Sí Àwọn Hébérù
11 Ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú* ohun tí à ń retí,+ ẹ̀rí tó dájú* nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí. 2 Torí àwọn èèyàn àtijọ́* rí ẹ̀rí nípasẹ̀ rẹ̀.
3 Ìgbàgbọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló mú kí àwọn ètò àwọn nǹkan* wà létòlétò, tó fi jẹ́ pé ohun tí à ń rí jáde wá látinú àwọn ohun tí a kò rí.
4 Ìgbàgbọ́ mú kí Ébẹ́lì rú ẹbọ tó níye lórí ju ti Kéènì+ lọ sí Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ náà sì mú kó rí ẹ̀rí pé ó jẹ́ olódodo, torí Ọlọ́run fọwọ́ sí* àwọn ẹ̀bùn rẹ̀,+ bó tiẹ̀ kú, ó ṣì ń sọ̀rọ̀+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀.
5 Ìgbàgbọ́ mú ká ṣí Énọ́kù+ nípò pa dà kó má bàa rí ikú, a ò sì rí i níbì kankan torí pé Ọlọ́run ti ṣí i nípò pa dà;+ torí ká tó ṣí i nípò pa dà, ó rí ẹ̀rí pé ó ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa. 6 Bákan náà, láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa, torí ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.+
7 Ìgbàgbọ́ mú kí Nóà + fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn, lẹ́yìn tó gba ìkìlọ̀ láti ọ̀run nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí,+ ó kan ọkọ̀ áàkì+ kí agbo ilé rẹ̀ lè rí ìgbàlà; ó dá ayé lẹ́bi nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí,+ ó sì di ajogún òdodo irú èyí tí ìgbàgbọ́ ń mú wá.
8 Ìgbàgbọ́ mú kí Ábúráhámù+ ṣègbọràn nígbà tí a pè é, ó lọ sí ibì kan tó máa gbà, tó sì máa jogún; ó jáde lọ, bí kò tiẹ̀ mọ ibi tó ń lọ.+ 9 Ìgbàgbọ́ mú kó máa gbé bí àjèjì ní ilẹ̀ ìlérí, bíi pé ó jẹ́ ilẹ̀ àjèjì,+ ó ń gbé inú àgọ́ + pẹ̀lú Ísákì àti Jékọ́bù, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ajogún ìlérí kan náà.+ 10 Torí ó ń retí ìlú tó ní ìpìlẹ̀ tòótọ́, tí Ọlọ́run ṣètò,* tó sì kọ́.+
11 Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ,* kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ẹni tó lè bímọ,+ torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.* 12 Torí èyí, nípasẹ̀ ọkùnrin kan tó ti ń kú lọ,+ a bí àwọn ọmọ + tó pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí wọn ò sì ṣeé kà bí iyanrìn etí òkun.+
13 Gbogbo àwọn yìí ní ìgbàgbọ́ títí wọ́n fi kú, bí wọn ò tiẹ̀ rí àwọn ohun tí ó ṣèlérí náà gbà; + àmọ́ wọ́n rí i láti òkèèrè,+ wọ́n tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n sì kéde ní gbangba pé àwọn jẹ́ àjèjì àti olùgbé fún ìgbà díẹ̀* ní ilẹ̀ náà. 14 Torí àwọn tó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà yẹn jẹ́ kó ṣe kedere pé tọkàntọkàn ni àwọn ń wá ibi tó jẹ́ tiwọn. 15 Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé wọ́n ṣì ń rántí ibi tí wọ́n ti kúrò ni,+ àyè ì bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti pa dà. 16 Àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń sapá láti dé ibi tó dáa jù, ìyẹn èyí tó jẹ́ ti ọ̀run. Torí náà, Ọlọ́run ò tijú, pé kí wọ́n máa pe òun ní Ọlọ́run wọn,+ torí ó ti ṣètò ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.+
17 Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò,+ ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́—ọkùnrin tó gba àwọn ìlérí náà tayọ̀tayọ̀ fẹ́ fi ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí rúbọ+— 18 bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ fún un pé: “Látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.” 19 Àmọ́, ó ronú pé Ọlọ́run lè gbé e dìde tó bá tiẹ̀ kú, ó sì rí i gbà láti ibẹ̀ lọ́nà àpèjúwe.+
20 Ìgbàgbọ́ mú kí Ísákì náà súre fún Jékọ́bù+ àti Ísọ̀+ nípa àwọn ohun tó ń bọ̀.
21 Ìgbàgbọ́ mú kí Jékọ́bù súre fún àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù+ níkọ̀ọ̀kan nígbà tó fẹ́ kú,+ ó sì jọ́sìn bó ṣe sinmi lé orí ọ̀pá rẹ̀.+
22 Ìgbàgbọ́ mú kí Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jáde lọ bí ọjọ́ ikú rẹ̀ ṣe ń sún mọ́lé, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni* nípa àwọn egungun rẹ̀.*+
23 Ìgbàgbọ́ mú kí àwọn òbí Mósè gbé e pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n bí i,+ torí wọ́n rí i pé ọmọ kékeré náà rẹwà,+ wọn ò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.+ 24 Ìgbàgbọ́ mú kí Mósè kọ̀ kí wọ́n máa pe òun ní ọmọ ọmọbìnrin Fáráò+ nígbà tó dàgbà,+ 25 ó yàn pé kí wọ́n fìyà jẹ òun pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run dípò kó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í tọ́jọ́, 26 torí pé ó ka ẹ̀gàn Kristi sí ọrọ̀ tó tóbi ju àwọn ìṣúra Íjíbítì lọ, torí ó tẹjú mọ́ gbígba èrè náà. 27 Ìgbàgbọ́ mú kó kúrò ní Íjíbítì,+ àmọ́ kò bẹ̀rù ìbínú ọba,+ torí ó dúró ṣinṣin bíi pé ó ń rí Ẹni tí a kò lè rí.+ 28 Ìgbàgbọ́ mú kó ṣe Ìrékọjá, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀, kí apanirun má bàa pa àwọn àkọ́bí wọn lára.*+
29 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n la Òkun Pupa kọjá bíi pé ilẹ̀ gbígbẹ ni,+ àmọ́ nígbà tí àwọn ará Íjíbítì dán an wò, omi gbé wọn mì.+
30 Ìgbàgbọ́ mú kí àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náà fi ọjọ́ méje yan yí ibẹ̀ ká.+ 31 Ìgbàgbọ́ Ráhábù aṣẹ́wó kò jẹ́ kó ṣègbé pẹ̀lú àwọn tó ṣàìgbọràn, torí ó gba àwọn amí náà tọwọ́tẹsẹ̀.+
32 Kí ni kí n tún sọ? Torí àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìn,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ títí kan Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù. 33 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba,+ wọ́n mú kí òdodo fìdí múlẹ̀, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+ 34 wọ́n dáwọ́ agbára iná dúró,+ wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà,+ a sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìlera,+ wọ́n di akíkanjú lójú ogun,+ wọ́n mú kí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá sá lọ.+ 35 Àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde,+ àmọ́ wọ́n dá àwọn ọkùnrin míì lóró torí pé wọn ò gbà kí wọ́n tú àwọn sílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tó dáa jù. 36 Àní, àdánwò tí àwọn míì kojú ni pé wọ́n fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, wọ́n sì nà wọ́n lẹ́gba, kódà ó jùyẹn lọ, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,+ wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n.+ 37 Wọ́n sọ wọ́n lókùúta,+ wọ́n dán wọn wò, wọ́n fi ayùn rẹ́ wọn sí méjì,* wọ́n fi idà pa wọ́n,+ wọ́n rìn kiri pẹ̀lú awọ àgùntàn àti awọ ewúrẹ́ lọ́rùn,+ nígbà tí wọ́n ṣaláìní, nínú ìpọ́njú,+ nígbà tí wọ́n hùwà àìdáa sí wọn;+ 38 ayé ò sì yẹ wọ́n. Wọ́n rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀, lórí àwọn òkè, nínú àwọn ihò àpáta àti àwọn ihò inú ilẹ̀.+
39 Síbẹ̀, bí a tiẹ̀ jẹ́rìí tó dáa nípa gbogbo àwọn yìí torí ìgbàgbọ́ wọn, wọn ò rí ohun tó ṣèlérí náà gbà, 40 torí pé Ọlọ́run ti rí ohun tó dáa jù fún wa ṣáájú,+ kí a má bàa sọ wọ́n di pípé láìsí àwa.