Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MAY 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 27-29
“Yẹra fún Ojúsàájú, Kó O Lè Fìwà Jọ Jèhófà”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 528 ¶5
Ọrẹ
Ọrẹ ohun mímu. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ mú ọrẹ wá fún Jèhófà, ní pàtàkì lẹ́yìn tí wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí, ọrẹ ohun mímu sábà máa ń wà lára ohun tí wọ́n máa ń mú wá. (Nọ 15:2, 5, 8-10) Wáìnì (“ohun mímu tó ní ọtí”) wà lára ọrẹ ohun mímu tí wọ́n máa ń mú wá, wọ́n sì máa ń dà á sórí pẹpẹ. (Nọ 28:7, 14; fi wé Ẹk 30:9; Nọ 15:10.) Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì, ó sọ pé: “Bí a tilẹ̀ ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu sórí ẹbọ àti iṣẹ́ mímọ́ tí ìgbàgbọ́ yín ń mú kí ẹ ṣe, inú mi ń dùn.” Nínú ẹsẹ yìí, ó fi ara ẹ̀ wé ọrẹ ohun mímu, kí wọ́n lè mọ̀ pé ó múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti ran àwọn ará lọ́wọ́. (Flp 2:17) Nígbà tó kù díẹ̀ kó kú, ó kọ̀wé sí Tímótì pé: “Ní báyìí, a ti ń tú mi jáde bí ọrẹ ohun mímu, a sì máa tó tú mi sílẹ̀.”—2Ti 4:6.
MAY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 30-31
“San Ẹ̀jẹ́ Rẹ”
it-2 1162
Ẹ̀jẹ́
Wọn Kì Í Fipá Mú Kí Èèyàn Jẹ́jẹ̀ẹ́, àmọ́ Tẹ́nì Kan Bá Jẹ́jẹ̀ẹ́, Ó Gbọ́dọ̀ San Án. Kì í ṣe dandan kéèyàn jẹ́jẹ̀ẹ́. Àmọ́, tẹ́nì kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́, òfin Ọlọ́run fi dandan lé e pé ẹni náà gbọ́dọ̀ san án. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé ẹni tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ‘fi ohun kan de ọkàn ara ẹ̀,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n pa òun tóun ò bá san ẹ̀jẹ́ náà. (Nọ 30:2; tún wo Ro 1:31, 32.) Ẹ̀mí èèyàn lè lọ si, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé ó yẹ kéèyàn fara balẹ̀ ronú kó tó jẹ́jẹ̀ẹ́, kó sì wò ó bóyá òun máa lè san án. Òfin Ọlọ́run sọ pé: “Tí o bá jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà . . . Ọlọ́run rẹ máa béèrè rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn. Àmọ́ tí o ò bá jẹ́jẹ̀ẹ́, kò ní di ẹ̀ṣẹ̀ sí ọ lọ́rùn.”—Di 23:21, 22.
it-2 1162
Ẹ̀jẹ́
Ẹ̀jẹ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Torí ṣe lẹni tó bá jẹ́jẹ̀ẹ́ ń ṣèlérí pé òun á ṣe ohun kan fún Ọlọ́run, òun á fún un ní ọrẹ tàbí ẹ̀bùn, òun á fayé òun sìn ín tàbí yẹra fún àwọn nǹkan kan, bí òfin Ọlọ́run ò tiẹ̀ ka àwọn nǹkan yẹn léèwọ̀. Tẹ́nì kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́, òun fúnra ẹ̀ ló yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kì í fipá mú èèyàn pé kó jẹ́jẹ̀ẹ́. Jèhófà ka ẹ̀jẹ́ sí pàtàkì, kódà ojú kan náà ló fi ń wo ìbúra àti ẹ̀jẹ́. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n lo ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí pa pọ̀ nínú Bíbélì. (Nọ 30:2; Mt 5:33) Ṣe lẹni tó ‘jẹ́jẹ̀ẹ́’ ń sọ ohun tó pinnu láti ṣe, àmọ́ ní ti ẹni tó “búra,” ohun tó ń sọ ni pé òun máa ṣe ohun tóun ṣèlérí, kí wọ́n sì fìyà jẹ òun tóun ò bá mú ìlérí náà ṣẹ. Ìbúra yìí ló máa fìdí májẹ̀mú tó ṣe múlẹ̀.—Jẹ 26:28; 31:44, 53.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 28 ¶1
Jẹ́fútà
Ẹnì kan lè pinnu pé òun máa fi gbogbo ayé òun sin Jèhófà nínú ibi mímọ́. Àwọn òbí láṣẹ láti ṣe irú ìpinnu yìí fún ọmọ wọn. Àpẹẹrẹ kan ni ti Sámúẹ́lì, kí Hánà tó bí i ló ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà pé òun máa jẹ́ kí Sámúẹ́lì sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn. Ẹlikénà ọkọ ẹ̀ sì fọwọ́ sí i pé kó mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ. Kété lẹ́yìn tí Hánà gbọmú lẹ́nu Sámúẹ́lì ló mú un lọ sí àgọ́ ìjọsìn, ó sì mú ẹran dání kó lè fi rúbọ sí Jèhófà. (1Sa 1:11, 22-28; 2:11) Àpẹẹrẹ míì ni ti Sámúsìn, àtikékeré ni Jèhófà ti dìídì yàn án láti jẹ́ Násírì.—Ond 13:2-5, 11-14; fi wé ohun tí Nọ 30:3-5, 16 sọ nípa àṣẹ tí bàbá ní lórí ọmọbìnrin rẹ̀.
MAY 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 32-33
“Ẹ Lé Gbogbo Àwọn Tó Ń Gbé Ilẹ̀ Náà Kúrò”
it-1 404 ¶2
Kénáánì
“Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè” lórí bí wọ́n ṣe máa pa àwọn ọmọ Kénáánì run “ni Jóṣúà ṣe láìṣẹ́ ìkankan kù.” (Joṣ 11:15) Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù ò ṣe bíi tiẹ̀, wọn ò lé gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì kúrò pátápátá kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn wọ́n. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn ọmọ Kénáánì ṣì ń gbé ilẹ̀ náà ṣàkóbá fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, torí ọ̀pọ̀ lára wọn ló kú nígbà tó yá (ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tí pé wọ́n lọ́wọ́ sí ìwà ipá, ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà), kódà àwọn tó kú pọ̀ ju àwọn ọmọ Kénáánì tíì bá kú ká láwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí Jèhófà sọ. (Nọ 33:55, 56; Ond 2:1-3, 11-23; Sm 106:34-43) Jèhófà ti kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣáájú pé onídàájọ́ òdodo lòun àti pé òun ò ní ṣe ojúsàájú. Ó tún sọ fún wọn pé irú ìyà táwọn ọmọ Kénáánì jẹ làwọn náà máa jẹ tí wọ́n bá gbìyànjú láti bá wọn da nǹkan pọ̀, tí wọ́n ń fẹ́ wọn, tí wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn wọn, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àṣà wọn, tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ sáwọn ìwà àìmọ́ míì. Ṣe ni ‘ilẹ̀ yẹn máa pọ àwọn náà jáde’ bíi tàwọn ọmọ Kénáánì.—Ẹk 23:32, 33; 34:12-17; Le 18:26-30; Di 7:2-5, 25, 26.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 359 ¶2
Ààlà
Lẹ́yìn tí kèké bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ apá ibi tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa wà, wọ́n á wá lo ohun kejì, ìyẹn bí ẹ̀yà náà bá ṣe tóbi tó láti mọ bí ibi tí wọ́n máa pín fún wọn ṣe máa fẹ̀ tó. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ fi kèké pín ilẹ̀ náà bí ohun ìní láàárín àwọn ìdílé yín. Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Ibi tí kèké kálukú bá bọ́ sí ni ohun ìní rẹ̀ máa wà.” (Nọ 33:54) Wọn ò ní yí ibi tí kèké bá mú fún ẹ̀yà kan pa dà, àmọ́ wọ́n lè dín bó ṣe tóbi tó kù tàbí kí wọ́n fi kún un. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n rí i pé ibi tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Júdà ti fẹ̀ jù, wọ́n dín in kù, wọ́n sì fún ẹ̀yà Síméónì ní díẹ̀ lára rẹ̀.—Joṣ 19:9.
JUNE 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 3-4
“Àwọn Òfin Jèhófà Bọ́gbọ́n Mu, Wọ́n sì Bá Ìdájọ́ Òdodo Mu”
it-2 1140 ¶5
Òye
Téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, tó sì ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ẹni náà máa ní òye tó jinlẹ̀ ju àwọn tó dà bí olùkọ́ ẹ̀, á sì máa fòye hùwà ju àwọn àgbààgbà lọ. (Sm 119:99, 100, 130; fi wé Lk 2:46, 47.) Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn òfin àti àṣẹ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pé, ẹni tó bá sì ń pa á mọ́ máa ní ọgbọ́n àti òye. Torí náà, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń fi tọkàntọkàn pa òfin Ọlọ́run mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká máa gbà pé “ọlọ́gbọ́n àti olóye ni” wọ́n. (Di 4:5-8; Sm 111:7, 8, 10; fi wé 1Ọb 2:3.) Ẹni tó bá jẹ́ olóye á gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò ṣeé rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, á máa wá bí ìwà àti ìṣe òun á ṣe bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, á sì máa bẹ Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sm 119:169) Ẹni náà á jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ lọ́kàn òun (Mt 13:19-23), á dà bí ìgbà tó kọ ọ́ sí wàláà ọkàn rẹ̀ (Owe 3:3-6; 7:1-4), ìyẹn á sì mú kó kórìíra “gbogbo ọ̀nà èké” (Sm 119:104). Ohun tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run ṣe nígbà tó wà láyé fi hàn pé ó jẹ́ olóye, kò wá bó ṣe máa yẹ ikú sílẹ̀, ó gbà pé dandan ni kóun kú kóun lè mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ.—Mt 26:51-54.
JUNE 28–JULY 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DIUTARÓNÓMÌ 9-10
“Kí Ni Jèhófà Ọlọ́run Rẹ Fẹ́ Kó O Ṣe?”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 103
Ánákímù
Àwọn èèyàn Ánákímù tóbi yàtọ̀, wọ́n ń gbé lápá ibi tó lókè nílẹ̀ Kénáánì àtàwọn etíkun, pàápàá lápá gúúsù ilẹ̀ náà. Ìgbà kan wà táwọn ọkùnrin mẹ́ta tó lókìkí lára àwọn ọmọ Ánákímù ń gbé ní Hébúrónì, ìyẹn Áhímánì, Ṣéṣáì àti Tálímáì. (Nọ 13:22) Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjìlá tó lọ ṣamí ilẹ̀ Kénáánì rí àwọn Ánákímù, torí náà mẹ́wàá lára wọn mú ìròyìn tó ń bani lẹ́rù wá fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù. Wọ́n sọ pé àtọmọdọ́mọ àwọn Néfílímù tó wà láyé ṣáájú ìkun omi làwọn rí, wọ́n sì ní ṣe làwọn dà bíi “tata” lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn náà. (Nọ 13:28-33; Di 1:28) Àwọn Ánákímù rí fìrìgbọ̀n, torí náà Bíbélì fi wọ́n ṣàpèjúwe báwọn Émímù àtàwọn Réfáímù ṣe tóbi tó. Àwọn Ánákímù lágbára gan-an, abájọ táwọn èèyàn fi máa ń sọ ọ̀rọ̀ òwe yìí pé: “Ta ló lè ko àwọn ọmọ Ánákì lójú?”—Di 2:10, 11, 20, 21; 9:1-3.