Ẹ Fi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba Fún Ọlá Àṣẹ Ọlọ́run
“Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.”—Aísáyà 33:22.
1. Kí làwọn nǹkan tó mú kí Ísírẹ́lì ìgbàanì yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè yòókù?
ỌDÚN 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa la dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀. Nígbà yẹn, kò ní olú ìlú, kò ní ilẹ̀ ìbílẹ̀, kò sì ní ọba tó ṣeé fojú rí. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tuntun yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ ti oko ẹrú dé ni. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè tuntun yìí tún ta yọ lọ́nà mìíràn. Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí kò ṣeé fi ojúyòójú rí, ni Onídàájọ́ wọn, Òun ló ń fún wọn ní òfin, òun sì ni Ọba wọn. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Aísáyà 33:22) Kò tún sí orílẹ̀-èdè mìíràn tó nírú àǹfààní yẹn!
2. Ìbéèrè wo ló dìde lórí bá a ṣe ṣètò Ísírẹ́lì, èé sì ti ṣe tí ìdáhùn ìbéèrè yìí fi ṣe pàtàkì fún wa?
2 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run ètò, àti Ọlọ́run àlàáfíà, a ó retí pé kí gbogbo nǹkan wà létòlétò ní orílẹ̀-èdè tó bá ń ṣàkóso. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ ní Ísírẹ́lì nìyẹn. Àmọ́ báwo ni Ọlọ́run tí kò ṣeé fojú rí ṣe lè máa darí ètò kan tó ṣeé fojú rí lórí ilẹ̀ ayé? Á dáa ká ṣe àgbéyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe ṣàkóso orílẹ̀-èdè àtijọ́ yẹn, ká pe àfiyèsí pàtàkì sí bí ọ̀nà tó gbà ṣàkóso Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ ká rí ìjẹ́pàtàkì fífi ìdúróṣinṣin tẹrí ba fún ọlá àṣẹ Ọlọ́run.
Bá A Ṣe Ṣàkóso Ísírẹ́lì Ìgbàanì
3. Ètò gbígbéṣẹ́ wo ni Jèhófà ṣe láti tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà?
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ọba tí kò ṣeé fojú rí fún Ísírẹ́lì, ó yan àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó ṣeé fojú rí pé kí wọ́n máa ṣojú fóun. Àwọn ìjòyè ń bẹ, àwọn olórí agboolé ń bẹ, àwọn àgbà ọkùnrin sì ń bẹ, tí wọ́n jẹ́ agbaninímọ̀ràn àti onídàájọ́ àwọn èèyàn náà. (Ẹ́kísódù 18:25, 26; Diutarónómì 1:15) Àmọ́ ṣá o, láìsí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run kò sí bí àwọn èèyàn tá a fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ yìí ṣe lè fi ìmọ̀ àti òye tara wọn dájọ́ láìṣàṣìṣe rárá. Wọn kì í ṣe ẹni pípé, wọn ò sì lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. Síbẹ̀ náà, àwọn onídàájọ́ tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè fún àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ látinú Òfin Jèhófà.—Diutarónómì 19:15; Sáàmù 119:97-100.
4. Ìwà wo làwọn onídàájọ́ olóòótọ́ ní Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ yẹra fún, èé sì ti ṣe?
4 Àmọ́ o, kì í ṣe mímọ Òfin nìkan ni jíjẹ́ onídàájọ́ wé mọ́. Níwọ̀n bí àwọn àgbààgbà wọ̀nyí ti jẹ́ aláìpé, wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà àìpé tara wọn—bí ìmọtara-ẹni-nìkan, ojúsàájú àti ìwọra—mú kí wọ́n yí ìdájọ́ po. Mósè sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú nínú ìdájọ́. Ẹ gbọ́dọ̀ gbọ́ ti ẹni kékeré bákan náà bí ti ẹni ńlá. Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí jìnnìjìnnì bá yín nítorí ènìyàn kan, nítorí pé ti Ọlọ́run ni ìdájọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run làwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì ń ṣojú fún. Àǹfààní ńlá mà lèyí o!—Diutarónómì 1:16, 17.
5. Ní àfikún sí yíyan àwọn onídàájọ́, ètò mìíràn wo ni Jèhófà ṣe láti bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀?
5 Jèhófà ṣe àwọn ètò mìíràn láti kájú àìní àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Kódà kó tó di pé wọ́n dé Ilẹ̀ Ìlérí ló ti pàṣẹ pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn, tí í ṣe ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Ó tún ṣètò àwọn àlùfáà tí yóò máa fi Òfin kọ́ni, tí yóò máa fi ẹran rúbọ, tí yóò sì máa sun tùràrí láàárọ̀ àti lálẹ́. Ọlọ́run fi Áárónì ẹ̀gbọ́n Mósè jẹ àlùfáà àgbà àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì, ó sì yan àwọn ọmọkùnrin Áárónì láti máa ran bàbá wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀.—Ẹ́kísódù 28:1; Númérì 3:10; 2 Kíróníkà 13:10, 11.
6, 7. (a) Kí ni àjọṣe tó wà láàárín àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì tí kì í ṣe àlùfáà? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú òtítọ́ náà pé ọ̀kan-kò-jọ̀kan iṣẹ́ làwọn ọmọ Léfì ń ṣe? (Kólósè 3:23)
6 Iṣẹ́ bàǹtà-banta ni bíbójútó àìní tẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, àwọn àlùfáà kò sì pọ̀ níye. Ìdí nìyẹn tí wọ́n ṣètò pé kí àwọn yòókù nínú ẹ̀yà Léfì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kí o sì fi àwọn ọmọ Léfì fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn ẹni tí a fi fúnni, tí a fi fún un láti inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—Númérì 3:9, 39.
7 A ṣètò àwọn ọmọ Léfì dáadáa. A pín wọn sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí níbàámu pẹ̀lú ìdílé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta—ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì, àwọn ọmọ Kóhátì, àtàwọn ọmọ Mérárì—kálukú ló ní iṣẹ́ tirẹ̀. (Númérì 3:14-17, 23-37) Àwọn iṣẹ́ kan lè dà bí èyí tó ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ o, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ ló ṣe pàtàkì tó ṣe kókó. Iṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì tó wá láti ìlà ìdílé Kóhátì mú kí wọ́n wà nídìí àpótí májẹ̀mú mímọ́ àtàwọn ohun èlò inú àgọ́ ìjọsìn. Àmọ́, gbogbo ọmọ Léfì, yálà látinú ìdílé Kóhátì tàbí ìdílé mìíràn, ló ní àgbàyanu àǹfààní. (Númérì 1:51, 53) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan kò mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní. Dípò kí wọ́n fi ìṣòtítọ́ tẹrí ba fún ọlá àṣẹ Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fapá jánú kiri, tí wọ́n ń ganpá, tí wọ́n ń wá ipò ọlá, tí wọ́n sì ń jowú. Ọmọ Léfì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kórà wà lára wọn.
‘Ṣé Ó Yẹ Kẹ́ Ẹ Tún Fẹ́ Gbaṣẹ́ Àlùfáà Ṣe Ni?’
8. (a) Ta ni Kórà? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Kórà fi bẹ̀rẹ̀ sí fojú yẹpẹrẹ wo àwọn àlùfáà?
8 Kórà kọ́ ni olórí ìdílé nínú ẹ̀yà Léfì, òun sì kọ́ ni olórí àwọn ìdílé tó wà lágboolé Kóhátì. (Númérì 3:30, 32) Síbẹ̀síbẹ̀, ìjòyè ńlá ni ní Ísírẹ́lì. Ó ṣeé ṣe kíṣẹ́ Kórà ti jẹ́ kó rí àríṣá Áárónì àtàwọn ọmọ rẹ̀. (Númérì 4:18, 19) Àléébù àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ò ní ṣàì hàn sí Kórà. Èyí sì lè jẹ́ kó ronú pé: ‘Aláìpé paraku tiẹ̀ làwọn àlùfáà tí wọ́n ní kí n máa tẹrí ba fún wọ̀nyí! Ṣebí lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Áárónì ṣe ọmọ màlúù oníwúrà. Bíbọ ọmọ màlúù yẹn ló sún àwọn èèyàn wa dẹ́ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà. Áárónì kan náà, ìyẹn ẹ̀gbọ́n Mósè, mà ló ti di àlùfáà àgbà báyìí! Ojúsàájú ọ̀hún mà kúkú pọ̀ o! Tá a bá tilẹ̀ ní ká fìyẹn sẹ́nu ká dákẹ́, ti Nádábù àti Ábíhù, àwọn ọmọ Áárónì ńkọ́? Ṣebí àìnáání àǹfààní iṣẹ́ ìsìn wọn ló jẹ́ kí Jèhófà pa wọ́n!’a (Ẹ́kísódù 32:1-5; Léfítíkù 10:1, 2) Ohun yòówù kí Kórà máa rò lọ́kàn, ó ṣe kedere pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí fojú yẹpẹrẹ wo ipò àlùfáà. Ìyẹn ló jẹ́ kó ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè àti Áárónì, àti sí Jèhófà níkẹyìn.—1 Sámúẹ́lì 15:23; Jákọ́bù 1:14, 15.
9, 10. Ẹ̀sùn wo ni Kórà àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ tó kó sòdí fi kan Mósè, kí sì nìdí tá a fi sọ pé wọn ò rò ó re?
9 Níwọ̀n bí Kórà ti jẹ́ abẹnugan, kò ṣòro fún un láti rí àwọn èèyàn bíi tirẹ̀ kó sòdí. Òun, àti Dátánì àti Ábírámù, rí àádọ́ta lérúgba [250] ìsọ̀ǹgbè—kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ìjòyè ni gbogbo wọn láwùjọ o. Gbogbo wọ́n kóra wọn wá bá Mósè àti Áárónì, wọ́n ń pariwo ẹnu pé: “Gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn. Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?”—Númérì 16:1-3.
10 Ká ní àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyẹn rò ó re ni, kì í ṣàwọn ló yẹ kó máa fọwọ́ pa idà Mósè lójú. Ẹnu àìpẹ́ sígbà yẹn sáà ni Áárónì àti Míríámù ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kódà, ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu wọn ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti Kórà! Gẹ́gẹ́ bí Númérì 12:1, 2 ti wí, wọ́n béèrè pé: “Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?” Jèhófà kúkú ń gbọ́. Ó pàṣẹ pé kí Mósè, Áárónì àti Míríámù pé jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí Òun lè fi aṣáájú tí òun yàn hàn. Jèhófà wá sọ láìfọ̀rọ̀bọpo-bọyọ̀ pé: “Bí wòlíì kan bá wà nínú yín fún Jèhófà, yóò jẹ́ nínú ìran ni èmi yóò ti sọ ara mi di mímọ̀ fún un. Ojú àlá ni èmi yóò ti bá a sọ̀rọ̀. Ìránṣẹ́ mi Mósè kò rí bẹ́ẹ̀! Ìkáwọ́ rẹ̀ ni a fi gbogbo ilé mi sí.” Lẹ́yìn ìyẹn ni Jèhófà fi àrùn ẹ̀tẹ̀ kọlu Míríámù fún sáà kan.—Númérì 12:4-7, 10.
11. Ọwọ́ wo ni Mósè fi mú ọ̀ràn ọ̀tẹ̀ Kórà?
11 Kò sí ni, Kórà àtàwọn elégbè lẹ́yìn rẹ̀ á ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Àwíjàre ò sí fún ìwà ọ̀tẹ̀ wọn. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Mósè fẹ́ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tún ojú ìwòye wọn ṣe. Ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n túbọ̀ fojú pàtàkì wo àwọn àǹfààní tí wọ́n ní, ó sọ pé: “Ohun kékeré bẹ́ẹ̀ ha ni lójú yín pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò nínú àpéjọ Ísírẹ́lì láti mú yín wá síwájú ara rẹ̀?” Ó tì o, “ohun kékeré” mà kọ́! Àǹfààní táwọn ọmọ Léfì ní kò kéré rárá. Kí ni wọ́n tún ń fẹ́? Ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ tẹ̀ lé e tú ohun tó wà lọ́kàn wọn fó. Ó ní: “Ẹ̀yin yóò ha tún gbìyànjú láti gba iṣẹ́ àlùfáà síkàáwọ́?”b (Númérì 12:3; 16:9, 10) Àmọ́ o, ojú wo ni Jèhófà fi wo ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù sí ọlá àṣẹ rẹ̀ yìí?
Onídàájọ́ Ísírẹ́lì Dá Sọ́ràn Náà
12. Kí ni Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí àjọṣe rere tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́?
12 Nígbà tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní Òfin, ó sọ fáwọn èèyàn náà pé bí wọ́n bá jẹ́ elétí ọmọ, wọn yóò di “orílẹ̀-èdè mímọ́,” orílẹ̀-èdè náà yóò sì máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ mímọ́ bí wọ́n bá fara mọ́ ìṣètò Jèhófà. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Pẹ̀lú ègbìnrìn ọ̀tẹ̀ tó fẹ́ rú yìí, àkókò tó kí Onídàájọ́, tó ń fún Ísírẹ́lì lófin dá sọ́ràn náà! Mósè sọ fún Kórà pé: “Ìwọ àti gbogbo àpéjọ rẹ, ẹ pésẹ̀ síwájú Jèhófà, ìwọ àti àwọn àti Áárónì, lọ́la. Kí olúkúlùkù sì mú ìkóná rẹ̀, kí ẹ sì fi tùràrí sórí wọn, kí olúkúlùkù sì mú ìkóná rẹ̀ wá síwájú Jèhófà, àádọ́ta-lérúgba ìkóná, àti ìwọ àti Áárónì olúkúlùkù pẹ̀lú ìkóná rẹ̀.”—Númérì 16:16, 17.
13. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìwà ọ̀yájú làwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn hù nígbà tí wọ́n lọ sun tùràrí níwájú Jèhófà? (b) Ẹjọ́ wo ni Jèhófà dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà?
13 Ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ ni pé àwọn àlùfáà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ àtisun tùràrí. Nítorí náà kíkí èrò pé kí ọmọ Léfì tí kì í ṣe àlùfáà wá sun tùràrí níwájú Jèhófà yẹ kó mú káwọn ọlọ̀tẹ̀ náà séra ró, kí ó sì pe orí wọn wálé. (Ẹ́kísódù 30:7; Númérì 4:16) Àmọ́ ìyẹn ò pe orí Kórà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ wálé o! Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, ńṣe ló “kó gbogbo àpéjọ náà jọ lòdì sí [Mósè àti Áárónì] ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Jèhófà bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀ wàyí, pé: ‘Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò ní àárín àpéjọ yìí, kí èmi lè pa wọ́n run pátápátá ní ìṣẹ́jú akàn.’” Ṣùgbọ́n Mósè àti Áárónì bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà jọ̀wọ́ dá ẹ̀mí àwọn èèyàn kan sí. Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn. Ní ti Kórà àti ogunlọ́gọ̀ rẹ̀, “iná . . . jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin tí ń sun tùràrí run.”—Númérì 16:19-22, 35.c
14. Kí nìdí tí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi rí pupa ojú Jèhófà?
14 Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó rí ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà kò fèyí kọ́gbọ́n. “Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e gan-an, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì, pé: ‘Ẹ̀yin, ẹ ti fi ikú pa àwọn ènìyàn Jèhófà.’” Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún lọ ń gbè sẹ́yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀! Bí wọ́n ṣe tán Jèhófà ní sùúrù nìyẹn o. Kódà bí Mósè tàbí Áárónì tiẹ̀ bá àwọn èèyàn náà bẹ̀bẹ̀ báyìí, ẹ̀bẹ̀ ò ràn án mọ́. Jèhófà fi àrùn àrànkálẹ̀ kọlu àwọn aláìgbọràn náà, “àwọn tí ó sì kú nínú òjòjò àrànkálẹ̀ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin, yàtọ̀ sí àwọn tí ó ti kú ní tìtorí Kórà.”—Númérì 16:41-49.
15. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tọkàntọkàn gba Mósè àti Áárónì ní aṣáájú wọn? (b) Kí ni ẹ̀kọ́ tí ìtàn yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà?
15 Ikú àfọwọ́fà ló pa gbogbo àwọn aráabí yẹn. Ṣebí wọn ì bá ti rorí wọn dáadáa. Ṣebí wọn ì bá ti bi ara wọn ní àwọn ìbéèrè bíi: ‘Àwọn wo ló fẹ̀mí ara wọn wewu láti lọ fara hàn níwájú Fáráò? Àwọn wo ló lọ jà fún ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ta ni ẹnì kan ṣoṣo tá a pè lọ sórí Òkè Hórébù lẹ́yìn ìdáǹdè Ísírẹ́lì láti bá áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lójúkojú?’ Kò sírọ́ ńbẹ̀, Mósè àti Áárónì ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà, wọ́n fi ìdúróṣinṣin wọn hàn sí Jèhófà, wọ́n sì fi hàn pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn náà. (Ẹ́kísódù 10:28; 19:24; 24:12-15) Kì í ṣe pé inú Jèhófà dùn sí ikú àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n láwọn ò ní dẹ̀yìn lẹ́yìn ìwà ọ̀tẹ̀ ńkọ́, ìyẹn ló jẹ́ kó rẹ́yìn wọn. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n gidi ni gbogbo èyí jẹ́ fún wa lónìí. Èé ṣe?
Mímọ Ọ̀nà Náà Lónìí
16. (a) Kí ni ẹ̀rí tó yẹ kó mú un dá àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní lójú pé Jésù ni aṣojú Jèhófà? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi fi ẹgbẹ́ mìíràn rọ́pò ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì, ẹgbẹ́ wo ló sì fi rọ́pò rẹ̀?
16 Lónìí, “orílẹ̀-èdè” tuntun kan wà tí Jèhófà jẹ́ Onídàájọ́ rẹ̀ tí kò ṣeé fojú rí, tó jẹ́ pé Òun ló ń fún wọn lófin, tó sì tún jẹ́ Ọba wọn. (Mátíù 21:43) A dá “orílẹ̀-èdè” yẹn sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Nígbà yẹn, tẹ́ńpìlì ẹlẹ́wà kan, tí àwọn ọmọ Léfì ń sìn nínú rẹ̀, ti rọ́pò àgọ́ ìjọsìn ìgbà ayé Mósè. (Lúùkù 1:5, 8, 9) Ṣùgbọ́n, tẹ́ńpìlì mìíràn, tó jẹ́ tẹ̀mí wá sójú táyé lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, èyí tí Jésù Kristi jẹ́ Àlùfáà Àgbà rẹ̀. (Hébérù 9:9, 11) Ìgbà yẹn ni ọ̀ràn nípa ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tún dìde. Ta ni Jèhófà yóò lò láti darí “orílẹ̀-èdè” tuntun yìí? Jésù fi ìdúróṣinṣin hàn sí Ọlọ́run láìkù síbì kan. Ó fẹ́ràn àwọn èèyàn. Ó tún ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Léfì kọ Jésù. Ìṣe wọn ò yàtọ̀ sí tàwọn baba ńlá wọn ọlọ́rùn líle. (Mátíù 26:63-68; Ìṣe 4:5, 6, 18; 5:17) Níkẹyìn, Jèhófà fi ẹgbẹ́ àlùfáà tó yàtọ̀ pátápátá—ìyẹn ẹgbẹ́ àlùfáà aládé—rọ́pò ẹgbẹ́ àlùfáà ti àwọn ọmọ Léfì. Ẹgbẹ́ àlùfáà aládé yẹn ló wà títí di òní olónìí.
17. (a) Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà aládé lónìí? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo ẹgbẹ́ àlùfáà aládé náà?
17 Àwọn wo ni ẹgbẹ́ àlùfáà aládé yìí lónìí? Àpọ́sítélì Pétérù dáhùn ìbéèrè yẹn nínú lẹ́tà onímìísí tó kọ́kọ́ kọ. Pétérù kọ̀wé sáwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ara Kristi, pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.” (1 Pétérù 2:9) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn kedere pé, gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí ló para pọ̀ jẹ́ “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé,” tí Pétérù tún pè ní “orílẹ̀-èdè mímọ́.” Àwọn ló para pọ̀ jẹ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń lò láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni àti láti darí wọn nípa tẹ̀mí.—Mátíù 24:45-47.
18. Kí ni ìsopọ̀ tó wà láàárín àwọn alàgbà tá a yàn sípò àti ẹgbẹ́ àlùfáà aládé?
18 Àwọn tó ń ṣojú fún ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ni àwọn alàgbà tá a yàn sípò, tí wọ́n ní oríṣiríṣi ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ àwọn èèyàn Jèhófà kárí ayé. Ó yẹ ká máa bọlá fáwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ká sì máa tì wọ́n lẹ́yìn gbágbáágbá, yálà wọ́n jẹ́ ara ẹni àmì òróró tàbí wọn kì í ṣe ara wọn. Kí nìdí? Nítorí pé Jèhófà ló fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yan àwọn àgbà ọkùnrin wọ̀nyí sípò. (Hébérù 13:7, 17) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
19. Báwo ló ṣe jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn alàgbà sípò?
19 Àwọn àgbà ọkùnrin wọ̀nyí dé ojú ìlà ohun tá a là sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a kọ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9) Ìyẹn la fi lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló yàn wọ́n sípò. (Ìṣe 20:28) Àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà wọ̀nyí, gbọ́dọ̀ mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú. Gẹ́gẹ́ bíi ti Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ tó yàn wọ́n, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kórìíra ohunkóhun tó jẹ mọ́ ojúsàájú nínú ìdájọ́.—Diutarónómì 10:17, 18.
20. Kí ló wú ọ lórí nípa àwọn alàgbà tí ń ṣiṣẹ́ kára?
20 Dípò gbígbéjàko ọlá àṣẹ wọn, a mọyì àwọn alàgbà wa tí ń ṣiṣẹ́ kára gan-an ni! Iṣẹ́ ìsìn àtọkànwá tí wọ́n ti ń fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe bọ̀, ń jẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Wọ́n tún ń darí àwọn ìpàdé wọ̀nyí. Wọ́n ń bá wa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ nínú wíwàásù “ìhìn rere Ìjọba” náà. Wọ́n sì ń fún wa ní ìmọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́ nígbà tó bá yẹ. (Mátíù 24:14; Hébérù 10:23, 25; 1 Pétérù 5:2) Wọ́n ń bẹ̀ wá wò nígbà tára wa ò bá yá. Wọ́n sì ń tù wá nínú nígbà tá a bá ń ṣọ̀fọ̀. Wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin àti àìmọtara-ẹni-nìkan kọ́wọ́ ti ire Ìjọba náà. Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára wọn; wọ́n rí ojú rere rẹ̀.—Gálátíà 5:22, 23.
21. Kí ló yẹ káwọn alàgbà máa rántí, èé sì ti ṣe?
21 Àmọ́, aláìpé làwọn alàgbà o. Nítorí pé àwọn náà mọ èyí, wọn kì í fẹ́ jẹ gàba lórí agbo, tí í ṣe “ogún Ọlọ́run.” Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n ka ara wọn sí ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú àwọn arákùnrin wọn.’ (1 Pétérù 5:3; 2 Kọ́ríńtì 1:24) Àwọn alàgbà tó níwà ìrẹ̀lẹ̀, tó sì ń ṣiṣẹ́ kára fẹ́ràn Jèhófà. Wọ́n sì mọ̀ pé bí wọ́n bá ṣe túbọ̀ ń fara wé e, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò ṣe túbọ̀ máa ṣe ìjọ láǹfààní. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, wọ́n ń sapá nígbà gbogbo láti fara wé Ọlọ́run nípa níní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìyọ́nú àti sùúrù.
22. Báwo ni àtúnyẹ̀wò ìtàn Kórà ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú ètò Jèhófà tó ṣeé fojú rí túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀?
22 Inú wa mà dùn o, pé Jèhófà ni Alákòóso wa tí kò ṣeé fojú rí, pé Jésù Kristi ni Àlùfáà Àgbà wa, pé àwọn ẹni àmì òróró tí í ṣe ẹgbẹ́ àlùfáà aládé ni olùkọ́ wa, àti pé àwọn Kristẹni àgbà ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n ń gbà wá nímọ̀ràn! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò tí ẹ̀dá ènìyàn ń bójú tó kò lè ṣe kí ó má kù síbì kan, síbẹ̀ inú wa dùn pé à ń sin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, tí wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹrí ba fún ọlá àṣẹ Ọlọ́run!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Élíásárì àti Ítámárì, ìyẹn àwọn ọmọ Áárónì méjì yòókù jẹ́ àwòkọ́ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà.—Léfítíkù 10:6.
b Ọmọ Rúbẹ́nì ni Dátánì àti Ábírámù tó bá Kórà lẹ̀dí àpò pọ̀. Fún ìdí yìí, kò jọ pé ipò àlùfáà làwọn ń dù. Ní tiwọn, ohun tó ń bí wọn nínú ni jíjẹ́ tí Mósè jẹ́ aṣáájú lórí wọn, àti bó ṣe jẹ́ pé títí dìgbà yẹn, wọn ò tíì dé Ilẹ̀ Ìlérí tí wọ́n ń lọ.—Númérì 16:12-14.
c Láyé àwọn baba ńlá ìgbàanì, olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ń ṣojú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kódà wọ́n tilẹ̀ ń rú ẹbọ nítorí wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 8:20; 46:1; Jóòbù 1:5) Àmọ́, nígbà tí Jèhófà fún wọn ní Òfin, ó yan àwọn ọkùnrin nínú ìdílé Áárónì gẹ́gẹ́ bí àlùfáà kí wọ́n máa rúbọ fáwọn èèyàn náà. Ó jọ pé ńṣe làwọn àádọ́ta-lérúgba náà kò fara mọ́ ìlànà tuntun yìí.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?
• Ìpèsè onífẹ̀ẹ́ wo ni Jèhófà ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
• Kí nìdí tí kò fi sí àwíjàre fún ìwà ọ̀tẹ̀ tí Kórà hù sí Mósè àti Áárónì?
• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà lẹ́jọ́?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì àwọn ìṣètò Jèhófà lónìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ǹjẹ́ o máa ń fojú ribiribi wo iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá yàn fún ọ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn alàgbà tá a yàn sípò ń ṣojú fún ẹgbẹ́ àlùfáà aládé