlùfáà náà rú ẹbọ àkọ́kọ́ lẹ́yìn tí wọ́n yàn wọ́n sípò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ kí wọ́n lè rí i. (Léf. 9:1-5) Kí ni Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn àlùfáà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn sípò? Bí Áárónì àti Mósè ṣe súre fún àwọn èèyàn náà tán, Jèhófà jẹ́ kí iná bọ́ látọ̀run, ó sì jó ẹbọ tó wà lórí pẹpẹ.—Ka Léfítíkù 9:23, 24.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìdí Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́
Àṣẹ tí Jèhófà pa fún àwọn àlùfáà nílẹ̀ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wà ní mímọ́ nípa tara ń ṣe àwa èèyàn Jèhófà lóde òní láǹfààní. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sábà máa ń kíyè sí i pé àwọn ibi ìjọsìn wa máa ń mọ́ tónítóní àti pé a máa ń wọṣọ tó mọ́ a sì ń múra dáadáa. Síbẹ̀, bí àwọn àlùfáà ṣe máa ń wà ní mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá ń wá síbi ìjọsìn Jèhófà tí a gbé ga gbọ́dọ̀ “mọ́ ní ọkàn-àyà.” (Ka Sáàmù 24:3, 4; Aísá. 2:2, 3.) A gbọ́dọ̀ máa fi ọkàn àti èrò mímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ara mímọ́ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. Èyí gba pé ká máa ṣe àyẹ̀wò ara wa déédéé, téyìí á sì mú káwọn kan ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan kí wọ́n lè jẹ́ mímọ́. (2 Kọ́r. 13:5) Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni tó ti ṣèrìbọmi bá ń mọ̀ọ́mọ̀ wo àwòrán oníhòòhò, ó yẹ kó bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́?’ Lẹ́yìn náà, ó yẹ kó wá ìrànlọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà.—Ják. 5:14.
it-2 437 ¶3
Mósè
Ọlọ́run fi Mósè ṣe alárinà májẹ̀mú Òfin tó bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá, kò sí èèyàn tó nírú àjọṣe tímọ́tímọ́ yìí pẹ̀lú Ọlọ́run rí àfi Jésù Kristi, tó jẹ́ Alárinà májẹ̀mú tuntun. Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran sára ìwé májẹ̀mú, ìyẹn májẹ̀mú tí Jèhófà bá àwọn èèyàn náà dá (ó dájú pé àwọn àgbààgbà ló ṣojú fún àwọn èèyàn náà). Mósè ka ìwé májẹ̀mú náà fáwọn èèyàn, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe, a ó sì máa ṣègbọràn.” (Ẹk 24:3-8; Heb 9:19) Mósè ni alárìna májẹ̀mú yẹn, torí náà ó láǹfààní láti bójú tó kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn àti bí wọ́n ṣe ṣe àwọn ohun èlò rẹ̀ bó ṣe wà nínú àwòrán tí Ọlọ́run fi hàn án. Òun ló tún faṣẹ́ lé àwọn àlùfáà lọ́wọ́, ó sì fi òróró tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yan àgọ́ ìjọsìn àti Áárónì tó jẹ́ àlùfáà àgbà. Lẹ́yìn náà, ó bójú tó iṣẹ́ tí àwọn àlùfáà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbaṣẹ́ yẹn kọ́kọ́ ṣe.—Ẹk orí 25 sí 29; Le orí 8 àti 9.
Bíbélì Kíkà