Ìgbàgbọ́ Àti Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Fún Wọn Ní Ìgboyà
“Jẹ́ onígboyà àti alágbára . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.”—JÓṢÚÀ 1:9.
1, 2. (a) Téèyàn bá fojú ẹ̀dá èèyàn wò ó, ǹjẹ́ ó jọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè ṣẹ́gun àwọn ará ilẹ̀ Kénáánì? (b) Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ni Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà?
LỌ́DÚN 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ṣe tán láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Nítorí àwọn ìṣòro tó wà níwájú wọn, Mósè rán wọn létí pé: “Ìwọ ń sọdá Jọ́dánì lónìí, láti wọlé lọ, láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi jù ọ́, tí wọ́n sì lágbára ńlá jù ọ́ lọ kúrò, àwọn ìlú ńlá tí ó tóbi, tí a sì mọdi wọn kan ọ̀run, àwọn ènìyàn títóbi, tí wọ́n sì ga, àwọn ọmọ Ánákímù, àwọn ẹni tí ìwọ fúnra rẹ . . . ti gbọ́, tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ta ní lè mú ìdúró gbọn-in gbọn-in níwájú àwọn ọmọ Ánákì?’” (Diutarónómì 9:1, 2) Lóòótọ́, kò síbi tí wọn ò ti mọ àwọn jagunjagun tó jẹ́ òmìrán yìí lákòókò yẹn! Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará Kénáánì kan wà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn ní àwọn ohun ìjà tó pọ̀, irú bí ẹṣin àtàwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun tó ní dòjé irin nínú àwọn àgbá ẹsẹ̀ wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 4:13.
2 Àmọ́ ẹrú làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀, wọ́n sì tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lo ogójì ọdún tán nínú aginjù ni. Nítorí náà, téèyàn bá fojú ẹ̀dá èèyàn wò ó, kò jọ pé wọ́n lè jà kí wọ́n sì ṣẹ́gun. Síbẹ̀ Mósè ní ìgbàgbọ́, ó ‘rí i’ pé Jèhófà ló ń darí àwọn. (Hébérù 11:27) Ó sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń sọdá níwájú rẹ . . . Òun yóò pa wọ́n rẹ́ ráúráú, òun fúnra rẹ̀ yóò sì tẹ̀ wọ́n lórí ba níwájú rẹ.” (Diutarónómì 9:3; Sáàmù 33:16, 17) Lẹ́yìn tí Mósè kú, Jèhófà mú un dá Jóṣúà lójú pé òun yóò tì í lẹ́yìn. Ó sọ fún Jóṣúà pé: “Dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn, fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹnikẹ́ni kì yóò mú ìdúró gbọn-in gbọn-in níwájú rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti wà pẹ̀lú Mósè ni èmi yóò ṣe wà pẹ̀lú rẹ.”—Jóṣúà 1:2, 5.
3. Kí ló ran Jóṣúà lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
3 Kí Jóṣúà tó lè rí àtìlẹ́yìn àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ máa ka Òfin Ọlọ́run kó sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀, kó tún máa fi í sílò. Jèhófà sọ fun un pé: “Nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ onígboyà àti alágbára. Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” (Jóṣúà 1:8, 9) Nítorí pé Jóṣúà ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ fún un yìí, ó di onígboyà, ó lágbára, ọ̀nà rẹ̀ sì yọrí sí rere. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ojúgbà ni kò ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ. Àbájáde rẹ̀ ni pé wọn ò ṣàṣeyọrí, ńṣe ni wọ́n sì kú sínú aginjù.
Àìnígbàgbọ́ Kò Jẹ́ Kí Wọ́n Ní Ìgboyà
4, 5. (a) Báwo ni ẹ̀mí táwọn amí mẹ́wàá yẹn fi hàn ṣe yàtọ̀ sí ẹ̀mí tí Jóṣúà àti Kálébù fi hàn? (b) Kí ni Jèhófà sọ fáwọn èèyàn náà nítorí àìnígbàgbọ́ wọn?
4 Ní ogójì ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́kọ́ fẹ́ wọ ilẹ̀ Kénáánì, Mósè rán àwọn ọkùnrin méjìlá pé kí wọ́n lọ ṣamí ilẹ̀ náà. Ńṣe ni mẹ́wàá lára wọn padà wá tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. Wọ́n kígbe pé: ‘Gbogbo àwọn ọkùnrin tí a rí nínú rẹ̀ jẹ́ àwọn ọkùnrin tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. A rí àwọn Néfílímù níbẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Ánákì, tí wọ́n wá láti inú àwọn Néfílímù; tó bẹ́ẹ̀ tí a fi dà bí tata ní ojú ara wa.’ Ṣé pé “gbogbo àwọn ọkùnrin” tí wọ́n rí níbẹ̀ ló jẹ́ òmìrán lóòótọ́ yàtọ̀ sáwọn Ánákímù? Rárá o. Ṣé pé àtọmọdọ́mọ àwọn Néfílímù tó wà ṣáájú Ìkún Omi làwọn Ánákímù yẹn? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Síbẹ̀, yíyí tí wọ́n yí irọ́ pọ̀ mọ́ òtítọ́ yìí mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan. Àwọn èèyàn náà tiẹ̀ fẹ́ padà sílẹ̀ Íjíbítì, níbi tí wọ́n ti ń fi wọ́n ṣe ẹrú tẹ́lẹ̀!—Númérì 13:31–14:4.
5 Àmọ́, àwọn méjì lára àwọn amí náà, ìyẹn Jóṣúà àti Kálébù ti ń fojú sọ́nà gan-an láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n sọ pé: “Oúnjẹ ni wọ́n jẹ́ fún wa. Ibi ààbò wọn ti ṣí kúrò lórí wọn, Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa. Ẹ má bẹ̀rù wọn.” (Númérì 14:9) Ṣé pé ọkàn Jóṣúà àti Kálébù kàn balẹ̀ lórí asán ni? Rárá o! Ojú wọn àtojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ló ṣe nígbà tí Jèhófà lo Ìyọnu Mẹ́wàá láti rẹ orílẹ̀-èdè Íjíbítì alágbára ńlá àtàwọn òrìṣà rẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n rí i nígbà tí Jèhófà mú kí Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ rì sínú Òkun Pupa. (Sáàmù 136:15) Èyí fi hàn pé kò sídìí tó fi yẹ káwọn amí mẹ́wàá náà àtàwọn tó gba ọ̀rọ̀ wọn gbọ́ bẹ̀rù. Jèhófà fi bí ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe dùn òun tó hàn, ó ní: “Yóò sì ti pẹ́ tó tí wọn kì yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi fún gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo mú ṣe láàárín wọn?”—Númérì 14:11.
6. Kí ló fi hàn pé téèyàn ò bá ní ìgboyà kò lè nígbàgbọ́, báwo la sì ṣe ń rí ẹ̀rí èyí lóde òní?
6 Jèhófà sọ ohun tó jẹ́ ìṣòro àwọn èèyàn náà. Ìṣòro náà ni pé ojo ni wọ́n, èyí sì fi hàn pé wọn ò nígbàgbọ́. Dájúdájú, téèyàn ò bá ní ìgboyà èèyàn ò lè nígbàgbọ́. Èyí ló mú kí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa ìjọ Kristẹni àti ogun tẹ̀mí tí wọ́n ń jà pé: ‘Èyí ni ìṣẹ́gun tí ó ti ṣẹ́gun ayé, ìgbàgbọ́ wa.’ (1 Jòhánù 5:4) Lóde òní, irú ìgbàgbọ́ bíi ti Jóṣúà àti Kálébù ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà, láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé. Bí ọmọdé ṣe wà lára wọn làwọn àgbà náà wà, bí àwọn aláìlera sì ṣe wà làwọn tó lera náà wà lára wọn. Kò sí ọ̀tá kankan tó lè pa àwọn èèyàn tí wọ́n pọ̀ tí wọ́n sì nígboyà yìí lẹ́nu mọ́.—Róòmù 8:31.
Ẹ Má Ṣe “Fà Sẹ́yìn”
7. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn “fà sẹ́yìn”?
7 Ohun tó mú káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí lè máa fìgboyà wàásù ni pé, irú èrò tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní làwọn náà ní. Ó kọ̀wé pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun, ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) “Fà sẹ́yìn” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbi kì í ṣe kí ẹ̀rù kàn ba èèyàn fúngbà díẹ̀ o, torí pé ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni ẹ̀rù bà láwọn ìgbà kan. (1 Sámúẹ́lì 21:12; 1 Àwọn Ọba 19:1-4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn “padà sẹ́yìn,” “kó jáwọ́” tàbí “kó fọwọ́ yẹpẹrẹ mú òtítọ́.” Ìwé náà tún sọ pé ọ̀rọ̀ náà, “fà sẹ́yìn,” lè jẹ́ àfiwé kan tó dá lórí “dída ìgbòkun ọkọ̀ sílẹ̀ kí eré ọkọ̀ òkun náà sì dín kù,” ìyẹn ni pé kéèyàn dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Àmọ́ o, àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára kì í ronú pé káwọn “dẹwọ́” nígbà tí ìṣòro bá yọjú, ì báà jẹ́ inúnibíni, àìsàn, tàbí àdánwò mìíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń bá iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà nìṣó, torí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an, ó sì mọ ibi tágbára àwọn mọ. (Sáàmù 55:22; 103:14) Ǹjẹ́ o nírú ìgbàgbọ́ yẹn?
8, 9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni ìjímìjí lágbára? (b) Kí ló yẹ ká ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára?
8 Ìgbà kan wà táwọn àpọ́sítélì rí i pé Ìgbàgbọ́ àwọn kò tó, ni wọ́n bá sọ fún Jésù pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Wọ́n rí ohun tí wọ́n béèrè tọkàntọkàn yìí gbà, pàápàá nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí wá sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tó sì jẹ́ kí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. (Jòhánù 14:26; Ìṣe 2:1-4) Èyí fún ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lágbára, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu, débi pé, láìka inúnibíni tí wọ́n rí sí, “gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run” ni wọ́n wàásù ìhìn rere náà fún.—Kólósè 1:23; Ìṣe 1:8; 28:22.
9 Kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára ká sì lè máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́, ká tún máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run jinlẹ̀ nínú ọkàn wa àti nínú èrò wa bíi ti Jóṣúà, Kálébù, àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní ìjímìjí. Èyí nìkan la fi lè ní ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ ká ní ìgboyà láti máa ja ogun tẹ̀mí nìṣó, tá a ó sì ṣẹ́gun.—Róòmù 10:17.
Ìgbàgbọ́ Pé Ọlọ́run Wà Nìkan Kò Tó
10. Kí ni níní ojúlówó ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí?
10 Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láyé ọjọ́un ti fi hàn, ká tó lè ní ìgbàgbọ́ tó máa jẹ́ ká ní ìgboyà àti ìfaradà, kì í kàn ṣe ọ̀rọ̀ pé ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà nìkan ni. (Jákọ́bù 2:19) A gbọ́dọ̀ mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ gan-an, ká sì gbẹ́kẹ̀ wa lé e pátápátá. (Sáàmù 78:5-8; Òwe 3:5, 6) A gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa pé, pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ àti títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀ ló ń ṣeni láǹfààní jù lọ. (Aísáyà 48:17, 18) Ìgbàgbọ́ tún túmọ̀ sí pé ó ní láti dá wa lójú hán-ún pé Jèhófà yóò mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ, àti pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.”—Hébérù 11:1, 6; Aísáyà 55:11.
11. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà bù kún Jóṣúà àti Kálébù nítorí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
11 Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìgbàgbọ́ tó ń dúró sójú kan o. Ó jẹ́ ìgbàgbọ́ tó ń pọ̀ sí i bá a ti ń fi òtítọ́ sílò nígbèésí ayé wa, tí à ń rí àwọn àǹfààní rẹ̀, tí à sì ń rí ìdáhùn sáwọn àdúrà wa, tá a tún ń rí ìtọ́sọ́nà Jèhófà láwọn ọ̀nà mìíràn nínú ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 34:8; 1 Jòhánù 5:14, 15) Dájúdájú, àwa náà gbà pé bí Jóṣúà àti Kálébù ti ń tọ́ oore Jèhófà wò ni ìgbàgbọ́ wọn ń jinlẹ̀ sí i. (Jóṣúà 23:14) Gbé àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò: Wọ́n la ìrìn ogójì ọdún nínú aginjù já gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún wọn. (Númérì 14:27-30; 32:11, 12) Wọ́n kó ipa tó pọ̀ láàárín ọdún mẹ́fà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun ilẹ̀ Kénáánì. Paríparí rẹ̀ ni pé, Ọlọ́run fún wọn ní ẹ̀mí gígún àti ara líle, kódà wọ́n tún gba ogún tiwọn ní ilẹ̀ náà. Dájúdájú, Jèhófà ń san èrè fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń sìn ín tìgboyàtìgboyà àti pẹ̀lú òótọ́ inú!—Jóṣúà 14:6, 9-14; 19:49, 50; 24:29.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ‘gbé àsọjáde rẹ̀ ga lọ́lá’?
12 Inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sí Jóṣúà àti Kálébù rán wa létí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù kan sọ pé: “Ìwọ ti gbé àsọjáde rẹ ga lọ́lá àní lékè gbogbo orúkọ rẹ.” (Sáàmù 138:2) Nígbà tí Jèhófà bá ṣe ìlérí kan ní orúkọ rẹ̀, ìmúṣẹ ìlérí yẹn jẹ́ èyí tó ‘gbé ga lọ́lá’ ní ti pé ó máa ń kọjá ohunkóhun tá a rò. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà kò já àwọn tó “ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú” rẹ̀ kulẹ̀ rí.—Sáàmù 37:3, 4.
Ọkùnrin Kan Tó “Wu Ọlọ́run Dáadáa”
13, 14. Kí nìdí tí Énọ́kù fi nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà?
13 A lè mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àti ìgboyà gan-an tá a bá gbé àpẹẹrẹ ẹlẹ́rìí mìíràn tó wà ṣáájú àkókò Kristẹni yẹ̀ wò, ìyẹn ni Énọ́kù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kí Énọ́kù tiẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí í sàsọtẹ́lẹ̀ rárá ló ti mọ̀ pé òun máa rí àdánwò nítorí ìgbàgbọ́ àti ìgboyà òun. Lọ́nà wo? Nítorí pé Jèhófà ti sọ ní ọgbà Édẹ́nì pé ìṣọ̀tá, tàbí ìkórìíra yóò wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àtàwọn tó ń sin Sátánì Èṣù. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Énọ́kù tún mọ̀ pé ìkórìíra yìí ti yọjú látìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ìran èèyàn, ìyẹn nígbà tí Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Kódà, bàbá wọn, ìyẹn Ádámù, ṣì wà láàyè fún àádọ́rùn-ún dín nírínwó [310] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Énọ́kù.—Jẹ́nẹ́sísì 5:3-18.
14 Àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, Énọ́kù ń fi ìgboyà “bá a lọ ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́” ó sì ń wàásù pé àwọn “ohun amúnigbọ̀nrìrì” táwọn èèyàn ń sọ sí Jèhófà kò dára rárá. (Jẹ́nẹ́sísì 5:22; Júúdà 14, 15) Ó dájú pé rírọ̀ tí Énọ́kù rọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́ láìbẹ̀rù mú kó ní ọ̀pọ̀ ọ̀tá, èyí sì fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu. Ìdí nìyí tí Jèhófà fi gba wòlíì yìí lọ́wọ́ ikú gbígbóná. Lẹ́yìn tí Jèhófà ti jẹ́ kí Énọ́kù mọ̀ pé “ó ti wu Ọlọ́run dáadáa,” ó “ṣí i nípò padà” láti iyè sí ikú. Ó ṣeé ṣe kí èyí jẹ́ nígbà tí Énọ́kù ń rí ìran kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀.—Hébérù 11:5, 13; Jẹ́nẹ́sísì 5:24.
15. Àpẹẹrẹ dáradára wo ni Énọ́kù fi lélẹ̀ fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí?
15 Kété tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán nípa ṣíṣí tí Ọlọ́run ṣí Énọ́kù nípò padà, ó sọ nípa bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó, ó ní: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti [wu Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàgbọ́ tí Énọ́kù ní ló fún un nígboyà láti bá Jèhófà rìn, òun ló sì jẹ́ kó lè kéde ìdájọ́ Ọlọ́run fáwọn èèyàn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ tó dára gan-an ni Énọ́kù fi lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀ràn yìí. Àwa náà sì ní iṣẹ́ tó jọ tirẹ̀ láti ṣe nínú ayé táwọn èèyàn kò ti nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn tòótọ́, tí onírúurú ìwà abèṣe sì kún ọwọ́ wọn.—Mátíù 24:14; Mátíù 24:14; Ìṣípayá 12:17.
Ìgboyà Tí Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní
16, 17. Ta ni Ọbadáyà, inú àwọn ipò wo ló sì bá ara rẹ̀?
16 Yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́, ànímọ́ mìíràn tún ṣe pàtàkì tó ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, ìyẹn ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ ẹnì kan yẹ̀ wò tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run gan-an, tó gbé ayé nígbà tí wòlíì Èlíjà àti Áhábù Ọba wà láyé. Nígbà tí Áhábù ń ṣàkóso ìjọba àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ìjọsìn Báálì gba gbogbo ilẹ̀ náà kan lọ́nà tí kò ṣẹlẹ̀ rí. Àní, àádọ́ta lé nírínwó [450] wòlíì Báálì àti irínwó [400] wòlíì òpó ọlọ́wọ̀, ìyẹn ohun kan tó dúró fún ẹ̀yà ìbímọ akọ, ló “ń jẹun lórí tábìlì Jésíbẹ́lì” tó jẹ́ aya Áhábù.—1 Àwọn Ọba 16:30-33; 18:19.
17 Ọ̀tá Jèhófà ni Jésíbẹ́lì, kò láàánú, ó sì gbìyànjú láti pa ìjọsìn tòótọ́ rẹ́ kúrò lórílẹ̀-èdè náà. Ó pa àwọn wòlíì Jèhófà kan, kódà ó gbìyànjú láti pa Èlíjà, àmọ́ Èlíjà sá àsálà nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa sísọdá odò Jọ́dánì. (1 Àwọn Ọba 17:1-3; 18:13) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí yóò ṣe nira tó nígbà yẹn láti ṣe ìjọsìn tòótọ́ lágbègbè ìjọba àríwá? Bó bá wá lọ jẹ́ pé ààfin ọba gangan lo ti ń ṣiṣẹ́ ńkọ́? Ipò tí Ọbadáyàa tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó sì tún jẹ́ alámòójútó ilé Áhábù bá ara rẹ̀ nìyẹn.—1 Àwọn Ọba 18:3.
18. Kí ló mú kí Ọbadáyà jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
18 Kò sí àní-àní pé bí Ọbadáyà ti ń jọ́sìn Jèhófà, ó jẹ́ ẹni tó ṣọ́ra gan-an ó sì tún jẹ́ ọlọgbọ́n. Síbẹ̀, kò ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run. Àní, 1 Àwọn Ọba 18:3 sọ fún wa pé: “Ọbadáyà alára jẹ́ ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà gidigidi.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí Ọbadáyà ní ṣàrà ọ̀tọ̀! Èyí ló wá jẹ́ kó ní ìgboyà gan-an. Ohun tó ṣe ní gbàrà tí Jésíbẹ́lì pa àwọn wòlíì Jèhófà fi èyí hàn.
19. Kí ni Ọbadáyà ṣe tó fi hàn pé ó ní ìgboyà?
19 A kà pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Jésíbẹ́lì ké àwọn wòlíì Jèhófà kúrò, Ọbadáyà bẹ̀rẹ̀ sí kó ọgọ́rùn-ún wòlíì, ó sì fi wọ́n pa mọ́ ní àádọ́ta-àádọ́ta nínú hòrò kan, ó sì ń pèsè oúnjẹ àti omi fún wọn.” (1 Àwọn Ọba 18:4) Bó o bá fojú inú wò ó, wàá rí i pé iṣẹ́ tó léwu gan-an ni kéèyàn máa yọ́ kẹ́lẹ́ lọ fún ọgọ́rùn-ún èèyàn lóúnjẹ ní kọ̀rọ̀. Kì í ṣe pé Ọbadáyà ní láti ṣọ́ra kí Áhábù àti Jésíbẹ́lì má bàa rí i mú nìkan ni, ó tún gbọ́dọ̀ kíyè sára káwọn àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rin [850] wòlíì èké tó ń wá sí ààfin nígbà gbogbo máa bàa mọ ohun tó ń ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, ó dájú pé ọ̀pọ̀ àwọn olùjọ́sìn èké tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, látorí mẹ̀kúnnù títí dorí àwọn ọmọ ọba, ni yóò lo àǹfààní èyíkéyìí tí wọ́n bá rí láti tú àṣírí Ọbadáyà kí wọ́n lè rójú rere ọba àti ti ayaba. Síbẹ̀, igi imú àwọn abọ̀rìṣà náà báyìí ni Ọbadáyà ti ń fìgboyà pèsè ohun táwọn wòlíì Jèhófà náà nílò. Dájúdájú, ìbẹ̀rù Jèhófà ń ranni lọ́wọ́ gan-an láti ní ìgboyà!
20. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí Ọbadáyà ní ṣe ràn án lọ́wọ́, báwo ni àpẹẹrẹ rẹ̀ sì ṣe lè ran ìwọ náà lọ́wọ́?
20 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, Ọbadáyà fi ìgboyà hàn nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní, ó sì dájú pé èyí ló mú kí Jèhófà dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Òwe 29:25 sọ pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.” Èèyàn bíi tiwa ni Ọbadáyà. Ẹ̀rù bà á pé wọ́n lè mú òun kí wọ́n sì pa òun bí ẹ̀rù yóò ṣe ba àwa náà tá a bá bá ara wa nípò tó wà. (1 Àwọn Ọba 18:7-9, 12) Àmọ́, ìbẹ̀rù Ọlọ́run fún un nígboyà láti borí ìbẹ̀rù èèyàn tó ṣeé ṣe kó ní. Àpẹẹrẹ àtàtà ni Ọbadáyà jẹ́ fún gbogbo wa, àgàgà àwọn tó lè pàdánù òmìnira wọn nítorí pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà tàbí àwọn tó lè pàdánù ẹ̀mí wọn pàápàá. (Mátíù 24:9) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa sapá láti sin Jèhófà “pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.”—Hébérù 12:28.
21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
21 Ìgbàgbọ́ àti ìbẹ̀rù Ọlọ́run nìkan kọ́ ni àwọn ànímọ́ tó ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà, kódà ìfẹ́ lágbára jù wọ́n lọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.” (2 Tímótì 1:7) Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí bí ìfẹ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fìgboyà sin Jèhófà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí.—2 Tímótì 3:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe wòlíì Ọbadáyà o.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn
• Kí ló jẹ́ kí Jóṣúà àti Kálébù ní ìgboyà?
• Kí ni níní ojúlówó ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí?
• Kí nìdí tí Énọ́kù kò fi bẹ̀rù bó ti ń kéde ìdájọ́ Ọlọ́run?
• Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìgboyà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ọbadáyà ṣètọ́jú àwọn wòlíì Ọlọ́run ó sì dáàbò bò wọ́n
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Énọ́kù sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tìgboyàtìgboyà